Surah Al-Mutaffifin pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Al-Mutaffifin pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Mutaffifin Itumọ. Surah Al-Mutaffifin (Meccan) 36 Ẹsẹ.
Related
More Surah PDF
Surah Al-Mutaffifin

ﯖﯗﯘ
83:1
Egbe ni fun awon oludin-osuwon-ku
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
83:2
awon (ontaja) t’o je pe nigba ti won ba won nnkan lodo awon eniyan, won a gba a ni ekun
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
83:3
nigba ti awon (ontaja naa) ba si lo iwon fun awon (onraja) tabi lo osuwon fun won, won yoo din in ku
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
83:4
Se awon wonyen ko mo daju pe dajudaju A maa gbe won dide
ﭑﭒﭓ
83:5
ni Ojo nla kan
ﭔﭕﭖﭗﭘﭙ
83:6
Ni ojo ti awon eniyan yoo dide naro fun Oluwa gbogbo eda
ﭚﭛﭜﭝﭞﭟﭠ
83:7
Bee ni, dajudaju iwe ise awon eni ibi kuku wa ninu Sijjin
ﭡﭢﭣﭤﭥ
83:8
Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je Sijjin
ﭦﭧﭨ
83:9
Iwe ti won ti ko ise aburu eda sinu re (ti won si fi pamo sinu ile keje ni Sijjin)
ﭩﭪﭫﭬ
83:10
Ni ojo yen, egbe ni fun awon olupe-ododo- niro
ﭭﭮﭯﭰﭱ
83:11
awon t’o n pe Ojo esan niro
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
83:12
Ko si si eni t’o n pe e niro afi gbogbo alakoyo, elese
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁ
83:13
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: "Awon akosile alo awon eni akoko (niwonyi)
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
83:14
Rara ko ri bee, amo ohun ti won n se nise ibi l’o joba lori okan won
ﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓ
83:15
Ni ti ododo, dajudaju won yoo wa ninu gaga, won ko si nii ri Oluwa won ni ojo yen
ﮔﮕﮖﮗﮘ
83:16
Leyin naa, dajudaju won yoo wo inu ina Jehim
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
83:17
Leyin naa, won maa so (fun won) pe: "Eyi ni ohun ti e n pe niro
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
83:18
Bee ni. Dajudaju iwe ise awon eni rere wa ninu ‘illiyyun
ﮨﮩﮪﮫﮬ
83:19
Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je ‘illiyyun
ﮭﮮﮯ
83:20
Iwe ti won ti ko ise rere eda sinu re (ti won si fi pamo si oke sanmo ni ‘illiyyun)
ﮰﮱﯓ
83:21
Awon (molaika) ti won sunmo Allahu n jerii si i
ﯔﯕﯖﯗﯘ
83:22
Dajudaju awon eni rere maa wa ninu igbadun
ﯙﯚﯛﯜ
83:23
Won yoo maa woran lori awon ibusun
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
83:24
Iwo yoo da itutu oju igbadun mo ninu oju won
ﯣﯤﯥﯦﯧ
83:25
Won yoo maa fun won mu ninu oti onideeri
ﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
83:26
Alumisiki ni (oorun) ipari re. Ki awon alapaantete sapantete ninu iyen
ﯰﯱﯲﯳ
83:27
Tesnim ni won yoo maa popo (mo oti naa)
ﯴﯵﯶﯷﯸ
83:28
(Tesnim ni) omi iseleru kan, ti awon olusunmo (Allahu) yoo maa mu
ﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁ
83:29
Dajudaju awon t’o dese, won maa n fi awon t’o gbagbo ni ododo rerin-in
ﰂﰃﰄﰅﰆ
83:30
Nigba ti won ba gba egbe won koja, (awon adese) yoo maa seju sira won ni ti yeye
ﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
83:31
Nigba ti won ba si pada si odo awon eniyan won, won a pada ti won yoo maa se faari
ﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔ
83:32
Ati pe nigba ti won ba ri (awon onigbagbo ododo) won a wi pe: "Dajudaju awon wonyi ni olusina
ﰕﰖﰗﰘﰙ
83:33
Awa ko si ran won nise oluso si won
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
83:34
Nitori naa, ni oni awon t’o gbagbo ni ododo yoo fi awon alaigbagbo rerin-in
ﭘﭙﭚﭛ
83:35
Won yoo maa woran lori awon ibusun
ﭜﭝﭞﭟﭠﭡﭢ
83:36
Sebi won ti fi ohun ti awon alaigbagbo n se nise san won lesan (bayii)
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







