PDF —
31 Ẹsẹ Medinan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Insan pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Insan pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Insan Itumọ. Surah Al-Insan (Medinan) 31 Ẹsẹ.



31 Ẹsẹ · Medinan · Yorùbá
bismillah
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
76:1 Sebi akoko kan ninu igba ti re koja lori eniyan ti (eniyan) ko je kini kan ti won n daruko
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
76:2 Dajudaju Awa seda eniyan lati ara ato t’o ropo mora won (lati ara okunrin ati obinrin), ki A le dan an wo. A si se e ni olugbo, oluriran
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺ
76:3 Dajudaju A fi ona mo on; O le je oludupe, o si le je alaimoore
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
76:4 Dajudaju Awa pese awon ewon, ajaga ati Ina sile de awon alaigbagbo
ﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
76:5 Dajudaju awon eni rere, won yoo maa mu omi kan ninu ife. Ohun ti A popo mo (omi naa) ni kafura
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
76:6 Omi iseleru kan ni, ti awon erusin Allahu yoo maa mu, ti won yo si maa mu un san jade daadaa (si ibi ti won ba fe)
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
76:7 Won n mu eje won se. Won si n paya ojo kan, ti aburu re je ohun ti o maa fonka gan-an
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
76:8 Tohun ti bi won se ni ife si (oro to), won n fun mekunnu, omo orukan ati eru ni ounje je
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
76:9 (Won si n so pe:) "Nitori Oju rere Allahu (nikan) l’a fi n fun yin ni ounje; awa ko si gbero esan tabi idupe kan lati odo yin
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
76:10 Dajudaju awa n paya ni odo Oluwa wa ojo kan ti (eda yoo) faju ro koko
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
76:11 Nitori naa, Allahu yoo so won nibi aburu ojo yen. O si maa fun won ni itutu oju ati idunnu
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
76:12 O si maa san won ni esan Ogba Idera ati aso alari nitori pe won se suuru
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
76:13 Won yoo maa rogbo ku sori awon ibusun won. Won ko si nii ri oorun tabi otutu
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
76:14 Awon ooji (inu Ogba Idera) yoo sunmo won. A si maa mu awon eso ibe sunmo arowoto won ni ti sisunmo
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
76:15 Ati pe won yoo maa gbe ife imumi nla ti won se lati ara fadaka ati awon ife imumi kekere ti o je alawo kaa kiri odo won
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
76:16 Ife alawo ti won se lati ara fadaka ni (won). A si se won niwon-niwon (ti o se weku ohun ti won fe mu)
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
76:17 Ati pe won yoo maa fun won ni ife oti kan mu ninu (Ogba Idera). Ohun ti A popo mo (oti naa) ni atale
ﯕﯖﯗﯘﯙ
76:18 Ninu Ogba Idera (won yoo tun maa mu) omi iseleru kan, ti A n pe ni omi salsabil
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
76:19 Awon odokunrin ti ko nii gbo yo si maa lo bo laaarin won. Nigba ti iwo ba si ri won, iwo yoo ka won kun okuta olowo iyebiye ti won tan kale
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
76:20 Nigba ti iwo ba si wo ibe yen (ninu Ogba Idera), iwo yoo ri idera ati ola t’o tobi
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
76:21 Aso ara won ni aso aran felefele alawo eweko ati aso alagbaaa. A si maa fi egba-owo onifadaka se won ni oso. Oluwa won yo si fun won ni ohun mimu mimo mu
ﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄ
76:22 Dajudaju eyi je esan fun yin. Ise yin si ja si ope
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋ
76:23 Dajudaju Awa l’A so al-Ƙur’an kale fun o diedie
ﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕ
76:24 Nitori naa, se suuru fun idajo Oluwa re. Ma se tele elese tabi alaimoore kan ninu won
ﰖﰗﰘﰙﰚﰛ
76:25 Ranti oruko Oluwa re ni aaro ati ni asale
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘ
76:26 Ati ni oru, fori kanle fun Un. Ki o si safomo fun Un ni oru fun igba pipe
ﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡ
76:27 Dajudaju awon wonyi feran aye. Won si n pa ojo t’o wuwo ti seyin won
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
76:28 Awa l’A seda won. A si se won ni alagbara. Nigba ti A ba si fe, A oo fi iru won (miiran) paaro won ni ti ipaaro
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
76:29 Dajudaju eyi ni iranti. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu oju ona to si odo Oluwa re
ﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
76:30 Eyin ko si nii fe (kini kan) afi ti Allahu ba fe. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
76:31 O maa fi eni ti o ba fe sinu ike re. (Ni ti) awon alabosi, O si pese iya eleta-elero sile de won

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers