88 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
38:1 Sod. (Allahu bura pelu) al-Ƙur’an, tira iranti
ﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
38:2 Sibesibe awon t’o sai gbagbo wa ninu igberaga ati iyapa (ododo)
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
38:3 Meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Nigba naa, won kigbe too nigba ti ko si ibusasi kan
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
38:4 Won seemo pe olukilo kan ninu won wa ba won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni opidan, opuro
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
38:5 Se o maa so awon orisa di Olohun Okan soso ti A oo maa josin fun ni? Dajudaju eyi ma ni nnkan iyanu
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
38:6 Awon asiwaju ninu won si lo (kaakiri lati wi fun awon omoleyin won) pe: "E maa ba (iborisa) lo, ki e si duro sinsin ti awon orisa yin. Dajudaju eyi (jije okan soso Allahu) ni nnkan ti won n gba lero (lati fi pa awon orisa yin run)
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
38:7 Awa ko gbo eyi ninu esin ikeyin (iyen, esin kristieniti) . Eyi ko je kini kan bi ko se adapa iro
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
38:8 Se Won so Iranti kale fun un laaarin wa ni?" Rara, won wa ninu iyemeji nipa Iranti Mi (ti Mo sokale ni). Rara, won ko ti i to iya Mi wo ni
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
38:9 Tabi (se) awon ni won ni awon apoti oro Oluwa re, Alagbara, Olore
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞ
38:10 Tabi tiwon ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin mejeeji? Ti o ba ri bee, ki won wa awon ona lati fi gunke wa (ba Wa)
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
38:11 A maa segun omo ogun t’o wa nibe yen ninu omo ogun onijo
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
38:12 Awon ijo Nuh, ijo ‘Ad ati Fir‘aon, eleekan, won pe ododo niro siwaju won
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
38:13 Ijo Thamud, ijo Lut ati awon ara ’Aekah, awon wonyen (tun ni) awon ijo (t’o pe ododo niro)
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
38:14 Ko si eni kan ninu won ti ko pe awon Ojise ni opuro. Nitori naa, iya Mi si ko le won lori
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
38:15 Awon wonyi ko reti kini kan tayo igbe eyo kan, ti ko nii si idapada (tabi idaduro) kan fun un (t’o ba de)
ﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓ
38:16 Won wi pe: "Oluwa wa, yara fi iwe ise wa (ati esan wa) le wa lowo siwaju Ojo isiro-ise
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
38:17 Se suuru lori nnkan ti won n so. Ki o si seranti itan erusin Wa, (Anabi) Dawud, alagbara. Dajudaju o je oluronupiwada
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
38:18 Dajudaju Awa te awon apata lori ba ti won n se afomo pelu re (fun Allahu) ni asale ati nigba ti oorun ba yo
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
38:19 Ati awon eye naa, A ko won jo fun un. Ikookan (won) n tele ase re (lati safomo fun Allahu)
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
38:20 Ati pe A fun ijoba re ni agbara. A si fun un ni ipo Anabi ati eko oro ati idajo
ﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
38:21 Nje iro awon onija ti de odo re; nigba ti won pon ogiri ile ijosin
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
38:22 Nigba ti won wole to (Anabi) Dawud, eru ba a lati ara won. Won so pe: "Ma se beru. Onija meji (ni wa). Apa kan wa tayo enu-ala si apa kan. Nitori naa, dajo laaarin wa pelu ododo. Ma sabosi. Ki o si to wa si ona taara
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦ
38:23 Dajudaju eyi ni arakunrin mi. O ni abo ewure mokandin-logorun-un. Emi si ni abo ewure eyo kan. O si so pe: "Fa a le mi lowo. O si bori mi ninu oro
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
38:24 (Anabi Dawud) so pe: "O ti sabosi si o nipa bibeere abo ewure tire mo awon abo ewure tire. Dajudaju opolopo ninu awon olubada-nnkanpo, apa kan won maa n tayo enu-ala lori apa kan afi awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Die si ni won. (Anabi) Dawud si mo daju pe A kan fi (ibeere naa) sadanwo fun oun ni. Nitori naa, o toro aforijin lodo Oluwa re (nipa aiteti gbo oro lenu eni- afesunkan). O doju bole lati fori kanle. O si ronu piwada (sodo Allahu). onka iyawo won le po ni onka ki i se ni ti igbadun adun-ara bi ko se pe Allahu (subhanahu wa ta’ala) fe ko Anabi Dawud (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni eko igbejo nitori pe Allahu (subhanahu wa ta’ala) fe fi se adajo laaarin awon ijo re. Aiteti gbo oro lenu eni-afesunkan ni asise t’o sele si Anabi Dawud (’alaehi-ssolatu wa-ssalam). Eyi naa si ni ohun ti o toro aforijin Olohun fun
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
38:25 Nitori naa, A saforijin iyen fun un. Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un lodo Wa
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖ
38:26 (Anabi) Dawud, dajudaju Awa se o ni arole lori ile. Nitori naa, dajo laaarin awon eniyan pelu ododo. Ma se tele ife-inu nitori ki o ma baa sina kuro loju ona (esin) Allahu. Dajudaju awon t’o n sonu kuro ninu esin Allahu, iya lile wa fun won nitori pe won gbagbe Ojo isiro-ise
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
38:27 A ko seda sanmo, ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji pelu iro. (Iro), iyen ni ero awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo ninu Ina
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
38:28 Se ki A se awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere bi (A o ti se) awon obileje lori ile? Tabi se ki A se awon oluberu (Mi bi A o ti se) awon asebi
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
38:29 (Eyi ni) Tira ibukun ti A so kale fun o nitori ki won le ronu jinle nipa awon ayah re ati nitori ki awon onilaakaye le lo iranti
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
38:30 A fi (Anabi) Sulaemon ta (Anabi) Dawud lore. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri sodo (Allahu) ni (nipa ironupiwada)
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
38:31 (Ranti) nigba ti won ko awon esin akawooja-leri asaretete wa ba a ni irole
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
38:32 o so pe: "Dajudaju emi feran ife ohun rere (iyen, awon esin naa) dipo iranti Oluwa Mi (iyen, irun ‘Asr) titi oorun fi wo
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟ
38:33 E da won pada sodo mi. "O si bere si i fi ida ge won ni ese ati ni orun
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
38:34 Dajudaju A dan (Anabi) Sulaemon wo. A ju abara kan sori aga re. Leyin naa, (Anabi Sulaemon) seri pada (pelu ironupiwada). Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni iyawo t’o to ogorun-un labe ofin eto (iyen ni pe Allahu s.w.t. l’O se e ni eto fun un). Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) si fi Allahu bura ni ojo kan pe ki i se ara oruka Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni awo Anabi Sulaemon wa. Bawo wa ni o se maa je pe nipase oruka Anabi Sulaemon ni awo re fi maa kuro lara re si ara esu alujannu nigba ti Anabi Sulaemon ki i se opidan? Anabi Sulaemon ko si fi oruka joba ambosibosi pe nigba ti ko ba si oruka re lowo re l’o maa fun elomiiran ni aye lati di oba! E tun wo itose-oro fun surah al-Baƙorah; 2:102. W-Allahu ’a‘lam
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
38:35 O so pe: "Oluwa mi, fori jin mi. Ki O si ta mi ni ore ijoba kan eyi ti ko nii to si eni kan kan mo leyin mi. Dajudaju Iwo, Iwo ni Olore
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
38:36 Nitori naa, A te ategun ba fun un. O n fe pelu ase re ni irorun sibi ti o ba fe
ﯥﯦﯧﯨﯩ
38:37 Ati awon esu alujannu; gbogbo awon omole ati awon awakusa (ni A te ba fun un)
ﯪﯫﯬﯭﯮ
38:38 Ati awon (alujannu) miiran ti won fi ewon de mole (A te won ba fun un)
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
38:39 Eyi ni ore Wa. Nitori naa, fi tore tabi ki o mu un dani lai la isiro lo (lorun)
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
38:40 Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un ni odo Wa
ﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉ
38:41 Seranti erusin Wa, (Anabi) ’Ayyub. Nigba ti o pe Oluwa re (pe): "Dajudaju Esu ti ko inira (aisan) ati iya ba mi
ﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑ
38:42 (Molaika so fun un pe): "Fi ese re janle. Eyi ni omi iwe tutu ati omi mimu (fun iwosan re)
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
38:43 A si ta a lore awon ara ile re (pada) ati iru won pelu won. (O je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon onilaakaye
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
38:44 Fi owo re mu idi igi koriko tutu ki o fi lu (iyawo) re. Ma se yapa ibura re. Dajudaju Awa ri (’Ayyub) ni onisuuru. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri si odo Allahu ni (nipa ironupiwada)
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
38:45 Seranti awon erusin Wa, (Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub; awon alagbara, oluriran (nipa esin)
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
38:46 Dajudaju Awa sa won lesa pelu esa kan; iranti Ile Ikeyin
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
38:47 Dajudaju won wa ninu awon eni esa, eni rere julo ni odo Wa
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
38:48 Seranti (awon Anabi) ’Ismo‘il, al-Yasa‘ ati Thul-Kifl. Ikookan won wa ninu awon eni rere julo
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
38:49 Eyi ni iranti. Ati pe dajudaju abo rere wa fun awon oluberu (Allahu)
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
38:50 Awon Ogba Idera gbere (ni). Won si maa si awon ilekun re sile fun won
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
38:51 Won yoo rogboku ninu re. Won yoo maa beere fun awon eso pupo ati ohun mimu ninu re
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
38:52 Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, ti ojo ori won ko jura won lo yo si wa ni odo won
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
38:53 Eyi ni ohun ti Won n se ni adehun fun yin fun Ojo isiro-ise
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
38:54 Dajudaju eyi ni arisiki Wa. Ko si nii tan
ﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
38:55 Eyi (ri bee). Ati pe dajudaju abo buruku ni ti awon alagbeere (si Allahu)
ﯞﯟﯠﯡﯢ
38:56 Ina Jahanamo ni won yo wo. O si buru ni ibugbe
ﯣﯤﯥﯦﯧ
38:57 Eyi (ri bee). Nitori naa, ki won to o wo; omi gbigbona ati awoyunweje
ﯨﯩﯪﯫﯬ
38:58 Orisirisi (iya) miiran bi iru re (tun wa fun won)
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
38:59 Eyi ni ijo kan t’o maa wo inu Ina pelu yin. (Awon asiwaju ninu Ina si maa wi pe:) "Ko si maawole-maarora fun won." Dajudaju won yoo wo inu Ina ni
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
38:60 (Awon omoleyin ninu Ina) maa wi pe: "Rara, eyin naa ko si maawole-maarora fun yin. Eyin l’e pe wa sibi eyi (t’o bi Ina)." O si buru ni ibugbe
ﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒ
38:61 Won (tun) wi pe: "Oluwa wa, eni ti o pe wa (sibi iya) yii, se alekun adipele iya fun un ninu Ina
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
38:62 Won tun wi pe: "Ki lo sele si wa ti a o ri awon okunrin kan, awon ti a n ka mo awon eni buruku
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
38:63 Sebi a fi won se yeye tabi awon oju ti fo won ni (l’a o fi ri won ninu Ina)
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨﭩ
38:64 Dajudaju iyen, ariyanjiyan awon ero inu Ina, ododo ma ni
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
38:65 So pe: "Emi ni olukilo. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si ayafi Allahu, Okan soso, Olubori
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾ
38:66 Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji, Alagbara, Alaforijin
ﭿﮀﮁﮂﮃ
38:67 So pe: "(al-Ƙur’an) ni iro nla
ﮄﮅﮆﮇ
38:68 Eyin si n gbunri kuro nibe
ﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
38:69 Emi ko si nimo nipa awon molaika ti o wa ni aye giga nigba ti won n saroye
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
38:70 Ki ni won fi ranse si mi bi ko se pe emi ni olukilo ponnbele
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣﮤ
38:71 (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: "Dajudaju Emi yoo da abara kan lati inu erupe
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮ
38:72 Nigba ti Mo ba se e t’o dogba jale tan, ti Mo si fe ninu ategun emi ti Mo da sinu re, nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini
ﮯﮰﮱﯓﯔ
38:73 Gbogbo awon molaika patapata si fori kanle ki i
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛ
38:74 Ayafi ’Iblis, ti o segberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
38:75 (Allahu) so pe: "’Iblis, ki l’o ko fun o lati fori kanle ki ohun ti Mo fi owo Mi mejeeji da? Se o segberaga ni tabi o wa ninu awon eni giga
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴﯵﯶ
38:76 O wi pe: "Emi loore julo si oun; O da emi lati ara ina. O si da oun lati ara erupe amo
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
38:77 (Allahu) so pe: "Jade kuro ninu (Ogba Idera) nitori pe dajudaju iwo ni eni eko
ﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
38:78 Ati pe dajudaju egun Mi yoo wa lori re titi di Ojo esan
ﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
38:79 (Esu) wi pe: "Oluwa mi, lo mi lara titi di ojo ti Won yoo gbe eda dide
ﰋﰌﰍﰎﰏ
38:80 (Allahu) so pe: "Dajudaju iwo wa ninu awon ti won maa lo lara
ﰐﰑﰒﰓﰔ
38:81 titi di ojo akoko ti A ti mo
ﰕﰖﰗﰘﰙ
38:82 (Esu) wi pe: "Mo fi agbara Re bura, dajudaju emi yoo ko gbogbo won sinu isina
ﰚﰛﰜﰝﰞ
38:83 afi awon erusin Re, awon eni esa ninu won
ﭑﭒﭓﭔﭕ
38:84 (Allahu) so pe: "Ododo (ni ibura Mi), ododo si ni Emi n so, (pe)
ﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
38:85 dajudaju Mo maa fi iwo ati gbogbo awon t’o ba tele o ninu won kun inu ina Jahanamo
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
38:86 So pe: "Emi ko bi yin leere owo-oya kan lori re. Emi ko si si ninu awon onitan-aroso
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
38:87 Ki ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda
ﭯﭰﭱﭲﭳ
38:88 Ati pe dajudaju e maa mo iro re (si ododo) laipe

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers