PDF —
40 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah An-Naba pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah An-Naba pdf Yorùbá — Gbà Surah An-Naba Itumọ. Surah An-Naba (Meccan) 40 Ẹsẹ.



40 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﭑﭒﭓ
78:1 Nipa ki ni won n bira won leere na
ﭔﭕﭖﭗ
78:2 Nipa iro ikoko nla ni
ﭘﭙﭚﭛﭜ
78:3 eyi ti won n yapa enu si
ﭝﭞﭟ
78:4 Rara! Won n bo wa mo
ﭠﭡﭢﭣ
78:5 Leyin naa, ni ti ododo won n bo wa mo
ﭤﭥﭦﭧﭨ
78:6 Nje Awa ko se ile ni ite bi
ﭩﭪﭫ
78:7 ati awon apata ni eekan (fun ile)
ﭬﭭﭮ
78:8 A si seda yin ni orisirisi (ako ati abo)
ﭯﭰﭱﭲ
78:9 A se oorun yin ni isinmi
ﭳﭴﭵﭶ
78:10 A tun se ale ni ibora
ﭷﭸﭹﭺ
78:11 A tun se osan ni (asiko fun) wiwa ije-imu
ﭻﭼﭽﭾﭿ
78:12 A tun mo sanmo meje t’o lagbara soke yin
ﮀﮁﮂﮃ
78:13 A tun se oorun ni imole t’o n tan gbola
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
78:14 Ati pe A so omi t’o n bo telera won kale lati inu awon esujo
ﮊﮋﮌﮍﮎ
78:15 nitori ki A le fi mu koro eso ati irugbin jade
ﮏﮐﮑ
78:16 pelu awon ogba t’o kun digbi fun nnkan oko
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
78:17 Dajudaju ojo ipinya, o ni gbedeke akoko kan
ﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞ
78:18 (Iyen ni) ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Eyin yo si maa wa nijo-nijo
ﮟﮠﮡﮢﮣ
78:19 Won si maa si sanmo sile. O si maa di awon ilekun
ﮤﮥﮦﮧﮨ
78:20 Won maa mu awon apata rin (bo si aye miiran). O si maa di ahunpeena
ﮩﮪﮫﮬﮭ
78:21 Dajudaju ina Jahanamo, o lugo sile loju ona
ﮮﮯﮰ
78:22 (O je) ibugbe fun awon alakoyo
ﮱﯓﯔﯕ
78:23 Won yoo maa gbe inu re fun igba gbooro
ﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜ
78:24 Won ko nii ri itura tabi ohun mimu kan towo ninu re
ﯝﯞﯟﯠ
78:25 ayafi omi gbigbona ati awoyunweje
ﯡﯢﯣ
78:26 (O je) esan t’o se weku (ise won)
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
78:27 Dajudaju won ki i reti isiro-ise
ﯪﯫﯬﯭ
78:28 Won si pe awon ayah Wa niro gan-an
ﯮﯯﯰﯱﯲ
78:29 Gbogbo nnkan si ni A ti se akosile re sinu Tira kan
ﯳﯴﯵﯶﯷﯸ
78:30 Nitori naa, e to (iya) wo. A o si nii se alekun kan fun yin bi ko se iya
ﭑﭒﭓﭔ
78:31 Dajudaju igbala wa fun awon oluberu (Allahu)
ﭕﭖﭗ
78:32 Awon ogba ati eso ajara
ﭘﭙﭚ
78:33 ati awon olomoge, ti won ko jura won lo lojo-ori
ﭛﭜﭝ
78:34 ati ife oti t’o kun denu (ni esan won)
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
78:35 Won ko nii gbo isokuso ati oro iro ninu re
ﭥﭦﭧﭨﭩﭪ
78:36 (O je) esan lati odo Oluwa re, (o si je) ore ni ibamu si isiro-ise (won)
ﭫﭬﭭﭮﭯﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
78:37 (Esan naa wa lati odo) Oluwa awon sanmo, ile ati ohun t’o wa laaarin mejeeji, Ajoke-aye. Won ko si ni ikapa oro lodo Re
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃﮄﮅﮆ
78:38 Ojo ti molaika Jibril ati awon molaika (miiran) yoo duro ni owoowo. Won ko si nii soro afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun. Onitoun si maa soro t’o se weku
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐﮑ
78:39 Iyen ni ojo ododo. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu ona to maa gba seri pada si odo Oluwa re pon (ni ti ironupiwada)
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
78:40 Dajudaju A fi iya t’o sunmo se ikilo fun yin. Ojo ti eniyan yoo maa wo ohun ti o ti siwaju, alaigbagbo yo si wi pe: "Yee, emi iba si je erupe, (emi iba la ninu iya)

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers