Surah Al-Muddaththir ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Muddaththir pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (56 Ẹsẹ — مكية). Al-Muddaththir Gbọ, Al-Muddaththir Itumọ, Al-Muddaththir mp3, Al-Muddaththir pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Muddaththir

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
يَا أَيُّهَا الْمُدَّثِّرُ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Iwo oludasobora
قُمْ فَأَنذِرْ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Dide ki o sekilo
وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Oluwa re si ni ki o gbe titobi fun
وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Aso re ni ki o fo mo
وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Orisa ni ki o jinna si
وَلَا تَمْنُن تَسْتَكْثِرُ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Ma se tore nitori ki o le ri pupo gba
وَلِرَبِّكَ فَاصْبِرْ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Oluwa re ni ki o se suuru fun
فَإِذَا نُقِرَ فِي النَّاقُورِ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde
فَذَٰلِكَ يَوْمَئِذٍ يَوْمٌ عَسِيرٌ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
iyen, ni ojo yen, ni ojo inira
عَلَى الْكَافِرِينَ غَيْرُ يَسِيرٍ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
ti ko nii rorun fun awon alaigbagbo
ذَرْنِي وَمَنْ خَلَقْتُ وَحِيدًا ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Fi Mi da eni ti Mo da ni oun nikan
وَجَعَلْتُ لَهُ مَالًا مَّمْدُودًا ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Mo si fun un ni opolopo dukia
وَبَنِينَ شُهُودًا ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
ati awon omokunrin t’o n be pelu re
وَمَهَّدتُّ لَهُ تَمْهِيدًا ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Mo si se aye nirorun fun un gan-an
ثُمَّ يَطْمَعُ أَنْ أَزِيدَ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Leyin naa, o tun n jerankan pe ki Ng se alekun
كَلَّا ۖ إِنَّهُ كَانَ لِآيَاتِنَا عَنِيدًا ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Rara o! Dajudaju o je alatako si awon ayah Wa
سَأُرْهِقُهُ صَعُودًا ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Emi yoo la iya ponkeponke bo o lorun (ninu Ina)
إِنَّهُ فَكَّرَ وَقَدَّرَ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Dajudaju o ronu (lodi nipa al-Ƙur’an). O si pinnu (oro kan ninu emi re)
فَقُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Won si sebi le e nipa bi o se pinnu
ثُمَّ قُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
Leyin naa, Won tun sebi le e nipa bi o se pinnu
ثُمَّ نَظَرَ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Leyin naa, o wo sun
ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Leyin naa, o faju ro, o si diju magbari
ثُمَّ أَدْبَرَ وَاسْتَكْبَرَ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
Leyin naa, o peyin da, o si segberaga
فَقَالَ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ يُؤْثَرُ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
O si wi pe: "Ki ni eyi bi ko se idan atowodowo
إِنْ هَٰذَا إِلَّا قَوْلُ الْبَشَرِ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Ki ni eyi bi ko se oro abara
سَأُصْلِيهِ سَقَرَ ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Emi yoo fi sinu ina Saƙor
وَمَا أَدْرَاكَ مَا سَقَرُ ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
Ki l’o mu o mo ohun t’o n je ina Saƙor
لَا تُبْقِي وَلَا تَذَرُ ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
(Saƙor) ko nii se e ku, ko si nii pa a ti
لَوَّاحَةٌ لِّلْبَشَرِ ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
O maa jo awo ara di dudu
عَلَيْهَا تِسْعَةَ عَشَرَ ۝٣٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 30
(Awon molaika) mokandinlogun ni eso re
وَمَا جَعَلْنَا أَصْحَابَ النَّارِ إِلَّا مَلَائِكَةً ۙ وَمَا جَعَلْنَا عِدَّتَهُمْ إِلَّا فِتْنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُوا لِيَسْتَيْقِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَيَزْدَادَ الَّذِينَ آمَنُوا إِيمَانًا ۙ وَلَا يَرْتَابَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَالْمُؤْمِنُونَ ۙ وَلِيَقُولَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَالْكَافِرُونَ مَاذَا أَرَادَ اللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللَّهُ مَن يَشَاءُ وَيَهْدِي مَن يَشَاءُ ۚ وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ ۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْبَشَرِ ۝٣١
📖 Itumọ Ẹsẹ 31
Awa ko se eni kan ni eso Ina afi awon molaika. Awa ko si se onka won (bee) bi ko se (nitori ki o le je) adanwo fun awon t’o sai gbagbo, ati nitori ki awon ti A fun ni Tira le ni amodaju ati nitori ki awon ti won gbagbo ni ododo le lekun ni igbagbo ododo. (O ri bee) nitori ki awon ti A fun ni Tira ati awon onigbagbo ododo ma baa seyemeji ati nitori ki awon ti arun wa ninu okan won ati awon alaigbagbo le wi pe: "Ki ni Allahu gba lero pelu apejuwe yii?" Bayen ni Allahu se n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Ko si si eni ti o mo awon omo ogun Oluwa re afi Oun naa. (Ina Saƙor) ko si je kini kan bi ko se iranti fun abara
كَلَّا وَالْقَمَرِ ۝٣٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 32
E gbo! Allahu bura pelu osupa
وَاللَّيْلِ إِذْ أَدْبَرَ ۝٣٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 33
O tun bura pelu ale nigba ti o ba lo
وَالصُّبْحِ إِذَا أَسْفَرَ ۝٣٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 34
O tun bura pelu owuro nigba ti ojumo ba mo
إِنَّهَا لَإِحْدَى الْكُبَرِ ۝٣٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 35
Dajudaju (ina Saƙor) ni okan ninu (awon adanwo) t’o tobi
نَذِيرًا لِّلْبَشَرِ ۝٣٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 36
(O je) ikilo fun abara
لِمَن شَاءَ مِنكُمْ أَن يَتَقَدَّمَ أَوْ يَتَأَخَّرَ ۝٣٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 37
Fun eni ti o ba fe ninu yin lati te siwaju tabi lati fa seyin
كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ رَهِينَةٌ ۝٣٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 38
Emi kookan ni oniduuro fun ohun t’o se nise
إِلَّا أَصْحَابَ الْيَمِينِ ۝٣٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 39
Ayafi awon ero owo otun
فِي جَنَّاتٍ يَتَسَاءَلُونَ ۝٤٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 40
Won yoo maa bira won leere oro ninu awon Ogba Idera
عَنِ الْمُجْرِمِينَ ۝٤١
📖 Itumọ Ẹsẹ 41
nipa awon elese pe
مَا سَلَكَكُمْ فِي سَقَرَ ۝٤٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 42
Ki ni o mu yin wo inu ina Saƙor
قَالُوا لَمْ نَكُ مِنَ الْمُصَلِّينَ ۝٤٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 43
Won yoo wi pe: "Awa ko si ninu awon olukirun ni
وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ الْمِسْكِينَ ۝٤٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 44
Awa ko si si ninu awon t’o n bo awon mekunnu
وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ الْخَائِضِينَ ۝٤٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 45
Awa si maa n so isokuso pelu awon onisokuso
وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ الدِّينِ ۝٤٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 46
Ati pe awa maa n pe Ojo esan niro
حَتَّىٰ أَتَانَا الْيَقِينُ ۝٤٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 47
titi iku fi de ba wa
فَمَا تَنفَعُهُمْ شَفَاعَةُ الشَّافِعِينَ ۝٤٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 48
Ipe awon olusipe ko si nii se won ni anfaani
فَمَا لَهُمْ عَنِ التَّذْكِرَةِ مُعْرِضِينَ ۝٤٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 49
Ki lo mu won na ti won n gbunri kuro nibi iranti
كَأَنَّهُمْ حُمُرٌ مُّسْتَنفِرَةٌ ۝٥٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 50
bi eni pe awon ni ketekete t’o n sa lo
فَرَّتْ مِن قَسْوَرَةٍ ۝٥١
📖 Itumọ Ẹsẹ 51
t’o sa fun kinihun
بَلْ يُرِيدُ كُلُّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُؤْتَىٰ صُحُفًا مُّنَشَّرَةً ۝٥٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 52
Rara, nse ni enikookan ninu won n fe ki A fun oun naa ni Tira ti o maa see te han awon eniyan (bii ti al-Ƙur’an)
كَلَّا ۖ بَل لَّا يَخَافُونَ الْآخِرَةَ ۝٥٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 53
Rara. Won ko paya orun ni
كَلَّا إِنَّهُ تَذْكِرَةٌ ۝٥٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 54
E gbo! Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti
فَمَن شَاءَ ذَكَرَهُ ۝٥٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 55
Nitori naa, eni ti o ba fe ko ranti re
وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ ۚ هُوَ أَهْلُ التَّقْوَىٰ وَأَهْلُ الْمَغْفِرَةِ ۝٥٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 56
Won ko si nii ranti (al-Ƙur’an) afi ti Allahu ba fe. (Allahu) Oun l’a gbodo beru. Oun l’o si laforijin
← 73 Al-Muddaththir (74/114) 75 →
Kika Surah Al-Muddaththir ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

74المدثر Al-Muddaththir 📚 56 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Muddaththir — 56 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers