Surah At-Tur pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah At-Tur pdf Yorùbá — Gbà Surah At-Tur Itumọ. Surah At-Tur (Meccan) 49 Ẹsẹ.
Related
- Surah At-Tur ItumọYorùbá
- Surah At-Tur mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah At-Tur

ﮞﮟ
52:1
(Allahu bura pelu) apata Tur
ﮠﮡﮢ
52:2
(O tun bura pelu) Tira ti won ko sile
ﮣﮤﮥﮦ
52:3
sinu takada ti won te sile
ﮧﮨﮩ
52:4
(O tun bura pelu) Ile Abewo naa
ﮪﮫﮬ
52:5
(O tun bura pelu) aja ti won gbe soke (iyen, sanmo)
ﮭﮮﮯ
52:6
(O tun bura pelu) agbami odo ina
ﮰﮱﯓﯔﯕ
52:7
Dajudaju iya Oluwa re maa sele
ﯖﯗﯘﯙﯚ
52:8
Ko si oludena kan fun un
ﯛﯜﯝﯞﯟ
52:9
(O maa sele) ni ojo ti sanmo maa mi titi taara
ﯠﯡﯢﯣ
52:10
Awon apata si maa rin lo taara (bi eruku afedanu)
ﯤﯥﯦﯧ
52:11
Ni ojo yen, egbe ni fun awon olupe-ododo-niro
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
52:12
awon ti won wa ninu isokuso, ti won n sere
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
52:13
(Ranti) ojo ti won yoo ti won lo sinu ina Jahanamo ni itikuti
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
52:14
Eyi ni Ina naa ti e n pe niro
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
52:15
Se idan ni eyi ni tabi e o riran
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
52:16
E wo inu re lo. E fara da a tabi e o fara da a, bakan naa ni fun yin. Ohun ti e n se nise ni A oo fi san yin ni esan
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
52:17
Dajudaju awon oluberu (Allahu) maa wa ninu awon Ogba ati idera
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
52:18
Won yoo maa je igbadun pelu ohun ti Oluwa won fun won. Ati pe (Allahu) yoo so won ninu iya ina Jehim
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
52:19
E maa je, e maa mu ni gbedemuke nitori ohun ti e n se nise
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
52:20
Won yoo rogboku sori awon ibusun ti won to ni owoowo. A si maa fun won ni awon iyawo eleyinju ege
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
52:21
Ati pe awon t’o gbagbo ni ododo, ti awon aromodomo won tun tele won ninu igbagbo ododo, A maa da awon aromodomo won po mo won. A o si nii din kini kan ku ninu ise won. Eni kookan ni oniduuro fun ohun t’o se nise
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
52:22
A maa fun won ni alekun eso ati eran ti won nifee si
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
52:23
Won yo si maa gba ife oti mu laaarin ara won ninu Ogba Idera. Ko si oro isokuso ati iwa ese ninu Ogba Idera
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
52:24
Awon omo-odo won yo si maa lo bo laaarin won. (Won) da bi aluuulu afipamo
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
52:25
Apa kan won yoo doju ko apa kan, won yo si maa beere oro lowo ara won
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
52:26
Won yoo so pe: "Dajudaju teletele awa je olupaya laaarin awon eniyan wa
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
52:27
Sugbon Allahu saanu wa. O si la wa nibi iya Ina
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
52:28
Dajudaju awa maa n pe E teletele. Dajudaju Allahu, Oun ni Oloore, Asake-orun
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
52:29
Nitori naa, seranti. Iwo ki i se adabigba tabi were lori idera Oluwa re
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
52:30
Tabi won n wi pe: "Elewi kan ti a n reti iku re ni
ﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
52:31
So pe: "E maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
52:32
Tabi opolo won n pa won lase eyi ni? Tabi ijo alakoyo ni won ni
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
52:33
Tabi won n wi pe: "O da (al-Ƙur’an) hun funra re ni." Rara o, won ko gbagbo ni
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
52:34
Ki awon naa mu oro kan bi iru re wa ti won ba je olododo
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
52:35
Tabi won seda won lai si Aseda? Tabi awon ni won seda ara won ni
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
52:36
Tabi awon ni won seda awon sanmo ati ile? Rara o, won ko mamo daju ni
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
52:37
Tabi lodo won ni awon apoti oro Oluwa re wa? Tabi awon ni olubori
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
52:38
Tabi won ni akaba ti won n fi gboro (ninu sanmo ni)? Ki olugboro won mu eri ponnbele wa
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
52:39
Tabi awon omobinrin ni tiRe, awon omokunrin si ni tiyin
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
52:40
Tabi o n beere owo-oya kan lodo won, ni gbese fi wo won lorun
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
52:41
Tabi imo ikoko wa lodo won, ti won si n ko o sile
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
52:42
Tabi won n gbero ete kan ni? Nigba naa, awon t’o sai gbagbo, awon l’o maa f’ori ko ete
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
52:43
Tabi won ni olohun kan leyin Allahu ni? Mimo ni fun Allahu tayo nnkan ti won n fi sebo si I
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
52:44
Ti won ba si ri apa kan ninu sanmo t’o ya lule, won a wi pe: "Esujo regede ni (won ko nii gbagbo)
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
52:45
Nitori naa, fi won sile titi won yoo fi ba ojo won ti won maa pa won sinu re pade
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
52:46
Ojo ti ete won ko nii fi kini kan ro won loro. A o si nii ran won lowo
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
52:47
Ati pe dajudaju iya kan n be fun awon t’o sabosi yato si (iya orun) yen, sugbon opolopo won ni ko mo
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
52:48
Se suuru fun idajo Oluwa Re, dajudaju iwo wa ni ojuto Wa. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa re nigba ti o ba n dide naro (fun irun kiki)
ﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
52:49
Ati ni ale (nigba ti) awon irawo ba kuro nita tan, safomo fun Un
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







