Surah Al-Mu'minun ni Arabic ati Yorùbá
Ka Surah Al-Mu'minun pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (118 Ẹsẹ — مكية). Al-Mu'minun Gbọ, Al-Mu'minun Itumọ, Al-Mu'minun mp3, Al-Mu'minun pdf.Ka ati Gbọ Surah Al-Mu'minun
🎧 Ẹsẹ
M
Mishary Rashid Alafasy
✓
Mishary Rashid Alafasy
✓
M
Mahmoud Khalil Al-Husary
✓
Mahmoud Khalil Al-Husary
✓
A
Abdurrahman As-Sudais
✓
Abdurrahman As-Sudais
✓
M
Mohamed Siddiq Al-Minshawi
✓
Mohamed Siddiq Al-Minshawi
✓
A
Abdul Basit Abdul Samad
✓
Abdul Basit Abdul Samad
✓
A
Ali Al-Hudhaify
✓
Ali Al-Hudhaify
✓
A
Ahmed ibn Ali al-Ajamy
✓
Ahmed ibn Ali al-Ajamy
✓
A
Abu Bakr Ash-Shaatree
✓
Abu Bakr Ash-Shaatree
✓
M
Muhammad Ayyoub
✓
Muhammad Ayyoub
✓
A
Abdullah Basfar
✓
Abdullah Basfar
✓
A
Abdullah Al-Juhani
✓
Abdullah Al-Juhani
✓
M
Maher Al Muaiqly
✓
Maher Al Muaiqly
✓
—
x1
إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِينَ ٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 6
afi ni odo awon iyawo won ati erubinrin won. Dajudaju won ki i se eni eebu (ti won ba sunmo won)
فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ ٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 7
nitori naa, enikeni ti o ba wa omiran (sunmo) leyin iyen, awon wonyen ni awon olutayo enu-ala
وَالَّذِينَ هُمْ لِأَمَانَاتِهِمْ وَعَهْدِهِمْ رَاعُونَ ٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 8
ati awon t’o n so agbafipamo won ati adehun won
الَّذِينَ يَرِثُونَ الْفِرْدَوْسَ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ ١١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 11
awon t’o maa jogun ogba idera Firdaos. Olusegbere ni won ninu re
وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ مِن سُلَالَةٍ مِّن طِينٍ ١٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 12
Dajudaju A ti se eda eniyan lati inu ohun ti A mo jade lati inu erupe amo
ثُمَّ جَعَلْنَاهُ نُطْفَةً فِي قَرَارٍ مَّكِينٍ ١٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 13
Leyin naa, A se e ni ato sinu aye aabo (iyen, ile-omo)
ثُمَّ خَلَقْنَا النُّطْفَةَ عَلَقَةً فَخَلَقْنَا الْعَلَقَةَ مُضْغَةً فَخَلَقْنَا الْمُضْغَةَ عِظَامًا فَكَسَوْنَا الْعِظَامَ لَحْمًا ثُمَّ أَنشَأْنَاهُ خَلْقًا آخَرَ ۚ فَتَبَارَكَ اللَّهُ أَحْسَنُ الْخَالِقِينَ ١٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 14
Leyin naa, A so ato di eje didi. Leyin naa, A so eje didi di baasi eran. Leyin naa, A so baasi eran di eegun. Leyin naa, A fi eran bo eegun. Leyin naa, A so o di eda miiran.1 Nitori naa, ibukun ni fun Allahu, Eni t’O dara julo ninu awon eledaa (onise-ona)
ثُمَّ إِنَّكُم بَعْدَ ذَٰلِكَ لَمَيِّتُونَ ١٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 15
Leyin naa, leyin iyen, dajudaju eyin yo si di oku
ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ تُبْعَثُونَ ١٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 16
Leyin naa, dajudaju ni Ojo Ajinde Won maa gbe yin dide
وَلَقَدْ خَلَقْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعَ طَرَائِقَ وَمَا كُنَّا عَنِ الْخَلْقِ غَافِلِينَ ١٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 17
Dajudaju A da awon sanmo meje si oke yin. Awa ko si nii dagunla si awon eda
وَأَنزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً بِقَدَرٍ فَأَسْكَنَّاهُ فِي الْأَرْضِ ۖ وَإِنَّا عَلَىٰ ذَهَابٍ بِهِ لَقَادِرُونَ ١٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 18
A n so omi kale lati sanmo niwon niwon. Leyin naa, A n mu un duro sinu ile. Dajudaju Awa kuku lagbara lati mu un lo
فَأَنشَأْنَا لَكُم بِهِ جَنَّاتٍ مِّن نَّخِيلٍ وَأَعْنَابٍ لَّكُمْ فِيهَا فَوَاكِهُ كَثِيرَةٌ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ ١٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 19
Leyin naa, A da awon ogba oko dabinu ati ajara fun yin; opolopo eso wa ninu re fun yin, e si n je ninu re
وَشَجَرَةً تَخْرُجُ مِن طُورِ سَيْنَاءَ تَنبُتُ بِالدُّهْنِ وَصِبْغٍ لِّلْآكِلِينَ ٢٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 20
Ati igi kan t’o n hu jade nibi apata Sina’; o n mu epo ati nnkan isebe jade fun awon t’o n je e
وَإِنَّ لَكُمْ فِي الْأَنْعَامِ لَعِبْرَةً ۖ نُّسْقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهَا وَلَكُمْ فِيهَا مَنَافِعُ كَثِيرَةٌ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ ٢١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 21
Ati pe dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin; A n fun yin mu ninu ohun ti o wa ninu ikun won. Awon anfaani opolopo (miiran) tun wa fun yin lara won, e si n je ninu re
وَعَلَيْهَا وَعَلَى الْفُلْكِ تُحْمَلُونَ ٢٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 22
E si n ko eru si ori awon eran osin ati oko oju-omi
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ أَفَلَا تَتَّقُونَ ٢٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 23
Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Se e o nii beru (Re) ni?”
فَقَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن قَوْمِهِ مَا هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يُرِيدُ أَن يَتَفَضَّلَ عَلَيْكُمْ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَأَنزَلَ مَلَائِكَةً مَّا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي آبَائِنَا الْأَوَّلِينَ ٢٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 24
Awon olori ti won sai gbagbo ninu awon eniyan re so pe: “Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin, ti o fe gbe ajulo fun ara re lori yin. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe (ranse si wa ni), iba so molaika kan kale ni. A ko si gbo eyi ri lodo awon baba wa, awon eni akoko
إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ بِهِ جِنَّةٌ فَتَرَبَّصُوا بِهِ حَتَّىٰ حِينٍ ٢٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 25
Ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti alujannu n be lara re. Nitori naa, e maa reti (ikangun) re titi di igba kan na.”
قَالَ رَبِّ انصُرْنِي بِمَا كَذَّبُونِ ٢٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 26
(Anabi) Nuh so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro
فَأَوْحَيْنَا إِلَيْهِ أَنِ اصْنَعِ الْفُلْكَ بِأَعْيُنِنَا وَوَحْيِنَا فَإِذَا جَاءَ أَمْرُنَا وَفَارَ التَّنُّورُ ۙ فَاسْلُكْ فِيهَا مِن كُلٍّ زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ وَأَهْلَكَ إِلَّا مَن سَبَقَ عَلَيْهِ الْقَوْلُ مِنْهُمْ ۖ وَلَا تُخَاطِبْنِي فِي الَّذِينَ ظَلَمُوا ۖ إِنَّهُم مُّغْرَقُونَ ٢٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 27
Nitori naa, A fi imisi ranse si i pe: "Se oko oju-omi ni oju Wa (bayii) pelu imisi Wa. Nigba ti ase Wa ba de, ti omi ba se yo ni oju aro, nigba naa ni ki o ko sinu oko oju-omi gbogbo nnkan ni orisi meji tako-tabo ati ara ile re, ayafi eni ti oro naa ko le lori ninu won (fun iparun). Ma se ba Mi soro nipa awon t’o sabosi; dajudaju A oo te won ri sinu omi ni
فَإِذَا اسْتَوَيْتَ أَنتَ وَمَن مَّعَكَ عَلَى الْفُلْكِ فَقُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي نَجَّانَا مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ ٢٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 28
Nigba ti o ba jokoo sinu oko oju-omi naa, iwo ati awon t’o wa pelu re, so pe: Ope ni fun Allahu, Eni ti O gba wa la lowo ijo alabosi
وَقُل رَّبِّ أَنزِلْنِي مُنزَلًا مُّبَارَكًا وَأَنتَ خَيْرُ الْمُنزِلِينَ ٢٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 29
So pe: “Oluwa mi, so mi kale si ibuso ibukun. Iwo si loore julo ninu awon amunigunle.”
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ وَإِن كُنَّا لَمُبْتَلِينَ ٣٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 30
Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Awa si ni A n dan eda wo
ثُمَّ أَنشَأْنَا مِن بَعْدِهِمْ قَرْنًا آخَرِينَ ٣١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 31
Leyin naa, A mu awon iran miiran wa leyin won
فَأَرْسَلْنَا فِيهِمْ رَسُولًا مِّنْهُمْ أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ أَفَلَا تَتَّقُونَ ٣٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 32
A tun ran Ojise kan si won laaarin ara won (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Nitori naa, se e o nii beru (Re) ni?”
وَقَالَ الْمَلَأُ مِن قَوْمِهِ الَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِلِقَاءِ الْآخِرَةِ وَأَتْرَفْنَاهُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا مَا هَٰذَا إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ يَأْكُلُ مِمَّا تَأْكُلُونَ مِنْهُ وَيَشْرَبُ مِمَّا تَشْرَبُونَ ٣٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 33
Awon olori t’o sai gbagbo ninu ijo re, awon t’o pe ipade Ojo Ikeyin niro, awon ti A se gbedemuke fun ninu isemi aye yii, won wi pe: "Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin; o n je ninu ohun ti e n je, o si n mu ninu ohun ti e n mu
وَلَئِنْ أَطَعْتُم بَشَرًا مِّثْلَكُمْ إِنَّكُمْ إِذًا لَّخَاسِرُونَ ٣٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 34
Ti e ba fi le tele abara kan bi iru yin, dajudaju e ma ti di eni ofo niyen
أَيَعِدُكُمْ أَنَّكُمْ إِذَا مِتُّمْ وَكُنتُمْ تُرَابًا وَعِظَامًا أَنَّكُم مُّخْرَجُونَ ٣٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 35
Se o n se adehun fun yin pe nigba ti e ba ku, ti e si di erupe ati egungun tan, dajudaju Won yoo mu yin jade (ni alaaye)
۞ هَيْهَاتَ هَيْهَاتَ لِمَا تُوعَدُونَ ٣٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 36
Ohun ti Won n se ni adehun fun yin (yii) jinna tefetefe (si ododo)
إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ ٣٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 37
Ko si isemi aye kan mo ayafi eyi ti a n lo yii; awa kan n ku, awa kan n waye. Ko si si pe Won yoo gbe wa dide mo
إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا وَمَا نَحْنُ لَهُ بِمُؤْمِنِينَ ٣٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 38
(Ojise naa) ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti o da adapa iro mo Allahu. Awa ko si nii gba a gbo
قَالَ رَبِّ انصُرْنِي بِمَا كَذَّبُونِ ٣٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 39
(Ojise naa) so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro
قَالَ عَمَّا قَلِيلٍ لَّيُصْبِحُنَّ نَادِمِينَ ٤٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 40
(Allahu) so pe: “Laipe nse ni won yoo di alabaamo.”
فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ بِالْحَقِّ فَجَعَلْنَاهُمْ غُثَاءً ۚ فَبُعْدًا لِّلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ ٤١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 41
Nitori naa, ohun igbe mu won lona eto. A si so won di panti. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo alabosi
ثُمَّ أَنشَأْنَا مِن بَعْدِهِمْ قُرُونًا آخَرِينَ ٤٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 42
Leyin naa, A tun mu awon iran miiran wa leyin won
مَا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ ٤٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 43
Ijo kan ko nii lo siwaju akoko (iparun) re, won ko si nii sun (iparun won) siwaju
ثُمَّ أَرْسَلْنَا رُسُلَنَا تَتْرَىٰ ۖ كُلَّ مَا جَاءَ أُمَّةً رَّسُولُهَا كَذَّبُوهُ ۚ فَأَتْبَعْنَا بَعْضَهُم بَعْضًا وَجَعَلْنَاهُمْ أَحَادِيثَ ۚ فَبُعْدًا لِّقَوْمٍ لَّا يُؤْمِنُونَ ٤٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 44
Leyin naa, A ran awon Ojise Wa nise ni telentele. Igbakigba ti Ojise ijo kan ba de, won n pe e ni opuro. A si mu apa kan won tele apa kan ninu iparun. A tun so won di itan. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo ti ko gbagbo lododo
ثُمَّ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ وَأَخَاهُ هَارُونَ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ ٤٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 45
Leyin naa, A ran (Anabi) Musa ati omo-iya re (Anabi) Harun nise pelu awon ami Wa ati eri ponnbele
إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَاسْتَكْبَرُوا وَكَانُوا قَوْمًا عَالِينَ ٤٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 46
(A ran won nise) si Fir‘aon ati awon ijoye re. Sugbon won segberaga, won si je ijo olujegaba
فَقَالُوا أَنُؤْمِنُ لِبَشَرَيْنِ مِثْلِنَا وَقَوْمُهُمَا لَنَا عَابِدُونَ ٤٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 47
Won wi pe: “Se ki a gba abara meji bi iru wa gbo, nigba ti o je pe eru wa ni awon eniyan won?”
فَكَذَّبُوهُمَا فَكَانُوا مِنَ الْمُهْلَكِينَ ٤٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 48
Nitori naa, won pe awon mejeeji ni opuro. Won si wa ninu awon eni- iparun
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ ٤٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 49
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira nitori ki won le mona
وَجَعَلْنَا ابْنَ مَرْيَمَ وَأُمَّهُ آيَةً وَآوَيْنَاهُمَا إِلَىٰ رَبْوَةٍ ذَاتِ قَرَارٍ وَمَعِينٍ ٥٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 50
A se omo Moryam ati iya re ni ami kan. A si se ibugbe fun awon mejeeji si ibi giga kan, t’o ni ibugbe, t’o si ni omi iseleru
يَا أَيُّهَا الرُّسُلُ كُلُوا مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَاعْمَلُوا صَالِحًا ۖ إِنِّي بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ ٥١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 51
Eyin Ojise, e je ninu awon nnkan daadaa, ki e si se ise rere. Dajudaju Emi ni Onimo nipa ohun ti e n se nise
وَإِنَّ هَٰذِهِ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَأَنَا رَبُّكُمْ فَاتَّقُونِ ٥٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 52
Ati pe dajudaju (’Islam) yii ni esin yin. (O je) esin kan soso. Emi si ni Oluwa yin. Nitori naa, e beru Mi
فَتَقَطَّعُوا أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ زُبُرًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ ٥٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 53
Sugbon won ge oro esin won laaarin ara won si kelekele. Ijo kookan si n yo si ohun t’o n be ni odo won
فَذَرْهُمْ فِي غَمْرَتِهِمْ حَتَّىٰ حِينٍ ٥٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 54
Nitori naa, fi won sile sinu isina won titi di igba kan na
أَيَحْسَبُونَ أَنَّمَا نُمِدُّهُم بِهِ مِن مَّالٍ وَبَنِينَ ٥٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 55
Se won n lero pe (bi) A se n fi dukia ati omo nikan se iranlowo fun won
نُسَارِعُ لَهُمْ فِي الْخَيْرَاتِ ۚ بَل لَّا يَشْعُرُونَ ٥٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 56
ni A oo se maa yara ti awon oore si odo won lo (titi laelae). Rara, won ko fura ni
إِنَّ الَّذِينَ هُم مِّنْ خَشْيَةِ رَبِّهِم مُّشْفِقُونَ ٥٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 57
Dajudaju awon t’o n paya (isiro-ise) fun ipaya won ninu Oluwa won
وَالَّذِينَ هُم بِآيَاتِ رَبِّهِمْ يُؤْمِنُونَ ٥٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 58
ati awon t’o n gba awon ayah Oluwa won gbo
وَالَّذِينَ يُؤْتُونَ مَا آتَوا وَّقُلُوبُهُمْ وَجِلَةٌ أَنَّهُمْ إِلَىٰ رَبِّهِمْ رَاجِعُونَ ٦٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 60
ati awon t’o n se ohun rere (ninu ise) ti won se, pelu iberu ninu okan won pe dajudaju awon yoo pada si odo Oluwa won
أُولَٰئِكَ يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَهُمْ لَهَا سَابِقُونَ ٦١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 61
awon wonyen ni won n yara se awon ise rere. Awon si ni asiwaju ninu (awon esan) ise naa
وَلَا نُكَلِّفُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا ۖ وَلَدَيْنَا كِتَابٌ يَنطِقُ بِالْحَقِّ ۚ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ ٦٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 62
Ati pe A ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Tira kan t’o n so ododo (nipa ise eda) n be lodo Wa. A o si nii sabosi si won
بَلْ قُلُوبُهُمْ فِي غَمْرَةٍ مِّنْ هَٰذَا وَلَهُمْ أَعْمَالٌ مِّن دُونِ ذَٰلِكَ هُمْ لَهَا عَامِلُونَ ٦٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 63
Amo okan awon alaigbagbo wa ninu ifonufora nipa (al-Ƙur’an) yii. Ati pe won ni awon ise kan lowo, ti o yato si ise rere yen. Won si n se ise naa
حَتَّىٰ إِذَا أَخَذْنَا مُتْرَفِيهِم بِالْعَذَابِ إِذَا هُمْ يَجْأَرُونَ ٦٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 64
titi di igba ti A maa gba awon onigbedemuke ninu won mu pelu iya. Nigba naa ni won maa ke gbajari
لَا تَجْأَرُوا الْيَوْمَ ۖ إِنَّكُم مِّنَّا لَا تُنصَرُونَ ٦٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 65
E ma kee gbajari lonii. Dajudaju ko si eni ti o maa ran yin lowo lodo Wa
قَدْ كَانَتْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنتُمْ عَلَىٰ أَعْقَابِكُمْ تَنكِصُونَ ٦٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 66
Won kuku n ka awon ayah Mi fun yin. Amo nse ni e n fa seyin (nibi ododo)
مُسْتَكْبِرِينَ بِهِ سَامِرًا تَهْجُرُونَ ٦٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 67
E si n fi Kaaba segberaga, e tun n fi oru yin so isokuso (nipa al-Ƙur’an)
أَفَلَمْ يَدَّبَّرُوا الْقَوْلَ أَمْ جَاءَهُم مَّا لَمْ يَأْتِ آبَاءَهُمُ الْأَوَّلِينَ ٦٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 68
Se won ko ronu si oro naa ni? Tabi ohun t’o de ba won je ohun ti ko de ba awon baba won akoko ri ni
أَمْ لَمْ يَعْرِفُوا رَسُولَهُمْ فَهُمْ لَهُ مُنكِرُونَ ٦٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 69
Tabi won ko mo Ojise won mo ni won fi di alatako re
أَمْ يَقُولُونَ بِهِ جِنَّةٌ ۚ بَلْ جَاءَهُم بِالْحَقِّ وَأَكْثَرُهُمْ لِلْحَقِّ كَارِهُونَ ٧٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 70
Tabi won n wi pe alujannu kan n be lara re ni? Rara o. O mu ododo wa ba won ni. Amo opolopo won si je olukorira ododo
وَلَوِ اتَّبَعَ الْحَقُّ أَهْوَاءَهُمْ لَفَسَدَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ وَمَن فِيهِنَّ ۚ بَلْ أَتَيْنَاهُم بِذِكْرِهِمْ فَهُمْ عَن ذِكْرِهِم مُّعْرِضُونَ ٧١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 71
Ti o ba je pe (Allahu), Oba Ododo tele ife-inu won ni, awon sanmo ati ile ati awon t’o wa ninu won iba kuku ti baje. Sugbon A mu isiti nipa oro ara won wa fun won ni, won si n gbunri kuro nibi isiti (ti A mu wa fun) won
أَمْ تَسْأَلُهُمْ خَرْجًا فَخَرَاجُ رَبِّكَ خَيْرٌ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ ٧٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 72
Tabi o n beere owo-oya kan lowo won ni? Owo-oya Oluwa re loore julo. Ati pe Oun l’oore julo ninu awon olupese
وَإِنَّكَ لَتَدْعُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ ٧٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 73
Ati pe dajudaju o n pe won soju ona taara ni
وَإِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ عَنِ الصِّرَاطِ لَنَاكِبُونَ ٧٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 74
Awon ti ko si gba Ojo Ikeyin gbo ni won n seri kuro loju ona naa
۞ وَلَوْ رَحِمْنَاهُمْ وَكَشَفْنَا مَا بِهِم مِّن ضُرٍّ لَّلَجُّوا فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ ٧٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 75
Ti o ba je pe A ke won (nile aye), ti A si gbe gbogbo isoro ara won kuro fun won, won iba tun wonkoko mo itayo enu-ala won, ti won yoo maa pa ridarida (ninu isina)
وَلَقَدْ أَخَذْنَاهُم بِالْعَذَابِ فَمَا اسْتَكَانُوا لِرَبِّهِمْ وَمَا يَتَضَرَّعُونَ ٧٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 76
Dajudaju A fi iya je won. Amo won ko teriba fun Oluwa won, won ko si rawo rase si I
حَتَّىٰ إِذَا فَتَحْنَا عَلَيْهِم بَابًا ذَا عَذَابٍ شَدِيدٍ إِذَا هُمْ فِيهِ مُبْلِسُونَ ٧٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 77
titi di igba ti A fi silekun iya lile fun won; nigba naa ni won soreti nu
وَهُوَ الَّذِي أَنشَأَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۚ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ ٧٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 78
(Allahu), Oun ni Eni ti O se igboro, iriran ati okan fun yin, idupe yin si kere
وَهُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ ٧٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 79
Oun ni Eni ti O da yin sori ile, odo Re si ni won yoo ko yin jo si
وَهُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ وَلَهُ اخْتِلَافُ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ ٨٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 80
Oun ni Eni t’O n so eda di alaaye, O n so eda di oku, tiRe si ni itelentele ati iyato oru ati osan, se e o nii se laakaye ni
بَلْ قَالُوا مِثْلَ مَا قَالَ الْأَوَّلُونَ ٨١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 81
Rara (won ko nii se laakaye, sebi) iru ohun ti awon eni akoko wi ni awon naa wi
قَالُوا أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ ٨٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 82
Won wi pe: “Se nigba ti a ba ti ku, ti a ti di erupe ati egungun, se won yoo gbe wa dide ni
لَقَدْ وُعِدْنَا نَحْنُ وَآبَاؤُنَا هَٰذَا مِن قَبْلُ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ ٨٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 83
Won kuku ti se adehun yii fun awa ati awon baba wa teletele. Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko.”
قُل لِّمَنِ الْأَرْضُ وَمَن فِيهَا إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ ٨٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 84
So pe: “Ta ni Eni ti O ni ile ati eni ti o wa ni ori re ti e ba mo?”
سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ ٨٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 85
Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii lo iranti ni?”
قُلْ مَن رَّبُّ السَّمَاوَاتِ السَّبْعِ وَرَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ ٨٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 86
So pe: “Ta ni Oluwa awon sanmo mejeeje ati Oluwa Ite nla?”
سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ أَفَلَا تَتَّقُونَ ٨٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 87
Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii beru (Re) ni?”
قُلْ مَن بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ يُجِيرُ وَلَا يُجَارُ عَلَيْهِ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ ٨٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 88
So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?” So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?”
سَيَقُولُونَ لِلَّهِ ۚ قُلْ فَأَنَّىٰ تُسْحَرُونَ ٨٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 89
Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Nitori naa, bawo ni won se n dan yin?”
بَلْ أَتَيْنَاهُم بِالْحَقِّ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ ٩٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 90
Amo sa, ododo ni A mu wa ba won. Dajudaju awon si ni opuro
مَا اتَّخَذَ اللَّهُ مِن وَلَدٍ وَمَا كَانَ مَعَهُ مِنْ إِلَٰهٍ ۚ إِذًا لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَٰهٍ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلَا بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ ٩١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 91
Allahu ko fi eni kan kan se omo, ko si si olohun kan pelu Re. (Ti ko ba ri bee) nigba naa, olohun kookan iba ti ko eda t’o da lo, apa kan won iba si bori apa kan. Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re nipa omo bibi)
عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ ٩٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 92
(Allahu) Onimo-ikoko ati gbangba. Nitori naa, O ga tayo nnkan ti won fi n sebo si I
قُل رَّبِّ إِمَّا تُرِيَنِّي مَا يُوعَدُونَ ٩٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 93
So pe: “Oluwa mi, O see se ki O fi ohun ti won n se ni adehun fun won han mi
رَبِّ فَلَا تَجْعَلْنِي فِي الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ ٩٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 94
Oluwa mi, ma se fi mi sinu ijo alabosi.”
وَإِنَّا عَلَىٰ أَن نُّرِيَكَ مَا نَعِدُهُمْ لَقَادِرُونَ ٩٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 95
Dajudaju Awa lagbara lati fi ohun ti A se ni ileri fun won han o
ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ السَّيِّئَةَ ۚ نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَصِفُونَ ٩٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 96
Fi eyi t’o dara ti aidara danu. Awa nimo julo nipa ohun ti won fi n royin (Wa)
وَقُل رَّبِّ أَعُوذُ بِكَ مِنْ هَمَزَاتِ الشَّيَاطِينِ ٩٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 97
So pe: "Oluwa mi, mo n sadi O nibi royiroyi t’awon esu
حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ رَبِّ ارْجِعُونِ ٩٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 99
(Won n semi lo) titi di igba ti iku fi maa de ba okan ninu won. O si maa wi pe: “Oluwa mi, E da mi pada (sile aye)
لَعَلِّي أَعْمَلُ صَالِحًا فِيمَا تَرَكْتُ ۚ كَلَّا ۚ إِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَائِلُهَا ۖ وَمِن وَرَائِهِم بَرْزَخٌ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ ١٠٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 100
nitori ki ng le se ise rere ninu eyi ti mo gbe ju sile. Ko ri bee rara, dajudaju o je oro kan ti o kan n wi ni, (amo) gaga ti wa ni eyin won titi di ojo ti A oo gbe won dide. ayeta okigbe
فَإِذَا نُفِخَ فِي الصُّورِ فَلَا أَنسَابَ بَيْنَهُمْ يَوْمَئِذٍ وَلَا يَتَسَاءَلُونَ ١٠١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 101
Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde, ko nii si ibatan laaarin won ni ojo yen, won ko si nii bira won leere ibeere
فَمَن ثَقُلَتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ ١٠٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 102
Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba tewon, awon wonyen ni olujere
وَمَنْ خَفَّتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ فِي جَهَنَّمَ خَالِدُونَ ١٠٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 103
Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba fuye, awon wonyen ni awon t’o se emi ara won lofo. Olusegbere si ni won ninu ina Jahanamo
تَلْفَحُ وُجُوهَهُمُ النَّارُ وَهُمْ فِيهَا كَالِحُونَ ١٠٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 104
Ina yoo maa jo won loju. Won yo si wa ninu re, ti Ina yoo ti ba won loju je
أَلَمْ تَكُنْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ ١٠٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 105
Se won ki i ka awon ayah Mi fun yin ni, amo ti e n pe e niro
قَالُوا رَبَّنَا غَلَبَتْ عَلَيْنَا شِقْوَتُنَا وَكُنَّا قَوْمًا ضَالِّينَ ١٠٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 106
Won wi pe: "Oluwa wa, ori buruku l’o kolu wa; awa si je ijo olusina
رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْهَا فَإِنْ عُدْنَا فَإِنَّا ظَالِمُونَ ١٠٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 107
Oluwa wa, mu wa jade kuro ninu Ina. Ti a ba fi le pada (sibi ise ibi nile aye), dajudaju nigba naa alabosi ni awa
قَالَ اخْسَئُوا فِيهَا وَلَا تُكَلِّمُونِ ١٠٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 108
(Allahu) so pe: “E teri sinu re. E ma se ba Mi soro.”
إِنَّهُ كَانَ فَرِيقٌ مِّنْ عِبَادِي يَقُولُونَ رَبَّنَا آمَنَّا فَاغْفِرْ لَنَا وَارْحَمْنَا وَأَنتَ خَيْرُ الرَّاحِمِينَ ١٠٩
📖 Itumọ
Ẹsẹ 109
Dajudaju igun kan wa ninu awon erusin Mi, ti won n so pe: “Oluwa wa, a gbagbo ni ododo. Nitori naa, forijin wa, ki O si ke wa. Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.”
فَاتَّخَذْتُمُوهُمْ سِخْرِيًّا حَتَّىٰ أَنسَوْكُمْ ذِكْرِي وَكُنتُم مِّنْهُمْ تَضْحَكُونَ ١١٠
📖 Itumọ
Ẹsẹ 110
Sugbon e so won di oniyeye to bee ge ti awon yeye (yin) fi mu yin gbagbe iranti Mi. Eyin si n fi won rerin-in
إِنِّي جَزَيْتُهُمُ الْيَوْمَ بِمَا صَبَرُوا أَنَّهُمْ هُمُ الْفَائِزُونَ ١١١
📖 Itumọ
Ẹsẹ 111
Dajudaju Mo san won ni esan ni oni nitori suuru won; dajudaju awon, awon ni olujere
قَالَ كَمْ لَبِثْتُمْ فِي الْأَرْضِ عَدَدَ سِنِينَ ١١٢
📖 Itumọ
Ẹsẹ 112
(Allahu) so pe: "Odun meloo ni eyin (alaigbagbo) lo lori ile aye
قَالُوا لَبِثْنَا يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ فَاسْأَلِ الْعَادِّينَ ١١٣
📖 Itumọ
Ẹsẹ 113
Won wi pe: “A lo ojo kan tabi abala ojo kan, bi awon olusiro-ojo leere wo.”
قَالَ إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا قَلِيلًا ۖ لَّوْ أَنَّكُمْ كُنتُمْ تَعْلَمُونَ ١١٤
📖 Itumọ
Ẹsẹ 114
(Allahu) so pe: “E ko gbe ile aye bi ko se fun igba die, ti o ba je pe e mo.”
أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ ١١٥
📖 Itumọ
Ẹsẹ 115
Se e lero pe A kan seda yin fun iranu ni, ati pe dajudaju won o nii da yin pada sodo Wa?”
فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ ١١٦
📖 Itumọ
Ẹsẹ 116
Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun, Oluwa Ite alapon-onle
وَمَن يَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ لَا بُرْهَانَ لَهُ بِهِ فَإِنَّمَا حِسَابُهُ عِندَ رَبِّهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُونَ ١١٧
📖 Itumọ
Ẹsẹ 117
Eni ti o ba pe olohun miiran pelu Allahu, ko ni eri lowo lori re. Dajudaju isiro-ise re si wa lodo Oluwa re. Dajudaju awon alaigbagbo ko nii jere
وَقُل رَّبِّ اغْفِرْ وَارْحَمْ وَأَنتَ خَيْرُ الرَّاحِمِينَ ١١٨
📖 Itumọ
Ẹsẹ 118
So pe: “Oluwa mi, saforijin, ki O si ke (mi). Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.”
Kika Surah Al-Mu'minun ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun
Al-Kur'an
Tuesday, August 18, 2026
Don't forget us in your sincere prayers

