PDF —
50 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Mursalat pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Mursalat pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Mursalat Itumọ. Surah Al-Mursalat (Meccan) 50 Ẹsẹ.

← Al-InsanSurah Al-Mursalat An-Naba →


50 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮑﮒﮓ
77:1 Allahu bura pelu awon ategun t’o n sare ni telentele
ﮔﮕﮖ
77:2 O bura pelu awon iji ategun t’o n ja
ﮗﮘﮙ
77:3 O bura pelu awon ategun t’o n tu esujo ka
ﮚﮛﮜ
77:4 O bura pelu awon t’o n sepinya laaarin ododo ati iro
ﮝﮞﮟ
77:5 O tun bura pelu awon molaika t’o n mu iranti wa (ba awon Ojise)
ﮠﮡﮢﮣ
77:6 (Iranti naa je) awijare tabi ikilo
ﮤﮥﮦﮧ
77:7 Dajudaju ohun ti A se ni adehun fun yin kuku maa sele
ﮨﮩﮪﮫ
77:8 Nitori naa, nigba ti won ba pa (imole) irawo re
ﮬﮭﮮﮯ
77:9 ati nigba ti won ba si sanmo sile gbagada
ﮰﮱﯓﯔ
77:10 ati nigba ti won ba ku awon apata danu
ﯕﯖﯗﯘ
77:11 ati nigba ti won ba fun awon Ojise ni asiko lati kojo, (Akoko naa ti de niyen)
ﯙﯚﯛﯜ
77:12 Ojo wo ni won so (awon isele wonyi) ro fun na
ﯝﯞﯟ
77:13 Fun ojo ipinya (laaarin awon eda) ni
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
77:14 Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo ipinya
ﯦﯧﯨﯩ
77:15 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﯪﯫﯬﯭ
77:16 Nje Awa ko ti pa awon eni akoko re bi
ﯮﯯﯰﯱ
77:17 Leyin naa, A si maa fi awon eni Ikeyin tele won (ninu iparun)
ﯲﯳﯴﯵ
77:18 Bayen ni A o ti se pelu awon elese
ﯶﯷﯸﯹ
77:19 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
77:20 Se A o seda yin lati inu omi lile yepere bi
ﭗﭘﭙﭚﭛ
77:21 Leyin naa, A fi sinu aye aabo (iyen, ile-omo)
ﭜﭝﭞﭟ
77:22 titi di gbedeke akoko kan ti A ti mo (iyen, ojo ibimo)
ﭠﭡﭢﭣ
77:23 A si ni ikapa ati ayanmo (lori re). (Awa si ni) Olukapa ati Olupebubu eda t’o dara
ﭤﭥﭦﭧ
77:24 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﭨﭩﭪﭫﭬ
77:25 Nje Awa ko se ile ni ohun t’o n ko eda jo mora won
ﭭﭮﭯ
77:26 (iyen) awon alaaye ati awon oku
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
77:27 A si fi awon apata gbagidi giga-giga sinu re. A si fun yin ni omi didun mu
ﭸﭹﭺﭻ
77:28 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
77:29 E maa lo si ibi ti e n pe niro
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
77:30 E maa lo si ibi eefin eleka meta
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
77:31 Ki i se iboji tutu. Ko si nii ro won loro ninu ijofofo Ina
ﮑﮒﮓﮔﮕ
77:32 Dajudaju (Ina naa) yoo maa ju etapara (re soke t’o maa da) bi peteesi
ﮖﮗﮘﮙ
77:33 (O maa da) bi awon rakunmi alawo omi osan
ﮚﮛﮜﮝ
77:34 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﮞﮟﮠﮡﮢ
77:35 Eyi ni ojo ti won ko nii soro
ﮣﮤﮥﮦﮧ
77:36 A o si nii yonda (oro siso) fun won, ambosibosi pe won yoo mu awawi wa
ﮨﮩﮪﮫ
77:37 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
77:38 Eyi ni ojo ipinya. Awa yo si ko eyin ati awon eni akoko jo
ﯔﯕﯖﯗﯘﯙ
77:39 Ti e ba ni ete kan lowo, e dete si Mi wo
ﯚﯛﯜﯝ
77:40 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣ
77:41 Dajudaju awon oluberu Allahu yoo wa nibi iboji ati awon omi iseleru
ﯤﯥﯦﯧ
77:42 ati awon eso eyi ti won ba n fe
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮ
77:43 E je, ki e si mu pelu igbadun nitori ohun ti e n se nise
ﯯﯰﯱﯲﯳ
77:44 Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
ﯴﯵﯶﯷ
77:45 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽ
77:46 E je, ki e si gbadun fun igba die. Dajudaju elese ni yin
ﯾﯿﰀﰁ
77:47 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﰂﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
77:48 Nigba ti won ba so fun won pe ki won kirun, won ko nii kirun
ﰉﰊﰋﰌ
77:49 Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
ﰍﰎﰏﰐﰑ
77:50 Nigba naa, oro wo ni won yoo gbagbo leyin re

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers