Surah Al-Anam with Yoruba

  1. Surah mp3
  2. More
  3. Yoruba
The Holy Quran | Quran translation | Language Yoruba | Surah Anam | الأنعام - Ayat Count 165 - The number of the surah in moshaf: 6 - The meaning of the surah in English: The Cattle.

الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَجَعَلَ الظُّلُمَاتِ وَالنُّورَ ۖ ثُمَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ يَعْدِلُونَ(1)

 Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile. O tun da okunkun ati imole. Sibesibe awon t’o sai gbagbo n ba Oluwa won wa akegbe

هُوَ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن طِينٍ ثُمَّ قَضَىٰ أَجَلًا ۖ وَأَجَلٌ مُّسَمًّى عِندَهُ ۖ ثُمَّ أَنتُمْ تَمْتَرُونَ(2)

 Oun ni Eni ti O da yin lati inu erupe amo. Leyin naa, O fi gbedeke igba kan si (isemi aye yin). Ati pe gbedeke akoko kan (tun wa fun aye) lodo Re. Leyin naa, e tun n seyemeji

وَهُوَ اللَّهُ فِي السَّمَاوَاتِ وَفِي الْأَرْضِ ۖ يَعْلَمُ سِرَّكُمْ وَجَهْرَكُمْ وَيَعْلَمُ مَا تَكْسِبُونَ(3)

 Oun ni Allahu ninu awon sanmo ati ninu ile. O mo ikoko yin ati gbangba yin. O si mo ohun ti e n se nise

وَمَا تَأْتِيهِم مِّنْ آيَةٍ مِّنْ آيَاتِ رَبِّهِمْ إِلَّا كَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ(4)

 Ko si ami kan ti o maa de ba won ninu awon ami Oluwa won, afi ki won maa gbunri kuro nibe

فَقَدْ كَذَّبُوا بِالْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ ۖ فَسَوْفَ يَأْتِيهِمْ أَنبَاءُ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(5)

 Won kuku pe ododo niro nigba ti o de ba won. Nitori naa, laipe awon iro ohun ti won maa n fi se yeye n bo wa ba won

أَلَمْ يَرَوْا كَمْ أَهْلَكْنَا مِن قَبْلِهِم مِّن قَرْنٍ مَّكَّنَّاهُمْ فِي الْأَرْضِ مَا لَمْ نُمَكِّن لَّكُمْ وَأَرْسَلْنَا السَّمَاءَ عَلَيْهِم مِّدْرَارًا وَجَعَلْنَا الْأَنْهَارَ تَجْرِي مِن تَحْتِهِمْ فَأَهْلَكْنَاهُم بِذُنُوبِهِمْ وَأَنشَأْنَا مِن بَعْدِهِمْ قَرْنًا آخَرِينَ(6)

 Se won ko ri i pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won? Awon ti A fun ni ipo lori ile, (iru) ipo ti A ko fun eyin. A si ro omi ojo pupo fun won lati sanmo. A si se awon odo ti n san si isale (ile) won. Leyin naa, A pa won re nitori ese won. A si da awon iran miiran leyin won

وَلَوْ نَزَّلْنَا عَلَيْكَ كِتَابًا فِي قِرْطَاسٍ فَلَمَسُوهُ بِأَيْدِيهِمْ لَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّبِينٌ(7)

 Ti o ba je pe A so tira kan ti A ko sinu takada kale fun o, ki won si fi owo won gba a mu (bayii), dajudaju awon t’o sai gbagbo iba wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”

وَقَالُوا لَوْلَا أُنزِلَ عَلَيْهِ مَلَكٌ ۖ وَلَوْ أَنزَلْنَا مَلَكًا لَّقُضِيَ الْأَمْرُ ثُمَّ لَا يُنظَرُونَ(8)

 Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so molaika kan kale fun un?” Ti o ba je pe A so molaika kan kale, oro iba ti yanju. Leyin naa, A o si nii lo won lara mo

وَلَوْ جَعَلْنَاهُ مَلَكًا لَّجَعَلْنَاهُ رَجُلًا وَلَلَبَسْنَا عَلَيْهِم مَّا يَلْبِسُونَ(9)

 Ti o ba je pe A se e ni molaika ni, Awa iba se e ni okunrin. Ati pe Awa iba tun fi ohun ti won n daru mora won loju ru won loju

وَلَقَدِ اسْتُهْزِئَ بِرُسُلٍ مِّن قَبْلِكَ فَحَاقَ بِالَّذِينَ سَخِرُوا مِنْهُم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ(10)

 Won kuku ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re! Nitori naa, ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi awon t’o n fi won se yeye po

قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ ثُمَّ انظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ(11)

 So pe: “E rin ori ile lo, leyin naa ki e wo bawo ni atubotan awon t’o n pe ododo niro se ri.”

قُل لِّمَن مَّا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ قُل لِّلَّهِ ۚ كَتَبَ عَلَىٰ نَفْسِهِ الرَّحْمَةَ ۚ لَيَجْمَعَنَّكُمْ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ لَا رَيْبَ فِيهِ ۚ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ(12)

 So pe: “Ti ta ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile?” So pe: “Ti Allahu ni.” O se aanu ni oran-anyan lera Re lori. Dajudaju O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ko si iyemeji ninu re. Awon t’o se emi won lofo (sinu aigbagbo), won ko nii gbagbo

۞ وَلَهُ مَا سَكَنَ فِي اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(13)

 TiRe ni ohunkohun t’o n be ninu oru ati osan. Oun si ni Olugbo, Onimo

قُلْ أَغَيْرَ اللَّهِ أَتَّخِذُ وَلِيًّا فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَهُوَ يُطْعِمُ وَلَا يُطْعَمُ ۗ قُلْ إِنِّي أُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ أَوَّلَ مَنْ أَسْلَمَ ۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُشْرِكِينَ(14)

 So pe: “Se ki ng mu oluranlowo kan yato si Allahu, Eledaa awon sanmo ati ile? Oun si ni O n bo (eda), won ki i bo O.” So pe: “Dajudaju Won pa mi lase pe ki ng je eni akoko ti o maa se ’Islam (ni asiko temi).” Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo. ofin Re ati ilana Re. Eyi ni awon kan mo si “sise ife-Olohun”. Ewo ninu awon Anabi Olohun ati Ojise Re ni ko juwo-juse sile patapata fun ase Allahu ofin Re ati ilana Re? Ewo ninu won se ni ko se ife-Olohun? Ko si. Idi niyi ti gbogbo won fi je musulumi gege bi Allahu (subhanahu wa ta’ala) se fi rinle ninu surah al-Baƙorah; 2:128-141. ofin Re ati ilana Re. Amo ninu ijo re oun ni eni akoko ti o koko se bee

قُلْ إِنِّي أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّي عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ(15)

 So pe: “Dajudaju emi n paya iya Ojo Nla, ti mo ba fi le yapa Oluwa mi.”

مَّن يُصْرَفْ عَنْهُ يَوْمَئِذٍ فَقَدْ رَحِمَهُ ۚ وَذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْمُبِينُ(16)

 Enikeni ti A ba dari re kuro nibi (iya) ni Ojo yen, (Allahu) ti saanu re. Iyen si ni erenje ponnbele

وَإِن يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ ۖ وَإِن يَمْسَسْكَ بِخَيْرٍ فَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(17)

 Ti Allahu ba fi inira kan kan o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun naa. Ti O ba si mu oore kan ba o, Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

وَهُوَ الْقَاهِرُ فَوْقَ عِبَادِهِ ۚ وَهُوَ الْحَكِيمُ الْخَبِيرُ(18)

 Oun si ni Olubori t’O wa loke awon eru Re. Oun ni Ologbon, Onimo-ikoko

قُلْ أَيُّ شَيْءٍ أَكْبَرُ شَهَادَةً ۖ قُلِ اللَّهُ ۖ شَهِيدٌ بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۚ وَأُوحِيَ إِلَيَّ هَٰذَا الْقُرْآنُ لِأُنذِرَكُم بِهِ وَمَن بَلَغَ ۚ أَئِنَّكُمْ لَتَشْهَدُونَ أَنَّ مَعَ اللَّهِ آلِهَةً أُخْرَىٰ ۚ قُل لَّا أَشْهَدُ ۚ قُلْ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ وَإِنَّنِي بَرِيءٌ مِّمَّا تُشْرِكُونَ(19)

 So pe: “Ki ni ohun ti o tobi julo ni eri?” So pe: “Allahu ni Elerii laaarin emi ati eyin.” O si fi imisi al-Ƙur’an yii ranse si mi, nitori ki ng le fi se ikilo fun eyin ati enikeni ti (al-Ƙur’an) ba de eti igbo re. Se dajudaju eyin n jerii pe awon olohun miiran tun wa pelu Allahu ni? So pe: “Emi ko nii jerii bee.” So pe: “Oun nikan ni Olohun Okan soso ti ijosin to si. Ati pe dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo (si Allahu).”

الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يَعْرِفُونَهُ كَمَا يَعْرِفُونَ أَبْنَاءَهُمُ ۘ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ(20)

 Awon ti A fun ni Tira, won mo on gege bi won se mo awon omo won. Awon t’o se emi won lofo (sinu aigbagbo), won ko si nii gbagbo

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِآيَاتِهِ ۗ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ(21)

 Ta l’o si sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi (eni ti) o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon alabosi ko nii jere

وَيَوْمَ نَحْشُرُهُمْ جَمِيعًا ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشْرَكُوا أَيْنَ شُرَكَاؤُكُمُ الَّذِينَ كُنتُمْ تَزْعُمُونَ(22)

 Ati pe (ranti) Ojo ti A oo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa A oo so fun awon t’o ba (Allahu) wa akegbe pe: “Nibo ni awon orisa yin wa, awon ti e n so nipa won lai ni eri lowo pe won je akegbe Allahu?”

ثُمَّ لَمْ تَكُن فِتْنَتُهُمْ إِلَّا أَن قَالُوا وَاللَّهِ رَبِّنَا مَا كُنَّا مُشْرِكِينَ(23)

 Leyin naa, ifooro won (lori ibeere naa) ko je kini kan tayo pe won a wi pe: “A fi Allahu, Oluwa wa bura, awa ki i se osebo.”

انظُرْ كَيْفَ كَذَبُوا عَلَىٰ أَنفُسِهِمْ ۚ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ(24)

 Wo bi won se paro mora won. Ohun ti won n da ni adapa iro si dofo mo won lowo

وَمِنْهُم مَّن يَسْتَمِعُ إِلَيْكَ ۖ وَجَعَلْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ أَكِنَّةً أَن يَفْقَهُوهُ وَفِي آذَانِهِمْ وَقْرًا ۚ وَإِن يَرَوْا كُلَّ آيَةٍ لَّا يُؤْمِنُوا بِهَا ۚ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوكَ يُجَادِلُونَكَ يَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ(25)

 Eni ti n gbo oro ni odo re n be ninu won. A si fi ebibo bo okan won ki won ma baa gbo agboye re. (A tun fi) edidi sinu eti won. Ti won ba ri gbogbo ami, won ko nii gba a gbo debi pe nigba ti won ba wa ba o, won yo si maa ba o jiyan; awon t’o sai gbagbo si maa wi pe: “Ki ni eyi bi ko se akosile alo awon eni akoko.”

وَهُمْ يَنْهَوْنَ عَنْهُ وَيَنْأَوْنَ عَنْهُ ۖ وَإِن يُهْلِكُونَ إِلَّا أَنفُسَهُمْ وَمَا يَشْعُرُونَ(26)

 Awon ni won n ko (fun awon eniyan lati tele Anabi s.a.w.), awon naa si n takete si i. Won ko si ko iparun ba enikeni bi ko se emi ara won; won ko si fura

وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ وُقِفُوا عَلَى النَّارِ فَقَالُوا يَا لَيْتَنَا نُرَدُّ وَلَا نُكَذِّبَ بِآيَاتِ رَبِّنَا وَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ(27)

 Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti A ba da won duro sibi Ina, won si maa wi pe: “Yee! Ki won si da wa pada (sile aye), awa ko si nii pe awon ayah Oluwa wa niro (mo), a si maa wa ninu awon onigbagbo ododo.”

بَلْ بَدَا لَهُم مَّا كَانُوا يُخْفُونَ مِن قَبْلُ ۖ وَلَوْ رُدُّوا لَعَادُوا لِمَا نُهُوا عَنْهُ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ(28)

 Ko ri bee, ohun ti won n fi pamo siwaju ti han si won ni. Ti o ba je pe A ba da won pada (sile aye), won yoo kuku pada sibi ohun ti A ko fun won. Dajudaju opuro ma ni won

وَقَالُوا إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ(29)

 Won wi pe: "Ki ni (o tun je isemi orun) bi ko se isemi wa nile aye; Won ko si nii gbe wa dide (ni orun)

وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ وُقِفُوا عَلَىٰ رَبِّهِمْ ۚ قَالَ أَلَيْسَ هَٰذَا بِالْحَقِّ ۚ قَالُوا بَلَىٰ وَرَبِّنَا ۚ قَالَ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ(30)

 Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti won ba da won duro si odo Oluwa won, O si maa so pe: “Se eyi ki i se ododo bi?” Won a si wi pe: “Rara (ododo ni), Oluwa wa.” (Allahu) so pe: “Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e maa n sai gbagbo.”

قَدْ خَسِرَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِلِقَاءِ اللَّهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءَتْهُمُ السَّاعَةُ بَغْتَةً قَالُوا يَا حَسْرَتَنَا عَلَىٰ مَا فَرَّطْنَا فِيهَا وَهُمْ يَحْمِلُونَ أَوْزَارَهُمْ عَلَىٰ ظُهُورِهِمْ ۚ أَلَا سَاءَ مَا يَزِرُونَ(31)

 Dajudaju awon t’o pe pipade Allahu (lorun) niro ti sofo debi pe nigba ti Akoko naa ba de ba won lojiji, won a wi pe: “A ka abamo lori ohun ti a fi jafira.” Won si maa ru ese won seyin won. Kiye si i, ohun ti won yoo ru lese si buru

وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا لَعِبٌ وَلَهْوٌ ۖ وَلَلدَّارُ الْآخِرَةُ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ يَتَّقُونَ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(32)

 Isemi aye ko si je kini kan bi ko se ere ati iranu. Ogba Ikeyin si loore julo fun awon t’o n beru (Allahu). Se e o se laakaye ni

قَدْ نَعْلَمُ إِنَّهُ لَيَحْزُنُكَ الَّذِي يَقُولُونَ ۖ فَإِنَّهُمْ لَا يُكَذِّبُونَكَ وَلَٰكِنَّ الظَّالِمِينَ بِآيَاتِ اللَّهِ يَجْحَدُونَ(33)

 A kuku ti mo pe ohun ti won n wi yoo ba o ninu je. Dajudaju won ko le pe o ni opuro, sugbon awon alabosi n tako awon ayah Allahu ni

وَلَقَدْ كُذِّبَتْ رُسُلٌ مِّن قَبْلِكَ فَصَبَرُوا عَلَىٰ مَا كُذِّبُوا وَأُوذُوا حَتَّىٰ أَتَاهُمْ نَصْرُنَا ۚ وَلَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَاتِ اللَّهِ ۚ وَلَقَدْ جَاءَكَ مِن نَّبَإِ الْمُرْسَلِينَ(34)

 Won kuku ti pe awon Ojise kan lopuro siwaju re. Won si se suuru lori nnkan ti won fi pe won ni opuro. Won si fi inira kan won titi di igba ti aranse Wa fi de ba won. Ko si si alayiipada kan fun awon oro Allahu. Dajudaju iro awon Ojise ti de ba o

وَإِن كَانَ كَبُرَ عَلَيْكَ إِعْرَاضُهُمْ فَإِنِ اسْتَطَعْتَ أَن تَبْتَغِيَ نَفَقًا فِي الْأَرْضِ أَوْ سُلَّمًا فِي السَّمَاءِ فَتَأْتِيَهُم بِآيَةٍ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَجَمَعَهُمْ عَلَى الْهُدَىٰ ۚ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْجَاهِلِينَ(35)

 Ti o ba si je pe gbigbunri won lagbara lara re, nigba naa ti o ba lagbara lati wa iho kan sinu (aja) ile, tabi akaba kan sinu sanmo (se bee) ki o le mu ami kan wa fun won. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, dajudaju iba ko won jo sinu imona (’Islam). Nitori naa, o o gbodo wa lara awon alaimokan

۞ إِنَّمَا يَسْتَجِيبُ الَّذِينَ يَسْمَعُونَ ۘ وَالْمَوْتَىٰ يَبْعَثُهُمُ اللَّهُ ثُمَّ إِلَيْهِ يُرْجَعُونَ(36)

 Awon t’o n gboro ni awon t’o n jepe. Awon oku, Allahu yo si gbe won dide. Leyin naa, odo Re ni won yoo da won pada si

وَقَالُوا لَوْلَا نُزِّلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِّن رَّبِّهِ ۚ قُلْ إِنَّ اللَّهَ قَادِرٌ عَلَىٰ أَن يُنَزِّلَ آيَةً وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ(37)

 Won tun wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Dajudaju Allahu lagbara lati so ami kan kale, sugbon opolopo won ni ko mo.”

وَمَا مِن دَابَّةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا طَائِرٍ يَطِيرُ بِجَنَاحَيْهِ إِلَّا أُمَمٌ أَمْثَالُكُم ۚ مَّا فَرَّطْنَا فِي الْكِتَابِ مِن شَيْءٍ ۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِمْ يُحْشَرُونَ(38)

 Ko si ohun abemi kan (t’o n rin) lori ile, tabi eye kan t’o n fo pelu apa re mejeeji bi ko se awon eda kan (bi) iru yin. A ko fi kini kan sile (lai sakosile re) sinu Tira (iyen, ummul-kitab). Leyin naa, odo Oluwa won ni won yoo ko won jo si

وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا صُمٌّ وَبُكْمٌ فِي الظُّلُمَاتِ ۗ مَن يَشَإِ اللَّهُ يُضْلِلْهُ وَمَن يَشَأْ يَجْعَلْهُ عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(39)

 Awon t’o pe awon ayah Wa niro, aditi ati ayaya t’o wa ninu awon okunkun ni won. Enikeni ti Allahu ba fe, O maa si i lona. Enikeni ti O ba si fe, O maa fi soju ona taara (’Islam)

قُلْ أَرَأَيْتَكُمْ إِنْ أَتَاكُمْ عَذَابُ اللَّهِ أَوْ أَتَتْكُمُ السَّاعَةُ أَغَيْرَ اللَّهِ تَدْعُونَ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(40)

 So pe: "E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin tabi ti Akoko naa ba de ba yin, se nnkan miiran leyin Allahu ni eyin maa pe, ti e ba je olododo

بَلْ إِيَّاهُ تَدْعُونَ فَيَكْشِفُ مَا تَدْعُونَ إِلَيْهِ إِن شَاءَ وَتَنسَوْنَ مَا تُشْرِكُونَ(41)

 Rara, Oun (nikan) l’e n pe. O si maa mu (inira) ti e n pe E si kuro (fun yin), ti O ba fe. Eyin yo si gbagbe ohun ti e n fi sebo si I

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا إِلَىٰ أُمَمٍ مِّن قَبْلِكَ فَأَخَذْنَاهُم بِالْبَأْسَاءِ وَالضَّرَّاءِ لَعَلَّهُمْ يَتَضَرَّعُونَ(42)

 Dajudaju A ti ranse si awon ijo kan siwaju re. A si fi iponju ati ailera gba won mu nitori ki won le rawo rase (si Allahu)

فَلَوْلَا إِذْ جَاءَهُم بَأْسُنَا تَضَرَّعُوا وَلَٰكِن قَسَتْ قُلُوبُهُمْ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(43)

 Won ko se rawo rase (si Wa) nigba ti iya Wa de ba won! Sugbon okan won ti le koko. Esu si se ohun ti won n se nise ni oso fun won

فَلَمَّا نَسُوا مَا ذُكِّرُوا بِهِ فَتَحْنَا عَلَيْهِمْ أَبْوَابَ كُلِّ شَيْءٍ حَتَّىٰ إِذَا فَرِحُوا بِمَا أُوتُوا أَخَذْنَاهُم بَغْتَةً فَإِذَا هُم مُّبْلِسُونَ(44)

 Nitori naa, nigba ti won gbagbe ohun ti A fi se iranti fun won, A si awon ona gbogbo nnkan sile fun won, titi di igba ti won yo ayoporo si ohun ti A fun won (ninu oore aye.), A si mu won lojiji. Won si di olusoretinu

فَقُطِعَ دَابِرُ الْقَوْمِ الَّذِينَ ظَلَمُوا ۚ وَالْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ(45)

 Nitori naa, A pa ijo t’o sabosi run patapata. Gbogbo ope si n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَخَذَ اللَّهُ سَمْعَكُمْ وَأَبْصَارَكُمْ وَخَتَمَ عَلَىٰ قُلُوبِكُم مَّنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُم بِهِ ۗ انظُرْ كَيْفَ نُصَرِّفُ الْآيَاتِ ثُمَّ هُمْ يَصْدِفُونَ(46)

 So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba gba igboro yin ati iriran yin, ti O si di okan yin pa, olohun wo leyin Allahu ni o maa mu un wa fun yin? Wo bi A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona. Leyin naa, won si n gbunri

قُلْ أَرَأَيْتَكُمْ إِنْ أَتَاكُمْ عَذَابُ اللَّهِ بَغْتَةً أَوْ جَهْرَةً هَلْ يُهْلَكُ إِلَّا الْقَوْمُ الظَّالِمُونَ(47)

 So pe: “E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin ni ojiji tabi ni ojukoju, se won maa pa eni kan run bi ko se ijo alabosi!”

وَمَا نُرْسِلُ الْمُرْسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ ۖ فَمَنْ آمَنَ وَأَصْلَحَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(48)

 A ko ran awon Ojise naa nise bi ko se pe (ki won je) oniroo idunnu ati olukilo. Nitori naa, enikeni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se atunse (ise re), ko nii si iberu fun won, won ko si nii banuje

وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا يَمَسُّهُمُ الْعَذَابُ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ(49)

 Awon t’o si pe awon ayah Wa niro, owo iya yoo te won nitori pe won maa n sebaje

قُل لَّا أَقُولُ لَكُمْ عِندِي خَزَائِنُ اللَّهِ وَلَا أَعْلَمُ الْغَيْبَ وَلَا أَقُولُ لَكُمْ إِنِّي مَلَكٌ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ ۚ قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ ۚ أَفَلَا تَتَفَكَّرُونَ(50)

 So pe: “Emi ko so fun yin pe awon ile-owo Allahu wa lodo mi, emi ko si nimo ikoko. Emi ko si so fun yin pe molaika kan ni mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi.” So pe: "Nje afoju ati oluriran dogba bi? Se e o ronu jinle ni

وَأَنذِرْ بِهِ الَّذِينَ يَخَافُونَ أَن يُحْشَرُوا إِلَىٰ رَبِّهِمْ ۙ لَيْسَ لَهُم مِّن دُونِهِ وَلِيٌّ وَلَا شَفِيعٌ لَّعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ(51)

 Fi (al-Ƙur’an) se ikilo fun awon t’o n paya pe Won maa ko awon jo si odo Oluwa won, ko si nii si alaabo tabi olusipe kan fun won leyin Re. (Kilo fun won) ki won le beru (Allahu)

وَلَا تَطْرُدِ الَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُم بِالْغَدَاةِ وَالْعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُ ۖ مَا عَلَيْكَ مِنْ حِسَابِهِم مِّن شَيْءٍ وَمَا مِنْ حِسَابِكَ عَلَيْهِم مِّن شَيْءٍ فَتَطْرُدَهُمْ فَتَكُونَ مِنَ الظَّالِمِينَ(52)

 Ma se le awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale danu; won n fe Oju rere Re ni. Isiro-ise won ko si ni orun re ni ona kan kan. Ko si si isiro-ise tire naa ni orun won ni ona kan kan. Ti o ba le won danu, o si maa wa ninu awon alabosi

وَكَذَٰلِكَ فَتَنَّا بَعْضَهُم بِبَعْضٍ لِّيَقُولُوا أَهَٰؤُلَاءِ مَنَّ اللَّهُ عَلَيْهِم مِّن بَيْنِنَا ۗ أَلَيْسَ اللَّهُ بِأَعْلَمَ بِالشَّاكِرِينَ(53)

 Bayen ni A se fi apa kan won se adanwo fun apa kan nitori ki (awon alaigbagbo) le wi pe: “Se awon (musulumi alaini) wonyi naa ni Allahu se idera (imona) fun laaarin wa!?” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa awon oludupe ni

وَإِذَا جَاءَكَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِآيَاتِنَا فَقُلْ سَلَامٌ عَلَيْكُمْ ۖ كَتَبَ رَبُّكُمْ عَلَىٰ نَفْسِهِ الرَّحْمَةَ ۖ أَنَّهُ مَنْ عَمِلَ مِنكُمْ سُوءًا بِجَهَالَةٍ ثُمَّ تَابَ مِن بَعْدِهِ وَأَصْلَحَ فَأَنَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(54)

 Nigba ti awon t’o gba awon ayah Wa gbo ba wa ba o, so (fun won) pe: "Ki alaafia maa ba yin. Oluwa yin se aanu ni oran-anyan lera Re lori pe, dajudaju enikeni ninu yin ti o ba se ise aburu pelu aimokan, leyin naa, ti o ronu piwada leyin re, ti o si se atunse, dajudaju Oun ni Alaforijin, Asake-orun

وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ وَلِتَسْتَبِينَ سَبِيلُ الْمُجْرِمِينَ(55)

 Bayen ni A se n salaye awon ayah nitori ki ona awon elese le foju han kedere

قُلْ إِنِّي نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ ۚ قُل لَّا أَتَّبِعُ أَهْوَاءَكُمْ ۙ قَدْ ضَلَلْتُ إِذًا وَمَا أَنَا مِنَ الْمُهْتَدِينَ(56)

 So pe: “Dajudaju Won ko fun mi lati josin fun awon ti e n pe leyin Allahu.” So pe: “Emi ko nii tele ife-inu yin. Bi bee ko nigba naa, mo ti sina (ti mo ba tele ife-inu yin). Emi ko si si ninu awon olumona.”

قُلْ إِنِّي عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّي وَكَذَّبْتُم بِهِ ۚ مَا عِندِي مَا تَسْتَعْجِلُونَ بِهِ ۚ إِنِ الْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۖ يَقُصُّ الْحَقَّ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الْفَاصِلِينَ(57)

 So pe: “Dajudaju mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, eyin si pe e niro. Ko si ohun ti e n wa pelu ikanju ni odo mi. Ko si idajo naa (fun enikeni) ayafi fun Allahu, Eni ti n so (idajo) ododo. O si loore julo ninu awon oludajo.”

قُل لَّوْ أَنَّ عِندِي مَا تَسْتَعْجِلُونَ بِهِ لَقُضِيَ الْأَمْرُ بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۗ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِالظَّالِمِينَ(58)

 So pe: “Ti o ba je pe dajudaju ohun ti e n wa pelu ikanju n be ni odo mi ni, Won iba ti se idajo oro naa laaarin emi ati eyin. Allahu si nimo julo nipa awon alabosi.”

۞ وَعِندَهُ مَفَاتِحُ الْغَيْبِ لَا يَعْلَمُهَا إِلَّا هُوَ ۚ وَيَعْلَمُ مَا فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ ۚ وَمَا تَسْقُطُ مِن وَرَقَةٍ إِلَّا يَعْلَمُهَا وَلَا حَبَّةٍ فِي ظُلُمَاتِ الْأَرْضِ وَلَا رَطْبٍ وَلَا يَابِسٍ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ(59)

 Odo Re si ni awon kokoro ikoko wa. Ko si eni t’o nimo re afi Oun. O nimo ohun ti n be ninu ile ati odo. Ewe kan ko si nii ja bo afi ki O nimo re. Ko si si koro eso kan ninu okunkun (inu) ile, ko si ohun tutu tabi gbigbe kan afi ki o wa ninu akosile t’o yanju

وَهُوَ الَّذِي يَتَوَفَّاكُم بِاللَّيْلِ وَيَعْلَمُ مَا جَرَحْتُم بِالنَّهَارِ ثُمَّ يَبْعَثُكُمْ فِيهِ لِيُقْضَىٰ أَجَلٌ مُّسَمًّى ۖ ثُمَّ إِلَيْهِ مَرْجِعُكُمْ ثُمَّ يُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ(60)

 Oun ni Eni t’O n kun yin ni oorun ni ale. O si nimo nipa ohun ti e se nise ni osan. Leyin naa, O n gbe yin dide (fun ije-imu) ni (osan) nitori ki won le pari gbedeke akoko kan. Leyin naa, odo Re ni ibupadasi yin. Leyin naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

وَهُوَ الْقَاهِرُ فَوْقَ عِبَادِهِ ۖ وَيُرْسِلُ عَلَيْكُمْ حَفَظَةً حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ تَوَفَّتْهُ رُسُلُنَا وَهُمْ لَا يُفَرِّطُونَ(61)

 Oun ni Olubori t’O wa loke awon eru Re. O si n ran awon eso kan si yin titi di igba ti iku yoo fi de ba eni kookan yin. Awon Ojise wa yo si gba emi re, won ko si nii jafira

ثُمَّ رُدُّوا إِلَى اللَّهِ مَوْلَاهُمُ الْحَقِّ ۚ أَلَا لَهُ الْحُكْمُ وَهُوَ أَسْرَعُ الْحَاسِبِينَ(62)

 Leyin naa, won yoo da won pada si odo Allahu, Oluwa won, Ododo. Kiye si i, tiRe ni idajo. Oun si yara julo ninu awon olusiro

قُلْ مَن يُنَجِّيكُم مِّن ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ تَدْعُونَهُ تَضَرُّعًا وَخُفْيَةً لَّئِنْ أَنجَانَا مِنْ هَٰذِهِ لَنَكُونَنَّ مِنَ الشَّاكِرِينَ(63)

 So pe: “Ta ni eni t’o n gba yin la ninu okunkun ile ati ibudo, Eni ti e n pe pelu iraworase ati ni ikoko pe: "Dajudaju ti O ba gba wa la ninu eyi, dajudaju awa yoo wa ninu awon oludupe (fun Un)

قُلِ اللَّهُ يُنَجِّيكُم مِّنْهَا وَمِن كُلِّ كَرْبٍ ثُمَّ أَنتُمْ تُشْرِكُونَ(64)

 So pe: “Allahu l’O n gba yin la ninu re ati ninu gbogbo ibanuje. Leyin naa, e tun n sebo.”

قُلْ هُوَ الْقَادِرُ عَلَىٰ أَن يَبْعَثَ عَلَيْكُمْ عَذَابًا مِّن فَوْقِكُمْ أَوْ مِن تَحْتِ أَرْجُلِكُمْ أَوْ يَلْبِسَكُمْ شِيَعًا وَيُذِيقَ بَعْضَكُم بَأْسَ بَعْضٍ ۗ انظُرْ كَيْفَ نُصَرِّفُ الْآيَاتِ لَعَلَّهُمْ يَفْقَهُونَ(65)

 So pe: “O lagbara lati fi iya ranse si yin lati oke yin tabi lati isale ese yin, tabi ki O da yin po mo oniruuru ijo, nitori ki O le mu apa kan yin finira kan apa kan. Wo bi A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona nitori ki won le gbo agboye.”

وَكَذَّبَ بِهِ قَوْمُكَ وَهُوَ الْحَقُّ ۚ قُل لَّسْتُ عَلَيْكُم بِوَكِيلٍ(66)

 Awon eniyan re pe al-Ƙur’an niro! (Amo) ododo ni. So pe: “Emi ki i se oluso lori yin.”

لِّكُلِّ نَبَإٍ مُّسْتَقَرٌّ ۚ وَسَوْفَ تَعْلَمُونَ(67)

 Gbogbo asotele l’o ni akoko (isele). Laipe e maa mo

وَإِذَا رَأَيْتَ الَّذِينَ يَخُوضُونَ فِي آيَاتِنَا فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ حَتَّىٰ يَخُوضُوا فِي حَدِيثٍ غَيْرِهِ ۚ وَإِمَّا يُنسِيَنَّكَ الشَّيْطَانُ فَلَا تَقْعُدْ بَعْدَ الذِّكْرَىٰ مَعَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ(68)

 Nigba ti o ba ri awon t’o n so isokuso nipa awon ayah Wa, nigba naa seri kuro ni odo won titi won yoo fi bo sinu oro miiran. Ti Esu ba n mu o gbagbe (tele), ni bayii leyin iranti ma se jokoo ti ijo alabosi

وَمَا عَلَى الَّذِينَ يَتَّقُونَ مِنْ حِسَابِهِم مِّن شَيْءٍ وَلَٰكِن ذِكْرَىٰ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ(69)

 Kini kan ninu isiro-ise won ko si lorun awon t’o n beru (Allahu), sugbon isiti ni nitori ki won le sora (fun Ina)

وَذَرِ الَّذِينَ اتَّخَذُوا دِينَهُمْ لَعِبًا وَلَهْوًا وَغَرَّتْهُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا ۚ وَذَكِّرْ بِهِ أَن تُبْسَلَ نَفْسٌ بِمَا كَسَبَتْ لَيْسَ لَهَا مِن دُونِ اللَّهِ وَلِيٌّ وَلَا شَفِيعٌ وَإِن تَعْدِلْ كُلَّ عَدْلٍ لَّا يُؤْخَذْ مِنْهَا ۗ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ أُبْسِلُوا بِمَا كَسَبُوا ۖ لَهُمْ شَرَابٌ مِّنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ(70)

 Pa awon t’o so esin won di ere sise ati iranu ti. Isemi aye si tan won je. Fi (al-Ƙur’an) se isiti nitori ki won ma baa fa emi kale sinu iparun nipase ohun ti o se nise (aburu). Ko si si alaabo tabi olusipe kan fun un leyin Allahu. Ti o ba si fi gbogbo aaro serapada, A o nii gba a lowo re. Awon wonyen ni awon ti won fa kale fun iparun nipase ohun ti won se nise. Ohun mimu gbigbona ati iya eleta elero n be fun won nitori pe won maa n sai gbagbo

قُلْ أَنَدْعُو مِن دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنفَعُنَا وَلَا يَضُرُّنَا وَنُرَدُّ عَلَىٰ أَعْقَابِنَا بَعْدَ إِذْ هَدَانَا اللَّهُ كَالَّذِي اسْتَهْوَتْهُ الشَّيَاطِينُ فِي الْأَرْضِ حَيْرَانَ لَهُ أَصْحَابٌ يَدْعُونَهُ إِلَى الْهُدَى ائْتِنَا ۗ قُلْ إِنَّ هُدَى اللَّهِ هُوَ الْهُدَىٰ ۖ وَأُمِرْنَا لِنُسْلِمَ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ(71)

 So pe: “Se a oo maa pe leyin Allahu, ohun ti ko le se wa ni anfaani, ti ko si le ko inira ba wa; (se) ki won tun da wa pada si ese-aaro wa leyin igba ti Allahu ti fi ona mo wa (ki a le da) bi eni ti Esu mu tele ife-inu re lori ile aye, ti idaamu de ba? O (si) ni awon ore kan ti won n pe e sibi imona (pe), “Maa bo ni odo wa.” So pe: “Dajudaju imona ti Allahu (’Islam), ohun ni imona. Won si pa wa lase pe ki a gba esin ’Islam nitori ti Oluwa gbogbo eda.”

وَأَنْ أَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَاتَّقُوهُ ۚ وَهُوَ الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(72)

 Ati pe ki e kirun, ki e si beru Allahu. Oun ni Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re

وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۖ وَيَوْمَ يَقُولُ كُن فَيَكُونُ ۚ قَوْلُهُ الْحَقُّ ۚ وَلَهُ الْمُلْكُ يَوْمَ يُنفَخُ فِي الصُّورِ ۚ عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ ۚ وَهُوَ الْحَكِيمُ الْخَبِيرُ(73)

 Oun si ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Ati pe (ranti) ojo ti (Allahu maa yi ile ati sanmo pada si nnkan miiran), O si maa so pe: "Je bee." O si maa je bee. Ododo ni oro Re. TiRe si ni ijoba ni ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Onimo-ikoko ati gbangba ni. Oun si ni Ologbon, Alamotan

۞ وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ لِأَبِيهِ آزَرَ أَتَتَّخِذُ أَصْنَامًا آلِهَةً ۖ إِنِّي أَرَاكَ وَقَوْمَكَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ(74)

 (Ranti) nigba ti ’Ibrohim so fun baba re, Azar, (pe): “Se o maa so awon ere orisa di olohun ni? Dajudaju emi ri iwo ati awon eniyan re ninu isina ponnbele.”

وَكَذَٰلِكَ نُرِي إِبْرَاهِيمَ مَلَكُوتَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلِيَكُونَ مِنَ الْمُوقِنِينَ(75)

 Bayen ni won se fi (awon ami) ijoba Allahu ti n be ninu awon sanmo ati ile han (Anabi) ’Ibrohim nitori ki o le wa ninu awon alamodaju

فَلَمَّا جَنَّ عَلَيْهِ اللَّيْلُ رَأَىٰ كَوْكَبًا ۖ قَالَ هَٰذَا رَبِّي ۖ فَلَمَّا أَفَلَ قَالَ لَا أُحِبُّ الْآفِلِينَ(76)

 Nigba ti okunkun ale bo o mole, o ri irawo kan, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Emi ko nifee si awon (oluwa) t’o n wookun.”

فَلَمَّا رَأَى الْقَمَرَ بَازِغًا قَالَ هَٰذَا رَبِّي ۖ فَلَمَّا أَفَلَ قَالَ لَئِن لَّمْ يَهْدِنِي رَبِّي لَأَكُونَنَّ مِنَ الْقَوْمِ الضَّالِّينَ(77)

 Nigba ti o ri osupa t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Dajudaju ti Oluwa mi ko ba to mi sona, dajudaju mo maa wa ninu awon olusina eniyan.”

فَلَمَّا رَأَى الشَّمْسَ بَازِغَةً قَالَ هَٰذَا رَبِّي هَٰذَا أَكْبَرُ ۖ فَلَمَّا أَفَلَتْ قَالَ يَا قَوْمِ إِنِّي بَرِيءٌ مِّمَّا تُشْرِكُونَ(78)

 Nigba ti o ri oorun t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi; eyi tobi julo.” Nigba t’o wo, o so pe: “Eyin eniyan mi, dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo (si Allahu)

إِنِّي وَجَّهْتُ وَجْهِيَ لِلَّذِي فَطَرَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ حَنِيفًا ۖ وَمَا أَنَا مِنَ الْمُشْرِكِينَ(79)

 Dajudaju emi doju mi ko Eni ti O pile iseda awon sanmo ati ile, (mo) duro deede (sinu ’Islam fun Un). Emi ko si si ninu awon osebo.”

وَحَاجَّهُ قَوْمُهُ ۚ قَالَ أَتُحَاجُّونِّي فِي اللَّهِ وَقَدْ هَدَانِ ۚ وَلَا أَخَافُ مَا تُشْرِكُونَ بِهِ إِلَّا أَن يَشَاءَ رَبِّي شَيْئًا ۗ وَسِعَ رَبِّي كُلَّ شَيْءٍ عِلْمًا ۗ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ(80)

 Awon eniyan re si ja a niyan. O so pe: "Se eyin yoo ja mi niyan nipa Allahu, O si ti fi ona mo mi? Emi ko si paya (awon orisa) ti e so di akegbe fun Un, afi bi Allahu ba fe kini kan (pe ko sele). Oluwa mi fi imo gbooro ju gbogbo nnkan. Nitori naa, se e o nii lo iranti ni

وَكَيْفَ أَخَافُ مَا أَشْرَكْتُمْ وَلَا تَخَافُونَ أَنَّكُمْ أَشْرَكْتُم بِاللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ عَلَيْكُمْ سُلْطَانًا ۚ فَأَيُّ الْفَرِيقَيْنِ أَحَقُّ بِالْأَمْنِ ۖ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ(81)

 Bawo ni emi yoo se paya (awon orisa) ti e so di akegbe fun Allahu, ti eyin ko si paya pe e n ba Allahu wa akegbe pelu ohun ti ko so eri kan kale fun yin lori re? Ewo ninu iko mejeeji l’o letoo julo si ifokanbale ti e ba nimo

الَّذِينَ آمَنُوا وَلَمْ يَلْبِسُوا إِيمَانَهُم بِظُلْمٍ أُولَٰئِكَ لَهُمُ الْأَمْنُ وَهُم مُّهْتَدُونَ(82)

 Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won ko si da igbagbo won po mo abosi (iborisa), awon wonyen ni ifokanbale n be fun. Awon si ni olumona

وَتِلْكَ حُجَّتُنَا آتَيْنَاهَا إِبْرَاهِيمَ عَلَىٰ قَوْمِهِ ۚ نَرْفَعُ دَرَجَاتٍ مَّن نَّشَاءُ ۗ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٌ(83)

 Iyen ni awijare Wa ti A fun (Anabi) ’Ibrohim lori awon eniyan re. A n se agbega ipo fun eni ti A ba fe. Dajudaju Oluwa re ni Ologbon, Onimo

وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ ۚ كُلًّا هَدَيْنَا ۚ وَنُوحًا هَدَيْنَا مِن قَبْلُ ۖ وَمِن ذُرِّيَّتِهِ دَاوُودَ وَسُلَيْمَانَ وَأَيُّوبَ وَيُوسُفَ وَمُوسَىٰ وَهَارُونَ ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(84)

 Ati pe A ta a lore (Anabi) ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (ti o je omo ’Ishaƙ). Ikookan won ni A fi mona. A si fi (Anabi) Nuh mona siwaju. Ati pe ninu aromodomo (Anabi ’Ibrohim ti A fi mona ni awon Anabi) Dawud, Sulaemon, ’Ayyub, Yusuf, Musa ati Harun. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

وَزَكَرِيَّا وَيَحْيَىٰ وَعِيسَىٰ وَإِلْيَاسَ ۖ كُلٌّ مِّنَ الصَّالِحِينَ(85)

 Ati (Anabi) Zakariyya, Yahya, ‘Isa ati ’Ilyas; gbogbo won wa ninu awon eni rere

وَإِسْمَاعِيلَ وَالْيَسَعَ وَيُونُسَ وَلُوطًا ۚ وَكُلًّا فَضَّلْنَا عَلَى الْعَالَمِينَ(86)

 Ati ’Ismo‘il, al-Yasa‘, Yunus ati Lut; ikookan won ni A soore ajulo fun lori awon eda (asiko won)

وَمِنْ آبَائِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ وَإِخْوَانِهِمْ ۖ وَاجْتَبَيْنَاهُمْ وَهَدَيْنَاهُمْ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(87)

 Ati pe ninu awon baba won, aromodomo won ati awon arakunrin won, A sa won lesa. A si fi won mona taara (’Islam)

ذَٰلِكَ هُدَى اللَّهِ يَهْدِي بِهِ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۚ وَلَوْ أَشْرَكُوا لَحَبِطَ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ(88)

 Iyen ni imona Allahu. O si n fi to eni ti O ba fe si ona ninu awon eru Re. Ti won ba fi le sebo ni, dajudaju ohun ti won n se nise (rere) iba baje mo won lowo

أُولَٰئِكَ الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ وَالْحُكْمَ وَالنُّبُوَّةَ ۚ فَإِن يَكْفُرْ بِهَا هَٰؤُلَاءِ فَقَدْ وَكَّلْنَا بِهَا قَوْمًا لَّيْسُوا بِهَا بِكَافِرِينَ(89)

 Awon wonyen ni awon ti A fun ni Tira, ijinle oye (iyen, sunnah) ati (ipo) Anabi. Nitori naa, ti awon wonyi ba sai gbagbo ninu re, dajudaju A ti gbe e le awon eniyan kan lowo, ti won ko nii sai gbagbo ninu re

أُولَٰئِكَ الَّذِينَ هَدَى اللَّهُ ۖ فَبِهُدَاهُمُ اقْتَدِهْ ۗ قُل لَّا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ أَجْرًا ۖ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْعَالَمِينَ(90)

 Awon wonyen ni awon ti Allahu to si ona. Nitori naa, ona won ni ki o tele. So pe: “Emi ko bi yin ni owo-oya kan lori re. Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda.”

وَمَا قَدَرُوا اللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِ إِذْ قَالُوا مَا أَنزَلَ اللَّهُ عَلَىٰ بَشَرٍ مِّن شَيْءٍ ۗ قُلْ مَنْ أَنزَلَ الْكِتَابَ الَّذِي جَاءَ بِهِ مُوسَىٰ نُورًا وَهُدًى لِّلنَّاسِ ۖ تَجْعَلُونَهُ قَرَاطِيسَ تُبْدُونَهَا وَتُخْفُونَ كَثِيرًا ۖ وَعُلِّمْتُم مَّا لَمْ تَعْلَمُوا أَنتُمْ وَلَا آبَاؤُكُمْ ۖ قُلِ اللَّهُ ۖ ثُمَّ ذَرْهُمْ فِي خَوْضِهِمْ يَلْعَبُونَ(91)

 Won ko fun Allahu ni iyi ti o to si I, nigba ti won wi pe: “Allahu ko so nnkan kan kale fun abara kan.” So pe: "Ta ni O so tira ti (Anabi) Musa mu wa kale, (eyi t’o je) imole ati imona fun awon eniyan, eyi ti e sakosile re sinu iwe ajako, ti e n se afihan re, ti e si n fi opolopo re pamo, A si fi ohun ti e o mo mo yin, eyin ati awon baba yin?" So pe: "Allahu ni." Leyin naa, fi won sile sinu isokuso won, ki won maa sere

وَهَٰذَا كِتَابٌ أَنزَلْنَاهُ مُبَارَكٌ مُّصَدِّقُ الَّذِي بَيْنَ يَدَيْهِ وَلِتُنذِرَ أُمَّ الْقُرَىٰ وَمَنْ حَوْلَهَا ۚ وَالَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَهُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ(92)

 Eyi (al-Ƙur’an) tun ni Tira ibukun ti A sokale; o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ati pe nitori ki o le se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku). Awon t’o gbagbo ninu Ojo Ikeyin, won gbagbo ninu re. Awon si ni won n so irun won

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ قَالَ أُوحِيَ إِلَيَّ وَلَمْ يُوحَ إِلَيْهِ شَيْءٌ وَمَن قَالَ سَأُنزِلُ مِثْلَ مَا أَنزَلَ اللَّهُ ۗ وَلَوْ تَرَىٰ إِذِ الظَّالِمُونَ فِي غَمَرَاتِ الْمَوْتِ وَالْمَلَائِكَةُ بَاسِطُو أَيْدِيهِمْ أَخْرِجُوا أَنفُسَكُمُ ۖ الْيَوْمَ تُجْزَوْنَ عَذَابَ الْهُونِ بِمَا كُنتُمْ تَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ غَيْرَ الْحَقِّ وَكُنتُمْ عَنْ آيَاتِهِ تَسْتَكْبِرُونَ(93)

 Ta l’o sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi eni ti o wi pe won fi imisi ranse si mi - A o si fi kini kan ranse si i - ati eni ti o wi pe "Emi naa yoo so iru ohun ti Allahu sokale kale."? Ti o ba je pe iwo ri i nigba ti awon alabosi ba wa ninu ipokaka iku, ti awon molaika nawo won (si won pe) “E mu emi yin jade wa. Lonii ni Won yoo san yin ni esan abuku iya nitori ohun ti e maa n so nipa Allahu ni aito. E si maa n se igberaga si awon ayah Re.”

وَلَقَدْ جِئْتُمُونَا فُرَادَىٰ كَمَا خَلَقْنَاكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَتَرَكْتُم مَّا خَوَّلْنَاكُمْ وَرَاءَ ظُهُورِكُمْ ۖ وَمَا نَرَىٰ مَعَكُمْ شُفَعَاءَكُمُ الَّذِينَ زَعَمْتُمْ أَنَّهُمْ فِيكُمْ شُرَكَاءُ ۚ لَقَد تَّقَطَّعَ بَيْنَكُمْ وَضَلَّ عَنكُم مَّا كُنتُمْ تَزْعُمُونَ(94)

 Dajudaju e ti wa ba wa ni ikookan gege bi A se seda yin nigba akoko. E si ti fi ohun ti A fun yin sile si eyin yin. A o ma ri awon olusipe yin pelu yin, awon ti e so lai ni eri pe dajudaju laaarin yin awon ni akegbe (fun Allahu). Dajudaju asepo aarin yin ti ja patapata. Ati pe ohun ti e n so nipa won (lai ni eri lowo lori isipe yin) ti dofo mo yin lowo

۞ إِنَّ اللَّهَ فَالِقُ الْحَبِّ وَالنَّوَىٰ ۖ يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَمُخْرِجُ الْمَيِّتِ مِنَ الْحَيِّ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ(95)

 Dajudaju Allahu l’O n mu koro eso irugbin ati koro eso dabinu hu jade. O n mu alaaye jade lati ara oku. O si n mu oku jade lati ara alaaye. Iyen ni Allahu. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo

فَالِقُ الْإِصْبَاحِ وَجَعَلَ اللَّيْلَ سَكَنًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ حُسْبَانًا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ(96)

 O n mu ojumo mo. O se oru ni isinmi. (O n mu) oorun ati osupa (rin) fun isiro (ojo aye). Iyen ni eto Alagbara, Onimo

وَهُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ النُّجُومَ لِتَهْتَدُوا بِهَا فِي ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ(97)

 Oun ni Eni ti O fi awon irawo se (imole) fun yin ki e le fi riran ninu okunkun ile ati ibudo. A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o nimo

وَهُوَ الَّذِي أَنشَأَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ فَمُسْتَقَرٌّ وَمُسْتَوْدَعٌ ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَفْقَهُونَ(98)

 Oun ni Eni ti O seda yin lati ara emi eyo kan. Nitori naa, ibugbe (nile aye) ati ibupadasi (ni orun wa fun yin). A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o ni agboye

وَهُوَ الَّذِي أَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجْنَا بِهِ نَبَاتَ كُلِّ شَيْءٍ فَأَخْرَجْنَا مِنْهُ خَضِرًا نُّخْرِجُ مِنْهُ حَبًّا مُّتَرَاكِبًا وَمِنَ النَّخْلِ مِن طَلْعِهَا قِنْوَانٌ دَانِيَةٌ وَجَنَّاتٍ مِّنْ أَعْنَابٍ وَالزَّيْتُونَ وَالرُّمَّانَ مُشْتَبِهًا وَغَيْرَ مُتَشَابِهٍ ۗ انظُرُوا إِلَىٰ ثَمَرِهِ إِذَا أَثْمَرَ وَيَنْعِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكُمْ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ(99)

 Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. A fi mu gbogbo nnkan ogbin jade. A tun mu eweko t’o n dan logbologbo jade lati inu re. A tun n mu siri eso jade ninu re. (A si n mu jade) lati ara igi dabinu, lati ara eso akoyo re, eso t’o sujo mora won t’o ro dede wale. (A n se) awon ogba oko eso ajara, eso zaetun ati eso rummon (ni awon eso t’o) jora ati (awon eyi ti) ko jora. E wo eso re nigba ti o ba so ati (nigba ti o ba) pon. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo

وَجَعَلُوا لِلَّهِ شُرَكَاءَ الْجِنَّ وَخَلَقَهُمْ ۖ وَخَرَقُوا لَهُ بَنِينَ وَبَنَاتٍ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يَصِفُونَ(100)

 Won si fi awon alujannu se akegbe fun Allahu. Oun si l’O sedaa won! Won tun paro mo On (pe) O bi omokunrin ati omobinrin, lai nimo kan (nipa Re). Mimo ni fun Un. O si ga tayo ohun ti won n fi royin (Re)

بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ أَنَّىٰ يَكُونُ لَهُ وَلَدٌ وَلَمْ تَكُن لَّهُ صَاحِبَةٌ ۖ وَخَلَقَ كُلَّ شَيْءٍ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(101)

 Olupileda awon sanmo ati ile ni. Bawo ni O se ni omo nigba ti ko ni aya. O da gbogbo nnkan. Oun si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ فَاعْبُدُوهُ ۚ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ(102)

 Iyen ni Allahu, Oluwa yin; ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Eledaa gbogbo nnkan. Nitori naa, e josin fun Un. Oun si ni Oluso lori gbogbo nnkan

لَّا تُدْرِكُهُ الْأَبْصَارُ وَهُوَ يُدْرِكُ الْأَبْصَارَ ۖ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ(103)

 Awon oju (eda) ko le ka Allahu. Oun si ka awon oju. Oun si ni Alaaanu, Alamotan

قَدْ جَاءَكُم بَصَائِرُ مِن رَّبِّكُمْ ۖ فَمَنْ أَبْصَرَ فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ عَمِيَ فَعَلَيْهَا ۚ وَمَا أَنَا عَلَيْكُم بِحَفِيظٍ(104)

 Awon eri t’o daju kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, enikeni t’o ba riran, fun emi ara re ni. Enikeni t’o ba si foju, fun emi ara re ni. Emi ki i se oluso lori yin

وَكَذَٰلِكَ نُصَرِّفُ الْآيَاتِ وَلِيَقُولُوا دَرَسْتَ وَلِنُبَيِّنَهُ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ(105)

 Bayen ni A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona nitori ki won le wi pe: "O kekoo (re lodo awon eniyan ni." Dipo ki won wi pe: "Won so o kale fun o ni." ati nitori ki A le se alaye re fun awon eniyan t’o nimo)

اتَّبِعْ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ وَأَعْرِضْ عَنِ الْمُشْرِكِينَ(106)

 Tele ohun ti won fi ran o ni imisi lati odo Oluwa re. Ko si eni ti ijosin to si afi Oun. Ki o si seri kuro ni odo awon osebo

وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا أَشْرَكُوا ۗ وَمَا جَعَلْنَاكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا ۖ وَمَا أَنتَ عَلَيْهِم بِوَكِيلٍ(107)

 Ti o ba je pe Allahu ba fe (imona fun won), won iba ti sebo. A o si fi o se oluso lori won. Ati pe iwo ko ni alamojuuto won

وَلَا تَسُبُّوا الَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ فَيَسُبُّوا اللَّهَ عَدْوًا بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ كَذَٰلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِم مَّرْجِعُهُمْ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(108)

 E ma se bu awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu, ki awon (aborisa) ma baa bu Allahu ni ti abosi ati ainimo. Bayen ni A ti se ise ijo kookan ni oso fun won. Leyin naa, odo Oluwa won ni ibupadasi won. Nitori naa, O maa fun won ni iro ohun ti won maa n se nise

وَأَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ لَئِن جَاءَتْهُمْ آيَةٌ لَّيُؤْمِنُنَّ بِهَا ۚ قُلْ إِنَّمَا الْآيَاتُ عِندَ اللَّهِ ۖ وَمَا يُشْعِرُكُمْ أَنَّهَا إِذَا جَاءَتْ لَا يُؤْمِنُونَ(109)

 Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe, dajudaju ti ami (iyanu) kan ba de ba awon, awon gbodo gba a gbo. So pe: "Odo Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa." Ki si ni o maa mu yin fura mo pe dajudaju nigba ti o ba de (ba won) won maa gba a gbo

وَنُقَلِّبُ أَفْئِدَتَهُمْ وَأَبْصَارَهُمْ كَمَا لَمْ يُؤْمِنُوا بِهِ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَنَذَرُهُمْ فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ(110)

 A maa yi okan won ati oju won sodi ni; (won ko nii gba a gbo) gege bi won ko se gbagbo ninu (eyi t’o siwaju ninu awon ami iyanu) nigba akoko. A o si fi won sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida

۞ وَلَوْ أَنَّنَا نَزَّلْنَا إِلَيْهِمُ الْمَلَائِكَةَ وَكَلَّمَهُمُ الْمَوْتَىٰ وَحَشَرْنَا عَلَيْهِمْ كُلَّ شَيْءٍ قُبُلًا مَّا كَانُوا لِيُؤْمِنُوا إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ يَجْهَلُونَ(111)

 Dajudaju ti A ba so awon molaika kale fun won, ti awon oku n ba won soro, ti A tun ko gbogbo nnkan jo siwaju won, won ko nii gbagbo afi ti Allahu ba fe. Sugbon opolopo won ni alaimokan

وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَا لِكُلِّ نَبِيٍّ عَدُوًّا شَيَاطِينَ الْإِنسِ وَالْجِنِّ يُوحِي بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ زُخْرُفَ الْقَوْلِ غُرُورًا ۚ وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ مَا فَعَلُوهُ ۖ فَذَرْهُمْ وَمَا يَفْتَرُونَ(112)

 Bayen ni A ti se awon esu eniyan ati esu alujannu ni ota fun Anabi kookan; apa kan won n fi odu iro ranse si apa kan ni ti etan. Ti o ba je pe Oluwa re ba fe (lati to won sona ni) won iba ti se bee. Nitori naa, fi won sile tohun ti adapa iro ti won n da

وَلِتَصْغَىٰ إِلَيْهِ أَفْئِدَةُ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ وَلِيَرْضَوْهُ وَلِيَقْتَرِفُوا مَا هُم مُّقْتَرِفُونَ(113)

 Ki awon okan ti won ko gba Ojo Ikeyin gbo maa teti beleje si (odu iro Esu), ki won maa yonu si i, ki won si maa da ohun ti won n da lese n so

أَفَغَيْرَ اللَّهِ أَبْتَغِي حَكَمًا وَهُوَ الَّذِي أَنزَلَ إِلَيْكُمُ الْكِتَابَ مُفَصَّلًا ۚ وَالَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يَعْلَمُونَ أَنَّهُ مُنَزَّلٌ مِّن رَّبِّكَ بِالْحَقِّ ۖ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُمْتَرِينَ(114)

 Se nnkan miiran ni ki ng wa ni oludajo leyin Allahu ni? Oun si ni Eni ti O so Tira kale fun yin ti won fi salaye idajo. Awon ti A si fun ni tira mo pe, dajudaju won so o kale pelu ododo lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji

وَتَمَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ صِدْقًا وَعَدْلًا ۚ لَّا مُبَدِّلَ لِكَلِمَاتِهِ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(115)

 Oro Oluwa re pe ni ododo ati ni deede. Ko si alayiipada kan fun awon oro Re. Oun si ni Olugbo, Onimo

وَإِن تُطِعْ أَكْثَرَ مَن فِي الْأَرْضِ يُضِلُّوكَ عَن سَبِيلِ اللَّهِ ۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ(116)

 Ti o ba tele opolopo awon ti n be lori ile, won maa si o lona kuro loju ona (esin) Allahu. Won ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni won (n se) bi ko se pe won n paro

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ مَن يَضِلُّ عَن سَبِيلِهِ ۖ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ(117)

 Dajudaju Oluwa re, Oun l’O nimo julo nipa eni t’o sina loju ona (esin) Re. Ati pe, Oun si l’O nimo julo nipa awon olumona

فَكُلُوا مِمَّا ذُكِرَ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ إِن كُنتُم بِآيَاتِهِ مُؤْمِنِينَ(118)

 Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba fi oruko Allahu pa, ti e ba gbagbo ninu awon ayah Re

وَمَا لَكُمْ أَلَّا تَأْكُلُوا مِمَّا ذُكِرَ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ وَقَدْ فَصَّلَ لَكُم مَّا حَرَّمَ عَلَيْكُمْ إِلَّا مَا اضْطُرِرْتُمْ إِلَيْهِ ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا لَّيُضِلُّونَ بِأَهْوَائِهِم بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِالْمُعْتَدِينَ(119)

 Ki ni o maa ko fun yin lati je ninu ohun ti won fi oruko Allahu pa! O kuku ti salaye fun yin ohun ti O se ni eewo fun yin ayafi eyi ti inira (ebi) ba ti yin debe. Dajudaju opolopo ni won n fi ife-inu won pelu ainimo (won) si awon eniyan lona. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa awon olutayo enu-ala

وَذَرُوا ظَاهِرَ الْإِثْمِ وَبَاطِنَهُ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَكْسِبُونَ الْإِثْمَ سَيُجْزَوْنَ بِمَا كَانُوا يَقْتَرِفُونَ(120)

 E fi eyi t’o han ninu ese ati eyi t’o pamo ninu re sile. Dajudaju awon t’o n se ise ese, A oo san won ni esan ohun ti won n da lese

وَلَا تَأْكُلُوا مِمَّا لَمْ يُذْكَرِ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ وَإِنَّهُ لَفِسْقٌ ۗ وَإِنَّ الشَّيَاطِينَ لَيُوحُونَ إِلَىٰ أَوْلِيَائِهِمْ لِيُجَادِلُوكُمْ ۖ وَإِنْ أَطَعْتُمُوهُمْ إِنَّكُمْ لَمُشْرِكُونَ(121)

 Eyin ko si gbodo je ninu ohun ti won ko fi oruko Allahu pa. Dajudaju ibaje ni. Ati pe dajudaju awon esu, won yoo maa fi irande odu iro ranse si awon eni won, nitori ki won le tako yin. Ti e ba fi le tele won, dajudaju e ti di osebo

أَوَمَن كَانَ مَيْتًا فَأَحْيَيْنَاهُ وَجَعَلْنَا لَهُ نُورًا يَمْشِي بِهِ فِي النَّاسِ كَمَن مَّثَلُهُ فِي الظُّلُمَاتِ لَيْسَ بِخَارِجٍ مِّنْهَا ۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلْكَافِرِينَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(122)

 Nje eni ti (afiwe re) je oku (iyen, alaigbagbo), ti A so di alaaye (nipa pe o gba ’Islam), ti A si fun un ni imole (iyen, imo esin), ti o si n lo o laaarin awon eniyan, (nje) o da bi eni ti afiwe tire je (eni ti) n be ninu awon okunkun (aigbagbo), ti ko si jade kuro ninu re? Bayen ni won ti se ni oso fun awon alaigbagbo ohun ti won n se nise

وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَا فِي كُلِّ قَرْيَةٍ أَكَابِرَ مُجْرِمِيهَا لِيَمْكُرُوا فِيهَا ۖ وَمَا يَمْكُرُونَ إِلَّا بِأَنفُسِهِمْ وَمَا يَشْعُرُونَ(123)

 Bayen ni A se so awon agba kan di odaran ilu ninu ilu kookan, nitori ki won le maa dete nibe. Won ko si dete si enikeni bi ko se si ara won, won ko si fura

وَإِذَا جَاءَتْهُمْ آيَةٌ قَالُوا لَن نُّؤْمِنَ حَتَّىٰ نُؤْتَىٰ مِثْلَ مَا أُوتِيَ رُسُلُ اللَّهِ ۘ اللَّهُ أَعْلَمُ حَيْثُ يَجْعَلُ رِسَالَتَهُ ۗ سَيُصِيبُ الَّذِينَ أَجْرَمُوا صَغَارٌ عِندَ اللَّهِ وَعَذَابٌ شَدِيدٌ بِمَا كَانُوا يَمْكُرُونَ(124)

 Nigba ti ayah kan ba si de ba won, won a wi pe: “Awa ko nii gba a gbo titi di igba ti won ba to fun awa naa ni iru ohun ti won fun awon Ojise Allahu.” Allahu nimo julo nipa ibi ti O n fi ise-riran Re si. Laipe iyepere ati iya lile lati odo Allahu yoo de ba awon t’o dese nitori ohun ti won n da lete

فَمَن يُرِدِ اللَّهُ أَن يَهْدِيَهُ يَشْرَحْ صَدْرَهُ لِلْإِسْلَامِ ۖ وَمَن يُرِدْ أَن يُضِلَّهُ يَجْعَلْ صَدْرَهُ ضَيِّقًا حَرَجًا كَأَنَّمَا يَصَّعَّدُ فِي السَّمَاءِ ۚ كَذَٰلِكَ يَجْعَلُ اللَّهُ الرِّجْسَ عَلَى الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ(125)

 Enikeni ti Allahu ba fe fona mo, O maa si igba-aya re paya fun ’Islam. Enikeni ti O ba si fe si lona, O maa fun igba-aya re pa gadigadi bi eni pe o n gunke lo sinu sanmo. Bayen ni Allahu se de wahala asan si awon ti ko gbagbo

وَهَٰذَا صِرَاطُ رَبِّكَ مُسْتَقِيمًا ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَذَّكَّرُونَ(126)

 Eyi ni oju ona Oluwa re (t’o je) ona taara. A kuku ti salaye awon ayah fun ijo t’o n lo iranti

۞ لَهُمْ دَارُ السَّلَامِ عِندَ رَبِّهِمْ ۖ وَهُوَ وَلِيُّهُم بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ(127)

 Ile alaafia n be fun won ni odo Oluwa won. Oun si ni Alatileyin won nipa ohun ti won n se nise

وَيَوْمَ يَحْشُرُهُمْ جَمِيعًا يَا مَعْشَرَ الْجِنِّ قَدِ اسْتَكْثَرْتُم مِّنَ الْإِنسِ ۖ وَقَالَ أَوْلِيَاؤُهُم مِّنَ الْإِنسِ رَبَّنَا اسْتَمْتَعَ بَعْضُنَا بِبَعْضٍ وَبَلَغْنَا أَجَلَنَا الَّذِي أَجَّلْتَ لَنَا ۚ قَالَ النَّارُ مَثْوَاكُمْ خَالِدِينَ فِيهَا إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ ۗ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٌ(128)

 (Ranti) Ojo ti (Allahu) yoo ko gbogbo won jo patapata, (O maa so pe): “Eyin awujo alujannu, dajudaju e ti ko opolopo eniyan sonu.” Awon ore won ninu awon eniyan yoo wi pe: “Oluwa wa, apa kan wa gbadun apa kan ni. A si ti lo asiko wa ti O bu fun wa (lati lo).” (Allahu) so pe: “Ina ni ibugbe yin; olusegbere ni yin ninu re afi ohun ti Allahu ba fe . Dajudaju Oluwa re ni Ologbon, Onimo

وَكَذَٰلِكَ نُوَلِّي بَعْضَ الظَّالِمِينَ بَعْضًا بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ(129)

 Bayen ni A se fi apa kan awon alabosi sore apa kan (won) nitori ohun ti won n se nise

يَا مَعْشَرَ الْجِنِّ وَالْإِنسِ أَلَمْ يَأْتِكُمْ رُسُلٌ مِّنكُمْ يَقُصُّونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِي وَيُنذِرُونَكُمْ لِقَاءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا ۚ قَالُوا شَهِدْنَا عَلَىٰ أَنفُسِنَا ۖ وَغَرَّتْهُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا وَشَهِدُوا عَلَىٰ أَنفُسِهِمْ أَنَّهُمْ كَانُوا كَافِرِينَ(130)

 Eyin awujo alujannu ati eniyan, se awon Ojise kan laaarin yin ko wa ba yin, ti won n ke awon ayah Mi fun yin, ti won si n fi ipade yin Oni yii sekilo fun yin? Won wi pe: “A jerii lera wa lori (pe won wa).” Isemi aye tan won je. Won si jerii lera won lori pe dajudaju awon je alaigbagbo

ذَٰلِكَ أَن لَّمْ يَكُن رَّبُّكَ مُهْلِكَ الْقُرَىٰ بِظُلْمٍ وَأَهْلُهَا غَافِلُونَ(131)

 Iyen nitori pe Oluwa re ko nii pa awon ilu run nipase abosi (owo won), lasiko ti awon ara ilu naa je alaimo (titi Ojise yoo fi de ba won)

وَلِكُلٍّ دَرَجَاتٌ مِّمَّا عَمِلُوا ۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَافِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ(132)

 Awon ipo (ike ati ipo iya) n be fun enikookan nipase ohun ti won ba se nise. Oluwa re ki i se onigbagbe nipa nnkan ti won n se nise

وَرَبُّكَ الْغَنِيُّ ذُو الرَّحْمَةِ ۚ إِن يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَسْتَخْلِفْ مِن بَعْدِكُم مَّا يَشَاءُ كَمَا أَنشَأَكُم مِّن ذُرِّيَّةِ قَوْمٍ آخَرِينَ(133)

 Oluwa re ni Oloro, Alaaanu. Ti O ba fe, O maa ko yin kuro (lori ile). O si maa fi ohun ti O ba fe ropo (yin) leyin (iparun) yin gege bi O ti se mu yin jade leyin (iparun) aromodomo awon ijo miiran

إِنَّ مَا تُوعَدُونَ لَآتٍ ۖ وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ(134)

 Dajudaju ohun ti A n se ni adehun fun yin, o kuku n bo wa sele; eyin ko si nii mori bo

قُلْ يَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ مَن تَكُونُ لَهُ عَاقِبَةُ الدَّارِ ۗ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ(135)

 So pe: “Eyin eniyan mi, e duro sori ona yin, dajudaju emi naa yoo duro (sori ona mi), laipe e maa mo eni ti Ogba (Idera) yoo je ikangun tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”

وَجَعَلُوا لِلَّهِ مِمَّا ذَرَأَ مِنَ الْحَرْثِ وَالْأَنْعَامِ نَصِيبًا فَقَالُوا هَٰذَا لِلَّهِ بِزَعْمِهِمْ وَهَٰذَا لِشُرَكَائِنَا ۖ فَمَا كَانَ لِشُرَكَائِهِمْ فَلَا يَصِلُ إِلَى اللَّهِ ۖ وَمَا كَانَ لِلَّهِ فَهُوَ يَصِلُ إِلَىٰ شُرَكَائِهِمْ ۗ سَاءَ مَا يَحْكُمُونَ(136)

 Won si fi ipin kan fun Allahu ninu ohun ti O da ninu nnkan oko ati eran-osin; won wi pe: "Eyi ni ti Allahu – pelu oro won lai ni eri lowo, - eyi si ni ti awon orisa wa." Nitori naa, ohun ti o ba je ti awon orisa ko nii dapo mo ti Allahu. Ohun ti o ba si je ti Allahu, o n dapo mo ti awon orisa won; ohun ti won n da lejo buru

وَكَذَٰلِكَ زَيَّنَ لِكَثِيرٍ مِّنَ الْمُشْرِكِينَ قَتْلَ أَوْلَادِهِمْ شُرَكَاؤُهُمْ لِيُرْدُوهُمْ وَلِيَلْبِسُوا عَلَيْهِمْ دِينَهُمْ ۖ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا فَعَلُوهُ ۖ فَذَرْهُمْ وَمَا يَفْتَرُونَ(137)

 Bayen ni awon orisa won se pipa awon omo won ni oso fun opolopo ninu awon osebo nitori ki won le pa won run ati nitori ki won le d’oju esin won ru mo won lowo. Ti o ba je pe Allahu ba fe, won iba ti se (bee). Nitori naa, fi won sile tohun ti ohun ti won n da ni adapa iro

وَقَالُوا هَٰذِهِ أَنْعَامٌ وَحَرْثٌ حِجْرٌ لَّا يَطْعَمُهَا إِلَّا مَن نَّشَاءُ بِزَعْمِهِمْ وَأَنْعَامٌ حُرِّمَتْ ظُهُورُهَا وَأَنْعَامٌ لَّا يَذْكُرُونَ اسْمَ اللَّهِ عَلَيْهَا افْتِرَاءً عَلَيْهِ ۚ سَيَجْزِيهِم بِمَا كَانُوا يَفْتَرُونَ(138)

 Won tun wi pe: "Eewo ni awon eran-osin ati nnkan oko wonyi. Eni kan ko gbodo je e afi eni ti a ba fe, pelu oro won lai ni eri lowo." - Awon eran-osin kan tun n be ti won se eyin won ni eewo (fun gigun ati eru riru), awon eran kan tun n be ti won ki i fi oruko Allahu pa. (Won fi awon nnkan wonyi) da adapa iro mo Allahu ni. O si maa san won ni esan ohun ti won n da ni adapa iro

وَقَالُوا مَا فِي بُطُونِ هَٰذِهِ الْأَنْعَامِ خَالِصَةٌ لِّذُكُورِنَا وَمُحَرَّمٌ عَلَىٰ أَزْوَاجِنَا ۖ وَإِن يَكُن مَّيْتَةً فَهُمْ فِيهِ شُرَكَاءُ ۚ سَيَجْزِيهِمْ وَصْفَهُمْ ۚ إِنَّهُ حَكِيمٌ عَلِيمٌ(139)

 Won tun wi pe: "Ohun ti n be ninu ikun awon eran-osin wonyi je ti awon okunrin wa nikan soso, o si je eewo fun awon obinrin wa." Ti o ba si je oku omo-eran, akegbe si ni won ninu (ipin) re. (Allahu) yoo san won ni esan iro (enu) won. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo

قَدْ خَسِرَ الَّذِينَ قَتَلُوا أَوْلَادَهُمْ سَفَهًا بِغَيْرِ عِلْمٍ وَحَرَّمُوا مَا رَزَقَهُمُ اللَّهُ افْتِرَاءً عَلَى اللَّهِ ۚ قَدْ ضَلُّوا وَمَا كَانُوا مُهْتَدِينَ(140)

 Awon t’o fi ago ati aimo pa awon omo won kuku ti sofo; won tun se ohun ti Allahu pa lese fun won ni eewo, ni ti dida adapa iro mo Allahu. Won kuku ti sina, won ko si je olumona

۞ وَهُوَ الَّذِي أَنشَأَ جَنَّاتٍ مَّعْرُوشَاتٍ وَغَيْرَ مَعْرُوشَاتٍ وَالنَّخْلَ وَالزَّرْعَ مُخْتَلِفًا أُكُلُهُ وَالزَّيْتُونَ وَالرُّمَّانَ مُتَشَابِهًا وَغَيْرَ مُتَشَابِهٍ ۚ كُلُوا مِن ثَمَرِهِ إِذَا أَثْمَرَ وَآتُوا حَقَّهُ يَوْمَ حَصَادِهِ ۖ وَلَا تُسْرِفُوا ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ(141)

 (Allahu) Oun ni Eni ti O seda awon nnkan ogba oko eyi ti e n fowo ara yin gbin ati eyi t’o n lale hu ati dabinu ati irugbin ti (adun) jije re yato sira won, ati eso zaetun ati eso rummon t’o jora won ati eyi ti ko jora won. E je ninu eso re nigba ti o ba so, ki e si yo Zakah re ni ojo ikore re. Ki e si ma yapa. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon apa

وَمِنَ الْأَنْعَامِ حَمُولَةً وَفَرْشًا ۚ كُلُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ وَلَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ(142)

 O si n be ninu awon eran-osin, eyi t’o le ru eru ati eyi ti ko le ru eru. E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin. Ki e si ma se tele awon oju-ese Esu; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

ثَمَانِيَةَ أَزْوَاجٍ ۖ مِّنَ الضَّأْنِ اثْنَيْنِ وَمِنَ الْمَعْزِ اثْنَيْنِ ۗ قُلْ آلذَّكَرَيْنِ حَرَّمَ أَمِ الْأُنثَيَيْنِ أَمَّا اشْتَمَلَتْ عَلَيْهِ أَرْحَامُ الْأُنثَيَيْنِ ۖ نَبِّئُونِي بِعِلْمٍ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(143)

 (Allahu da eran) mejo ni tako-tabo; meji ninu agutan (tako-tabo), meji ninu ewure (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. E fun mi ni iro pelu imo ti e ba je olododo

وَمِنَ الْإِبِلِ اثْنَيْنِ وَمِنَ الْبَقَرِ اثْنَيْنِ ۗ قُلْ آلذَّكَرَيْنِ حَرَّمَ أَمِ الْأُنثَيَيْنِ أَمَّا اشْتَمَلَتْ عَلَيْهِ أَرْحَامُ الْأُنثَيَيْنِ ۖ أَمْ كُنتُمْ شُهَدَاءَ إِذْ وَصَّاكُمُ اللَّهُ بِهَٰذَا ۚ فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا لِّيُضِلَّ النَّاسَ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ(144)

 Meji ninu rakunmi (tako-tabo) ati meji ninu maalu (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. Tabi se eyin wa nibe nigba ti Allahu pa yin lase eyi ni?" Nitori naa, ta ni o se abosi t’o tun tayo eni t’o da adapa iro mo Allahu lati le si awon eniyan lona pelu ainimo. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

قُل لَّا أَجِدُ فِي مَا أُوحِيَ إِلَيَّ مُحَرَّمًا عَلَىٰ طَاعِمٍ يَطْعَمُهُ إِلَّا أَن يَكُونَ مَيْتَةً أَوْ دَمًا مَّسْفُوحًا أَوْ لَحْمَ خِنزِيرٍ فَإِنَّهُ رِجْسٌ أَوْ فِسْقًا أُهِلَّ لِغَيْرِ اللَّهِ بِهِ ۚ فَمَنِ اضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَإِنَّ رَبَّكَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(145)

 So pe: "Emi ko ri ninu ohun ti Won fi ranse si mi ti Won se jije re ni eewo fun eni ti o n je e afi ohun ti o ba je eran okunbete tabi eje sisan,1 tabi eran elede nitori pe dajudaju egbin ni, tabi eran iyapa (ase Allahu) ti won pa pelu oruko t’o yato si Allahu. Nitori naa, enikeni ti inira (ebi) ba mu je e, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun

وَعَلَى الَّذِينَ هَادُوا حَرَّمْنَا كُلَّ ذِي ظُفُرٍ ۖ وَمِنَ الْبَقَرِ وَالْغَنَمِ حَرَّمْنَا عَلَيْهِمْ شُحُومَهُمَا إِلَّا مَا حَمَلَتْ ظُهُورُهُمَا أَوِ الْحَوَايَا أَوْ مَا اخْتَلَطَ بِعَظْمٍ ۚ ذَٰلِكَ جَزَيْنَاهُم بِبَغْيِهِمْ ۖ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ(146)

 A se e ni eewo fun awon t’o di yehudi gbogbo eran eleeekanna (tabi onipatako t’o supo mora won). Ninu eran maalu ati agutan, A tun se ora awon mejeeji ni eewo fun won afi eyi ti o ba le mo eyin won tabi ifun tabi eyi ti o ba ropo mo eegun. Iyen ni A fi san won ni esan nitori abosi owo won. Dajudaju Awa si ni Olododo

فَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل رَّبُّكُمْ ذُو رَحْمَةٍ وَاسِعَةٍ وَلَا يُرَدُّ بَأْسُهُ عَنِ الْقَوْمِ الْمُجْرِمِينَ(147)

 Ti won ba si pe o ni opuro, so nigba naa pe: "Oluwa yin ni Onikee to gbooro. Ko si si eni t’o le gbe iya Re kuro lori ijo elese

سَيَقُولُ الَّذِينَ أَشْرَكُوا لَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا أَشْرَكْنَا وَلَا آبَاؤُنَا وَلَا حَرَّمْنَا مِن شَيْءٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ حَتَّىٰ ذَاقُوا بَأْسَنَا ۗ قُلْ هَلْ عِندَكُم مِّنْ عِلْمٍ فَتُخْرِجُوهُ لَنَا ۖ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ أَنتُمْ إِلَّا تَخْرُصُونَ(148)

 Awon t’o n sebo yoo wi pe: "Ti ko ba je pe Allahu ba fe ni awa ati awon baba wa iba ti sebo, ati pe awa iba ti se nnkan kan leewo." Bayen ni awon t’o siwaju won se pe oro Allahu niro titi won fi to iya Wa wo. So pe: "Nje imo kan n be ni odo yin, ki e mu un jade fun wa?" Eyin ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni e n so bi ko se pe e n paro

قُلْ فَلِلَّهِ الْحُجَّةُ الْبَالِغَةُ ۖ فَلَوْ شَاءَ لَهَدَاكُمْ أَجْمَعِينَ(149)

 So pe: "Ti Allahu ni eri t’o pe perepere." Nitori naa, ti O ba fe ni, iba fi gbogbo yin mona patapata

قُلْ هَلُمَّ شُهَدَاءَكُمُ الَّذِينَ يَشْهَدُونَ أَنَّ اللَّهَ حَرَّمَ هَٰذَا ۖ فَإِن شَهِدُوا فَلَا تَشْهَدْ مَعَهُمْ ۚ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَالَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ وَهُم بِرَبِّهِمْ يَعْدِلُونَ(150)

 So pe: "E mu awon elerii yin jade, awon t’o maa jerii pe dajudaju Allahu l’o se eyi leewo." Ti won ba jerii (siro), iwo ma se ba won jerii (si i). Ma si se tele ife-inu awon t’o pe awon ayah Wa niro ati awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo. Awon si ni won n ba Oluwa won wa akegbe

۞ قُلْ تَعَالَوْا أَتْلُ مَا حَرَّمَ رَبُّكُمْ عَلَيْكُمْ ۖ أَلَّا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا ۖ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا ۖ وَلَا تَقْتُلُوا أَوْلَادَكُم مِّنْ إِمْلَاقٍ ۖ نَّحْنُ نَرْزُقُكُمْ وَإِيَّاهُمْ ۖ وَلَا تَقْرَبُوا الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ ۖ وَلَا تَقْتُلُوا النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللَّهُ إِلَّا بِالْحَقِّ ۚ ذَٰلِكُمْ وَصَّاكُم بِهِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ(151)

 So pe: "E wa ki ng ka ohun ti Oluwa yin se ni eewo fun yin; pe ki e ma se fi nnkan kan sebo si I, (ki e si se) daadaa si awon obi (yin) mejeeji, ki e si ma se pa awon omo yin nitori (iberu) osi, – Awa ni A n pese fun eyin ati awon – ki e si ma se sunmo awon iwa ibaje – eyi t’o han ninu re ati eyi t’o pamo, - ati pe ki e si ma se pa emi (eniyan) ti Allahu se ni eewo ayafi ni ona eto. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le se laakaye

وَلَا تَقْرَبُوا مَالَ الْيَتِيمِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ حَتَّىٰ يَبْلُغَ أَشُدَّهُ ۖ وَأَوْفُوا الْكَيْلَ وَالْمِيزَانَ بِالْقِسْطِ ۖ لَا نُكَلِّفُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا ۖ وَإِذَا قُلْتُمْ فَاعْدِلُوا وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَىٰ ۖ وَبِعَهْدِ اللَّهِ أَوْفُوا ۚ ذَٰلِكُمْ وَصَّاكُم بِهِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ(152)

 E ma se sunmo dukia omo orukan ayafi ni ona t’o dara julo titi o fi maa dagba. E won kongo ati osuwon pe daadaa. A ko labo emi kan lorun ayafi iwon agbara re. Ti e ba soro, e se deede, ibaa je ibatan. Ki e si pe adehun Allahu. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le lo iranti

وَأَنَّ هَٰذَا صِرَاطِي مُسْتَقِيمًا فَاتَّبِعُوهُ ۖ وَلَا تَتَّبِعُوا السُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمْ عَن سَبِيلِهِ ۚ ذَٰلِكُمْ وَصَّاكُم بِهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ(153)

 Ati pe dajudaju eyi ni ona Mi (ti o je ona) taara. Nitori naa, e tele e. E ma se tele awon oju ona (miiran) nitori ki o ma baa mu yin yapa oju ona (esin) Re. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le beru (Re)

ثُمَّ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ تَمَامًا عَلَى الَّذِي أَحْسَنَ وَتَفْصِيلًا لِّكُلِّ شَيْءٍ وَهُدًى وَرَحْمَةً لَّعَلَّهُم بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ يُؤْمِنُونَ(154)

 Leyin naa, A fun (Anabi) Musa ni Tira ni pipe perepere fun eni ti o maa se daadaa. (O je) alaye fun gbogbo nnkan. (O tun je) imona ati ike nitori ki won le ni igbagbo ninu ipade Oluwa won

وَهَٰذَا كِتَابٌ أَنزَلْنَاهُ مُبَارَكٌ فَاتَّبِعُوهُ وَاتَّقُوا لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ(155)

 Eyi ni Tira ibukun ti A sokale. Nitori naa, e tele e. Ki e si beru (Allahu) nitori ki A le ke yin

أَن تَقُولُوا إِنَّمَا أُنزِلَ الْكِتَابُ عَلَىٰ طَائِفَتَيْنِ مِن قَبْلِنَا وَإِن كُنَّا عَن دِرَاسَتِهِمْ لَغَافِلِينَ(156)

 Nitori ki e ma se wi pe: “Owo ijo meji ti o siwaju wa ni Won so Tira kale fun. A si je alainimo nipa eko won.”

أَوْ تَقُولُوا لَوْ أَنَّا أُنزِلَ عَلَيْنَا الْكِتَابُ لَكُنَّا أَهْدَىٰ مِنْهُمْ ۚ فَقَدْ جَاءَكُم بَيِّنَةٌ مِّن رَّبِّكُمْ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ ۚ فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن كَذَّبَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَصَدَفَ عَنْهَا ۗ سَنَجْزِي الَّذِينَ يَصْدِفُونَ عَنْ آيَاتِنَا سُوءَ الْعَذَابِ بِمَا كَانُوا يَصْدِفُونَ(157)

 Tabi ki e ma baa wi pe: “Dajudaju Won iba so Tira kale fun wa ni, awa iba mona ju won lo.” Eri t’o yanju, imona ati ike kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ta ni o se abosi ju eni t’o pe awon ayah Allahu niro, t’o tun gbunri kuro nibe? A maa san awon t’o n gbunri kuro nibi awon ayah Wa ni (esan) iya buruku nitori pe won n gbunri (kuro nibe)

هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا أَن تَأْتِيَهُمُ الْمَلَائِكَةُ أَوْ يَأْتِيَ رَبُّكَ أَوْ يَأْتِيَ بَعْضُ آيَاتِ رَبِّكَ ۗ يَوْمَ يَأْتِي بَعْضُ آيَاتِ رَبِّكَ لَا يَنفَعُ نَفْسًا إِيمَانُهَا لَمْ تَكُنْ آمَنَتْ مِن قَبْلُ أَوْ كَسَبَتْ فِي إِيمَانِهَا خَيْرًا ۗ قُلِ انتَظِرُوا إِنَّا مُنتَظِرُونَ(158)

 Se won n reti nnkan (miiran) bi ko se pe ki awon molaika wa ba won tabi ki Oluwa re wa ba won tabi ki apa kan awon ami Oluwa re wa ba won? Ni ojo ti apa kan awon ami Oluwa re ba wa ba won, igbagbo (ti) emi kan ko ti i gbagbo teletele tabi ise rere (ti) emi kan ko ti i fi igbagbo re se (teletele) ko nii se e ni anfaani (lasiko naa). So pe: “E maa reti, dajudaju Awa naa n reti (Ojo naa)

إِنَّ الَّذِينَ فَرَّقُوا دِينَهُمْ وَكَانُوا شِيَعًا لَّسْتَ مِنْهُمْ فِي شَيْءٍ ۚ إِنَّمَا أَمْرُهُمْ إِلَى اللَّهِ ثُمَّ يُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُوا يَفْعَلُونَ(159)

 Dajudaju awon t’o ya esin won si otooto, ti won si di ijo-ijo, iwo ko ni nnkan kan se po pelu won. Oro won si n be ni odo Allahu. Leyin naa, O maa fun won ni iro ohun ti won n se nise

مَن جَاءَ بِالْحَسَنَةِ فَلَهُ عَشْرُ أَمْثَالِهَا ۖ وَمَن جَاءَ بِالسَّيِّئَةِ فَلَا يُجْزَىٰ إِلَّا مِثْلَهَا وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ(160)

 Enikeni t’o ba mu ise daadaa wa, (esan) mewaa iru re l’o maa wa fun un. Enikeni t’o ba si mu ise aburu wa, A o nii san an ni esan ayafi iru re. A o si nii sabosi si won

قُلْ إِنَّنِي هَدَانِي رَبِّي إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ دِينًا قِيَمًا مِّلَّةَ إِبْرَاهِيمَ حَنِيفًا ۚ وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ(161)

 So pe: “Dajudaju Oluwa mi ti fi ona taara (’Islam) mo mi, esin t’o fese rinle, esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-esin, ko si si ninu awon osebo.”

قُلْ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحْيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ(162)

 So pe: "Dajudaju irun mi, eran (pipa) mi, isemi aye mi ati iku mi n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

لَا شَرِيكَ لَهُ ۖ وَبِذَٰلِكَ أُمِرْتُ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُسْلِمِينَ(163)

 Ko si akegbe fun Un. Iyen ni Won pa lase fun mi. Emi si ni eni-akoko awon musulumi (ni asiko temi)

قُلْ أَغَيْرَ اللَّهِ أَبْغِي رَبًّا وَهُوَ رَبُّ كُلِّ شَيْءٍ ۚ وَلَا تَكْسِبُ كُلُّ نَفْسٍ إِلَّا عَلَيْهَا ۚ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ ۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرْجِعُكُمْ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ(164)

 So pe: "Se emi yoo tun wa oluwa kan yato si Allahu ni, nigba ti o je pe Oun ni Oluwa gbogbo nnkan. Emi kan ko si nii se ise kan afi fun emi ara re. Eleru-ese kan ko si nii ru ese elomiiran. Leyin naa, odo Oluwa yin ni ibupadasi yin. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n yapa enu si.”

وَهُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلَائِفَ الْأَرْضِ وَرَفَعَ بَعْضَكُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ لِّيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ ۗ إِنَّ رَبَّكَ سَرِيعُ الْعِقَابِ وَإِنَّهُ لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ(165)

 Oun ni Eni ti O se yin ni arole lori ile. O si fi awon ipo gbe yin ga ju ara yin lo nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin. Dajudaju Oluwa re ni Oluyara nibi iya. Dajudaju Oun si ni Alaforijin, Asake-orun


More surahs in Yoruba:


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Download surah Al-Anam with the voice of the most famous Quran reciters :

surah Al-Anam mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Al-Anam Complete with high quality
surah Al-Anam Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah Al-Anam Bandar Balila
Bandar Balila
surah Al-Anam Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah Al-Anam Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah Al-Anam Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah Al-Anam Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah Al-Anam Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah Al-Anam Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah Al-Anam Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah Al-Anam Fares Abbad
Fares Abbad
surah Al-Anam Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah Al-Anam Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah Al-Anam Al Hosary
Al Hosary
surah Al-Anam Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah Al-Anam Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Saturday, May 4, 2024

لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب