Surah At-Takwir pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah At-Takwir pdf Yorùbá — Gbà Surah At-Takwir Itumọ. Surah At-Takwir (Meccan) 29 Ẹsẹ.
Related
More Surah PDF
Surah At-Takwir

ﭙﭚﭛﭜ
81:1
Nigba ti Won ba ka oorun korobojo danu
ﭝﭞﭟﭠ
81:2
ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri
ﭡﭢﭣﭤ
81:3
ati nigba ti Won ba mu awon apata rin (kuro ni aye won, ti won ku won danu)
ﭥﭦﭧﭨ
81:4
ati nigba ti won ba pa awon rakunmi aboyun ti
ﭩﭪﭫﭬ
81:5
ati nigba ti Won ba ko awon eranko jo
ﭭﭮﭯﭰ
81:6
ati nigba ti Won ba mu awon agbami odo gbina
ﭱﭲﭳﭴ
81:7
ati nigba ti Won ba so awon emi po mora won, (eni rere pelu eni rere, eni ibi pelu eni ibi)
ﭵﭶﭷﭸ
81:8
ati nigba ti omobinrin ti won bo mole laaye ba beere pe
ﭹﭺﭻﭼ
81:9
ese wo ni won pa oun fun
ﭽﭾﭿﮀ
81:10
ati nigba ti Won ba si awon takada (ise eda) sile
ﮁﮂﮃﮄ
81:11
ati nigba ti Won ba ka sanmo kuro loke
ﮅﮆﮇﮈ
81:12
ati nigba ti won ba mu ina Jehim jo fofo
ﮉﮊﮋﮌ
81:13
ati nigba ti Won ba sun Ogba Idera mo (awon onigbagbo ododo)
ﮍﮎﮏﮐﮑ
81:14
(nigba naa ni) emi (kookan) yoo mo ohun ti o mu wa (ninu ise ire ati ise ibi)
ﮒﮓﮔﮕ
81:15
Nitori naa, Emi (Allahu) n bura pelu awon irawo t’o n yo ni ale, t’o n wookun ni osan
ﮖﮗﮘ
81:16
(iyen) awon irawo t’o n rin lo rin bo, t’o n wookun si ibuwo won
ﮙﮚﮛﮜ
81:17
Mo tun bura pelu ale nigba ti o ba lo
ﮝﮞﮟﮠ
81:18
Mo tun bura pelu owuro nigba ti o ba mole
ﮡﮢﮣﮤﮥ
81:19
Dajudaju (al-Ƙur’an) ni oro (ti A fi ran Jibril) Ojise, alapon-onle
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬ
81:20
alagbara, eni pataki ni odo Eni t’O ni Ite-ola
ﮭﮮﮯﮰ
81:21
eni ti won n tele ase re nibe yen (ninu sanmo), olufokantan
ﮱﯓﯔﯕ
81:22
Ati pe eni yin (Anabi Muhammad s.a.w.) ki i se were
ﯖﯗﯘﯙﯚ
81:23
O kuku ri i ninu ofurufu kedere
ﯛﯜﯝﯞﯟﯠ
81:24
Ati pe ki i se ahun (tabi eni-afurasi) lori iro ikoko (ti A fi ranse si i)
ﯡﯢﯣﯤﯥﯦ
81:25
Al-Ƙur’an ki i si se oro (ti A fi ran) Esu, eni eko
ﯧﯨﯩ
81:26
Nitori naa, ibo l’e n lo
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
81:27
Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
81:28
(O wa) fun eni ti o ba fe ninu yin lati duro deede
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾ
81:29
Eyin ko si nii fe (lati duro deede) ayafi ti Allahu ba fe, Oluwa gbogbo eda
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







