PDF —
42 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah 'Abasa pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah 'Abasa pdf Yorùbá — Gbà Surah 'Abasa Itumọ. Surah 'Abasa (Meccan) 42 Ẹsẹ.



42 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓ
80:1 (Anabi s.a.w.) faju ro, o si peyin da
ﭔﭕﭖﭗ
80:2 nitori pe afoju wa ba a
ﭘﭙﭚﭛﭜ
80:3 Ki si l’o maa fi mo o pe o see se ki o safomo (ara re kuro ninu aigbagbo)
ﭝﭞﭟﭠﭡ
80:4 tabi ki o gbo iranti, ki iranti naa si se e ni anfaani
ﭢﭣﭤﭥ
80:5 Ni ti eni ti o ka ara re kun oloro
ﭦﭧﭨﭩ
80:6 oun ni iwo teti si
ﭪﭫﭬﭭﭮ
80:7 Ko si si ese fun o bi ko ba se afomo (ara re kuro ninu aigbagbo)
ﭯﭰﭱﭲﭳ
80:8 Ni ti eni ti o si wa ba o, t’o n yara gaga (si iranti, iyen afoju)
ﭴﭵﭶ
80:9 ti o si n paya (Allahu)
ﭷﭸﭹﭺ
80:10 iwo ko si kobi ara si i
ﭻﭼﭽﭾ
80:11 Rara (ko to bee). Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti
ﭿﮀﮁﮂ
80:12 Nitori naa, eni ti o ba fe ki o ranti re
ﮃﮄﮅﮆ
80:13 (Al-Ƙur’an) wa ninu awon takada alapon-onle
ﮇﮈﮉ
80:14 A gbe e ga, A si se e ni mimo
ﮊﮋﮌ
80:15 ni owo awon onkotia (iyen, awon molaika)
ﮍﮎﮏ
80:16 awon alapon-onle, awon eni rere
ﮐﮑﮒﮓﮔ
80:17 Won ti fi eniyan gegun-un (nipa) bi o se je alaimoore julo
ﮕﮖﮗﮘﮙ
80:18 Ki si ni Allahu fi seda re
ﮚﮛﮜﮝﮞ
80:19 Ninu ato l’O ti seda re. O si pebubu (eya-ara) re
ﮟﮠﮡﮢ
80:20 Leyin naa, O se ona atiwaye ni irorun fun un
ﮣﮤﮥﮦ
80:21 Leyin naa, O maa pa a. O si maa fi sinu saree
ﮧﮨﮩﮪﮫ
80:22 Leyin naa, nigba ti Allahu ba fe, O maa gbe e dide
ﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
80:23 E gbo, eniyan ko ti i se nnkan ti Allahu pa lase fun un
ﯓﯔﯕﯖﯗ
80:24 Nitori naa, ki eniyan woye si ounje re
ﯘﯙﯚﯛﯜ
80:25 Dajudaju Awa n ro ojo ni pupo
ﯝﯞﯟﯠﯡ
80:26 Leyin naa, A mu ile san kankan
ﯢﯣﯤﯥ
80:27 A si mu koro eso hu jade lati inu re
ﯦﯧﯨ
80:28 ati eso ajara ati kannafuru
ﯩﯪﯫ
80:29 ati igi ororo Zaetun ati dabinu
ﯬﯭﯮ
80:30 ati awon ogba t’o kun fun igi
ﯯﯰﯱ
80:31 ati awon eso (miiran) pelu ewe ti eranko n je, (A mu won hu jade)
ﯲﯳﯴﯵ
80:32 (Won je nnkan) igbadun fun eyin ati awon eran-osin yin
ﯶﯷﯸﯹ
80:33 Nigba ti fifon sinu iwo nigba keji ba sele
ﯺﯻﯼﯽﯾﯿ
80:34 ni ojo ti eniyan yoo sa fun arakunrin re
ﰀﰁﰂ
80:35 ati iya re pelu baba re
ﰃﰄﰅ
80:36 ati iyawo re pelu awon omo re
ﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
80:37 Eni kookan won ni ojo yen l’o ti ni oran t’o maa to o o ran
ﰍﰎﰏﰐ
80:38 Awon oju kan lojo yen yoo mole
ﰑﰒﰓ
80:39 Won yo maa rerin-in, won yo si maa dunnu
ﰔﰕﰖﰗﰘ
80:40 Awon oju kan lojo yen ni eruku yo si bo mole
ﭑﭒﭓ
80:41 Okunkun yo si bo won mole
ﭔﭕﭖﭗﭘ
80:42 Awon wonyen, awon ni alaigbagbo, elese

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers