Surah Al-Qiyamah pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Al-Qiyamah pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Qiyamah Itumọ. Surah Al-Qiyamah (Meccan) 40 Ẹsẹ.
Related
More Surah PDF
Surah Al-Qiyamah

ﮊﮋﮌﮍﮎ
75:1
Emi (Allahu) n bura pelu Ojo Ajinde
ﮏﮐﮑﮒﮓ
75:2
Mo tun n bura pelu emi t’o maa dara re lebi
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
75:3
Se eniyan lero pe A o nii ko awon eegun re jo ni
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
75:4
Rara o. A lagbara lati to eegun omonika re dogba
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
75:5
Sugbon eniyan gbero lati pe (Ojo Ajinde) t’o n be niwaju re niro
ﮧﮨﮩﮪﮫ
75:6
O n beere pe: "Igba wo ni Ojo Ajinde
ﮬﮭﮮﮯ
75:7
Nigba ti oju ba ko mona
ﮰﮱﯓ
75:8
ati (nigba) ti osupa ba wookun
ﯔﯕﯖﯗ
75:9
ati (nigba) ti A ba pa oorun ati osupa po mora won
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
75:10
eniyan yoo wi ni ojo yen pe: "Nibo ni ibusasi wa
ﯞﯟﯠﯡ
75:11
Rara, ko si ibusasi
ﯢﯣﯤﯥﯦ
75:12
Odo Oluwa re ni ibuduro ni ojo yen
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭ
75:13
Won maa fun eniyan ni iro ni ojo yen nipa ohun t’o ti siwaju (ninu ise re) ati ohun t’o fi keyin (ninu oripa ise re)
ﯮﯯﯰﯱﯲﯳ
75:14
Sebi eniyan da ara re mo
ﯴﯵﯶﯷ
75:15
ibaa mu awon awawi re wa
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
75:16
Ma se gbe ahon re si imisi lati kanju ke e
ﯿﰀﰁﰂﰃ
75:17
Dajudaju Awa l’A maa se ikojo re (sinu okan re) ati kike re
ﰄﰅﰆﰇﰈ
75:18
Nigba ti A ba n ke e (fun o), ki o si maa tele kike re
ﰉﰊﰋﰌﰍ
75:19
Leyin naa, dajudaju Awa l’A maa se alaye re fun o
ﭑﭒﭓﭔﭕ
75:20
E gbo! Nse l’e nifee aye
ﭖﭗﭘ
75:21
E si n pa orun ti
ﭙﭚﭛﭜ
75:22
Awon oju kan ni ojo yen yoo tutu (fun idunnu)
ﭝﭞﭟﭠ
75:23
Oluwa won ni won yoo maa wo
ﭡﭢﭣﭤ
75:24
Awon oju kan ni ojo yen si maa baje
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
75:25
(Oju naa) yoo mo daju pe Won maa fi aburu kan ohun
ﭫﭬﭭﭮﭯ
75:26
E gbo! Nigba ti emi ba de gogongo
ﭰﭱﭲﭳﭴ
75:27
A si maa so pe: "Nje olofo pipe kan wa bi (ti o maa gba a sile lowo iku)
ﭵﭶﭷﭸ
75:28
O si maa da a loju pe dajudaju ipinya aye ti de
ﭹﭺﭻﭼ
75:29
Ojugun yo si lomo ojugun
ﭽﭾﭿﮀﮁ
75:30
Odo Oluwa re si ni wiwa eda lo ni ojo yen
ﮂﮃﮄﮅﮆ
75:31
Ko kuku gba ododo gbo, ko si kirun
ﮇﮈﮉﮊ
75:32
Sugbon o pe ododo niro. O si keyin si i
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
75:33
Leyin naa, o lo si odo awon eniyan re, o si n se faari
ﮑﮒﮓﮔ
75:34
Egbe ni fun o, egbe ni se
ﮕﮖﮗﮘﮙ
75:35
Leyin naa, egbe ni fun o, egbe si se
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
75:36
Se eniyan lero pe A maa fi oun sile lasan ni
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
75:37
Se ko ti je ato moni ti won da jade sinu apoluke ni
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
75:38
Leyin naa, o di eje didi. (Allahu) si seda (re). O si se e t’o dogba jale leeyan
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
75:39
(Allahu) si se iran meji jade lati inu re, ako ati abo
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
75:40
Nje Eni ti O se iyen ko nii ni agbara lati ji awon oku dide bi
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







