Surah Al-Infitar pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Al-Infitar pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Infitar Itumọ. Surah Al-Infitar (Meccan) 19 Ẹsẹ.
Related
More Surah PDF
Surah Al-Infitar

ﭑﭒﭓﭔ
82:1
Nigba ti sanmo ba fa ya perepere
ﭕﭖﭗﭘ
82:2
ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri
ﭙﭚﭛﭜ
82:3
ati nigba ti awon ibudo ba san jara won
ﭝﭞﭟﭠ
82:4
ati (nigba ti A ba ta ile soke), ti A si mu awon oku jade (laaye) lati inu awon saree
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
82:5
(nigba naa ni) emi kookan yoo mo ohun ti o ti siwaju (ninu ise re) ati ohun ti o fi seyin (ninu oripa ise re)
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬﭭ
82:6
Iwo eniyan, ki ni o tan o je nipa Oluwa re, Alapon-onle
ﭮﭯﭰﭱﭲ
82:7
Eni t’O seda re? O seda re ni pipe. O si mu o dogba jale leeyan
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
82:8
O to eya ara re papo sinu eyikeyii aworan ti O fe
ﭺﭻﭼﭽﭾ
82:9
Ni ti ododo, nse l’e n pe Ojo esan niro
ﭿﮀﮁﮂ
82:10
Dajudaju awon eso si wa ni odo yin
ﮃﮄﮅ
82:11
(Won je) alapon-onle, onkowe-ise eda
ﮆﮇﮈﮉ
82:12
Won mo ohun ti e n se nise
ﮊﮋﮌﮍﮎ
82:13
Dajudaju awon eni rere yoo kuku wa ninu igbadun
ﮏﮐﮑﮒﮓ
82:14
Dajudaju awon eni ibi yo si kuku wa ninu ina Jehim
ﮔﮕﮖﮗ
82:15
Won yoo wo inu re ni Ojo esan
ﮘﮙﮚﮛﮜ
82:16
Won ko si nii kuro ninu re
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
82:17
Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan
ﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩ
82:18
Leyin naa, ki ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕ
82:19
(Ojo esan ni) ojo ti emi kan ko nii kapa kini kan fun emi kan. Gbogbo ase ojo yen si n je ti Allahu
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







