Surah An-Nazi'at ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah An-Nazi'at pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (46 Ẹsẹ — مكية). An-Nazi'at Gbọ, An-Nazi'at Itumọ, An-Nazi'at mp3, An-Nazi'at pdf.

Ka ati Gbọ Surah An-Nazi'at

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
وَالنَّازِعَاتِ غَرْقًا ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Allahu bura pelu awon molaika t’o n fi ona ele gba emi awon alaigbagbo
وَالنَّاشِطَاتِ نَشْطًا ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
O tun bura pelu awon molaika t’o n fi ona ero gba emi awon onigbagbo ododo
وَالسَّابِحَاتِ سَبْحًا ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
O tun bura pelu awon molaika t’o n yara gaga nibi ase Re
فَالسَّابِقَاتِ سَبْقًا ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
O tun bura pelu awon molaika t’o maa siwaju emi awon onigbagbo ododo wonu Ogba Idera taara
فَالْمُدَبِّرَاتِ أَمْرًا ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
O tun bura pelu awon molaika t’o n seto ile aye
يَوْمَ تَرْجُفُ الرَّاجِفَةُ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Ni ojo ti ifon akoko fun opin aye maa mi gbogbo aye titi pelu ohun igbe
تَتْبَعُهَا الرَّادِفَةُ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Ifon keji fun Ajinde si maa tele e
قُلُوبٌ يَوْمَئِذٍ وَاجِفَةٌ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Awon okan yoo maa gbon pepe ni ojo yen
أَبْصَارُهَا خَاشِعَةٌ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Oju won yo si wale ni ti iyepere
يَقُولُونَ أَإِنَّا لَمَرْدُودُونَ فِي الْحَافِرَةِ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Won yoo wi pe: "Se Won tun maa da wa pada si ibere isemi (bii taye ni)
أَإِذَا كُنَّا عِظَامًا نَّخِرَةً ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Se nigba ti a ti di eegun t’o kefun tan
قَالُوا تِلْكَ إِذًا كَرَّةٌ خَاسِرَةٌ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Won wi pe: "Idapada ofo niyen nigba naa (fun eni t’o pe e niro)
فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Nitori naa, igbe eyo kan si ni
فَإِذَا هُم بِالسَّاهِرَةِ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Nigba naa ni won yoo bara won lori ile gbansasa
هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ مُوسَىٰ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Nje oro (Anabi) Musa ti de odo re
إِذْ نَادَاهُ رَبُّهُ بِالْوَادِ الْمُقَدَّسِ طُوًى ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
(Ranti) nigba ti Oluwa re pe e ni afonifoji mimo, Tuwa
اذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُ طَغَىٰ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Lo ba Fir‘aon, dajudaju o ti tayo enu-ala
فَقُلْ هَل لَّكَ إِلَىٰ أَن تَزَكَّىٰ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Ki o si so pe: "Nje o maa safomo ara re (kuro ninu aigbagbo) bi
وَأَهْدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخْشَىٰ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Ki emi si fi ona mo o de odo Oluwa re. Nitori naa, ki o paya (Re)
فَأَرَاهُ الْآيَةَ الْكُبْرَىٰ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
O si fi ami t’o tobi han an
فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
(Amo) o pe e lopuro. O si yapa re
ثُمَّ أَدْبَرَ يَسْعَىٰ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Leyin naa, o keyin si i. O si n sise (tako o)
فَحَشَرَ فَنَادَىٰ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
O ko (awon eniyan) jo, o si ke gbajari
فَقَالَ أَنَا رَبُّكُمُ الْأَعْلَىٰ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
O si wi pe: "Emi ni oluwa yin, eni giga julo
فَأَخَذَهُ اللَّهُ نَكَالَ الْآخِرَةِ وَالْأُولَىٰ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Nitori naa, Allahu gba a mu pelu iya ikeyin ati akoko (nipa oro enu re ikeyin yii ati akoko)
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِّمَن يَخْشَىٰ ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun eni t’o n paya (Allahu)
أَأَنتُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمِ السَّمَاءُ ۚ بَنَاهَا ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
Se eyin le lagbara julo ni iseda ni tabi sanmo ti Allahu mo
رَفَعَ سَمْكَهَا فَسَوَّاهَا ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
Allahu gbe aja re ga soke. O si se e ni pipe t’o gun rege
وَأَغْطَشَ لَيْلَهَا وَأَخْرَجَ ضُحَاهَا ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
O se oru re ni dudu. O si fa iyaleta re yo jade
وَالْأَرْضَ بَعْدَ ذَٰلِكَ دَحَاهَا ۝٣٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 30
Ati ile, O te e perese leyin iyen
أَخْرَجَ مِنْهَا مَاءَهَا وَمَرْعَاهَا ۝٣١
📖 Itumọ Ẹsẹ 31
O mu omi re ati irugbin re jade lati inu re
وَالْجِبَالَ أَرْسَاهَا ۝٣٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 32
Ati awon apata, O fi idi won mule sinsin
مَتَاعًا لَّكُمْ وَلِأَنْعَامِكُمْ ۝٣٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 33
Igbadun ni fun yin ati fun awon eran-osin yin
فَإِذَا جَاءَتِ الطَّامَّةُ الْكُبْرَىٰ ۝٣٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 34
Sugbon nigba ti iparun nla ba de
يَوْمَ يَتَذَكَّرُ الْإِنسَانُ مَا سَعَىٰ ۝٣٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 35
ni ojo ti eniyan yoo ranti ohun t’o se nise
وَبُرِّزَتِ الْجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ ۝٣٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 36
Won si maa fi Ina han kedere fun (gbogbo) eni t’o riran
فَأَمَّا مَن طَغَىٰ ۝٣٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 37
Nitori naa, ni ti eni t’o ba tayo enu-ala
وَآثَرَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا ۝٣٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 38
ti o tun gbe ajulo fun isemi aye
فَإِنَّ الْجَحِيمَ هِيَ الْمَأْوَىٰ ۝٣٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 39
dajudaju ina Jehim, ohun ni ibugbe (re)
وَأَمَّا مَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِ وَنَهَى النَّفْسَ عَنِ الْهَوَىٰ ۝٤٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 40
Ni ti eni ti o ba paya iduro niwaju Oluwa re, ti o tun ko ife-inu fun emi (ara re)
فَإِنَّ الْجَنَّةَ هِيَ الْمَأْوَىٰ ۝٤١
📖 Itumọ Ẹsẹ 41
dajudaju Ogba Idera, ohun ni ibugbe (re)
يَسْأَلُونَكَ عَنِ السَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَاهَا ۝٤٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 42
Won n bi o leere nipa Akoko naa pe: "Igba wo l’o maa sele
فِيمَ أَنتَ مِن ذِكْرَاهَا ۝٤٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 43
Ona wo ni iwo le fi ni (imo) iranti re na
إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَاهَا ۝٤٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 44
Odo Oluwa re ni opin imo nipa re wa
إِنَّمَا أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخْشَاهَا ۝٤٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 45
Iwo kuku ni olukilo fun eni t’o n paya re
كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَاهَا ۝٤٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 46
Ni ojo ti won maa ri i, won maa da bi eni pe won ko lo tayo irole tabi iyaleta (ojo) kan lo (nile aye)
← 78 An-Nazi'at (79/114) 80 →
Kika Surah An-Nazi'at ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

79النازعات An-Nazi'at 📚 46 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah An-Nazi'at — 46 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers