PDF —
56 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Muddaththir pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Muddaththir pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Muddaththir Itumọ. Surah Al-Muddaththir (Meccan) 56 Ẹsẹ.

← Al-MuzzammilSurah Al-Muddaththir Al-Qiyamah →


56 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮪﮫﮬ
74:1 Iwo oludasobora
ﮭﮮﮯ
74:2 Dide ki o sekilo
ﮰﮱﯓ
74:3 Oluwa re si ni ki o gbe titobi fun
ﯔﯕﯖ
74:4 Aso re ni ki o fo mo
ﯗﯘﯙ
74:5 Orisa ni ki o jinna si
ﯚﯛﯜﯝ
74:6 Ma se tore nitori ki o le ri pupo gba
ﯞﯟﯠ
74:7 Oluwa re ni ki o se suuru fun
ﯡﯢﯣﯤﯥ
74:8 Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde
ﯦﯧﯨﯩﯪ
74:9 iyen, ni ojo yen, ni ojo inira
ﯫﯬﯭﯮﯯ
74:10 ti ko nii rorun fun awon alaigbagbo
ﯰﯱﯲﯳﯴ
74:11 Fi Mi da eni ti Mo da ni oun nikan
ﯵﯶﯷﯸﯹ
74:12 Mo si fun un ni opolopo dukia
ﯺﯻﯼ
74:13 ati awon omokunrin t’o n be pelu re
ﯽﯾﯿﰀ
74:14 Mo si se aye nirorun fun un gan-an
ﰁﰂﰃﰄﰅ
74:15 Leyin naa, o tun n jerankan pe ki Ng se alekun
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
74:16 Rara o! Dajudaju o je alatako si awon ayah Wa
ﰍﰎﰏ
74:17 Emi yoo la iya ponkeponke bo o lorun (ninu Ina)
ﰐﰑﰒﰓ
74:18 Dajudaju o ronu (lodi nipa al-Ƙur’an). O si pinnu (oro kan ninu emi re)
ﭑﭒﭓﭔ
74:19 Won si sebi le e nipa bi o se pinnu
ﭕﭖﭗﭘﭙ
74:20 Leyin naa, Won tun sebi le e nipa bi o se pinnu
ﭚﭛﭜ
74:21 Leyin naa, o wo sun
ﭝﭞﭟﭠ
74:22 Leyin naa, o faju ro, o si diju magbari
ﭡﭢﭣﭤ
74:23 Leyin naa, o peyin da, o si segberaga
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
74:24 O si wi pe: "Ki ni eyi bi ko se idan atowodowo
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
74:25 Ki ni eyi bi ko se oro abara
ﭲﭳﭴ
74:26 Emi yoo fi sinu ina Saƙor
ﭵﭶﭷﭸﭹ
74:27 Ki l’o mu o mo ohun t’o n je ina Saƙor
ﭺﭻﭼﭽﭾ
74:28 (Saƙor) ko nii se e ku, ko si nii pa a ti
ﭿﮀﮁ
74:29 O maa jo awo ara di dudu
ﮂﮃﮄﮅ
74:30 (Awon molaika) mokandinlogun ni eso re
ﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
74:31 Awa ko se eni kan ni eso Ina afi awon molaika. Awa ko si se onka won (bee) bi ko se (nitori ki o le je) adanwo fun awon t’o sai gbagbo, ati nitori ki awon ti A fun ni Tira le ni amodaju ati nitori ki awon ti won gbagbo ni ododo le lekun ni igbagbo ododo. (O ri bee) nitori ki awon ti A fun ni Tira ati awon onigbagbo ododo ma baa seyemeji ati nitori ki awon ti arun wa ninu okan won ati awon alaigbagbo le wi pe: "Ki ni Allahu gba lero pelu apejuwe yii?" Bayen ni Allahu se n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Ko si si eni ti o mo awon omo ogun Oluwa re afi Oun naa. (Ina Saƙor) ko si je kini kan bi ko se iranti fun abara
ﯥﯦﯧ
74:32 E gbo! Allahu bura pelu osupa
ﯨﯩﯪﯫ
74:33 O tun bura pelu ale nigba ti o ba lo
ﯬﯭﯮﯯ
74:34 O tun bura pelu owuro nigba ti ojumo ba mo
ﯰﯱﯲﯳ
74:35 Dajudaju (ina Saƙor) ni okan ninu (awon adanwo) t’o tobi
ﯴﯵﯶ
74:36 (O je) ikilo fun abara
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
74:37 Fun eni ti o ba fe ninu yin lati te siwaju tabi lati fa seyin
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
74:38 Emi kookan ni oniduuro fun ohun t’o se nise
ﰅﰆﰇﰈ
74:39 Ayafi awon ero owo otun
ﰉﰊﰋﰌ
74:40 Won yoo maa bira won leere oro ninu awon Ogba Idera
ﰍﰎﰏ
74:41 nipa awon elese pe
ﰐﰑﰒﰓﰔ
74:42 Ki ni o mu yin wo inu ina Saƙor
ﰕﰖﰗﰘﰙﰚ
74:43 Won yoo wi pe: "Awa ko si ninu awon olukirun ni
ﰛﰜﰝﰞﰟ
74:44 Awa ko si si ninu awon t’o n bo awon mekunnu
ﰠﰡﰢﰣﰤ
74:45 Awa si maa n so isokuso pelu awon onisokuso
ﰥﰦﰧﰨﰩ
74:46 Ati pe awa maa n pe Ojo esan niro
ﰪﰫﰬﰭ
74:47 titi iku fi de ba wa
ﭑﭒﭓﭔﭕ
74:48 Ipe awon olusipe ko si nii se won ni anfaani
ﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
74:49 Ki lo mu won na ti won n gbunri kuro nibi iranti
ﭜﭝﭞﭟ
74:50 bi eni pe awon ni ketekete t’o n sa lo
ﭠﭡﭢﭣ
74:51 t’o sa fun kinihun
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
74:52 Rara, nse ni enikookan ninu won n fe ki A fun oun naa ni Tira ti o maa see te han awon eniyan (bii ti al-Ƙur’an)
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
74:53 Rara. Won ko paya orun ni
ﭵﭶﭷﭸ
74:54 E gbo! Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti
ﭹﭺﭻﭼ
74:55 Nitori naa, eni ti o ba fe ko ranti re
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
74:56 Won ko si nii ranti (al-Ƙur’an) afi ti Allahu ba fe. (Allahu) Oun l’a gbodo beru. Oun l’o si laforijin

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers