PDF —
46 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah An-Nazi'at pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah An-Nazi'at pdf Yorùbá — Gbà Surah An-Nazi'at Itumọ. Surah An-Nazi'at (Meccan) 46 Ẹsẹ.

← An-NabaSurah An-Nazi'at 'Abasa →


46 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮢﮣﮤ
79:1 Allahu bura pelu awon molaika t’o n fi ona ele gba emi awon alaigbagbo
ﮥﮦﮧ
79:2 O tun bura pelu awon molaika t’o n fi ona ero gba emi awon onigbagbo ododo
ﮨﮩﮪ
79:3 O tun bura pelu awon molaika t’o n yara gaga nibi ase Re
ﮫﮬﮭ
79:4 O tun bura pelu awon molaika t’o maa siwaju emi awon onigbagbo ododo wonu Ogba Idera taara
ﮮﮯﮰ
79:5 O tun bura pelu awon molaika t’o n seto ile aye
ﮱﯓﯔﯕ
79:6 Ni ojo ti ifon akoko fun opin aye maa mi gbogbo aye titi pelu ohun igbe
ﯖﯗﯘ
79:7 Ifon keji fun Ajinde si maa tele e
ﯙﯚﯛﯜ
79:8 Awon okan yoo maa gbon pepe ni ojo yen
ﯝﯞﯟ
79:9 Oju won yo si wale ni ti iyepere
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
79:10 Won yoo wi pe: "Se Won tun maa da wa pada si ibere isemi (bii taye ni)
ﯦﯧﯨﯩﯪ
79:11 Se nigba ti a ti di eegun t’o kefun tan
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰ
79:12 Won wi pe: "Idapada ofo niyen nigba naa (fun eni t’o pe e niro)
ﯱﯲﯳﯴﯵ
79:13 Nitori naa, igbe eyo kan si ni
ﯶﯷﯸﯹ
79:14 Nigba naa ni won yoo bara won lori ile gbansasa
ﯺﯻﯼﯽﯾ
79:15 Nje oro (Anabi) Musa ti de odo re
ﯿﰀﰁﰂﰃﰄﰅ
79:16 (Ranti) nigba ti Oluwa re pe e ni afonifoji mimo, Tuwa
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
79:17 Lo ba Fir‘aon, dajudaju o ti tayo enu-ala
ﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
79:18 Ki o si so pe: "Nje o maa safomo ara re (kuro ninu aigbagbo) bi
ﭞﭟﭠﭡﭢ
79:19 Ki emi si fi ona mo o de odo Oluwa re. Nitori naa, ki o paya (Re)
ﭣﭤﭥﭦ
79:20 O si fi ami t’o tobi han an
ﭧﭨﭩ
79:21 (Amo) o pe e lopuro. O si yapa re
ﭪﭫﭬﭭ
79:22 Leyin naa, o keyin si i. O si n sise (tako o)
ﭮﭯﭰ
79:23 O ko (awon eniyan) jo, o si ke gbajari
ﭱﭲﭳﭴﭵ
79:24 O si wi pe: "Emi ni oluwa yin, eni giga julo
ﭶﭷﭸﭹﭺﭻ
79:25 Nitori naa, Allahu gba a mu pelu iya ikeyin ati akoko (nipa oro enu re ikeyin yii ati akoko)
ﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂ
79:26 Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun eni t’o n paya (Allahu)
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
79:27 Se eyin le lagbara julo ni iseda ni tabi sanmo ti Allahu mo
ﮋﮌﮍﮎ
79:28 Allahu gbe aja re ga soke. O si se e ni pipe t’o gun rege
ﮏﮐﮑﮒﮓ
79:29 O se oru re ni dudu. O si fa iyaleta re yo jade
ﮔﮕﮖﮗﮘ
79:30 Ati ile, O te e perese leyin iyen
ﮙﮚﮛﮜﮝ
79:31 O mu omi re ati irugbin re jade lati inu re
ﮞﮟﮠ
79:32 Ati awon apata, O fi idi won mule sinsin
ﮡﮢﮣﮤ
79:33 Igbadun ni fun yin ati fun awon eran-osin yin
ﮥﮦﮧﮨﮩ
79:34 Sugbon nigba ti iparun nla ba de
ﮪﮫﮬﮭﮮﮯ
79:35 ni ojo ti eniyan yoo ranti ohun t’o se nise
ﮰﮱﯓﯔﯕ
79:36 Won si maa fi Ina han kedere fun (gbogbo) eni t’o riran
ﯖﯗﯘﯙ
79:37 Nitori naa, ni ti eni t’o ba tayo enu-ala
ﯚﯛﯜﯝ
79:38 ti o tun gbe ajulo fun isemi aye
ﯞﯟﯠﯡﯢ
79:39 dajudaju ina Jehim, ohun ni ibugbe (re)
ﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬ
79:40 Ni ti eni ti o ba paya iduro niwaju Oluwa re, ti o tun ko ife-inu fun emi (ara re)
ﯭﯮﯯﯰﯱ
79:41 dajudaju Ogba Idera, ohun ni ibugbe (re)
ﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
79:42 Won n bi o leere nipa Akoko naa pe: "Igba wo l’o maa sele
ﯸﯹﯺﯻﯼ
79:43 Ona wo ni iwo le fi ni (imo) iranti re na
ﯽﯾﯿﰀ
79:44 Odo Oluwa re ni opin imo nipa re wa
ﰁﰂﰃﰄﰅﰆ
79:45 Iwo kuku ni olukilo fun eni t’o n paya re
ﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
79:46 Ni ojo ti won maa ri i, won maa da bi eni pe won ko lo tayo irole tabi iyaleta (ojo) kan lo (nile aye)

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers