PDF —
182 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah As-Saffat pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah As-Saffat pdf Yorùbá — Gbà Surah As-Saffat Itumọ. Surah As-Saffat (Meccan) 182 Ẹsẹ.

← YasinSurah As-Saffat Sad →


182 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓ
37:1 (Allahu bura pelu) awon molaika oluto-lowoowo taara
ﭔﭕﭖ
37:2 ati awon molaika t’o n wo esujo kiri taara
ﭗﭘﭙ
37:3 ati awon molaika onke-tira iranti
ﭚﭛﭜﭝ
37:4 Dajudaju Olohun yin, Okan soso ni
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
37:5 Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Oun si ni Oluwa awon ibuyo oorun
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
37:6 Dajudaju Awa fi awon irawo se sanmo ile aye ni oso
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
37:7 ati iso nibi (aburu) gbogbo esu olorikunkun
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺﭻﭼ
37:8 (Awon esu) ko si nii le teti si ijo (molaika t’o wa ni) aye giga julo (ninu sanmo). (Awon molaika) yo si maa ku (awon esu) loko (eta irawo) ni gbogbo agbegbe (sanmo)
ﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
37:9 Won n le won danu. Iya ailopin si wa fun won
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
37:10 (Won ko nii gbo oro ni kikun) ayafi eni ti o ba ri oro ajigbo gbe, nigba naa (ni molaika) yo si fi eta irawo ina t’o maa jo o tele e
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
37:11 Bi won leere wo pe se awon ni iseda won lagbara julo ni tabi awon (eniyan) ti A da? Dajudaju Awa da won lati ara erupe t’o le mora won
ﮙﮚﮛﮜ
37:12 Rara (ko jora won); iwo seemo (nipa al-Ƙur’an), awon si n se yeye
ﮝﮞﮟﮠﮡ
37:13 Ati pe nigba ti won ba se iranti fun won, won ko nii lo iranti
ﮢﮣﮤﮥﮦ
37:14 Nigba ti won ba tun ri ami kan, won yoo maa se yeye
ﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
37:15 Won si wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
37:16 Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo tun gbe wa dide ni
ﯗﯘﯙ
37:17 Se ati awon baba wa, awon eni akoko
ﯚﯛﯜﯝﯞ
37:18 So pe: "Bee ni. Eyin yo si di eni yepere
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
37:19 Nitori naa, igbe eyo kan ma ni. Nigba naa ni won yoo maa wo sun
ﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
37:20 Won a wi pe: "Egbe wa! Eyi ni Ojo esan
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
37:21 Eyi ni ojo Idajo eyi ti e n pe niro
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
37:22 E ko awon t’o sabosi jo, awon iyawo won ati ohun ti won n josin fun
ﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
37:23 leyin Allahu. Ki e si juwe won si oju ona ina Jehim
ﰆﰇﰈﰉﰊ
37:24 E da won duro na, dajudaju won maa bi won leere ibeere
ﭑﭒﭓﭔﭕ
37:25 Ki ni ko je ki e ranra yin lowo
ﭖﭗﭘﭙﭚ
37:26 Rara, won ti juwo juse sile ni oni ni
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
37:27 Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
37:28 (Awon eniyan) wi pe: "Dajudaju eyin l’e n gba otun wole si wa lara (lati si wa lona)
ﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
37:29 (Awon alujannu) wi pe: "Rara o (awa ko), eyin ni e ko je onigbagbo ododo
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
37:30 Ati pe awa ko ni agbara kan lori yin, sugbon eyin je ijo olutayo-enu ala
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
37:31 Oro Oluwa wa si ko le wa lori pe dajudaju awa yoo to Ina wo
ﮂﮃﮄﮅﮆ
37:32 Nitori naa, a si yin lona. Dajudaju awa naa si je olusina
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
37:33 Dajudaju ni ojo yen, akegbe ni won ninu Iya
ﮍﮎﮏﮐﮑ
37:34 Dajudaju bayen ni Awa yoo ti se pelu awon elese
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
37:35 Dajudaju nigba ti won ba so fun won pe "Ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu.", won yoo maa segberaga
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
37:36 Won si n wi pe: "Se a maa fi awon orisa wa sile nitori elewi were kan
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
37:37 Ko ri bee. O mu ododo wa ni. O si n jerii si ododo awon Ojise naa
ﮪﮫﮬﮭﮮ
37:38 Dajudaju e maa to iya eleta-elero wo
ﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖ
37:39 A o nii san yin ni esan kan afi ohun ti e n se nise
ﯗﯘﯙﯚﯛ
37:40 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa
ﯜﯝﯞﯟﯠ
37:41 Ti awon wonyen si ni arisiki ti won ti mo
ﯡﯢﯣﯤ
37:42 awon eso. Awon si ni alapon-onle
ﯥﯦﯧﯨ
37:43 ninu awon Ogba Idera
ﯩﯪﯫﯬ
37:44 Lori awon ite ni won yoo ti koju sira won
ﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
37:45 Won yoo maa gbe ife oti mimo kaa kiri odo won
ﯳﯴﯵﯶ
37:46 Funfun ni (oti naa). O n dun lenu awon t’o maa mu un
ﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
37:47 Ko si ipalara kan fun won ninu re, won ko si nii hunrira lori re
ﯿﰀﰁﰂﰃ
37:48 Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, awon eleyinju ege yo si wa lodo won
ﰄﰅﰆﰇ
37:49 Won da bi tinu eyin. o tun je ki a mo pe won ko reti ike kan kan lorun ni tiwon. Ti o ba je pe won n reti ike kan ni orun
ﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
37:50 Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere
ﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕ
37:51 Onsoro kan ninu won yoo so pe: "Dajudaju emi ni ore kan
ﭑﭒﭓﭔﭕ
37:52 ti o n wi pe, “Se dajudaju iwo wa ninu awon onigbagbo ninu Ojo Ajinde
ﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
37:53 Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo san wa ni esan ni?”
ﭞﭟﭠﭡﭢ
37:54 O so pe: "Se eyin yoo yoju wo (eni naa ti ko gbagbo ninu Ojo ajinde)
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
37:55 O yoju wo o. O si ri i laaarin gbungbun ninu ina Jehim
ﭩﭪﭫﭬﭭﭮ
37:56 O (si) so pe: "Mo fi Allahu bura, iwo fee ko iparun ba mi tan
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
37:57 Ati pe ti ki i ba se idera Oluwa mi ni, emi naa iba wa ninu eni ti won maa mu wa sinu Ina
ﭶﭷﭸﭹ
37:58 Awa ko sa nii ku mo bayii
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
37:59 Afi iku wa akoko. Won ko si nii je awa niya
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
37:60 Dajudaju eyi, ohun ni erenje nla
ﮇﮈﮉﮊﮋ
37:61 Nitori iru eyi, ki awon olusesin maa sesin lo
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
37:62 Nje iyen l’o loore julo ni ibudesi ni tabi igi zaƙum (igi elegun-un)
ﮓﮔﮕﮖﮗ
37:63 Dajudaju Awa se e ni adanwo fun awon alabosi
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
37:64 Dajudaju ohun ni igi kan ti o maa hu jade lati idi ina Jehim
ﮟﮠﮡﮢﮣ
37:65 Eso re da bi ori awon esu
ﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
37:66 Dajudaju won yoo maa je ninu re. Nitori naa, won yoo fi kun inu won bamubamu
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
37:67 Leyin naa, dajudaju won yoo mu nnkan mimu awoyunweje gbigbona le e lori
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
37:68 Leyin naa, dajudaju ibupadasi won ni ina Jehim
ﯚﯛﯜﯝﯞ
37:69 Dajudaju won ba awon baba won ni olusina
ﯟﯠﯡﯢﯣ
37:70 Awon naa si n yara tele oripa won
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
37:71 Dajudaju opolopo awon eni akoko ti sina siwaju won
ﯪﯫﯬﯭﯮ
37:72 Dajudaju A ti ran awon olukilo si won
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
37:73 Nitori naa, wo bi atubotan awon eni-akilo-fun ti ri
ﯵﯶﯷﯸﯹ
37:74 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
37:75 Dajudaju (Anabi) Nuh pe Wa. A si dara ni olujepe
ﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
37:76 A gba oun ati awon ara ile re la kuro ninu ibanuje nla
ﭑﭒﭓﭔﭕ
37:77 A da awon aromodomo re si leyin re
ﭖﭗﭘﭙﭚ
37:78 A si fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin
ﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
37:79 Alaafia ki o maa ba (Anabi) Nuh laaarin gbogbo eda
ﭡﭢﭣﭤﭥ
37:80 Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
ﭦﭧﭨﭩﭪ
37:81 Dajudaju oun wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo
ﭫﭬﭭﭮ
37:82 Leyin naa, A te awon yooku ri sinu agbami
ﭯﭰﭱﭲﭳﭴ
37:83 Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim wa ninu ijo (ti o tele ilana) re
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
37:84 (E ranti) nigba ti oun naa doju ko Oluwa re pelu okan mimo
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
37:85 (Ranti) nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Ki ni e n josin fun
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇ
37:86 Se e n gbero lati so iro di olohun leyin Allahu
ﮈﮉﮊﮋﮌ
37:87 Ki si ni ero okan yin si Oluwa gbogbo eda?”
ﮍﮎﮏﮐﮑ
37:88 O siju wo awon irawo gan-an
ﮒﮓﮔﮕ
37:89 O si so pe: "Dajudaju o re mi
ﮖﮗﮘﮙ
37:90 Nitori naa, won pa a ti, won si lo
ﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
37:91 Nigba naa, o lo si odo awon orisa won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni
ﮡﮢﮣﮤﮥ
37:92 Ki ni o se yin ti e o soro
ﮦﮧﮨﮩﮪ
37:93 Nigba naa, o doju lilu ko won pelu owo otun (o si run won womuwomu)
ﮫﮬﮭﮮ
37:94 (Awon aborisa) sare wa doju ko o
ﮯﮰﮱﯓﯔ
37:95 O so pe: "Se e oo maa josin fun nnkan ti e gbe kale lere ni
ﯕﯖﯗﯘﯙ
37:96 Allahu l’O si da eyin ati nnkan ti e n se nise
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
37:97 Won wi pe: "E mo ile kan fun un, ki e si ju u sinu ina
ﯢﯣﯤﯥﯦﯧ
37:98 Won gbero ete si i. A si so won di eni yepere
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
37:99 O so pe: "Dajudaju mo maa lo si (ilu ti) Oluwa mi (pa mi lase lati lo). O si maa to mi sona (lati de ibe)
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
37:100 Oluwa mi, ta mi lore omo ninu awon eni rere
ﯵﯶﯷﯸ
37:101 A si fun un ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin alafarada
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕ
37:102 Nigba ti (omo naa) dagba, ti o to ba (baba re) se ise, (baba re) so pe: "Omo mi, dajudaju emi la ala pe dajudaju mo n dunbu re. Nitori naa, woye si i, ki ni o ri si i." O so pe: "Baba mi, se ohun ti Won pa lase fun o. O maa ba mi ninu awon onisuuru, ti Allahu ba fe
ﭑﭒﭓﭔﭕ
37:103 Nigba ti awon mejeeji juwo juse sile, ti (Anabi ’Ibrohim) si doju (omo) re bole
ﭖﭗﭘﭙ
37:104 A pe e (bayii) pe, ’Ibrohim
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
37:105 o kuku ti mu ala naa se. Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
ﭣﭤﭥﭦﭧﭨ
37:106 Dajudaju eyi, ohun ni adanwo ponnbele
ﭩﭪﭫﭬ
37:107 A si fi agbo nla serapada re
ﭭﭮﭯﭰﭱ
37:108 A tun fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin
ﭲﭳﭴﭵ
37:109 Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ibrohim
ﭶﭷﭸﭹ
37:110 Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
ﭺﭻﭼﭽﭾ
37:111 Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo
ﭿﮀﮁﮂﮃﮄ
37:112 A tun fun un ni iro idunnu (nipa bibi) ’Ishaƙ, (o maa je) Anabi. (O si maa wa) ninu awon eni rere
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
37:113 Ati pe A fun oun ati ’Ishaƙ ni ibukun. Eni rere ati alabosi ponnbele (t’o n sabosi si) emi ara re wa ninu aromodomo awon mejeeji
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
37:114 Dajudaju A soore fun (Anabi) Musa ati Harun
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
37:115 A gba awon mejeeji ati ijo awon mejeeji la kuro ninu ibanuje nla
ﮝﮞﮟﮠﮡ
37:116 A tun saranse fun won. Awon ni won je olubori (ota won)
ﮢﮣﮤﮥ
37:117 A si fun awon mejeeji ni Tira t’o yanju
ﮦﮧﮨﮩ
37:118 A tun fi awon mejeeji mona taara
ﮪﮫﮬﮭﮮ
37:119 A fun awon mejeeji ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin
ﮯﮰﮱﯓﯔ
37:120 Alaafia ki o maa ba (Anabi) Musa ati Harun
ﯕﯖﯗﯘﯙ
37:121 Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
ﯚﯛﯜﯝﯞ
37:122 Dajudaju awon mejeeji wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo
ﯟﯠﯡﯢﯣ
37:123 Dajudaju (Anabi) ’Ilyas wa ninu awon Ojise
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
37:124 (E ranti) nigba ti o so fun ijo re pe: "Se e o nii beru Allahu ni
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
37:125 Se e oo maa pe orisa kan, e si maa fi Eni t’O dara julo ninu awon eledaa sile, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Oun l’O si dara julo ninu awon oludajo. (surah al-’A‘rof 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Oun si yara julo ninu awon onisiro. (surah al-’Ani‘am 6:62) oludajo alaaanu ibaa mo bii omo ina igun afi ki Allahu je Eledaa re. Koda adamo owo ati okowo ti won so di “oro-Aje. Awon t’o n bo elomiiran naa n sora won di olupese. Yato si pe Allahu ti fi rinle pe Oun nikan ni Olupese fun gbogbo eda Re. Ti eyi ko ba ti i da awon kan loju bee ti won si fe gbe gbogbo ipese olukuluku lori iwon ninu aanu ti Allahu fi si awon eda kan lokan ni won fi di alaaanu. Nitori naa Allahu ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
37:126 (e n fi) Allahu (sile), Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko
ﭑﭒﭓﭔ
37:127 Won si pe e ni opuro. Nitori naa, won maa mu won wa sinu Ina
ﭕﭖﭗﭘﭙ
37:128 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa
ﭚﭛﭜﭝﭞ
37:129 A fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin
ﭟﭠﭡﭢﭣ
37:130 Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ilyas
ﭤﭥﭦﭧﭨ
37:131 Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
ﭩﭪﭫﭬﭭ
37:132 Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo
ﭮﭯﭰﭱﭲ
37:133 Dajudaju (Anabi) Lut wa ninu awon Ojise
ﭳﭴﭵﭶﭷ
37:134 (E ranti) nigba ti A gba oun ati gbogbo awon ara ile re la
ﭸﭹﭺﭻﭼ
37:135 Ayafi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare)
ﭽﭾﭿﮀ
37:136 Leyin naa, A pa awon yooku run
ﮁﮂﮃﮄﮅ
37:137 Dajudaju eyin naa kuku n gba odo won koja laaaro-laaaro
ﮆﮇﮈﮉﮊ
37:138 ati ni alaale. Se e o nii se laakaye ni
ﮋﮌﮍﮎﮏ
37:139 Dajudaju (Anabi) Yunus kuku wa ninu awon Ojise
ﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
37:140 (E ranti) nigba ti o sa lo sinu oko oju-omi t’o kun keke
ﮖﮗﮘﮙﮚ
37:141 O si ba won muje po. O si wa ninu awon ti aje si mo lori
ﮛﮜﮝﮞﮟ
37:142 Nitori naa, eja gbe e mi; o si n da ara re lebi
ﮠﮡﮢﮣﮤﮥ
37:143 Nitori naa, ti ko ba je pe o wa ninu awon olusafomo fun Allahu
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
37:144 dajudaju iba wa ninu eja titi di ojo ti won yoo gbe eda dide
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
37:145 Nitori naa, A ju u si ori ile gbansasa leti omi. O si je alailera
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
37:146 A si mu igi Yeƙtin hu jade lati siji bo o
ﯚﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
37:147 A tun ran an nise si oke marun-un (eniyan) tabi ki won lekun si i
ﯡﯢﯣﯤﯥ
37:148 Won gbagbo ni ododo. A si fun won ni igbadun titi di igba die
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
37:149 Bi won leere wo pe: "Se Oluwa re l’o ni awon omobinrin, tiwon si ni omokunrin
ﯬﯭﯮﯯﯰﯱﯲ
37:150 Tabi A da awon molaika ni obinrin, ti awon si je elerii
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
37:151 Gbo, ninu iro won ni pe dajudaju won n wi pe
ﯹﯺﯻﯼﯽ
37:152 Allahu bimo." Dajudaju opuro ni won
ﯾﯿﰀﰁﰂ
37:153 Se (Allahu) sesa awon omobinrin lori awon omokunrin ni
ﭑﭒﭓﭔﭕ
37:154 Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii
ﭖﭗﭘ
37:155 Se e o nii lo iranti ni
ﭙﭚﭛﭜﭝ
37:156 Tabi e ni eri t’o yanju lowo ni
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
37:157 E mu tira yin wa nigba naa ti e ba je olododo
ﭤﭥﭦﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
37:158 Won tun fi ibatan saaarin (Allahu) ati alujannu! Awon alujannu si ti mo pe dajudaju won kuku maa mu awon wa sinu Ina ni
ﭰﭱﭲﭳﭴ
37:159 Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re)
ﭵﭶﭷﭸﭹ
37:160 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa
ﭺﭻﭼﭽ
37:161 Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun (leyin Allahu)
ﭾﭿﮀﮁﮂ
37:162 e o le fi si eni kan kan lona
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
37:163 afi eni ti o ba fe wo inu ina Jehim
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
37:164 Ko si eni kan ninu awa (molaika) afi ki o ni ibuduro ti won ti mo
ﮐﮑﮒﮓ
37:165 Dajudaju awa, a kuku wa ni owoowo
ﮔﮕﮖﮗ
37:166 Ati pe dajudaju awa, awa kuku ni olusafomo (fun Allahu)
ﮘﮙﮚﮛ
37:167 Won kuku n wi pe
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
37:168 Ti o ba je pe dajudaju a ba ni (tira) iranti kan ninu (awon tira) awon eni akoko
ﮣﮤﮥﮦﮧ
37:169 dajudaju awa iba je erusin Allahu, awon eni esa
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
37:170 Sugbon won sai gbagbo ninu (Allahu). Laipe won maa mo
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
37:171 Dajudaju oro Wa ti siwaju fun awon erusin Wa, awon Ojise
ﯕﯖﯗﯘ
37:172 Dajudaju awon, awon l’a kuku maa saranse fun
ﯙﯚﯛﯜﯝ
37:173 Ati pe dajudaju awon omo ogun Wa, awon kuku ni olubori
ﯞﯟﯠﯡﯢ
37:174 Nitori naa, seri kuro lodo won fun igba die
ﯣﯤﯥﯦ
37:175 Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo
ﯧﯨﯩ
37:176 Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
37:177 Nigba ti o ba sokale si agboole won, owuro ojo naa yo si buru fun awon eni-akilo-fun
ﯱﯲﯳﯴﯵ
37:178 Kuro lodo won titi di igba kan na
ﯶﯷﯸﯹ
37:179 Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀ
37:180 Mimo ni fun Oluwa re, Oluwa agbara, tayo ohun ti won n fi royin (Re)
ﰁﰂﰃﰄ
37:181 Ki alaafia maa ba awon Ojise
ﰅﰆﰇﰈﰉ
37:182 Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers