Yusuf suresi çevirisi Yoruba
’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira t’o yanju oro eda |
إِنَّا أَنزَلْنَاهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لَّعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ(2) Dajudaju Awa so o kale ni nnkan kike ni ede Larubawa nitori ki e le se laakaye |
Awa n so itan t’o dara julo fun o pelu ohun ti A fi ranse si o (ninu imisi) al-Ƙur’an yii, bi o tile je pe siwaju imisi naa iwo wa lara awon ti ko nimo (nipa re) |
(Ranti) nigba ti (Anabi) Yusuf so fun baba re pe: “Baba mi, dajudaju emi (lalaa) ri awon irawo mokanla, oorun ati osupa. Mo ri won ti won fori kanle fun mi.” |
O so pe: "Omo mi, ma se ro ala re fun awon obakan re nitori ki won ma baa dete si o. Dajudaju Esu ni ota ponnbele fun eniyan |
Bayen ni Oluwa re yoo se sa o lesa. O maa fi itumo ala mo o. O si maa pe idera Re fun iwo ati awon ebi Ya‘ƙub, gege bi O se pe e siwaju fun awon baba re mejeeji, (Anabi) ’Ibrohim ati ’Ishaƙ. Dajudaju Oluwa re ni Onimo, Ologbon |
۞ لَّقَدْ كَانَ فِي يُوسُفَ وَإِخْوَتِهِ آيَاتٌ لِّلسَّائِلِينَ(7) Dajudaju awon ami (ariwoye) n be fun awon onibeeere nipa (itan Anabi) Yusuf ati awon obakan re |
(Ranti) nigba ti won so pe: "Dajudaju Yusuf ati omo-iya re ni baba wa nifee si ju awa. Opo eniyan si ni awa. Dajudaju baba wa ma ti wa ninu asise ponnbele |
E pa Yusuf tabi ki e lo gbe e junu si ile (miiran) nitori ki baba yin le roju gbo tiyin. E si maa di eniyan rere leyin re |
Onsoro kan ninu won so pe: "E ma se pa Yusuf. Ti o ba je pe e sa fe wa nnkan se (si oro re), e gbe e ju sinu isaleesale kannga nitori ki apa kan ninu awon onirin-ajo le baa he e lo |
قَالُوا يَا أَبَانَا مَا لَكَ لَا تَأْمَنَّا عَلَىٰ يُوسُفَ وَإِنَّا لَهُ لَنَاصِحُونَ(11) Won so pe: “Baba wa, ki ni ko mu o fi okan tan wa lori Yusuf. Dajudaju awa si maa je olutoju re |
أَرْسِلْهُ مَعَنَا غَدًا يَرْتَعْ وَيَلْعَبْ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ(12) Je ki o ba wa lo ni ola nitori ki o le dara ya, ki o si le sere. Ati pe dajudaju awa ni oluso fun un.” |
O so pe: “Dajudaju o maa ba mi ninu je pe ki e mu u lo. Mo si n paya ki ikoko ma lo pa a je nigba ti eyin ba gbagbe re (sibi kan).” |
قَالُوا لَئِنْ أَكَلَهُ الذِّئْبُ وَنَحْنُ عُصْبَةٌ إِنَّا إِذًا لَّخَاسِرُونَ(14) Won so pe: “Ti ikoko ba fi pa a je, opo eniyan si ni wa, dajudaju awa nigba naa ni eni ofo.” |
Nigba ti won mu un lo tan, won panupo pe ki awon ju u si isaleesale kannga. A si fi imisi ranse si Yusuf pe: “Dajudaju iwo yoo fun won ni iro nipa oro won yii nigba ti won ko nii fura.” |
Won de ba baba won ni asale, ti won n sunkun |
Won so pe: “Baba wa, awa lo dije ere sisa. A si fi Yusuf sile sibi awon eru wa. Nigba naa ni ikoko pa a je. Iwo ko si nii gba wa gbo, awa ibaa je olododo.” |
Won de pelu eje iro lara ewu re. (Anabi Ya‘ƙub) so pe: "Rara o, emi yin l’o se oran kan losoo fun yin. Nitori naa, suuru abiyi (loro mi kan). Allahu ni Oluranlowo lori ohun ti e n royin |
Awon onirin-ajo kan si de. Won ran aponmi won (ni omi). O si ju doro re sinu kannga. (Yusuf si diro mo okun doro bo sita. Aponmi si) so pe: "Ire idunnu re e! Eyi ni omodekunrin." Won si fi pamo fun tita (bi oja). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise |
وَشَرَوْهُ بِثَمَنٍ بَخْسٍ دَرَاهِمَ مَعْدُودَةٍ وَكَانُوا فِيهِ مِنَ الزَّاهِدِينَ(20) Won ta a ni edinwo pelu owo diriham t’o niye. Won si je eni t’o mu un bin-intin |
Eni ti o ra a ni (ilu) Misro so fun aya re pe: “Se ibugbe re daadaa. O sunmo ki o wulo fun wa tabi ki a fi somo.” Bayen ni A se fi aye gba Yusuf lori ile. Ati pe ki A tun le fi itumo ala mo on. Allahu ni Olubori lori ase Re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo |
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُ آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(22) Nigba ti o di gende tan, A fun un ni ogbon ijinle ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan rere |
Obinrin ti Yusuf wa ninu ile re si jireebe fun ere ife lodo re. O si ti gbogbo ilekun pa. O so pe: “Sunmo mi.” (Yusuf) so pe: “Mo sadi Allahu. Dajudaju oko re ni oga mi. O si se ibugbe mi daadaa. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.” |
(Obinrin naa) kuku gbero ere ife si i. Oun naa gbero re, Ti ki i ba se pe o ri eri Oluwa re (pe haramu ni sina, iba sunmo on). Bayen ni (oro naa ri) nitori ki A le seri aburu ati sina sise kuro lodo re. Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon eni esa |
Awon mejeeji sare lo sibi ilekun. (Obinrin yii) si fa ewu (Yusuf) ya leyin. Awon mejeeji si ba oga re lenu ona. (Obinrin yii) si so pe: “Ki ni esan fun eni ti o gbero aburu si ara ile re bi ko se pe ki a so o sinu ogba ewon tabi iya eleta-elero.” |
(Yusuf) so pe: “Oun l’o jireebe fun ere ife lodo mi.” Elerii kan ninu ara ile (obinrin naa) si jerii pe: "Ti o ba je pe won fa ewu re ya niwaju, (obinrin yii) l’o so ododo, (Yusuf) si wa ninu awon opuro |
وَإِن كَانَ قَمِيصُهُ قُدَّ مِن دُبُرٍ فَكَذَبَتْ وَهُوَ مِنَ الصَّادِقِينَ(27) Ti o ba si je pe won fa ewu re ya leyin, (obinrin yii) l’o paro, (Yusuf) si wa ninu awon olododo |
فَلَمَّا رَأَىٰ قَمِيصَهُ قُدَّ مِن دُبُرٍ قَالَ إِنَّهُ مِن كَيْدِكُنَّ ۖ إِنَّ كَيْدَكُنَّ عَظِيمٌ(28) Nigba ti (oko) ri ewu re ti won ti fa a ya leyin, o so pe: "Dajudaju ninu ete eyin obinrin ni (eyi). Dajudaju ete yin tobi |
يُوسُفُ أَعْرِضْ عَنْ هَٰذَا ۚ وَاسْتَغْفِرِي لِذَنبِكِ ۖ إِنَّكِ كُنتِ مِنَ الْخَاطِئِينَ(29) Yusuf, seri kuro nibi eyi. Ki iwo (obinrin yii) si toro aforijin fun ese re. Dajudaju iwo wa lara awon alasise |
Awon obinrin kan ninu ilu so pe: “Ayaba n jireebe fun ere ife lodo omo odo re; ife kuku ti ko si i lokan. Dajudaju awa n ri oun pe o wa ninu asise ponnbele.” |
Nigba ti (ayaba) gbo ete (oro) won (ti won n so nipa re), o ranse si won. O si pese ohun jije ajokooje sile fun won. O fun ikookan won ni obe (ti o maa fi jeun). O si so pe: “Jade si won, (Yusuf).” Nigba ti won ri i, won gbe e tobi (fun ewa ara re). Won si rera won lowo (fun iyanu ewa ara re). Won si wi pe: “Mimo ni fun Allahu! Eyi ki i se abara. Ki ni eyi bi ko se molaika alapon-onle.” |
(Ayaba) so pe: “Iyen ni eni ti e bu mi fun. Dajudaju mo jireebe fun ere ife lodo re, o si wa isora. Dajudaju ti ko ba se ohun ti mo n pa lase fun un, won kuku maa fi sinu ogba ewon ni. Dajudaju o si maa wa ninu awon eni yepere.” |
(Yusuf) so pe: “Oluwa (Eledaa) mi, ogba ewon ni mo nifee si ju ohun ti won n pe mi si. Ti O o ba si seri ete won kuro lodo mi, emi yoo ko sinu ete won, emi yo si wa lara awon alaimokan.” |
فَاسْتَجَابَ لَهُ رَبُّهُ فَصَرَفَ عَنْهُ كَيْدَهُنَّ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(34) Nitori naa, Oluwa re jepe re. O si seri ete won kuro lodo re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo |
ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّن بَعْدِ مَا رَأَوُا الْآيَاتِ لَيَسْجُنُنَّهُ حَتَّىٰ حِينٍ(35) Leyin igba ti won ti ri awon ami (pe Yusuf ko jebi esun), leyin naa, o han si won pe awon gbodo so o sinu ogba ewon titi di asiko kan na |
Awon odokunrin meji kan wo inu ogba ewon pelu re. Okan ninu awon mejeeji so pe: “Emi lalaa ri ara mi pe mo n fun oti.” Eni keji so pe: “Dajudaju emi lalaa ri ara mi pe mo gbe buredi ru sori mi, eye si n je ninu re.” So itumo re fun wa. Dajudaju awa n ri o pe o wa ninu awon eni rere |
O so pe: "Ounje ti won n pese fun yin ko ni ti i de ba yin, afi ki emi ti so itumo re fun eyin mejeeji siwaju ki o to de ba yin. Iyen wa ninu nnkan ti Oluwa mi fi mo mi. Dajudaju emi fi esin awon eniyan ti ko gbagbo ninu Allahu sile. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin |
Mo si tele esin awon baba mi, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub. Ko to si wa pe ki a so nnkan kan di akegbe fun Allahu. Iyen wa ninu oore ajulo Allahu lori awa ati lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Allahu) |
يَا صَاحِبَيِ السِّجْنِ أَأَرْبَابٌ مُّتَفَرِّقُونَ خَيْرٌ أَمِ اللَّهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ(39) Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, se awon oluwa otooto l’o loore julo (lati josin fun) tabi Allahu, Okan soso, Olubori |
Ko si ohun kan ti e n josin fun leyin Re bi ko se awon oruko kan ti e so won - eyin ati awon baba yin - Allahu ko so eri kan kale fun un. Idajo (ta ni ijosin to si) ko si fun eni kan afi Allahu. O si ti pase pe e ma josin fun kini kan afi Oun nikan. Iyen ni esin t’o fese rinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo |
Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, ni ti eni kan ninu yin, o maa fun oga re ni oti mu. Ni ti eni keji, won yoo kan an mo igi, eye yo si maa je ninu ori re. Won ti pari oro ti eyin mejeeji n se ibeere nipa re |
O si so fun eni ti o ro pe o maa la ninu awon mejeeji pe: “Ranti mi lodo oga re.” Esu si mu (Yusuf) gbagbe iranti Oluwa re (nipa wiwa iranlowo sodo oga re). Nitori naa, o wa ninu ogba ewon fun awon odun die |
Oba so pe: “Dajudaju emi lalaa ri maalu meje t’o sanra. Awon maalu meje t’o ru si n je won. (Mo tun lalaa ri) siri meje tutu ati omiran gbigbe. Eyin ijoye, e fun mi ni alaye itumo ala mi ti e ba je eni t’o maa n tumo ala.” |
قَالُوا أَضْغَاثُ أَحْلَامٍ ۖ وَمَا نَحْنُ بِتَأْوِيلِ الْأَحْلَامِ بِعَالِمِينَ(44) Won so pe: “Awon ala t’o lopo mora won (niyi). Ati pe awa ki i se onimo nipa itumo awon ala.” |
Eni ti o la ninu awon (elewon) mejeeji so pe, - o ranti (Yusuf) leyin igba pipe -: “Emi yoo fun yin ni iro nipa itumo re. Nitori naa, e fi ise ran mi na (ki ng lo se iwadii re).” |
Yusuf, iwo olododo, fun wa ni alaye itumo ala (yii): maalu meje t’o sanra. Awon maalu meje t’o ru si n je won. Ati siri meje tutu ati omiran gbigbe. (Ki ni itumo re) nitori ki ng le fi abo sodo awon eniyan ati nitori ki won le mo (itumo re) |
O so pe: “Eyin yoo gbin nnkan ogbin fun odun meje gbako (gege bi) ise (yin). Ohunkohun ti e ba ko lere oko, ki e fi sile sinu siri re afi die ti e maa je ninu re |
Leyin naa, odun meje t’o le (fun oda ojo) yoo de leyin iyen, (awon ara ilu) yo si le je ohun ti e ti (ko lere oko) siwaju afi die ti e maa fi pamo (fun gbigbin) |
ثُمَّ يَأْتِي مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ عَامٌ فِيهِ يُغَاثُ النَّاسُ وَفِيهِ يَعْصِرُونَ(49) Leyin naa, odun kan ti Won yoo rojo fun awon eniyan yoo de leyin iyen. Awon eniyan yo si maa fun eso ati wara mu ninu odun naa |
Oba so pe: “E mu (Yusuf) wa fun mi.” Nigba ti iranse naa de odo re. (Yusuf) so pe: “Pada sodo oga re, ki o bi i leere pe, ki ni o sele si awon obinrin ti won re owo ara won. Dajudaju Oluwa mi ni Onimo nipa ete won.” |
(Oba) so pe: "Ki ni oro tiyin ti je ti e fi jireebe fun ere ife lodo Yusuf?" Won so pe: “Mimo ni fun Allahu. awa ko mo aburu kan mo Yusuf.” Ayaba so pe: “Nisinsin yii ni ododo foju han. Emi ni mo jireebe fun ere ife lodo re. Dajudaju o wa ninu awon olododo.” |
ذَٰلِكَ لِيَعْلَمَ أَنِّي لَمْ أَخُنْهُ بِالْغَيْبِ وَأَنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي كَيْدَ الْخَائِنِينَ(52) (Yusuf so pe): "Iyen nitori ki oba le mo pe dajudaju emi ko janba re ni ikoko. Ati pe dajudaju Allahu ko nii fi imona sibi ete awon onijanba |
Emi ko si fora mi mo (nibi erokero); dajudaju emi kuku n pase erokero (fun eda) ni afi eni ti Oluwa mi ba ke. Dajudaju Oluwa mi ni Alaforijin, Asake-orun |
Oba so pe: “E mu (Yusuf) wa fun mi. Emi yoo se e ni eni esa lodo mi.” Nigba ti oba ba a soro tan, o so pe: “Lodo wa ni oni dajudaju iwo ni eni pataki, olufokantan.” |
قَالَ اجْعَلْنِي عَلَىٰ خَزَائِنِ الْأَرْضِ ۖ إِنِّي حَفِيظٌ عَلِيمٌ(55) (Yusuf) so pe: “Fi mi se alase awon oro ilu, dajudaju alamojuuto onimo ni mi.” |
Bayen ni A se fun Yusuf ni ipo ati ibugbe lori ile. O si n gbe ni ibi ti o ba fe. Awa n mu ike Wa ba enikeni ti A ba fe. A o si nii fi esan awon oluse-rere rare |
وَلَأَجْرُ الْآخِرَةِ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ(57) Dajudaju esan ti orun loore julo fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n beru (Allahu) |
وَجَاءَ إِخْوَةُ يُوسُفَ فَدَخَلُوا عَلَيْهِ فَعَرَفَهُمْ وَهُمْ لَهُ مُنكِرُونَ(58) Awon obakan (Anabi) Yusuf de, won si wole to o. O da won mo. Awon ko si mo on mo |
Nigba ti o si ba won di eru ounje won tan, o so pe: "E lo mu obakan yin wa lati odo baba yin. Se e ko ri i pe dajudaju mo n won kongo ni ekun rere ni? Emi si dara julo ninu awon olugbalejo |
فَإِن لَّمْ تَأْتُونِي بِهِ فَلَا كَيْلَ لَكُمْ عِندِي وَلَا تَقْرَبُونِ(60) Ti e o ba si mu un wa, ko si (eru ounje) wiwon fun yin lodo mi. Ki e si ma se sunmo mi |
قَالُوا سَنُرَاوِدُ عَنْهُ أَبَاهُ وَإِنَّا لَفَاعِلُونَ(61) Won so pe: “A maa jireebe fun un lodo baba re. Dajudaju awa maa se bee.” |
O si so fun awon omo odo re pe: “E fi owo-oja won sinu eru (ounje) won nitori ki won le mo nigba ti won ba pada de odo ara ile won (pe a ti da a pada fun won), won yo si le pada wa.” |
Nigba ti won pada de odo baba won, won so pe: “Baba wa, won ko lati won ounje fun wa. Nitori naa, je ki obakan wa ba wa lo nitori ki a le ri ounje won (wale). Dajudaju awa ni oluso fun un.” |
O so pe: “Se ki ng gba yin gbo lori re bi ko se bi mo se gba yin gbo ni isaaju lori omo-iya re? Nitori naa, Allahu loore julo ni Oluso. Oun si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu.” |
Nigba ti won tu eru ounje won, won ri owo-oja won ti won da pada fun won (ninu re). Won so pe: “Baba wa, ki ni a tun n fe? Owo-oja wa niyi ti won ti da pada fun wa. A o si tun fi wa ounje ra fun awon ebi wa. A o si daabo bo obakan wa. A si maa ri alekun eru ounje (ti) rakunmi kan le ru si i. Iwon ounje kekere si niyen (lodo oba).” |
O so pe: “Emi ko nii je ki o ba yin lo titi e maa fi se adehun fun mi ni (oruko) Allahu pe dajudaju e maa mu un pada wa ba mi afi ti (awon ota) ba ka yin mo.” Nigba ti won fun un ni adehun won tan, o so pe: “Allahu ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).” |
O tun so pe: “Eyin omo mi, e ma se gba enu ona eyo kan wole. E gba enu ona otooto wole. Emi ko le fi nnkan kan ro yin loro lodo Allahu. Ko si idajo (fun eni kan) afi fun Allahu. Oun ni mo gbarale. Oun si ni ki awon olugbarale gbarale.” |
Nigba ti won wo (inu ilu) ni awon aye ti baba won pa lase fun won, ko si ro won loro kan kan lodo Allahu bi ko se bukata kan ninu emi (Anabi) Ya‘ƙub ti o muse. Dajudaju onimo ni nipa ohun ti A fi mo on, sugbon opolopo awon eniyan ko mo |
Nigba ti won wole ti (Anabi) Yusuf, o mu omo-iya re mora sodo re. O so pe: “Dajudaju emi ni omo-iya re. Nitori naa, ma se banuje nipa ohun ti won n se nise.” |
Nigba ti o si ba won di eru won tan, o fi ife-imumi sinu eru omo-iya re. Leyin naa, olupepe kan kede pe: “Eyin ero-rakunmi, dajudaju eyin ni ole.” |
Won doju ko won, won so pe: “Ki l’e safeku?” |
قَالُوا نَفْقِدُ صُوَاعَ الْمَلِكِ وَلِمَن جَاءَ بِهِ حِمْلُ بَعِيرٍ وَأَنَا بِهِ زَعِيمٌ(72) Won so pe: “A o ri ife oba ni. Eni ti o ba si mu un wa yoo ri eru ounje rakunmi kan gba. Emi si ni oniduroo fun ebun naa.” |
قَالُوا تَاللَّهِ لَقَدْ عَلِمْتُم مَّا جِئْنَا لِنُفْسِدَ فِي الْأَرْضِ وَمَا كُنَّا سَارِقِينَ(73) Won so pe: “A fi Allahu bura, dajudaju e mo pe a ko wa lati sebaje lori ile. Ati pe awa ki i se ole.” |
Won so pe: “Ki ni esan (fun eni ti) o ji i, ti (o ba han pe) eyin je opuro?” |
قَالُوا جَزَاؤُهُ مَن وُجِدَ فِي رَحْلِهِ فَهُوَ جَزَاؤُهُ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي الظَّالِمِينَ(75) Won so pe: “Esan re; eni ti won ba ba a ninu eru re, oun naa ni esan re. Bayen ni awa naa se n san awon alabosi ni esan.” |
O si bere (ayewo) apo won siwaju apo omo-iya re. Leyin naa, o mu un jade lati inu apo omo-iya re. Bayen ni A se fun (Anabi) Yusuf ni ete da. Ko le fi ofin oba mu omo-iya re afi ti Allahu ba fe. A n sagbega fun enikeni ti A ba fe. Onimo wa loke gbogbo onimo |
Won so pe: “Ti o ba jale, dajudaju omo-iya re kan ti jale siwaju.” (Anabi) Yusuf si fi oro naa pamo sinu emi re, ko si fi han si won pe (ko ri bee). O (si) so pe: “Ipo tiyin l’o buru julo. Allahu l’O si nimo julo nipa ohun ti e n so.” |
Won so pe: "Iwo oba, dajudaju o ni baba arugbo agbalagba kan. Nitori naa, mu eni kan ninu wa dipo re. Dajudaju awa n ri iwo pe o wa ninu awon eni-rere |
O so pe: “Mo sadi Allahu pe ki a mu eni kan afi eni ti a ba eru wa lodo re. (Ti a ba mu elomiiran) dajudaju nigba naa alabosi ni wa.” |
Nigba ti won soreti nu nipa re, won te soro. Agba (ninu) won so pe: “Se e ko mo pe dajudaju baba yin ti gba adehun yin ti (e se ni oruko) Allahu. Ati pe siwaju (eyi, e ti se) aseeto nipa oro (Anabi) Yusuf. Nitori naa, emi ko nii fi ile (Misro) sile titi baba mi yoo fi yonda fun mi tabi (titi) Allahu yoo fi se idajo fun mi. O si loore julo ninu awon oludajo |
E pada sodo baba yin, ki e si so pe: “Baba wa, dajudaju omo re jale. A ko si le jerii (si kini kan) afi ohun ti a ba nimo (nipa) re. Awa ko si je oluso fun ohun ti o pamo (fun wa) |
Ki o si bi awon ara ilu ti a wa ninu re ati ero-rakunmi ti a jo dari de leere wo. Dajudaju olododo ma ni wa.” |
(Anabi Ya‘ƙub) so pe: “Rara o, emi yin lo se oran kan losoo fun yin. Nitori naa, suuru t’o rewa (loro mi kan bayii). O see se ki Allahu ba mi mu gbogbo won wa. Dajudaju Allahu, Oun ni Onimo, Ologbon.” |
O pa won ti, o si so pe: “Ibanuje n be fun mi lori Yusuf!” Oju re mejeeji si funfun wa (ko si riran mo); o si pa ibanuje mora |
قَالُوا تَاللَّهِ تَفْتَأُ تَذْكُرُ يُوسُفَ حَتَّىٰ تَكُونَ حَرَضًا أَوْ تَكُونَ مِنَ الْهَالِكِينَ(85) Won so pe: “A fi Allahu bura, iwo ko ye ranti Yusuf titi o maa fi di yannayanna tabi (titi) o maa fi di ara awon oku.” |
قَالَ إِنَّمَا أَشْكُو بَثِّي وَحُزْنِي إِلَى اللَّهِ وَأَعْلَمُ مِنَ اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ(86) O so pe: “Allahu ma ni emi n ro edun okan mi ati ibanuje mi fun. Mo si mo ohun ti e ko mo nipa Allahu |
Eyin omo mi, e lo wadii nipa Yusuf ati omo-iya re. E si ma se soreti nu ninu ike Allahu. Dajudaju ko si eni kan ti o maa soreti nu ninu ike Allahu afi ijo alaigbagbo.” |
Nigba ti won wole to Yusuf, won so pe: “Iwo oba, inira ti mu awa ati ara ile wa. A si mu owo kan ti ko yanju wa. Nitori naa, won kongo (ounje) naa kun fun wa, ki o si ta wa lore. Dajudaju Allahu yoo san awon olutore ni esan rere.” |
قَالَ هَلْ عَلِمْتُم مَّا فَعَلْتُم بِيُوسُفَ وَأَخِيهِ إِذْ أَنتُمْ جَاهِلُونَ(89) O so pe: “Nje e mo ohun ti e se fun Yusuf ati omo-iya re nigba ti eyin je alaimokan.” |
Won so pe: “Se dajudaju iwo ni Yusuf?” O so pe: “Emi ni Yusuf. Omo-iya mi si niyi. Dajudaju Allahu ti se idera fun wa. Dajudaju enikeni ti o ba beru (Allahu), ti o si se suuru, dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare.” |
قَالُوا تَاللَّهِ لَقَدْ آثَرَكَ اللَّهُ عَلَيْنَا وَإِن كُنَّا لَخَاطِئِينَ(91) Won so pe: “A fi Allahu bura! Dajudaju Allahu ti gbola fun o ju wa lo. Ati pe dajudaju awa ni alasise.” |
قَالَ لَا تَثْرِيبَ عَلَيْكُمُ الْيَوْمَ ۖ يَغْفِرُ اللَّهُ لَكُمْ ۖ وَهُوَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ(92) O so pe: "Ko si ibawi fun yin ni oni. Allahu yoo forijin yin. Oun si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu |
E mu ewu mi yii lo, ki e fi le iwaju baba mi, o maa pada di oluriran. Ki e si ko gbogbo ebi yin wa ba mi |
وَلَمَّا فَصَلَتِ الْعِيرُ قَالَ أَبُوهُمْ إِنِّي لَأَجِدُ رِيحَ يُوسُفَ ۖ لَوْلَا أَن تُفَنِّدُونِ(94) Nigba ti ero-rakunmi naa si pinya (kuro lodo Anabi Yusuf), baba won so pe: “Dajudaju emi n gbo oorun Yusuf ti e o ba nii so pe mo n jaran.” |
Won so pe: “A fi Allahu bura! Dajudaju iwo si wa ninu asise re ti atijo (nipa ife Yusuf).” |
Nigba ti oniroo-idunnu de, o ju (ewu naa) le e niwaju, o si riran pada. O so pe: “Nje ng ko so fun yin pe dajudaju emi mo ohun ti e ko mo nipa Allahu.” |
قَالُوا يَا أَبَانَا اسْتَغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا إِنَّا كُنَّا خَاطِئِينَ(97) Won so pe: “Baba wa, toro aforijin ese wa fun wa, dajudaju awa je alasise.” |
قَالَ سَوْفَ أَسْتَغْفِرُ لَكُمْ رَبِّي ۖ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ(98) O so pe: “Laipe mo maa toro aforijin fun yin lodo Oluwa mi. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun.” |
Nigba ti won wole to (Anabi) Yusuf, o ko awon obi re mejeeji mora sodo re, o si so pe: “E wo ilu Misro ni olufayabale – ti Allahu ba fe.-” |
O gbe awon obi re mejeeji sori ite. Won si doju bole fun un ni oluforikanle-kini. O so pe: “Baba mi, eyi ni itumo ala mi (ti mo la) siwaju. Dajudaju Oluwa mi ti so o di ododo. O si se daadaa fun mi nigba ti O mu mi jade kuro ninu ogba ewon. O tun mu yin wa (ba mi) lati inu oko leyin ti Esu ti ba aarin emi ati awon oba-kan mi je. Dajudaju Oluwa mi ni Alaaanu fun ohun ti O ba fe. Dajudaju Allahu, Oun ni Onimo, Ologbon |
Oluwa mi, dajudaju O ti fun mi ni ijoba. O tun fun mi ni imo itumo ala. Olupileda awon sanmo ati ile, Iwo ni Oluranlowo mi ni aye ati ni orun, pa mi sipo musulumi. Ki O si fi mi pelu awon eni rere.” |
Iyen wa ninu iro ikoko ti A fi imisi (re) ranse si o. Ati pe iwo ko si lodo won nigba ti won panu po lori oro won, ti won n dete |
Iwo ibaa soju kokoro (igbala won), opolopo eniyan ni ko nii gbagbo |
وَمَا تَسْأَلُهُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَالَمِينَ(104) Iwo ko si bi won leere owo-oya kan lori re. Ko si je kini kan bi ko se iranti fun gbogbo eda |
وَكَأَيِّن مِّنْ آيَةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ يَمُرُّونَ عَلَيْهَا وَهُمْ عَنْهَا مُعْرِضُونَ(105) Ati pe meloo meloo ninu awon ami ti n be ni sanmo ati ni ori ile ti won n re koja lori re, ti won si n gbunri kuro nibe |
وَمَا يُؤْمِنُ أَكْثَرُهُم بِاللَّهِ إِلَّا وَهُم مُّشْرِكُونَ(106) Opolopo won si ni ko nii gba Allahu gbo ni ododo afi ki won tun maa sebo |
Se won faya bale pe ohun ti n bo eda mole ninu iya Allahu ko le de ba awon ni tabi pe Akoko naa ko le ko le awon lori ni ojiji, ti won ko si nii fura |
So pe: “Eyi ni oju ona (esin) mi, emi ati awon t’o tele mi si n pepe si (esin) Allahu pelu imo amodaju. Mimo ni fun Allahu. Emi ko si si lara awon osebo.” |
A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si ninu awon ara ilu. Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Dajudaju Ile ikeyin loore julo fun awon t’o beru (Allahu). Se e o se laakaye ni |
(A ki i je awon eniyan niya) titi di igba ti awon Ojise ba t’o soreti nu (nipa igbagbo won), ti won si mo pe won ti pe awon ni opuro. Aranse Wa yo si de ba won. A si maa gba eni ti A ba fe la. Won ko le da iya Wa pada lori ijo elese |
Dajudaju ariwoye wa ninu itan won fun awon onilaakaye. (Al-Ƙur’an) ki i se oro kan ti won n hun, sugbon o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re, o n salaye gbogbo nnkan; o je imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo |
Yoruba diğer sureler:
En ünlü okuyucuların sesiyle Yusuf Suresi indirin:
Surah Yusuf mp3: yüksek kalitede dinlemek ve indirmek için okuyucuyu seçerek
Ahmed El Agamy
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Ali Al Hudhaifi
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Muhammad Jibril
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Nasser Al Qatami
Yasser Al Dosari
Bizim için dua et, teşekkürler