سوره كهف به زبان یوروبا
الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَنزَلَ عَلَىٰ عَبْدِهِ الْكِتَابَ وَلَمْ يَجْعَل لَّهُ عِوَجًا ۜ(1) Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O so Tira kale fun erusin Re. Ko si doju oro kan ru ninu re |
(al-Ƙur’an) fese rinle nitori ki (Anabi) le fi se ikilo iya lile lati odo (Allahu) ati nitori ki (Anabi) le fun awon onigbagbo ododo, awon t’o n se ise rere ni iro idunnu pe dajudaju esan rere n be fun won (ninu Ogba Idera) |
Won yoo maa gbe ninu re lo titi laelae |
Ati nitori ki (Anabi) le se ikilo fun awon t’o wi pe: “Allahu mu eni kan ni omo.” |
Ko si imo fun awon ati baba won nipa re. Oro t’o n jade lenu won tobi. Dajudaju won ko wi kini kan bi ko se iro |
فَلَعَلَّكَ بَاخِعٌ نَّفْسَكَ عَلَىٰ آثَارِهِمْ إِن لَّمْ يُؤْمِنُوا بِهَٰذَا الْحَدِيثِ أَسَفًا(6) Nitori naa, nitori ki ni o se maa fi ibanuje para re lori igbese won pe won ko gba oro (al-Ƙur’an) yii gbo |
إِنَّا جَعَلْنَا مَا عَلَى الْأَرْضِ زِينَةً لَّهَا لِنَبْلُوَهُمْ أَيُّهُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا(7) Dajudaju Awa se ohun ti n be lori ile ni oso fun ara-aye nitori ki A le dan won wo (pe) ewo ninu won l’o maa dara julo nibi ise sise (fun esin) |
Ati pe dajudaju Awa maa so nnkan ti n be lori (ile) di erupe gbigbe ti ko nii hu irugbin |
أَمْ حَسِبْتَ أَنَّ أَصْحَابَ الْكَهْفِ وَالرَّقِيمِ كَانُوا مِنْ آيَاتِنَا عَجَبًا(9) Tabi o lero pe dajudaju awon ara inu iho apata ati walaha oruko won je eemo kan ninu awon ami Wa |
Nigba ti awon odokunrin naa kora won sinu iho apata, won so pe: “Oluwa wa, fun wa ni ike lati odo Re, ki O se imona ni irorun fun wa ninu oro wa.” |
فَضَرَبْنَا عَلَىٰ آذَانِهِمْ فِي الْكَهْفِ سِنِينَ عَدَدًا(11) A kun won l’oorun asunpiye ninu iho apata f’odun gbooro |
ثُمَّ بَعَثْنَاهُمْ لِنَعْلَمَ أَيُّ الْحِزْبَيْنِ أَحْصَىٰ لِمَا لَبِثُوا أَمَدًا(12) Leyin naa, A gbe won dide nitori ki A le safi han ewo ninu ijo mejeeji l’o mo gbedeke onka odun t’o lo (ninu iho apata naa) |
Awa n so iroyin won fun o pelu ododo. Dajudaju odokunrin ni won. Won gbagbo ninu Oluwa won. A si salekun imona fun won |
A si ki won lokan nigba ti won dide, ti won so pe: "Oluwa wa ni Oluwa awon sanmo ati ile. A o si nii pe olohun kan leyin Re. (Ti a ba pe olohun kan leyin Re) dajudaju a ti pa iro niyen |
Awon ijo wa wonyi so awon kan di olohun leyin Allahu. Ki ni ko je ki won mu eri t’o yanju wa nipa won? Nitori naa, ta ni o se abosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu |
(Awon odokunrin naa so funra won pe:) nigba ti e ba yera fun awon ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu, ti e si wa ibugbe sinu iho apata, Oluwa yin yoo te ninu ike Re sile fun yin. O si maa se oro yin ni irorun fun yin |
O maa ri oorun nigba ti o ba yo, o maa yeba kuro nibi iho won si owo otun. Nigba ti o ba tun wo, o maa fi won sile si owo osi. Won si wa ninu aye ti o feju ninu iho apata. Iyen wa ninu awon ami Allahu. Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si lona, o o si nii ri oluranlowo atoni-sona kan fun un |
O maa lero pe won laju sile ni, oju oorun ni won si wa. A si n yi won legbee pada sotun-un sosi. Aja won si na apa re mejeeji sile ni gbagede apata. Ti o ba je pe o yoju wo won ni, iwo iba peyin da lati ho fun won, iwo iba si kun fun iberu-bojo lati ara won |
Bayen (ni won wa) ti A fi gbe won dide pada nitori ki won le bi ara won leere ibeere. Onsoro kan ninu won so pe: “Igba wo le ti wa nibi?” Won so pe: “A wa nibi fun ojo kan tabi idaji ojo.” Won so pe: “Oluwa yin nimo julo nipa igba ti e ti wa nibi.” Nitori naa, e gbe okan ninu yin dide lo si inu ilu pelu owo fadaka yin yii. Ki o wo ewo ninu ounje ilu l’o mo julo, ki o si mu ase wa fun yin ninu re. Ki o se pelepele, ko si gbodo je ki eni kan kan fura si yin |
(Nitori pe) dajudaju ti won ba fi le mo nipa yin, won yoo ju yin loko tabi ki won da yin pada sinu esin won. (Ti o ba si fi ri bee) e o nii jere mo laelae niyen |
Bayen ni A se je ki awon eniyan ri won nitori ki won le mo pe dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ati pe dajudaju Akoko naa ko si iyemeji ninu re. Ranti (nigba ti awon eniyan) n se ariyanjiyan laaarin ara won nipa oro won. Won so pe: "E mo ile kan le won lori. Oluwa won nimo julo nipa won." Awon t’o bori lori oro won si wi pe: “Dajudaju a maa so ori apata won di mosalasi.” |
Won n wi pe: “Meta ni won. Aja won sikerin won.” Won tun n wi pe: "Marun-un ni won. Aja won sikefa won." Oro t’o pamo fun won (ni won n so). Won tun n wi pe: “Meje ni won. Aja won sikejo won.” So pe: "Oluwa mi nimo julo nipa onka won. Ko si (eni ti) o mo (onka) won afi awon die. Nitori naa, ma se ba won se ariyanjiyan nipa (onka) won afi (ki o fi) ariyanjiyan (naa ti sibi eri) t’o yanju (ti A sokale fun o yii). Ma si se bi eni kan ninu won leere nipa (onka) won |
Ma se so nipa kini kan pe: “Dajudaju emi yoo se iyen ni ola.” |
Ayafi (ki o fi kun un pe) "ti Allahu ba fe." Se iranti Oluwa re nigba ti o ba gbagbe (lati so bee lasiko naa). Ki o si so (fun won) pe: “O rorun ki Oluwa mi to mi sona pelu eyi ti o sunmo ju eyi lo ni imona (fun yin).” |
وَلَبِثُوا فِي كَهْفِهِمْ ثَلَاثَ مِائَةٍ سِنِينَ وَازْدَادُوا تِسْعًا(25) Won wa ninu iho apata won fun ogorun-un meta odun. Won tun lo alekun odun mesan-an |
So pe: “Allahu nimo julo nipa ohun ti won lo (ninu iho apata). TiRe ni ikoko awon sanmo ati ile. Ki ni ko ri tan, ki si ni ko gbo tan! Ko si alaabo kan fun won leyin Re. Ko si fi eni kan se akegbe ninu idajo Re.” |
Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira Oluwa re. Ko si eni ti o le yi awon oro Re pada. Iwo ko si le ri ibusasi kan yato si odo Re |
Se suuru fun emi re lati wa pelu awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale, ti won n wa Oju rere Re. Ma se foju pa won re lati wa oso isemi aye (yii). Ma si se tele eni ti A mu okan re gbagbe iranti Wa. O tele ife-inu re; oro re si je aseju |
So pe: “Ododo (niyi) lati odo Oluwa yin. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o gbagbo. Eni ti o ba si fe ki o sai gbagbo. Dajudaju Awa pese Ina sile de awon alabosi, ti ogba re yoo yi won po. Ti won ba n toro omi mimu, A oo fun won ni omi mimu kan t’o da bi oje ide gbigbona, ti (igbona re) yo si maa se awon oju. O buru ni mimu. O si buru ni ibukojo |
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجْرَ مَنْ أَحْسَنَ عَمَلًا(30) Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju Awa ko nii fi esan eni ti o ba se ise rere rare |
Awon wonyen, tiwon ni Ogba Idera gbere, ti awon odo yoo maa san ni isale won. Won yoo maa fi goolu orun se won ni oso ninu re. Won yoo maa wo aso aran alawo eweko (eyi ti o) fele ati (eyi ti) o nipon. Won yo si rogboku lori ibusun ola ninu (Ogba Idera). O dara ni esan. O si dara ni ibukojo |
Fi awon okunrin meji kan se apeere fun won; A fun okan ninu won ni ogba eso ajara meji. A si fi awon igi dabinu yi won ka. A tun fi awon igi eleso la won laaarin |
Ikini keji awon oko mejeeji n so eso won. Awon eso re ki i pe din. A si je ki odo san koja laaarin oko mejeeji |
O ni eso (se). O si so fun ore re nigba ti o n ba a jiyan (bayii) pe: “Emi ni dukia lowo ju o lo. Mo tun lero leyin julo.” |
وَدَخَلَ جَنَّتَهُ وَهُوَ ظَالِمٌ لِّنَفْسِهِ قَالَ مَا أَظُنُّ أَن تَبِيدَ هَٰذِهِ أَبَدًا(35) O wo inu oko re lo, o si ti sabosi si emi ara re, o wi pe: “Emi ko lero pe eyi maa parun laelae |
Emi ko si lero pe Akoko naa maa sele. Ati pe ti won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju mo tun maa ri ibudesi t’o dara ju eyi lo.” |
Ore re so fun un nigba ti o n ja a niyan (bayii) pe: “Se o maa sai gbagbo ninu Eni ti O seda re lati inu erupe, leyin naa, lati inu ato. Leyin naa, O se o ni okunrin t’o pe ni eda |
لَّٰكِنَّا هُوَ اللَّهُ رَبِّي وَلَا أُشْرِكُ بِرَبِّي أَحَدًا(38) Sugbon ni temi, Oluwa mi, Oun ni Allahu. Emi ko si nii so eni kan di akegbe fun Oluwa mi |
Nigba ti o wo inu ogba oko re, ki ni ko mu o so pe: "Ohun ti Allahu ba fe! Ko si agbara kan bi ko se pelu iyonda Allahu. Ti o ba si ri mi pe mo kere si o ni dukia ati omo |
o sunmo ki Oluwa mi fun emi naa ni ogba oko ti o maa dara ju ogba oko tire. (O si sunmo) ki O so iya kan kale sinu ogba oko re lati sanmo; o si maa di ile asale |
أَوْ يُصْبِحَ مَاؤُهَا غَوْرًا فَلَن تَسْتَطِيعَ لَهُ طَلَبًا(41) Tabi ki omi re gbe. O o si nii le wa omi kan |
Won si pa eso re run patapata. O si di eni t’o n fi owo re mejeeji lura won peepe nipa ohun ti o ti na sori re. O ti parun torule-torule re. O si n wi pe: “Yee! Emi iba ti so eni kan kan di akegbe fun Oluwa mi.” |
وَلَمْ تَكُن لَّهُ فِئَةٌ يَنصُرُونَهُ مِن دُونِ اللَّهِ وَمَا كَانَ مُنتَصِرًا(43) Ko ni ijo kan ti o maa ran an lowo mo leyin Allahu. Ko si le ran ara re lowo |
هُنَالِكَ الْوَلَايَةُ لِلَّهِ الْحَقِّ ۚ هُوَ خَيْرٌ ثَوَابًا وَخَيْرٌ عُقْبًا(44) Nibe yen, ti Allahu, Oba Ododo ni ijoba. O loore julo ni esan, O si loore julo ni ikangun (rere) |
Se akawe ile aye fun won; o da bi omi ti A sokale lati sanmo. Leyin naa, o ropo mo irugbin ile. Leyin naa, (irugbin) di gbigbe, ti ategun n fonka. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan |
Oso isemi aye ni dukia ati awon omo. Awon ise rere t’o maa wa titi laelae loore julo ni esan lodo Oluwa re, o si loore julo ni ireti |
(Ranti) ojo ti A maa mu awon apata rin lo. O si maa ri ile ni petele. A maa ko won jo. A o si nii fi eni kan sile ninu won |
Won yo si ko won wa siwaju Oluwa re ni owoowo. Dajudaju e ti wa ba Wa (bayii) gege bi A se da yin nigba akoko. Amo e so lai ni eri lowo pe A o nii mu ojo adehun se fun yin |
A maa gbe iwe ise eda kale (fun won). Nigba naa, o maa ri awon elese ti won yoo maa beru nipa ohun ti n be ninu iwe ise won. Won yoo wi pe: “Egbe wa! Iru iwe wo ni eyi na; ko fi ohun kekere ati nla kan sile lai ko o sile?” Won si ba ohun ti won se nise nibe. Oluwa re ko si nii sabosi si eni kan |
(Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Adam.” Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o je okan ninu awon alujannu. O si safojudi si ase Oluwa re. Nitori naa, se e maa mu oun ati awon aromodomo re ni alafeyinti leyin Mi ni, ota yin si ni won. Pasipaaro t’o buru ni fun awon alabosi |
Ng o pe won si dida awon sanmo ati ile, ati dida awon gan-an alara. Ng o si mu awon asinilona ni oluranlowo |
(Ranti) ojo ti (Allahu) yoo so pe: “E pe awon akegbe Mi ti e so nipa won lai ni eri lowo (pe olusipe ni won).” Won pe won. Won ko si da won lohun. A si ti fi koto iparun saaarin won |
وَرَأَى الْمُجْرِمُونَ النَّارَ فَظَنُّوا أَنَّهُم مُّوَاقِعُوهَا وَلَمْ يَجِدُوا عَنْهَا مَصْرِفًا(53) Awon elese si ri Ina. Won si mo pe awon yoo ko sinu re. Won ko si nii ri ibusasi kan ninu re |
Dajudaju A ti se alaye oniran-anran sinu al-Ƙur’an fun awon eniyan pelu gbogbo akawe. Eniyan si je alatako pupo ju ohunkohun lo |
Ko si ohun t’o di awon eniyan lowo lati gbagbo nigba ti imona de ba won, (ko si si ohun t’o di won lowo lati) toro aforijin Oluwa won, bi ko se pe (won fe) ki ise (Allahu nipa iparun) awon eni akoko de ba awon naa tabi ki iya de ba won ni ojukoju |
Ati pe A ko ran awon Ojise nise (lasan) afi ki won je oniroo-idunnu ati olukilo. Awon t’o sai gbagbo si n fi iro satako nitori ki won le fi wo ododo. Won si so awon ayah Mi ati ohun ti A fi sekilo fun won di yeye |
Ta si l’o sabosi ju eni ti won fi awon ayah Oluwa re seranti fun, ti o gbunri kuro nibe, ti o si gbagbe ohun ti owo re mejeeji ti siwaju? Dajudaju Awa fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. A si fi edidi sinu eti won. Ti iwo ba pe won sinu imona, nigba naa won ko si nii mona laelae |
Oluwa re, Alaforijin, Onikee, ti o ba je pe O maa fi ohun ti won se nise mu won ni, iba tete mu iya wa fun won. Sugbon akoko adehun (ajinde) wa fun won. Won ko si nii ri ibusasi kan leyin re |
وَتِلْكَ الْقُرَىٰ أَهْلَكْنَاهُمْ لَمَّا ظَلَمُوا وَجَعَلْنَا لِمَهْلِكِهِم مَّوْعِدًا(59) Iwonyi ni awon ilu ti A ti pare nigba ti won sabosi. A si fun won ni adehun fun iparun won |
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun omo-odo re pe: "Ng o nii ye rin titi mo maa fi de ibi ti odo meji ti pade tabi (titi) mo maa fi lo opolopo odun |
فَلَمَّا بَلَغَا مَجْمَعَ بَيْنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَاتَّخَذَ سَبِيلَهُ فِي الْبَحْرِ سَرَبًا(61) Nigba ti awon mejeeji si de ibi ti odo meji ti pade, won gbagbe eja won. (Eja naa) si bo si oju ona re (ti o ti di) poro ona ninu odo |
فَلَمَّا جَاوَزَا قَالَ لِفَتَاهُ آتِنَا غَدَاءَنَا لَقَدْ لَقِينَا مِن سَفَرِنَا هَٰذَا نَصَبًا(62) Nigba ti awon mejeeji re koja (ibi ti odo meji ti pade), o so fun omo-odo re pe: "Fun wa ni ounje osan wa. Dajudaju a ti ko wahala ninu irin-ajo wa yii |
(Omo-odo re) so pe: "So (ohun t’o sele) fun mi, nigba ti a wa nibi apata! Dajudaju mo ti gbagbe eja naa (sibe)? Ko si si ohun ti o mu mi gbagbe re bi ko se Esu, ti ko je ki ng ranti re. (Eja naa) si ti mu ona re to lo ninu odo pelu iyanu |
قَالَ ذَٰلِكَ مَا كُنَّا نَبْغِ ۚ فَارْتَدَّا عَلَىٰ آثَارِهِمَا قَصَصًا(64) (Anabi Musa) so pe: “(Ibi ti eja ti lo) yen ni ohun ti a n wa.” Awon mejeeji si pada seyin lati to oripa ese won bi won se to o wa |
Awon mejeeji si ri erusin kan ninu awon erusin Wa, ti A fun ni ike kan lati odo Wa. A si fun un ni imo lati odo Wa |
قَالَ لَهُ مُوسَىٰ هَلْ أَتَّبِعُكَ عَلَىٰ أَن تُعَلِّمَنِ مِمَّا عُلِّمْتَ رُشْدًا(66) (Anabi) Musa so fun un pe: “Se ki ng tele o nitori ki o le ko mi ninu ohun ti Won fi mo o ni imona.” amo bi musulumi kookan ba se sunmo Allahu to ninu igbagbo ati iberu re nipa lilo ofin esin ’Islam |
(Kidr) so pe: “Dajudaju o o le se suuru pelu mi |
Ati pe bawo ni o se le se suuru lori ohun ti o o fi imo rokiri ka re?” |
قَالَ سَتَجِدُنِي إِن شَاءَ اللَّهُ صَابِرًا وَلَا أَعْصِي لَكَ أَمْرًا(69) (Anabi Musa) so pe: “Ti Allahu ba fe, o maa ba mi ni onisuuru. Mi o si nii yapa ase re.” |
قَالَ فَإِنِ اتَّبَعْتَنِي فَلَا تَسْأَلْنِي عَن شَيْءٍ حَتَّىٰ أُحْدِثَ لَكَ مِنْهُ ذِكْرًا(70) (Kidr) so pe: “Ti o ba tele mi, ma se bi mi ni ibeere nipa nnkan kan titi mo fi maa koko mu iranti wa fun o nipa re.” |
Nitori naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi wo inu oko oju-omi. (Kidr) si da oko naa lu. (Anabi Musa) so pe: “O se da a lu, (se) ki awon ero re le te ri ni? Dajudaju o ti se nnkan aburu kan!” |
قَالَ أَلَمْ أَقُلْ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِيَ صَبْرًا(72) (Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.” |
قَالَ لَا تُؤَاخِذْنِي بِمَا نَسِيتُ وَلَا تُرْهِقْنِي مِنْ أَمْرِي عُسْرًا(73) (Anabi Musa) so pe: “Ma se ba mi wi nipa ohun ti mo gbagbe. Ma si se ko inira ba mi ninu oro (irin-ajo) mi (pelu re).” |
Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi pade omodekunrin kan. (Kidr) si pa a. (Anabi Musa) so pe: “O se pa emi (eniyan) mimo, lai gba emi? Dajudaju o ti se nnkan t’o buru o.” |
۞ قَالَ أَلَمْ أَقُل لَّكَ إِنَّكَ لَن تَسْتَطِيعَ مَعِيَ صَبْرًا(75) (Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.” |
قَالَ إِن سَأَلْتُكَ عَن شَيْءٍ بَعْدَهَا فَلَا تُصَاحِبْنِي ۖ قَدْ بَلَغْتَ مِن لَّدُنِّي عُذْرًا(76) (Anabi Musa) so pe: “Ti mo ba tun bi o nipa kini kan leyin re, ma se ba mi rin mo. Dajudaju o ti mu awawi de opin lodo mi.” |
Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won de odo awon ara ilu kan. Won toro ounje lodo awon ara ilu naa. Won si ko lati se won ni alejo. Awon mejeeji si ba ogiri kan nibe ti o fe wo. (Kidr) si gbe e dide. (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe o ba fe, o o ba si gba owo-oya lori re.” |
(Kidr) so pe: “Eyi ni opinya laaarin emi ati iwo. Mo si maa fun o ni itumo ohun ti o o le se suuru lori re.” |
Ni ti oko oju-omi, o je ti awon mekunnu ti won n sise lori omi. Mo si fe lati fi alebu kan an (nitori pe) oba kan wa niwaju won t’o n gba gbogbo oko oju-omi pelu ipa |
وَأَمَّا الْغُلَامُ فَكَانَ أَبَوَاهُ مُؤْمِنَيْنِ فَخَشِينَا أَن يُرْهِقَهُمَا طُغْيَانًا وَكُفْرًا(80) Ni ti omodekunrin naa, awon obi re mejeeji je onigbagbo ododo. A si n beru pe ki o maa ko itayo enu-ala ati aigbagbo ba awon mejeeji |
فَأَرَدْنَا أَن يُبْدِلَهُمَا رَبُّهُمَا خَيْرًا مِّنْهُ زَكَاةً وَأَقْرَبَ رُحْمًا(81) Nitori naa, A fe ki Oluwa awon mejeeji paaro re fun won pelu (eyi) t’o loore ju u lo ni ti mimo (ninu ese) ati (eyi) t’o sunmo ju u lo ni ti ike |
Nipa ti ogiri, o je ti awon omodekunrin, omo orukan meji kan ninu ilu naa. Apoti-oro kan si n be fun awon mejeeji labe ogiri naa. Baba awon mejeeji si je eni rere. Nitori naa, Oluwa re fe ki awon mejeeji dagba (ba dukia naa), ki won si hu dukia won jade (ki o le je) ike kan lati odo Oluwa re. Mi o da a se lati odo ara mi; (Allahu l’O pa mi lase re). Iyen ni itumo ohun ti o o le se suuru fun |
وَيَسْأَلُونَكَ عَن ذِي الْقَرْنَيْنِ ۖ قُلْ سَأَتْلُو عَلَيْكُم مِّنْهُ ذِكْرًا(83) Won n bi o leere nipa Thul-Ƙorneen. So pe: “Mo maa mu oro iranti wa fun yin nipa re.” |
إِنَّا مَكَّنَّا لَهُ فِي الْأَرْضِ وَآتَيْنَاهُ مِن كُلِّ شَيْءٍ سَبَبًا(84) Dajudaju Awa fun un ni ipo lori ile. A si fun un ni ona t’o le gba se gbogbo nnkan (ti o ba fe se) |
Nitori naa, o mu ona kan to |
titi o fi de ibuwo oorun aye. O ri i ti n wo sinu iseleru petepete dudu kan. O si ba awon eniyan kan nibe. A so fun un pe: “Thul-Ƙorneen, yala ki o je won niya tabi ki o mu ohun rere jade lara won.” |
(Allahu) so pe: “Ni ti eni ti o ba sabosi, laipe A maa je e niya. Leyin naa, won maa da a pada si odo Oluwa re. O si maa je e niya t’o buru |
Sugbon ni ti eni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, tire ni esan rere. A o si soro irorun fun un ninu ase Wa.” |
Leyin naa, o mu ona kan to |
titi o fi de ibuyo oorun aye. O ri i ti n yo lori awon eniyan kan, ti A ko fun ni gaga (aabo) kan nibi oorun |
Bayen ni (Thul-Ƙorneen se n te siwaju). Dajudaju A rokirika ohun ti n be lodo re pelu imo |
Leyin naa, o mu ona kan to |
titi o fi de aarin apata meji. O si ba awon eniyan kan niwaju re. Won ko si fee gbo agboye oro kan (ninu ede miiran) |
Won so pe: “Thul-Ƙorneen, dajudaju (iran) Ya’juj ati Ma’juj n se ibaje lori ile. Se ki a fun o ni owo-ode nitori ki o le ba wa mo odi kan saaarin awa ati awon?” |
O so pe: "Ohun ti Oluwa mi fun mi ninu ipo loore julo. Nitori naa, e fi agbara ran mi lowo ni nitori ki ng le mo odi saaarin eyin ati awon |
E maa fun mi ni egige irin titi di igba ti o fi maa ba egbe apata mejeeji dogba." O so pe: "E maa fe ategun ewiri (si i lara) titi di igba ti o maa (pon wee bi) ina." O so pe: "E mu ide wa fun mi ki ng yo o le e lori |
فَمَا اسْطَاعُوا أَن يَظْهَرُوهُ وَمَا اسْتَطَاعُوا لَهُ نَقْبًا(97) Nitori naa, won ko le gun un, won ko si le da a lu |
O so pe: “Eyi ni ike kan lati odo Oluwa mi. Nigba ti adehun Oluwa mi ba de, (Allahu) yo si so o di petele. Adehun Oluwa mi si je ododo.” |
A maa fi awon (eniyan ati alujannu) sile ni ojo yen, ti apa kan won yo si maa dapo mo apa kan. Won a fon fere oniwo fun ajinde. A o si ko gbogbo won jo papo patapata |
وَعَرَضْنَا جَهَنَّمَ يَوْمَئِذٍ لِّلْكَافِرِينَ عَرْضًا(100) Ni ojo yen, A o si fi ina Jahanamo han awon alaigbagbo kedere |
الَّذِينَ كَانَتْ أَعْيُنُهُمْ فِي غِطَاءٍ عَن ذِكْرِي وَكَانُوا لَا يَسْتَطِيعُونَ سَمْعًا(101) (Awon ni) awon ti oju won wa ninu ebibo nipa iranti Mi. Won ko si le gboro |
Se awon t’o sai gbagbo lero pe awon yoo mu awon erusin Mi ni oluranlowo leyin Mi ni? Dajudaju Awa pese ina Jahanamo sile ni ibudesi fun awon alaigbagbo |
So pe: “Se ki A fun yin ni iro awon eni ofo julo nipa ise (owo won) |
(Awon ni) awon ti ise won ti baje ninu isemi aye, (amo ti) won n lero pe dajudaju awon n se ise rere |
Awon wonyen ni awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won ati ipade Re. Awon ise won si baje. Nitori naa, A o nii je ki won jamo nnkan kan lori iwon ni Ojo Ajinde |
ذَٰلِكَ جَزَاؤُهُمْ جَهَنَّمُ بِمَا كَفَرُوا وَاتَّخَذُوا آيَاتِي وَرُسُلِي هُزُوًا(106) Jahanamo, iyen ni esan won nitori pe won sai gbagbo, won si so awon ayah Mi ati awon Ojise Mi di oniyeye |
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ كَانَتْ لَهُمْ جَنَّاتُ الْفِرْدَوْسِ نُزُلًا(107) Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, awon ogba Firdaos ti wa fun won ni ibudesi |
Olusegbere ni won ninu re. Won ko si nii fe kuro ninu re |
So pe: “Ti o ba je pe ibudo je tadaa fun awon oro Oluwa Mi, ibudo kuku maa tan siwaju ki awon oro Oluwa Mi to tan, koda ki A tun mu (ibudo) iru re wa ni alekun.” |
So pe: “Abara ni emi bi iru yin. Won n fi imisi ranse si mi pe Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, enikeni ti o ba n reti ipade Oluwa re, ki o se ise rere. Ko si gbodo fi eni kan kan se akegbe nibi jijosin fun Oluwa re.” |
سورهای بیشتر به زبان یوروبا:
دانلود سوره كهف با صدای معروفترین قراء:
انتخاب خواننده برای گوش دادن و دانلود کامل سوره كهف با کیفیت بالا.
أحمد العجمي
ابراهيم الاخضر
بندر بليلة
خالد الجليل
حاتم فريد الواعر
خليفة الطنيجي
سعد الغامدي
سعود الشريم
الشاطري
صلاح بوخاطر
عبد الباسط
عبدالرحمن العوسي
عبد الرشيد صوفي
عبدالعزيز الزهراني
عبد الله بصفر
عبد الله الجهني
علي الحذيفي
علي جابر
غسان الشوربجي
فارس عباد
ماهر المعيقلي
محمد أيوب
محمد المحيسني
محمد جبريل
المنشاوي
الحصري
مشاري العفاسي
ناصر القطامي
وديع اليمني
ياسر الدوسري
به قرآن کریم چنگ بزنید