PDF —
89 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Az-Zukhruf pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Az-Zukhruf pdf Yorùbá — Gbà Surah Az-Zukhruf Itumọ. Surah Az-Zukhruf (Meccan) 89 Ẹsẹ.

← Ash-ShuraSurah Az-Zukhruf Ad-Dukhan →


89 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮀﮁ
43:1 Ha mim
ﮂﮃﮄ
43:2 (Allahu) fi Tira t’o yanju oro eda bura
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
43:3 Dajudaju Awa so o ni al-Ƙur’an. (A si so o kale ni) ede Larubawa nitori ki e le se laakaye
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
43:4 Ati pe dajudaju ninu Tira Ipile t’o wa lodo Wa, al-Ƙur’an ga, o kun fun ogbon
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
43:5 Se ki A ka Tira Iranti (al-Ƙur’an) kuro nile fun yin, ki A maa wo yin niran nitori pe e je ijo alakoyo
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
43:6 Meloo meloo ninu awon Anabi ti A ti ran si awon eni akoko
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
43:7 Ko si Anabi kan ti o wa ba won ayafi ki won maa fi se yeye
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
43:8 Nitori naa, A ti pa awon t’o ni agbara ju awon (wonyi) re. Apejuwe (iparun) awon eni akoko si ti siwaju
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
43:9 Ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da awon sanmo ati ile?", dajudaju won a wi pe: "Eni t’o da won ni Alagbara, Onimo
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
43:10 Eni ti O se ile ni ite fun yin. O si fi awon oju ona sinu re fun yin nitori ki e le mona
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
43:11 Eni ti O n so omi kale lati sanmo niwon-niwon. O si n fi so oku ile di aye ile. Bayen naa ni won yoo se mu yin jade
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
43:12 Eni ti O seda gbogbo nnkan ni orisirisi. O si se nnkan ti e n gun fun yin lati ara awon oko oju-omi ati awon eran-osin
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
43:13 Nitori ki e le jokoo daadaa seyin re, leyin naa ki e le se iranti idera Oluwa yin nigba ti e ba jokoo daadaa tan sori re, ki e si so pe: "Mimo ni fun Eni ti O ro eyi fun wa, ki i se pe a je alagbara lori re
ﮀﮁﮂﮃﮄ
43:14 Ati pe dajudaju odo Oluwa wa ni awa yoo pada si
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
43:15 Won fi ipin kan ninu awon erusin (Allahu) ti si odo Re (ni ti omo bibi). Dajudaju eniyan ni alaimoore ponnbele
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
43:16 Tabi (eyin n wi pe): "O mu ninu nnkan ti O da ni omobinrin (funra Re). O si fi awon omokunrin sa eyin lesa
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
43:17 Nigba ti won ba fun eni kan ninu won ni iro idunnu ohun ti o fi se apeere fun Ajoke-aye (pe onitoun bi omobinrin), oju re maa sokunkun wa. O si maa kun fun ibanuje
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
43:18 Se eni ti won n to ninu oso (ti o n to oso mora), ti ko si le bo si gbangba nibi ija (ni e n pe ni omo Ajoke-aye)
ﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
43:19 Awon molaika, awon t’o je erusin Ajoke-aye, won tun so won di omobinrin! Se won foju ri iseda won ni? Won maa se akosile ohun ti won foju ri. Won si maa bi won leere (nipa re)
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
43:20 Won tun wi pe: "Ti Ajoke-aye ba fe, awa iba ti josin fun won." Ko si imo kan fun won nipa iyen. Won ko si je kini kan bi ko se pe won n paro
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
43:21 Tabi A ti fun won ni Tira kan siwaju al-Ƙur’an, ti won n lo ni eri
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
43:22 Rara. Won wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olumona lori oripa won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
43:23 Bakan naa, Awa ko ran olukilo kan si ilu kan siwaju re, ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olutele won lori oripa won
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
43:24 (Olukilo) si so pe: "Nje emi ko ti mu wa fun yin ohun ti o je imona julo si ohun ti e ba awon baba yin lori re?" Won wi pe: "Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
43:25 Nitori naa, A gbesan lara won. Wo bi ikangun awon olupe-ododo-niro ti ri
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
43:26 (Ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Dajudaju emi yowo yose kuro ninu ohun ti e n josin fun
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
43:27 Afi Eni ti O seda mi. Dajudaju Oun l’O maa fi ona taara mo mi
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
43:28 Allahu si se e ni oro kan t’o maa wa titi laelae laaarin awon aromodomo re nitori ki won le seri pada (sibi ododo)
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
43:29 Sugbon Mo fun awon wonyi ati awon baba won ni igbadun aye titi ododo ati Ojise ponnbele fi de ba won
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
43:30 Nigba ti ododo de ba won, won wi pe: "Idan ni eyi; dajudaju awa ko si nii gba a gbo
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
43:31 Won tun wi pe: "Ki ni ko je ki Won so al-Ƙur’an yii kale fun okunrin pataki kan ninu awon ilu mejeeji
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
43:32 Se awon ni won maa pin ike Oluwa re ni? Awa l’A pin nnkan isemi won fun won ninu igbesi aye. A si fi awon ipo giga gbe apa kan won ga ju apa kan lo nitori ki apa kan won le maa sise fun apa kan. Ike Oluwa re si loore julo si ohun ti won n ko jo
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇ
43:33 Ati pe ti ki i ba se pe awon eniyan maa je ijo kan soso (lori aigbagbo ni), A iba se awon orule ati awon akaba ti won yoo fi maa gunke ninu ile ni fadaka fun eni t’o n sai gbagbo ninu Ajoke-aye
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
43:34 (A iba tun se) awon enu ona ile won ati awon ibusun ti won yoo maa rogboku le lori (ni fadaka)
ﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
43:35 ati goolu. Gbogbo nnkan wonyi ko je nnkan kan bi ko se igbadun isemi aye lasan. (Ogba Idera) Orun si wa ni odo Oluwa re fun awon oluberu (Allahu)
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
43:36 Enikeni ti o ba gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye, A maa yan esu kan fun un. Oun si ni alabaarin re
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
43:37 Dajudaju awon esu naa yoo maa seri won kuro loju ona (esin Allahu). Won yo si maa lero pe dajudaju awon ni olumona
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
43:38 Titi di igba ti o fi maa wa ba Wa, o si maa wi pe: "Haa! Ki o si je pe (itakete bi) itakete ibuyo-oorun ati ibuwo re si wa laaarin emi ati iwo (esu alabaarin yii, iba dara); alabaarin buruku si ni
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
43:39 (Abamo yin) ko nii se yin ni anfaani ni Oni nigba ti e ti sabosi. (Ati pe) dajudaju eyin (ati orisa yin) ni akegbe ninu iya
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
43:40 Se iwo l’o maa fun awon aditi ni oro gbo tabi o maa fun awon afoju ni imona ati eni ti o wa ninu isina ponnbele
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
43:41 Nitori naa, o see se ki A ti mu o kuro (lori ile aye siwaju asiko iya won), dajudaju Awa yoo gbesan (iya) lara won
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
43:42 Tabi ki A fi ohun ti A se ni ileri fun won han o, dajudaju Awa je Alagbara lori won
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
43:43 Nitori naa, di ohun ti A fi ranse si o mu sinsin. Dajudaju iwo wa loju ona taara (’Islam)
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
43:44 Dajudaju al-Ƙur’an ni tira iranti fun iwo ati ijo re. Laipe Won maa bi yin leere (nipa re)
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
43:45 Beere wo lowo awon ti A ran nise siwaju re ninu awon Ojise Wa (pe): "Nje A so awon kan di olohun ti won yoo maa josin fun leyin Ajoke-aye bi
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
43:46 A kuku fi awon ami Wa ran (Anabi) Musa nise si Fir‘aon ati awon ijoye re. O si so pe: "Dajudaju emi ni Ojise Oluwa gbogbo eda
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
43:47 Sugbon nigba ti o mu awon ami Wa wa ba won, nse ni won n fi awon ami naa rerin-in nigba naa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
43:48 A o si nii fi ami kan han won ayafi ki o tobi ju iru re (t’o siwaju). A si fi iya je won nitori ki won le seri pada (sibi ododo)
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
43:49 Won si wi pe: "Iwo opidan, pe Oluwa re fun wa nitori adehun ti O se pelu re. Dajudaju awa maa tele imona Re
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
43:50 Sugbon nigba ti A mu iya kuro fun won, nigba naa ni won tun n ye adehun
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
43:51 Fir‘aon si pepe laaarin awon eniyan re, o wi pe: "Eyin eniyan mi, se temi ko ni ijoba Misro ati awon odo wonyi t’o n san nisale (odo) mi? Se e o riran ni
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
43:52 Tabi se emi ko loore julo si eyi ti o je ole yepere, ti o fee ma le da oro so yanju
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
43:53 Ki ni ko je ki Won fun un ni awon egba-owo goolu tabi (ki ni ko je ki) awon molaika wa pelu re, ki won je alabaarin (ti won yoo maa jerii re)
ﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
43:54 Nitori naa, o so awon eniyan re dope. Won si tele e. Dajudaju won je ijo obileje
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
43:55 Nigba ti won wa ibinu Wa, A gba esan (iya) lara won. Nitori naa, A te gbogbo won ri (sinu agbami odo)
ﮯﮰﮱﯓﯔ
43:56 A si se won ni ijo asiwaju (ninu iparun) ati apeere (feyikogbon) fun awon eni ikeyin
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
43:57 Nigba ti awon osebo fi omo Moryam se apeere (fun orisa won), nigba naa ni awon eniyan re ba n fi (apeere naa) rerin-in
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
43:58 Won si wi pe: "Se awon orisa wa l’o loore julo ni tabi oun? Won ko wule fi sapeere fun o bi ko se (fun) atako. Ani se, ijo oniyanjija ni won
ﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
43:59 Ki ni oun bi ko se erusin kan ti A se idera fun. A si se e ni apeere rere fun awon omo ’Isro’il
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
43:60 Ti o ba je pe A ba fe, A iba maa fi awon molaika ropo yin lori ile
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜ
43:61 Dajudaju oun ni imo (tabi ami fun isunmo) Akoko naa. Nitori naa, e o gbodo seyemeji nipa re. Ki e si tele mi. Eyi ni ona taara
ﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
43:62 E ma se je ki Esu se yin lori; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
43:63 Nigba ti (Anabi) ‘Isa de pelu awon eri t’o yanju, o so pe: "Dajudaju mo de wa ba yin pelu ijinle ogbon. (Mo si de) nitori ki ng le se alaye apa kan eyi ti e n yapa enu nipa re fun yin. Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
43:64 Dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
43:65 Awon ijo (re) si yapa (esin ’Islam) laaarin ara won. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sabosi ni ojo iya eleta-elero
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛ
43:66 Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa; ti o maa de ba won ni ojiji; won ko si nii fura
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
43:67 Awon ore ayo ni ojo yen, apa kan won yoo je ota fun apa kan ayafi awon oluberu (Allahu)
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
43:68 Eyin erusin Mi, ko si iberu fun yin ni oni. Eyin ko si nii banuje
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
43:69 (Awon ni) awon t’o gbagbo ninu awon ayah Wa, ti won si je musulumi (olujuwo-juse sile fun Allahu)
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
43:70 E wo inu Ogba Idera, eyin ati awon iyawo yin; ki e maa dunnu
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
43:71 Won yoo maa gbe awon awo goolu ati awon ife imumi kaa kiri odo won. Ohun ti emi n fe ati (ohun ti) oju yoo maa dunnu si wa ninu re. Olusegbere si ni yin ninu re
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
43:72 Iyen ni Ogba Idera ti A jogun re fun yin nitori ohun ti e n se nise
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
43:73 Eso pupo wa fun yin ninu re. Eyin yo si maa je ninu re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
43:74 Dajudaju awon elese ni olusegbere ninu iya ina Jahanamo
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
43:75 A o nii gbe e fuye fun won. Won yo si soreti nu ninu Ina
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
43:76 A o sabosi si won, sugbon awon ni won je alabosi
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
43:77 Won yoo pe (molaika kan) pe: "Molik (eso Ina), je ki Oluwa re pa wa raurau." (Molik) yoo so pe: "Dajudaju eyin yoo maa gbe inu re ni
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
43:78 Dajudaju A ti mu ododo wa ba yin, sugbon opolopo yin korira ododo
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
43:79 Tabi awon (alaigbagbo) ti pinnu oro kan ni? Dajudaju Awa naa n pinnu oro
ﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
43:80 Tabi won n lero pe Awa ko gbo oro asiri won ati oro ikoko won? Rara (A n gbo); awon Ojise Wa wa ni odo won, ti won n se akosile (oro won)
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
43:81 So pe: "Ko si omo kan fun Ajoke aye. Nitori naa, emi ni eni akoko ninu awon olujosin (fun Allahu ni asiko temi)
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
43:82 Mimo ni fun Oluwa awon sanmo ati ile, Oluwa Ite-ola tayo iro ti won n pa (mo On)
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
43:83 Nitori naa, fi won sile ki won maa so isokuso (won), ki won si maa sere won lo titi won yoo fi pade ojo won, ti A n se ni adehun fun won
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
43:84 (Allahu) Oun ni Olohun Eni ti ijosin to si ninu sanmo. Oun naa si ni Olohun Eni ti ijosin to si lori ile. Oun ni Ologbon, Onimo
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
43:85 Ibukun ni fun Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji. Odo Re si ni imo Akoko naa wa. Odo Re si ni won maa da yin pada si
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
43:86 Awon ti won n pe leyin Re, won ko kapa isipe ayafi eni ti o ba jerii si ododo (kalmotus-sahaadah), ti won si nimo (re)
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
43:87 Ati pe ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da won?", dajudaju won a wi pe: "Allahu ni." Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
43:88 Oro (ti Anabi n so fun Allahu ni pe): "Oluwa Mi, dajudaju awon wonyi ni ijo ti ko gbagbo.”
ﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
43:89 Nitori naa, samoju kuro fun won, ki o si so pe: "Alaafia!" Laipe won maa mo

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers