Surah Nuh pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Nuh pdf Yorùbá — Gbà Surah Nuh Itumọ. Surah Nuh (Meccan) 28 Ẹsẹ.
Related
- Surah Nuh ItumọYorùbá
- Surah Nuh mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Nuh

ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
71:1
Dajudaju Awa ran (Anabi) Nuh nise si ijo re pe: "Sekilo fun ijo re siwaju ki iya eleta-elero to de ba won
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
71:2
O so pe: "Eyin ijo mi, dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin
ﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
71:3
pe ki e josin fun Allahu, ki e beru Re, ki e si tele mi
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨ
71:4
(Allahu) maa saforijin awon ese yin fun yin. O si maa lo yin lara titi di gbedeke akoko kan. Dajudaju akoko (iku ti) Allahu (ko mo eda), nigba ti o ba de, won ko nii sun un siwaju ti o ba je pe e mo
ﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
71:5
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi pe ijo mi ni oru ati ni osan
ﮱﯓﯔﯕﯖﯗ
71:6
Ipe mi ko si se alekun kan fun won ayafi sisa seyin (fun ododo)
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
71:7
Ati pe igbakigba ti mo ba pe won pe ki O le forijin won, won n fi omonika won di eti won, won n yiso won bori, won n taku (sori ese), won si n segberaga gan-an
ﯧﯨﯩﯪﯫ
71:8
Leyin naa, dajudaju emi pe won pelu ohun oke
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
71:9
Leyin naa, dajudaju emi kede fun won, mo si tun pe won ni ida konko
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
71:10
Mo si so pe, e toro aforijin ni odo Oluwa yin, dajudaju O n je Alaforijin
ﭑﭒﭓﭔﭕ
71:11
O maa rojo fun yin ni ojo pupo
ﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟ
71:12
O maa fi awon dukia ati awon omokunrin ran yin lowo. O maa se awon ogba oko fun yin. O si maa se awon odo fun yin
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
71:13
Ki lo mu yin ti e ko paya titobi Allahu
ﭧﭨﭩﭪ
71:14
O si kuku seda yin lati irisi kan si omiran (ninu oyun)
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
71:15
Se e o ri bi Allahu se da awon sanmo meje ni ipele ipele ni
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
71:16
O si se osupa ni imole sinu won. O tun se oorun ni atupa
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
71:17
Allahu mu yin jade lati ara erupe ile
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
71:18
Leyin naa, O maa da yin pada sinu re. O si maa mu yin jade taara
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍ
71:19
Allahu se ile fun yin ni ite
ﮎﮏﮐﮑﮒ
71:20
nitori ki e le to awon oju ona fife gbegede lori re
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
71:21
(Anabi) Nuh so pe: "Oluwa mi, dajudaju won yapa mi. Won si tele eni ti dukia re ati omo re ko se alekun kan fun bi ko se ofo
ﮡﮢﮣﮤ
71:22
Won si dete ni ete t’o tobi
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
71:23
Won si wi pe: "E ma se fi awon orisa yin sile. E ma se fi orisa Wadd, Suwa‘u, Yeguth, Ye‘uƙ ati Nasr sile
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
71:24
Dajudaju won ti ko opolopo sina. (Oluwa mi) ma se je ki awon alabosi lekun ni kini kan bi ko se isina
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
71:25
Nitori ese won, won te won ri sinu omi. Won si maa fi won sinu Ina. Won ko si nii ri awon alaranse fun won leyin Allahu
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
71:26
(Anabi) Nuh tun so pe: "Oluwa mi, ma se fi eni kan kan ninu awon alaigbagbo sile lori ile
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
71:27
Dajudaju ti Iwo ba fi won sile, won yoo ko isina ba awon eru Re. Won ko si nii bi omo kan afi eni buruku, alaigbagbo
ﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑ
71:28
Oluwa mi forijin emi, awon obi mi mejeeji ati eni t’o ba wo inu ile mi (ti o je) onigbagbo ododo ati awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin. Ma si salekun kan fun awon alabosi afi iparun
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







