Surah Al-Jinn ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Jinn pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (28 Ẹsẹ — مكية). Al-Jinn Gbọ, Al-Jinn Itumọ, Al-Jinn mp3, Al-Jinn pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Jinn

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
قُلْ أُوحِيَ إِلَيَّ أَنَّهُ اسْتَمَعَ نَفَرٌ مِّنَ الْجِنِّ فَقَالُوا إِنَّا سَمِعْنَا قُرْآنًا عَجَبًا ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
So pe: "Won fi imisi ranse si mi pe dajudaju ijo kan ninu awon alujannu teti (si al-Ƙur’an)." Won si so pe: "Dajudaju awa gbo al-Ƙur’an iyanu
يَهْدِي إِلَى الرُّشْدِ فَآمَنَّا بِهِ ۖ وَلَن نُّشْرِكَ بِرَبِّنَا أَحَدًا ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
O n setosona sibi imona. Nitori naa, a gba a gbo. Awa ko si nii fi eni kan kan se akegbe fun Oluwa wa
وَأَنَّهُ تَعَالَىٰ جَدُّ رَبِّنَا مَا اتَّخَذَ صَاحِبَةً وَلَا وَلَدًا ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Ati pe dajudaju titobi Oluwa wa ga. Ko fi eni kan kan se aya ati omo
وَأَنَّهُ كَانَ يَقُولُ سَفِيهُنَا عَلَى اللَّهِ شَطَطًا ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Dajudaju omugo ninu wa maa n so isokuso nipa Allahu
وَأَنَّا ظَنَنَّا أَن لَّن تَقُولَ الْإِنسُ وَالْجِنُّ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Dajudaju awa si n ro pe eniyan ati alujannu ko nii pa iro mo Allahu ni
وَأَنَّهُ كَانَ رِجَالٌ مِّنَ الْإِنسِ يَعُوذُونَ بِرِجَالٍ مِّنَ الْجِنِّ فَزَادُوهُمْ رَهَقًا ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Ati pe dajudaju awon okunrin kan ninu eniyan maa n fi awon okunrin kan ninu awon alujannu wa aabo. Awon alujannu si se alekun aburu fun won
وَأَنَّهُمْ ظَنُّوا كَمَا ظَنَنتُمْ أَن لَّن يَبْعَثَ اللَّهُ أَحَدًا ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Dajudaju awon alujannu lero gege bi eyin eniyan naa se lero pe Allahu ko nii gbe eni kan kan dide (leyin iku)
وَأَنَّا لَمَسْنَا السَّمَاءَ فَوَجَدْنَاهَا مُلِئَتْ حَرَسًا شَدِيدًا وَشُهُبًا ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Dajudaju awa wa (oro ayogbo) wa si sanmo, a si ba a ti o ti kun fun awon eso t’o lagbara ati awon ogunna
وَأَنَّا كُنَّا نَقْعُدُ مِنْهَا مَقَاعِدَ لِلسَّمْعِ ۖ فَمَن يَسْتَمِعِ الْآنَ يَجِدْ لَهُ شِهَابًا رَّصَدًا ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Dajudaju awa maa n jokoo sibe ni awon ibudo kan fun gbigbo oro. Sugbon eni t’o ba joro gbo lasiko yii, o maa ri ogunna t’o ti lugo de e
وَأَنَّا لَا نَدْرِي أَشَرٌّ أُرِيدَ بِمَن فِي الْأَرْضِ أَمْ أَرَادَ بِهِمْ رَبُّهُمْ رَشَدًا ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Dajudaju awa ko si mo boya aburu ni won gba lero pelu awon t’o wa lori ile tabi Oluwa won gbero imona fun won
وَأَنَّا مِنَّا الصَّالِحُونَ وَمِنَّا دُونَ ذَٰلِكَ ۖ كُنَّا طَرَائِقَ قِدَدًا ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Dajudaju awon eni rere wa ninu wa. Awon miiran yato si iyen tun wa ninu wa. A wa loju ona (esin) otooto
وَأَنَّا ظَنَنَّا أَن لَّن نُّعْجِزَ اللَّهَ فِي الْأَرْضِ وَلَن نُّعْجِزَهُ هَرَبًا ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Dajudaju awa mo amodaju pe awa ko le mori bo mo Allahu lowo lori ile. Awa ko si le sa mo On lowo
وَأَنَّا لَمَّا سَمِعْنَا الْهُدَىٰ آمَنَّا بِهِ ۖ فَمَن يُؤْمِن بِرَبِّهِ فَلَا يَخَافُ بَخْسًا وَلَا رَهَقًا ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Dajudaju nigba ti a gbo nipa imona (lati inu al-Ƙur’an), a gba a gbo. Nitori naa, enikeni ti o ba gba Oluwa re gbo, ki o ma beru adinku (esan rere) ati (alekun) aburu
وَأَنَّا مِنَّا الْمُسْلِمُونَ وَمِنَّا الْقَاسِطُونَ ۖ فَمَنْ أَسْلَمَ فَأُولَٰئِكَ تَحَرَّوْا رَشَدًا ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Dajudaju awon musulumi wa ninu wa. Awon arufin naa wa ninu wa. Nitori naa, enikeni ti o ba se ’Islam, awon wonyen ni won se awari imona
وَأَمَّا الْقَاسِطُونَ فَكَانُوا لِجَهَنَّمَ حَطَبًا ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Ni ti awon arufin, awon ni won maa je igi ikona fun ina Jahanamo.”
وَأَن لَّوِ اسْتَقَامُوا عَلَى الطَّرِيقَةِ لَأَسْقَيْنَاهُم مَّاءً غَدَقًا ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Ati pe ti o ba je pe won duro sinsin loju ona (’Islam) ni, dajudaju Awa iba fun won ni omi pupo mu
لِّنَفْتِنَهُمْ فِيهِ ۚ وَمَن يُعْرِضْ عَن ذِكْرِ رَبِّهِ يَسْلُكْهُ عَذَابًا صَعَدًا ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Nitori ki A le fi dan won wo ni. Enikeni ti o ba gbunri kuro nibi iranti Oluwa re, O maa mu un wo inu iya inira
وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا مَعَ اللَّهِ أَحَدًا ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Dajudaju awon mosalasi n je ti Allahu. Nitori naa, e o gbodo fi pe eni kan pelu Allahu
وَأَنَّهُ لَمَّا قَامَ عَبْدُ اللَّهِ يَدْعُوهُ كَادُوا يَكُونُونَ عَلَيْهِ لِبَدًا ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Dajudaju nigba ti erusin Allahu dide duro t’o n pe Allahu, awon alujannu fee maa difun-un-unfun lodo re (lati teti si al-Ƙur’an)
قُلْ إِنَّمَا أَدْعُو رَبِّي وَلَا أُشْرِكُ بِهِ أَحَدًا ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
So pe: "Oluwa mi ni mo n pe. Ati pe emi ko nii so eni kan kan di akegbe fun Un
قُلْ إِنِّي لَا أَمْلِكُ لَكُمْ ضَرًّا وَلَا رَشَدًا ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
So pe: "Dajudaju emi ko ni ikapa lori inira ati imona fun yin
قُلْ إِنِّي لَن يُجِيرَنِي مِنَ اللَّهِ أَحَدٌ وَلَنْ أَجِدَ مِن دُونِهِ مُلْتَحَدًا ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
So pe: "Dajudaju emi, ko si eni kan t’o le gba mi la lodo Allahu. Emi ko si ri ibusasi kan leyin Re
إِلَّا بَلَاغًا مِّنَ اللَّهِ وَرِسَالَاتِهِ ۚ وَمَن يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَإِنَّ لَهُ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
Afi (ki ng se) ikede (t’o wa) lati odo Allahu ati awon ise Re (t’O fi ran mi). Enikeni t’o ba yapa Allahu ati Ojise Re, dajudaju ina Jahanamo n be fun un. Olusegbere ni won ninu re titi laelae
حَتَّىٰ إِذَا رَأَوْا مَا يُوعَدُونَ فَسَيَعْلَمُونَ مَنْ أَضْعَفُ نَاصِرًا وَأَقَلُّ عَدَدًا ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
(Alaigbagbo ko nii ye sai gbagbo) titi di igba ti won yoo fi ri ohun ti A n se ni adehun fun won. Nigba naa, won yoo mo ta ni o le julo ni alaranse, ti o si kere julo ni onka
قُلْ إِنْ أَدْرِي أَقَرِيبٌ مَّا تُوعَدُونَ أَمْ يَجْعَلُ لَهُ رَبِّي أَمَدًا ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
So pe: "Emi ko mo boya ohun ti Won n se ni adehun fun yin ti sunmo tabi Oluwa mi yoo fun un ni akoko (t’o jinna)
عَالِمُ الْغَيْبِ فَلَا يُظْهِرُ عَلَىٰ غَيْبِهِ أَحَدًا ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Onimo-ikoko, ko si fi (imo) ikoko Re han eni kan
إِلَّا مَنِ ارْتَضَىٰ مِن رَّسُولٍ فَإِنَّهُ يَسْلُكُ مِن بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ رَصَدًا ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
ayafi eni ti O salesa t’o je Ojise. Dajudaju O n mu eso kan rin niwaju Ojise naa ati leyin re
لِّيَعْلَمَ أَن قَدْ أَبْلَغُوا رِسَالَاتِ رَبِّهِمْ وَأَحَاطَ بِمَا لَدَيْهِمْ وَأَحْصَىٰ كُلَّ شَيْءٍ عَدَدًا ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
nitori ki O le safi han pe won ti je awon ise Oluwa won. Ati pe Allahu fi imo rokiri ka ohun ti n be lodo won. O si so onka gbogbo nnkan
← 71 Al-Jinn (72/114) 73 →
Kika Surah Al-Jinn ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

72الجن Al-Jinn 📚 28 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Jinn — 28 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers