La sourate Al Imran en Yoruba
الم(1) ’Alif lam mim |
Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuuto-eda |
O so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re. O si so Taorah ati ’Injil kale |
ni isaaju. Imona si ni fun awon eniyan.1 O tun so oro-ipinya (oro t’o n sepinya laaarin ododo ati iro) kale.2 Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, iya t’o le n be fun won. Allahu si ni Alagbara, Olugbesan |
إِنَّ اللَّهَ لَا يَخْفَىٰ عَلَيْهِ شَيْءٌ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ(5) Dajudaju Allahu, ko si kini kan t’o pamo fun Un ninu ile ati ninu sanmo |
Oun ni Eni ti O n yaworan yin sinu apoluke bi O se fe. Ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alagbara Ologbon |
Oun ni Eni ti O so Tira kale fun o; awon ayah alainipon-na wa ninu re - awon si ni ipile Tira -, onipon-na si ni iyoku. Ni ti awon ti igbunri kuro nibi ododo wa ninu okan won, won yoo maa tele eyi t’o ni pon-na ninu re lati fi wa wahala ati lati fi wa itumo (odi) fun un. Ko si si eni t’o nimo itumo re afi Allahu. Awon agba ninu imo esin, won n so pe: “A gba a gbo. Lati odo Oluwa wa ni gbogbo re (ti sokale).” Ko si eni t’o n lo iranti ayafi awon onilaakaye. ko si ayah tabi hadith kan ti o ni pon-na ti itakora won wa wo ipo “itakora toribee” (at-ta‘arudu al-haƙiƙiy). Eyi wa ni ibamu si surah an-Nisa’ |
Oluwa wa, ma se yi wa lokan pada leyin ti O ti to wa sona. Ta wa lore ike lati odo Re, dajudaju Iwo ni Olore |
Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O maa ko awon eniyan jo ni ojo kan, ti ko si iyemeji ninu re. Dajudaju Allahu ki i ye adehun |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan lodo Allahu. Awon wonyen, awon ni nnkan ikona |
(Isesi won) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won, ti won pe awon ayah Wa niro. Nitori naa, Allahu mu won nitori ese won. Allahu si le nibi iya |
قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُوا سَتُغْلَبُونَ وَتُحْشَرُونَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ ۚ وَبِئْسَ الْمِهَادُ(12) So fun awon t’o sai gbagbo pe: "Won maa segun yin. Won si maa ko yin jo sinu ina Jahanamo. Ibugbe naa si buru |
Ami kuku wa fun yin nibi awon ijo meji ti won pade (ara won). Ijo kan n ja fun aabo esin Allahu. Ikeji si je alaigbagbo. Ijo keji n ri ijo kiini bi ilopo meji won ni riri oju. Allahu n fi aranse Re se ikunlowo fun eni ti O ba fe. Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun awon oluriran |
Won se e ni oso fun awon eniyan; ife igbadun lara awon obinrin, awon omokunrin, awon owo wura ati fadaka pupo ati awon esin ti won se ni oso, awon eran-osin ati (nnkan) oko. Iyen ni nnkan igbaye-gbadun. Odo Allahu si ni abo rere wa |
So pe: “Se ki ng so nnkan t’o dara ju iyen lo fun yin?” Awon t’o ba beru (Allahu), awon Ogba ti awon odo n san ni isale re n be fun won ni odo Oluwa won. Olusegbere ni won ninu re. Awon iyawo mimo ati iyonu lati odo Allahu (tun n be fun won). Allahu si ni Oluriran nipa awon erusin |
الَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا إِنَّنَا آمَنَّا فَاغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ(16) awon t’o n so pe: "Oluwa wa, dajudaju awa gbagbo. Nitori naa, fori awon ese wa jin wa. Ki O si so wa nibi iya Ina |
الصَّابِرِينَ وَالصَّادِقِينَ وَالْقَانِتِينَ وَالْمُنفِقِينَ وَالْمُسْتَغْفِرِينَ بِالْأَسْحَارِ(17) (Ogba Idera yen wa fun) awon onisuuru, awon olododo, awon olutele-ase Allahu, awon olunawo-fesin ati awon olutoro-aforijin ni asiko saari |
Allahu jerii pe dajudaju ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun. Awon molaika ati onimo esin (tun jerii bee.), Allahu ni Onideede. Ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alagbara, Ologbon |
Dajudaju esin t’o wa lodo Allahu ni ’Islam. Awon ti A fun ni Tira (awon yehudi ati kristieni) ko yapa enu (si esin naa) afi leyin ti imo de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Eni t’o ba sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise |
Ti won ba si ja o niyan, so pe: “Emi ati eni ti o tele mi juwo juse sile fun Allahu.” Ki o si so fun awon ti A fun ni Tira ati awon alaimoonkomoonka (alainitira) pe: “Se e maa gba ’Islam?” Ti won ba gba ’Islam, won ti mona. Ti won ba si keyin (si ’Islam), ise-jije nikan ni ojuse tire. Allahu si ni Oluriran nipa awon erusin |
Dajudaju awon t’o n sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, ti won n pa awon Anabi lai letoo, ti won tun n pa awon eniyan ti n pase sise eto, fun won ni iro iya eleta-elero |
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ(22) Awon wonyen ni awon ti ise won ti baje ni ile aye ati ni orun. Won ko si nii ri awon oluranlowo |
Se o o ri awon ti A fun ni ipin kan ninu Tira, ti A n pe sibi Tira Allahu, ki o le se idajo laaarin won, leyin naa ti ijo kan ninu won n peyin da, ti won si n gbunri |
Iyen nitori pe dajudaju won wi pe: “Ina ko le jo wa tayo awon ojo t’o lonka.” Ohun ti won n da ni adapa iro si tan won je ninu esin won |
Nitori naa, bawo ni (o se maa ri fun won) nigba ti A ba ko won jo ni ojo kan, ti ko si iyemeji ninu re? Ati pe A maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise ni ekun-rere. Won ko si nii sabosi si won |
So pe: “Allahu, Olukapa ijoba, O n fi ijoba fun eni ti O ba fe. O n gba ijoba lowo eni ti O ba fe. O n buyi kun eni ti O ba fe. O si n tabuku eni ti O ba fe. Owo Re ni oore wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
O n mu oru wonu osan. O n mu osan wonu oru. O n mu alaaye jade lara oku. O n mu oku jade lara alaaye. O si n se arisiki fun eni ti O ba fe ni opolopo.” |
Ki awon onigbagbo ododo ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe won). Enikeni ti o ba se iyen, ko si kini kan fun un mo lodo Allahu. Afi (ti e ba mu won ni ore lori ahon) lati fi sora fun won ni ti wiwa aabo (fun igbagbo yin). Allahu n kilo ara Re fun yin. Odo Allahu si ni abo eda |
So pe: “Ti e ba fi ohun ti n be ninu okan yin pamo tabi e fi han, Allahu mo on. O si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Ni ojo ti emi kookan yoo ri ohun ti o se ninu ise rere niwaju (re) ati ohun ti o se ninu ise ibi, o maa fe ki akoko t’o jinna wa laaarin oun ati ise ibi re. Allahu si n kilo ara Re fun yin. Allahu si ni Alaaanu awon olujosin |
So pe: “Ti eyin ba nifee Allahu, e tele mi, Allahu maa nifee yin, O si maa fori ese yin jin yin. Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
قُلْ أَطِيعُوا اللَّهَ وَالرَّسُولَ ۖ فَإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ(32) So pe: “E tele (ti) Allahu ati Ojise. Ti e ba si peyin da, dajudaju Allahu ko nifee awon alaigbagbo |
۞ إِنَّ اللَّهَ اصْطَفَىٰ آدَمَ وَنُوحًا وَآلَ إِبْرَاهِيمَ وَآلَ عِمْرَانَ عَلَى الْعَالَمِينَ(33) Dajudaju Allahu sa Adam, Nuh, ara ile ’Ibrohim ati ara ile ‘Imron lesa lori awon eda (asiko tiwon) |
ذُرِّيَّةً بَعْضُهَا مِن بَعْضٍ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(34) Won je aromodomo; apa kan won wa lati ara apa kan. Allahu si ni Olugbo, Onimo |
(E ranti) nigba ti aya ‘Imron so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi fi ohun ti n be ninu mi jejee fun O (pe) mo maa ya a soto (fun esin Re). Nitori naa, gba a lowo mi, dajudaju Iwo ni Olugbo, Onimo |
Nigba ti o bi i, o so pe: “Oluwa mi, dajudaju mo bi i ni obinrin - Allahu si nimo julo nipa ohun ti o bi – okunrin ko si da bi obinrin. Dajudaju emi so o ni Moryam. Ati pe dajudaju mo n fi O wa aabo fun oun ati aromodomo re lodo Esu, eni eko.” |
Oluwa re si gba adua naa ni gbigba daadaa. O si mu omo naa dagba ni idagba daadaa. O si fi Zakariyya se alagbato re. Igbakigba ti Zakariyya ba wole to o ninu ile ijosin, o maa ba ese (eso) lodo re. (Zakariyya a) so pe: “Moryam, bawo ni eyi se je tire?” (Moryam a) so pe: "O wa lati odo Allahu. Dajudaju Allahu n se arisiki fun eni ti O ba fe ni opolopo |
Ibeyen ni Zakariyya ti pe Oluwa re. O so pe: "Oluwa mi, ta mi ni ore aromodomo daadaa lati odo Re. Dajudaju Iwo ni Olugbo adua |
Nitori naa, awon molaika pe e nigba ti o n kirun lowo ninu ile ijosin, (won so pe): "Dajudaju Allahu n fun o ni iro idunnu nipa (bibi) Yahya. O maa fi ododo rinle nipa oro kan lati odo Allahu. (O maa je) asiwaju, ti ko si nii sunmo obinrin. (O maa je) Anabi. O si wa ninu awon eni rere |
(Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, bawo ni emi yoo se ni omokunrin; mo ma ti dagbalagba, agan si ni obinrin mi?” (Molaika) so pe: “Bayen ni Allahu se n se ohun ti O ba fe.” |
(Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, fun mi ni ami kan.” (Molaika) so pe: "Ami re ni pe iwo ko nii le ba eniyan soro fun ojo meta ayafi titoka (si nnkan). Ranti Oluwa re lopolopo. Ki o si safomo (fun Un) ni asale ati ni owuro kutu |
(E ranti) nigba ti awon molaika so pe: “Moryam, dajudaju Allahu sa o lesa. O fo o mo. O si sa o lesa lori awon obinrin aye (asiko tire) |
يَا مَرْيَمُ اقْنُتِي لِرَبِّكِ وَاسْجُدِي وَارْكَعِي مَعَ الرَّاكِعِينَ(43) Moryam, tele ase Oluwa re. Fori kanle fun Un. Ki o si dawo te orunkun pelu awon oludawote-orunkun (lori irun) |
Iyen wa ninu iro ikoko ti A n fi imisi re ranse si o. Iwo ko kuku si lodo won nigba ti won n ju gege won (lati mo) ta ni ninu won ni o maa gba Moryam wo. Iwo ko si si lodo won nigba ti won n se ifanfa (lori re) |
(E ranti) nigba ti awon molaika so pe: "Moryam, dajudaju Allahu n fun o ni iro idunnu (nipa dida eda kan pelu) oro kan lati odo Re. Oruko re ni Mosih ‘Isa omo Moryam. Abiyi ni ni aye ati ni orun. O si wa lara alasun-unmo (Allahu). ninu ayah ti ali ‘Imron Allahu (subhanahu wa ta’ala) n so nipa bi awon mola’ikah se wa so asotele nipa bibi ‘Isa (’alaehi-ssolatu wa-ssalam). Awon molaika t’o wa so asotele naa ju eyo kan lo. Idi niyi ti “mola’ikah” fi je opo ninu ayah yen. Amo ninu ayah ti Moryam |
وَيُكَلِّمُ النَّاسَ فِي الْمَهْدِ وَكَهْلًا وَمِنَ الصَّالِحِينَ(46) O maa ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba t’o ba dagba. O si wa ninu awon eni rere |
(Moryam) so pe: “Oluwa mi bawo ni emi yo se ni omokunrin, (nigba ti) abara kan ko fowo kan mi.” O so pe: Bayen ni Allahu se n da ohun ti O ba fe. Nigba ti O ba (gbero) lati da eda kan ohun ti O maa so fun un ni pe: "Je bee." O si maa je bee |
وَيُعَلِّمُهُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَالتَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ(48) (Allahu) yoo fun un ni imo ikowe, ijinle oye, Taorah ati ’Injil |
(O si je) Ojise (ti A ran nise) si awon omo ’Isro’il. (O si maa so fun won pe) "Dajudaju emi ti mu ami kan wa fun yin lati odo Oluwa yin. Dajudaju emi yoo mo nnkan fun yin lati inu amo bi irisi eye. Emi yoo fe ategun sinu re. O si maa di eye pelu iyonda Allahu. Emi yoo se iwosan fun afoju ati adete, mo si maa so oku di alaaye pelu iyonda Allahu. Emi yoo maa fun yin ni iro ohun ti e n je ati ohun ti e n fi pamo sinu ile yin. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo |
Mo si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju mi ninu Taorah nitori ki emi le se ni eto fun yin apa kan eyi ti won se ni eewo fun yin. Mo ti mu ami kan wa fun yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
إِنَّ اللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۗ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ(51) Dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara |
Nigba ti (Anabi) ‘Isa fura si aigbagbo lodo won (pe won fe pa oun), o so pe: “Ta ni oluranlowo mi si odo Allahu?” Awon omoleyin (re) so pe: "Awa ni oluranlowo fun (esin) Allahu. A gba Allahu gbo. Ki o si jerii pe dajudaju musulumi ni wa |
رَبَّنَا آمَنَّا بِمَا أَنزَلْتَ وَاتَّبَعْنَا الرَّسُولَ فَاكْتُبْنَا مَعَ الشَّاهِدِينَ(53) Oluwa wa, a gbagbo ninu ohun ti O sokale. A si tele Ojise. Nitori naa, ko wa mo awon olujerii |
وَمَكَرُوا وَمَكَرَ اللَّهُ ۖ وَاللَّهُ خَيْرُ الْمَاكِرِينَ(54) Won dete, Allahu si dete. Allahu si l’oore julo ninu awon adete |
Wafat/wafah si tumo si ""ƙobd"" gbigba eni kan kuro lowo eni kan ninu surah ali ‘Imron 3:55 ati surah al-Mo’dah elesin ’Islam ni awon t’o tele ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam). Ati ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ati owo awon t’o tele e loju aye re musulumi ni won gege bi won se pera won bee ninu surah yii |
Ni ti awon t’o sai gbagbo, Emi yoo je won niya lile ni aye ati ni orun. Ko si nii si awon oluranlowo fun won |
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, (Allahu) maa fun won ni esan won ni kikun. Allahu ko si feran awon alabosi |
ذَٰلِكَ نَتْلُوهُ عَلَيْكَ مِنَ الْآيَاتِ وَالذِّكْرِ الْحَكِيمِ(58) Iyen ni A n ke fun o ninu awon ayah ati iranti ti o kun fun ogbon ijinle (iyen, al-Ƙur’an) |
Dajudaju iru ‘Isa lodo Allahu da bi iru Adam; (Allahu) da a lati ara erupe. Leyin naa, O so pe: “Je bee.” O si je bee. eru Olohun ati Anabi Olohun. Amo siso ti awon kristieni so Anabi ‘Isa (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) di oluwa won olugbala won |
Ododo ni lati odo Oluwa re. Nitori naa, ma se wa ninu awon oniyemeji |
Nitori naa, enikeni ti o ba ja o niyan nipa re leyin ohun ti o de ba o ninu imo, ki o so pe: “E wa! Ki a pe awon omokunrin wa ati awon omokunrin yin ati awon obinrin wa ati awon obinrin yin ati awa ati eyin naa. Leyin naa, ki a se adua taratara, ki a si toro egun Allahu le awon opuro lori.” |
Dajudaju eyi, ohun ni itan ododo. Ati pe ko si olohun kan ti ijosin to si afi Allahu. Dajudaju Allahu, Oun ni Alagbara, Ologbon |
فَإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِالْمُفْسِدِينَ(63) Ti won ba si peyin da (nibi ododo naa), dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon obileje |
So pe: “Eyin ahlu-l-kitab, e wa sibi oro kan t’o dogba laaarin awa ati eyin, pe a o nii josin fun eni kan afi Allahu. A o si nii fi kini kan wa akegbe fun Un. Ati pe apa kan wa ko nii so apa kan di oluwa leyin Allahu.” Ti won ba si gbunri, e so pe: “E jerii pe dajudaju musulumi ni awa.” |
Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi jiyan nipa (Anabi) ’Ibrohim? A ko si so at-Taorah ati al-’Injil kale bi ko se leyin re, se e ko se laakaye ni |
Eyin ni iwonyi ti e n jiyan nipa ohun ti e nimo nipa re! Ki ni o tun n mu yin jiyan nipa ohun ti e o nimo nipa re? Allahu nimo. Eyin ko si nimo |
(Anabi) ’Ibrohim ki i se yehudi, ki i se kristieni, sugbon o je oluduro-deede, musulumi. Ko si si ninu awon osebo |
Dajudaju awon eniyan t’o sunmo (Anabi) ’Ibrohim julo ni awon t’o tele e ati Anabi yii (Anabi Muhammad s.a.w.) ati awon t’o gbagbo ni ododo. Allahu ni Alatileyin fun awon onigbagbo ododo |
Igun kan ninu awon ahlul-kitab fe lati si yin lona. Won ko le si enikeni lona afi ara won, won ko si fura |
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لِمَ تَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَأَنتُمْ تَشْهَدُونَ(70) Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, e si n jerii (si ododo re) |
Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi da iro po mo ododo, e si n fi ododo pamo nigba ti eyin mo (ododo) |
Igun kan ninu awon ahlul-kitab wi pe: “E lo gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awon t’o gbagbo ni ododo nibere ojo, ki e si tako o nipari re, boya awon musulumi (kan) maa seri pada (seyin ninu esin ’Islam) |
(Won tun wi pe:) “E ma gbagbo ayafi eni ti o ba tele esin yin.” So pe: “Dajudaju imona (’Islam) ni imona ti Allahu.” (Won tun wi pe:) “(E ma gbagbo) pe won fun eni kan ni iru ohun ti Won fun yin tabi pe won yoo tako yin (ti won yo si jare yin) lodo Oluwa yin.” So pe: “Dajudaju oore ajulo wa ni owo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu ni Olugbaaye, Onimo.” |
يَخْتَصُّ بِرَحْمَتِهِ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ(74) (Allahu) n sa eni ti O ba fe lesa. Allahu ni Oloore nla |
O n be ninu awon ahlul-kitab, eni ti o je pe ti o ba fi okan tan an pelu opolopo owo, o maa da a pada fun o. O si n be ninu won, eni ti o je pe ti o ba fi okan tan an pelu owo dinar kan (owo kekere), ko nii da a pada fun o ayafi ti o ba dogo ti i lorun. Iyen nitori pe won wi pe: “Won ko le fi ona kan kan ba wa wi nitori awon alaimoonkomoonka.” Nse ni won n pa iro mo Allahu, won si mo |
بَلَىٰ مَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِ وَاتَّقَىٰ فَإِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ(76) Rara (A maa ba won wi). Enikeni ti o ba mu adehun re se, ti o si beru (Allahu), dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re) |
Dajudaju awon t’o n ta majemu Allahu ati ibura won ni owo kekere, awon wonyen, ko nii si ipin oore fun won ni Ojo Ikeyin. Allahu ko nii ba won soro, ko si nii siju wo won ni Ojo Ajinde. Ko si nii fo won mo (ninu ese) Iya eleta-elero si n be fun won |
Dajudaju ijo kan n be ninu won t’o n fi ahon won yi tira (Allahu) pada, nitori ki e le lero pe lara tira lo wa, ko si si lara tira. Won si n wi pe: “O wa lati odo Allahu.” Ko si wa lati odo Allahu. Won n paro mo Allahu, won si mo |
Ko letoo fun abara kan nigba ti Allahu ba fun un ni tira, ijinle oye ati ipo Anabi, leyin naa ki o maa so fun awon eniyan pe, "e je erusin fun mi leyin Allahu." Sugbon (o maa so pe) "e je olujosin fun Oluwa (ki e si maa fi eko Re ko awon eniyan) nitori pe e je eni ti n ko awon eniyan ni tira ati nitori pe e je eni ti n ko eko (nipa esin) |
(Anabi kan) ko si nii pa yin ni ase pe ki e so awon molaika ati awon Anabi di oluwa. Se o maa pa yin ni ase sise aigbagbo leyin ti e ti je musulumi ni |
(E ranti) nigba ti Allahu gba adehun lowo awon Anabi pe: “(E lo) eyi ti Mo ba fun yin ninu Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah eni kookan won). Leyin naa, Ojise kan (iyen, Anabi Muhammad s.a.w.) yoo de ba yin; o maa fi eyi t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin. Nitori naa, e gbodo gba a gbo, e si gbodo ran an lowo.” (Allahu) so pe: “Nje e gba? Se e si maa lo adehun Mi yii?” Won so pe: “A gba.” (Allahu) so pe: "Nitori naa, e jerii si (adehun naa). Emi n be pelu yin ninu awon Olujerii |
فَمَن تَوَلَّىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ(82) Nitori naa, eni ti o ba keyin si (Anabi Muhammad s.a.w.) leyin (adehun) yen, awon wonyen ni obileje |
Se esin miiran yato si esin Allahu ni won n wa ni? Nigba ti o je pe tiRe ni gbogbo eni ti n be ninu awon sanmo ati ile juwo juse sile fun, won fe won ko. Odo Re si ni Won maa da won pada si |
So pe: “A gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa pelu ohun ti Won sokale fun (Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub, ati awon aromodomo (re. A gbagbo ninu) ohun ti Won fun (Anabi) Musa ati ‘Isa ati awon Anabi lati odo Oluwa won; A ko ya eni kan kan soto ninu won. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.” |
Enikeni ti o ba wa esin kan se yato si ’Islam, A o nii gba a lowo re. Ni Ojo Ikeyin, o si maa wa ninu awon eni ofo |
Bawo ni Allahu yo se fi ona mo ijo kan t’o sai gbagbo leyin igbagbo won? Won si jerii pe dajudaju Ojise naa, ododo ni. Awon eri t’o yanju si ti de ba won. Allahu ki i fi ona mo ijo alabosi |
أُولَٰئِكَ جَزَاؤُهُمْ أَنَّ عَلَيْهِمْ لَعْنَةَ اللَّهِ وَالْمَلَائِكَةِ وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ(87) Awon wonyen, esan won ni pe, dajudaju egun Allahu ati (egun) awon molaika ati (egun) gbogbo awon eniyan n be lori won |
خَالِدِينَ فِيهَا لَا يُخَفَّفُ عَنْهُمُ الْعَذَابُ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ(88) Olusegbere ni won ninu egun. Nitori naa, A o nii gbe iya fuye fun won, A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina) |
إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ وَأَصْلَحُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(89) Ayafi awon t’o ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse, nitori pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo leyin igbagbo won, leyin naa, won lekun ni aigbagbo, A o nii gba ironupiwada won. Awon wonyen ni olusina |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si ku nigba ti won je alaigbagbo, A o nii gba ekun ile wura lowo enikeni ninu won, ibaa fi serapada (fun emi ara re nibi Ina). Awon wonyen ni iya eleta-elero n be fun. Ko si nii si awon oluranlowo fun won |
Owo yin ko le ba oore ayafi ti e ba n na ninu ohun ti e nifee si. Ati pe ohunkohun ti e ba na, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re |
Gbogbo ounje lo je eto fun awon omo ’Isro’il ayafi eyi ti ’Isro’il ba se ni eewo fun emi ara re siwaju ki A to so at-Taorah kale. So pe: “Nitori naa, e mu at-Taorah wa, ki e si ka a sita ti eyin ba je olododo.” |
فَمَنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ(94) Nitori naa, enikeni ti o ba da adapa iro mo Allahu leyin iyen, awon wonyen ni alabosi |
قُلْ صَدَقَ اللَّهُ ۗ فَاتَّبِعُوا مِلَّةَ إِبْرَاهِيمَ حَنِيفًا وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ(95) So pe: "Allahu so ododo. Nitori naa, e tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-’Islam. Ko si si ninu awon osebo |
إِنَّ أَوَّلَ بَيْتٍ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكًا وَهُدًى لِّلْعَالَمِينَ(96) Dajudaju ile akoko ti A fi lele fun awon eniyan ni eyi ti o wa ni Bakkah . (O je ile) ibukun ati imona fun gbogbo eda |
Awon ami t’o yanju wa ninu re; ibuduro (Anabi) ’Ibrohim. Enikeni ti o ba wo inu re ti di eni ifayabale. Allahu se abewo si Ile naa ni dandan fun awon eniyan, t’o lagbara ona ti o maa gba debe. Enikeni ti o ba si sai gbagbo,dajudaju Allahu ni Oloro ti ko bukata si gbogbo eda |
So pe: "Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi sai gbagbo ninu awon ayah Allahu? Allahu si ni Arinu-rode ohun ti e n se nise |
So pe: "Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e fi n seri eni t’o gbagbo lododo kuro loju ona (esin) Allahu, e si n fe ko wo, e si jerii (si ododo ’Islam)? Allahu ki i se Onigbagbe nipa ohun ti e n se nise |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba tele apa kan ninu awon ti A fun ni tira, won maa da yin pada leyin igbagbo ododo yin si ipo alaigbagbo |
Bawo ni eyin se le sai gbagbo, eyin ma ni won n ke awon ayah Allahu fun, Ojise Re si wa laaarin yin! Enikeni ti o ba duro sinsin ti Allahu, A ti to o si ona taara |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu bi o se to lati beru Re. Eyin ko si gbodo ku ayafi ki e wa ni ipo musulumi |
E duro sinsin ti okun Allahu (’Islam) ni apapo, e ma se pin si ijo otooto. Ki e si ranti ike Allahu ti n be lori yin (pe) nigba ti e je ota (ara yin nigba aimokan), O pa okan yin po mora won (pelu ’Islam), e si di omo iya pelu ike Re; ati (nigba ti) e wa leti ogbun Ina, O gba yin la kuro ninu re. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin nitori ki e le mona (’Islam) |
Ki o maa be ninu yin, ijo kan ti yoo maa pepe sibi ohun t’o loore julo, won yoo maa pase ohun rere, won yo si maa ko ohun buruku. Awon wonyen, awon si ni olujere |
E ma se da bi awon t’o sora won di ijo otooto, ti won si yapa enu (si ’Islam) leyin ti awon alaye t’o yanju ti de ba won. Awon wonyen si ni iya nla n be fun |
Ni ojo ti awon oju kan yoo funfun (imole). Awon oju kan yo si dudu. Ni ti awon ti oju won dudu, (A o bi won pe:) "Se e sai gbagbo leyin igbagbo yin ni?" Nitori naa, e to iya wo nitori pe e sai gbagbo |
وَأَمَّا الَّذِينَ ابْيَضَّتْ وُجُوهُهُمْ فَفِي رَحْمَةِ اللَّهِ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(107) Ni ti awon ti oju won funfun (imole), ninu ike Allahu ni won yoo wa. Olusegbere ni won ninu re |
تِلْكَ آيَاتُ اللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِالْحَقِّ ۗ وَمَا اللَّهُ يُرِيدُ ظُلْمًا لِّلْعَالَمِينَ(108) Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Allahu ko si gbero abosi kan si gbogbo eda |
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ(109) Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si |
E je ijo t’o loore julo, ti A gbe dide fun awon eniyan; e n pase ohun rere, e n ko ohun buruku, e si gbagbo ninu Allahu. Ti o ba je pe awon ahlul-kitab gbagbo lododo ni, iba loore julo fun won. Onigbagbo ododo wa ninu won , opolopo won si ni obileje |
لَن يَضُرُّوكُمْ إِلَّا أَذًى ۖ وَإِن يُقَاتِلُوكُمْ يُوَلُّوكُمُ الْأَدْبَارَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ(111) Won ko nii ko inira ba yin ayafi ipalara die. Ti won ba si ba yin ja, won a sa fun yin. Leyin naa, A o nii ran won lowo |
Abuku yoo maa ba won nibikibi ti owo awon (musulumi) ba ti ba won afi (ti won ba n be) pelu aabo lati odo Allahu (iyen ni pe, ki won gba ’Islam) ati aabo lati odo awon eniyan (iyen ni pe, ki won gba lati maa san owo isakole fun ijoba ’Islam). Won seri pada pelu ibinu lati odo Allahu. Won si ko osi ba won. Iyen nitori pe, dajudaju won sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, won tun n pa awon Anabi lai letoo. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu ala |
(Awon ahlul-kitab) ko ri bakan naa. Ijo kan t’o duro deede wa ninu awon ahlul-kitab, ti n ke awon ayah Allahu ni akoko oru, ti won si n fori kanle (lori irun) |
Won gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won si n yara nibi awon ise olooore. Awon wonyen wa ninu awon eni rere |
وَمَا يَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَلَن يُكْفَرُوهُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ(115) Ohunkohun ti won ba se ni ise rere, A o nii je ki won padanu esan re. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re) |
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan nibi iya lodo Allahu. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re |
Apejuwe ohun ti won n na ninu isemi aye yii da bi apejuwe afefe ti ategun otutu lile wa ninu re. O fe lu oko awon eniyan t’o se abosi s’ori ara won. O si pa a run. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu alafinuhan kan yato si ara yin. Won ko nii gewo aburu kuru fun yin. Won si nifee si ohun ti o maa ko inira ba yin. Ikorira kuku ti foju han lati enu won. Ohun ti o si pamo sinu okan won tobi julo. A ti salaye awon ayah fun yin, ti eyin ba je onilaakaye |
Kiye si i, eyin wonyi nifee won, awon ko si nifee yin. Eyin gbagbo ninu awon tira, gbogbo re (patapata). Nigba ti won ba si pade yin, won a wi pe: “Awa gbagbo.” Nigba ti o ba si ku awon nikan, won yoo maa deyin mo ika lori yin ni ti ibinu. So pe: “E ku pelu ibinu yin.” Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu awon igba-aya eda |
Ti daadaa kan ba kan yin, o maa ko ibanuje ba won. Ti aburu kan ba si sele si yin, won maa dunnu si i. Ti eyin ba se suuru, ti e si sora (fun won), ete won ko nii ko inira kan kan ba yin. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise |
(Ranti) nigba ti o ji kuro lodo awon ara ile re ni idaji kutukutu, ti o si n fi aye ibujagun han awon onigbagbo ododo, Allahu ni Olugbo, Onimo |
(Ranti) nigba ti ijo meji ninu yin fe sojo. Allahu si ni Alafeyinti awon mejeeji. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
Allahu kuku fun yin ni isegun ni ogun Badr, nigba ti eyin je alailagbara. Nitori naa, e beru Allahu ki e le dupe (fun Un) |
Ranti nigba ti o n so fun awon onigbagbo ododo pe: “Se ko nii to yin ti Oluwa yin ba se iranlowo fun yin pelu egberun meta ninu awon molaika, ti Won maa sokale?” |
Rara (o maa to wa.). Ti eyin ba se suuru, ti e si beru Allahu, ti awon (ota) ba de ba yin lojiji, Oluwa yin yoo ran yin lowo pelu egberun maarun ninu awon molaika pelu ami idanimo lara won |
Allahu ko se e lasan bi ko se ki o le je iro idunnu fun yin ati nitori ki okan yin le bale pelu re. Ko si aranse lori ota (lati ibi kan kan) bi ko se lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon |
لِيَقْطَعَ طَرَفًا مِّنَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَوْ يَكْبِتَهُمْ فَيَنقَلِبُوا خَائِبِينَ(127) (Allahu se aranse naa fun yin) nitori ki O le ge apa kan danu ninu awon t’o sai gbagbo, tabi nitori ki O le doju ti won, ti won si maa pada wale lofo |
لَيْسَ لَكَ مِنَ الْأَمْرِ شَيْءٌ أَوْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ أَوْ يُعَذِّبَهُمْ فَإِنَّهُمْ ظَالِمُونَ(128) Ko si ohun t’o kan o ninu oro naa. Yala (Allahu) maa gba ironupiwada won tabi O maa je won niya; dajudaju alabosi ni won |
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O n forijin eni ti O ba fe, O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
Eyin onigbagbo ododo, e ma se je ele, adipele lori adipele. Ki e si beru Allahu nitori ki e le jere |
Ki e si sora fun Ina ti Won ti pa lese sile de awon alaigbagbo |
وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَالرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ(132) Ki e tele ti Allahu ati Ojise nitori ki A le ke yin |
E yara wa aforijin lodo Oluwa yin ati Ogba Idera kan, eyi ti ibu re to awon sanmo ati ile, ti Won pa lese sile fun awon oluberu (Allahu) |
Awon t’o n na owo won nigba idera ati nigba inira, awon ti n gbe ibinu mi, awon alamojuukuro fun awon eniyan nibi asise; Allahu nifee awon oluse-rere |
Awon ti (o je pe) nigba ti won ba se ibaje kan tabi ti won ba sabosi si emi ara won, won a ranti Allahu, won a si toro aforijin fun ese won, - Ta si ni O n fori awon ese jin (eda) bi ko se Allahu. Won ko si taku sori ohun ti won se nigba ti won mo (pe ese ni) |
Awon wonyen, esan won lodo Oluwa won ni aforijin ati awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan oluse-ise rere si dara |
Awon oripa kan kuku ti lo siwaju yin. Nitori naa, e rin ile lo, ki e woye si bi igbeyin awon t’o pe ododo niro se ri |
هَٰذَا بَيَانٌ لِّلنَّاسِ وَهُدًى وَمَوْعِظَةٌ لِّلْمُتَّقِينَ(138) Eyi ni alaye fun awon eniyan. Imona ati waasi si ni fun awon oluberu (Allahu) |
وَلَا تَهِنُوا وَلَا تَحْزَنُوا وَأَنتُمُ الْأَعْلَوْنَ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(139) E ma se kole, e si ma se banuje; eyin l’e maa leke ti e ba je onigbagbo ododo |
Ti ipalara kan ba kan yin, iru ipalara bee kuku ti kan ijo keferi. Awon ojo wonyi, A n yi i po laaarin awon eniyan ni. Ati pe nitori ki Allahu le se afihan awon t’o gbagbo ni ododo ati nitori ki O le (tewo) gba awon t’o maa ku fun Un ninu yin. Allahu ko si nifee awon alabosi |
وَلِيُمَحِّصَ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَيَمْحَقَ الْكَافِرِينَ(141) Ati pe (o tun ri bee) nitori ki Allahu le safomo awon t’o gbagbo ni ododo ati nitori ki O le run awon alaigbagbo |
Tabi e lero pe e maa wo inu Ogba Idera nigba ti Allahu ko ti i safi han awon t’o maa jagun (esin) ninu yin, ti ko si ti i safi han awon onisuuru |
Dajudaju e ti n fe iku (ogun esin) siwaju ki e to pade re. E kuku ti ri i (bayii), e si n woran |
Ki ni (Anabi) Muhammad bi ko se Ojise, ti awon Ojise kan ti lo siwaju re. Se ti o ba ku tabi ti won ba pa a, e maa peyin da (sesin)? Enikeni ti o ba peyin da (sesin) ko le ko inira kan kan ba Allahu. Allahu yo si san awon oludupe ni esan rere. awo eran okunbete ti won pa lose ki i se eewo fun lilo fun oso ile tabi oso ara. Iru awo eran okunbete ti won pa lose bee si di eto lati fi se bata beliti |
Ko letoo fun emi kan lati ku afi pelu iyonda Allahu. (Iku je) akosile onigbedeke. Enikeni ti o ba n fe esan (ni) aye, A maa fun un ni aye. Enikeni ti o ba si n fe esan (ni) orun, A maa fun un ni orun. A o si san awon oludupe ni esan rere |
Meloo meloo ninu awon Anabi ti won ti jagun esin pelu opolopo omo-eyin (won). Won ko ni irewesi okan nipa ohun ti o sele si won ni oju ogun esin Allahu. Won ko kole, won ko si jura won sile fun ota esin. Allahu si nifee awon onisuuru |
Ko si si ohun kan ti won so tayo pe won so pe: "Oluwa wa fori awon ese wa ati aseju wa ninu oro wa jin wa, mu ese wa duro sinsin, ki O si se aranse fun wa lori ijo alaigbagbo |
فَآتَاهُمُ اللَّهُ ثَوَابَ الدُّنْيَا وَحُسْنَ ثَوَابِ الْآخِرَةِ ۗ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ(148) Nitori naa, Allahu fun won ni esan aye ati daadaa esan orun. Allahu si nifee awon oluse rere |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba tele awon t’o sai gbagbo, won maa yi yin lese pada kuro ninu esin. Nigba naa, e maa pada di eni ofo (sinu aigbagbo) |
Allahu si ni Alaranse yin. O si loore julo ninu awon alaranse |
A maa fi eru jeje sinu okan awon t’o sai gbagbo nitori pe won ba Allahu wa akegbe, eyi ti ko so eri kan kale fun. Ina si ni ibugbe won; ile awon alabosi si buru |
Dajudaju Allahu ti mu adehun Re se fun yin nigba ti e n pa won pelu iyonda Re, titi di igba ti e fi sojo, ti e si n jiyan si oro. E si yapa (ase Anabi) leyin ti Allahu fi ohun ti e nifee si han yin. - O wa ninu yin eni ti n fe aye, o si n be ninu yin eni ti n fe orun. - Leyin naa, (Allahu) yi oju yin kuro ni odo won, ki O le dan yin wo. O si ti samoju kuro fun yin; Allahu ni Oloore ajulo lori awon onigbagbo ododo |
(E ranti) nigba ti e n gunke sa lo, ti eyin ko si boju wo eni kan kan mo leyin, Ojise si n pe yin lati eyin yin. Nitori naa, (Allahu) fi ibanuje (pipa ti awon osebo pa awon kan laaarin yin) san yin ni esan ibanuje (ti e fi kan Anabi nipase aitele ase re loju ogun ’Uhd. (O ri bee) nitori ki e ma baa banuje lori ohun ti o bo fun yin ati ohun ti o sele si yin. Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Leyin naa, O so ifayabale kale fun yin leyin ibanuje; oogbe ta igun kan lo ninu yin. Igun kan ti emi ara won si ti ko ironu ba, ti won si n ni erokero si Allahu lona aito, erokero igba aimokan, won si n wi pe: “Nje a ni ase kan (ti a le mu wa) lori oro naa bi!” So pe: “Dajudaju gbogbo ase n je ti Allahu.” Won n fi pamo sinu okan won ohun ti won ko le safi han re fun o. Won n wi pe: "Ti o ba je pe a ni ase kan lori oro naa ni, won iba ti pa wa sibi." So pe: “Ti o ba je pe e wa ninu ile yin, awon ti A ti ko akoole pipa si ibujagun won mo iba kuku jade lo sibe.” (Ogun yii ri bee) nitori ki Allahu le gbidanwo ohun ti n be ninu igba-aya yin ati nitori ki O le safomo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda |
Dajudaju awon t’o peyin da ninu yin ni ojo ti ijo meji pade, dajudaju Esu l’o ye won lese nitori apa kan ohun ti won se nise. Allahu si kuku ti samoju kuro fun won. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alafarada |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se da bi awon t’o sai gbagbo, ti won so fun awon omo iya won, nigba ti won n rin kiri ni ori ile tabi (nigba) ti won n jagun, pe: “Ti o ba je pe won n be ni odo wa ni, won iba ti ku, ati pe won iba ti pa won.” (Won wi bee) nitori ki Allahu le fi iyen se abamo sinu okan won. Allahu l’O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise |
Dajudaju ti won ba pa yin s’oju ogun esin Allahu tabi e ku (sinu ile), dajudaju aforijin ati aanu lati odo Allahu loore ju ohun ti e n kojo (nile aye) |
وَلَئِن مُّتُّمْ أَوْ قُتِلْتُمْ لَإِلَى اللَّهِ تُحْشَرُونَ(158) Dajudaju ti e ba ku (sinu ile) tabi won pa yin (s’oju ogun esin), dajudaju odo Allahu ni won maa ko yin jo si |
Ike kan lati odo Allahu l’o kuku ro o fun won; ti o ba je pe o je eni buruku, olokan lile, won iba ti tuka kuro lodo re. Samoju kuro fun won, ba won toro aforijin, ki o si ba won jiroro lori oro. Ti o ba si pinnu (oro kan), ki o gbarale Allahu. Dajudaju Allahu nifee awon olugbarale E |
Ti Allahu ba se aranse fun yin, ko si eni ti o maa bori yin. Ti O ba si yepere yin, ta si ni eni ti o maa se aranse fun yin leyin Re? Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
Ko letoo fun Anabi kan lati ji mu ninu oro ogun siwaju ki won to pin in. Enikeni ti o ba ji oro ogun mu siwaju ki won to pin in, o maa da ohun ti o ji mu ninu oro ogun naa pada ni Ojo Ajinde. Leyin naa, A oo san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. A o si nii se abosi si won |
Se eni ti o (sise) to iyonu Allahu da bi eni ti o pada wale pelu ibinu lati odo Allahu, ibugbe re si ni ina Jahanamo? Ikangun naa si buru |
هُمْ دَرَجَاتٌ عِندَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا يَعْمَلُونَ(163) (Ekinni keji ero inu Ogba Idera ati ero inu Ina ni) won ni ipo (otooto) ni odo Allahu. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise |
Allahu kuku ti se oore fun awon onigbagbo ododo nigba ti O fi le gbe Ojise kan dide si won laaarin ara won. (Ojise naa) n ke awon ayah Re fun won. O n fo won mo (ninu ese). O si n ko won ni Tira (al-Ƙur’an) ati ijinle oye (sunnah), bi o tile je pe teletele won wa ninu isina ponnbele |
Se gbogbo igba ti adanwo kan ba kan yin, ti e si ti fi meji iru re (kan awon keferi), ni eyin yoo maa so pe: “Ona wo ni eyi gba sele si wa?” So pe: “O wa lati odo ara yin.” Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
وَمَا أَصَابَكُمْ يَوْمَ الْتَقَى الْجَمْعَانِ فَبِإِذْنِ اللَّهِ وَلِيَعْلَمَ الْمُؤْمِنِينَ(166) Ohun ti o sele si yin ni ojo ti iko ogun mejeeji pade (sele) pelu iyonda Allahu. Ati pe nitori ki O le safi han awon onigbagbo ododo ni |
(O tun ri bee) nitori ki O le safi han awon t’o sobe-selu (ninu awon musulumi). (Awon onigbagbo ododo) si so fun won pe: “E maa bo, ki a lo jagun fun esin Allahu tabi e wa daabo bo emi ara yin.” Won wi pe: “Awa iba mo ogun-un ja awa iba tele yin.” Won sunmo aigbagbo ni ojo yen ju igbagbo lo. Won n fi enu won so ohun ti ko si ninu okan won. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo |
Awon t’o so nipa awon omo iya won (t’o ku s’oju ogun esin) pe – ti awon si jokoo kale sile (ni tiwon), "Ti o ba je pe won tele tiwa ni, won iba ti pa won." So pe: “E yeku danu fun emi yin ti e ba je olododo.” |
E ma se lero pe oku (iya) ni awon ti won pa s’oju ogun esin Allahu, amo alaaye (eni ike) ni won. Won si n pese ije-imu fun won lodo Oluwa won |
Won n dunnu nitori ohun ti Allahu fun won ninu oore-ajulo Re. Won si n yo fun awon ti ko ti i pade won ninu awon ti won fi sile pe: “Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje.” |
Won n ba won yo fun ike ati oore-ajulo (ti n duro de won) lodo Allahu. Ati pe dajudaju Allahu ko nii fi esan awon onigbagbo ododo rare |
(Awon ni) awon t’o jepe Allahu ati Ojise leyin igba ti won ti f’ara gbogbe. Esan nla wa fun awon t’o se rere, ti won si beru (Allahu) ninu won |
(Awon ni) awon ti awon eniyan wi fun pe: “Won ma ti kora jo de yin, nitori naa e beru won.” (Eyi) lekun igbagbo ododo won. Won si so pe: “Allahu to fun wa. O si dara ni Alamoojuto.” |
Nitori naa, won pada dele pelu ike ati oore-ajulo lati odo Allahu. Aburu kan ko si kan won. Ati pe won (sise) to iyonu Allahu. Allahu si ni Oloore nla |
Dajudaju iyen ni Esu, ti n fi awon ore re deru ba yin. Nitori naa, e ma se beru won. Ki e si beru Mi ti e ba je onigbagbo ododo |
Ma se je ki awon ti n sare ko sinu aigbagbo ko ibanuje ba o. Dajudaju won ko le ko inira kan ba Allahu. Allahu ko fe ki ipin kan ninu oore wa fun won ni orun (ni); iya nla si n be fun won |
Dajudaju awon t’o fi igbagbo ododo ra aigbagbo, won ko le ko inira kan ba Allahu. Iya eleta-elero si wa fun won |
Ki awon t’o sai gbagbo ma se lero pe bi A se n lora fun won je oore fun won. A kan n lora fun won nitori ki won le lekun ninu ese ni. Iya ti i yepere eda si wa fun won |
Allahu ko nii gbe awon onigbagbo ododo ju sile lori ohun ti e wa lori re (nibi aimo onigbagbo ododo loto yato si sobe-selu) titi O maa fi ya eni buruku soto kuro lara eni daadaa. Allahu ko si nii fi imo ikoko mo yin, sugbon Allahu yoo sesa eni ti O ba fe ninu awon Ojise Re. Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. Ti e ba gbagbo ni ododo, ti e si beru (Allahu), esan nla yo si wa fun yin |
Ki awon t’o n sahun pelu ohun ti Allahu fun won ninu oore-ajulo Re ma se lero pe oore ni fun won. Rara, aburu ni fun won. A o fi ohun ti won fi sahun di won lorun ni Ojo Ajinde. Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
Allahu kuku ti gbo oro awon t’o wi pe: “Dajudaju alaini ni Allahu, awa si ni oloro.” A maa sakosile ohun ti won wi ati pipa ti won pa awon Anabi lai letoo. A si maa so pe: “E to iya Ina jonijoni wo.” |
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيكُمْ وَأَنَّ اللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِّلْعَبِيدِ(182) Iyen (ri bee) nitori ohun ti owo yin ti siwaju. Ati pe dajudaju Allahu ko nii se abosi fun awon eru (Re) |
Awon t’o wi pe: "Dajudaju Allahu sadehun fun wa pe a o gbodo gba Ojise kan gbo titi o maa fi mu saraa kan wa fun wa ti ina (atorunwa) yoo fi lanu." So pe: "Dajudaju awon Ojise kan ti wa ba yin siwaju mi pelu awon eri to yanju ati eyi ti e wi (yii), nitori ki ni e fi pa won ti e ba je olododo |
Ti won ba pe o ni opuro, won kuku ti pe awon Ojise t’o siwaju re ni opuro. Won wa pelu awon eri t’o yanju, ipin-ipin Tira ati Tira t’o n tanmole si oro esin |
Emi kookan lo maa to iku wo. A o si san yin ni esan yin ni ekunrere ni Ojo Ajinde. Nitori naa, enikeni ti A ba mu jinna tefe si Ina, ti A si mu wo inu Ogba Idera, o kuku ti jere. Ki si ni igbesi aye bi ko se igbadun etan |
Dajudaju A o maa dan yin wo ninu dukia yin ati emi yin. Dajudaju eyin yoo maa gbo opolopo oro ipalara lati odo awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon osebo. Ti eyin ba se suuru, ti e si beru (Allahu), dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan |
(E ranti) nigba ti Allahu gba adehun awon ti A fun ni tira pe e gbodo se alaye re fun awon eniyan, e o si gbodo fi pamo. Won si ju u seyin leyin won. Won si ta a ni owo kekere. Nitori naa, ohun ti won n ta ma si buru (niya) |
E ma se lero pe awon t’o n dunnu si ohun ti won se (ni aidaa maa la ninu iya). Won si nifee si ki awon (eniyan) maa yin won fun ohun ti won ko se (nise rere). Nitori naa, e ma se ro won ro igbala nibi Iya. Iya eleta elero si wa fun won |
وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(189) Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
Dajudaju awon ami wa ninu iseda awon sanmo ati ile, itelentele ati iyato oru ati osan; (ami wa ninu won) fun awon onilaakaye |
Awon t’o n ranti Allahu ni inaro, ijokoo ati ni idubule; ti won n ronu si iseda awon sanmo ati ile, (won si n so pe:) "Oluwa wa, Iwo ko sedaa eyi pelu iro. Mimo ni fun O. Nitori naa, so wa nibi iya Ina |
رَبَّنَا إِنَّكَ مَن تُدْخِلِ النَّارَ فَقَدْ أَخْزَيْتَهُ ۖ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ(192) Oluwa wa, dajudaju enikeni ti O ba mu wo inu Ina, O ti doju ti i. Ko si nii si awon oluranlowo fun awon alabosi |
Oluwa wa, dajudaju awa gbo olupepe kan t’o n pe (ipe) si ibi igbagbo pe: "E gba Oluwa yin gbo.” A si gbagbo ni ododo. Oluwa wa, nitori naa, fori awon ese wa jin wa, ki O si pa awon asise wa re, ki O si pa wa pelu awon eni rere |
Oluwa wa, fun wa ni ohun ti O sadehun re fun wa lori (ahon) awon Ojise Re. Ma si se doju ti wa ni Ojo Ajinde. Dajudaju Iwo ki i yapa adehun |
Oluwa won si jepe won pe: “Dajudaju Emi ko nii fi ise onise kan ninu yin rare; okunrin ni tabi obinrin, ara kan naa ni yin (nibi esan). Nitori naa, awon t’o gbe (ilu won) ju sile, ti won le jade kuro ninu ilu won, ti won si fi inira kan won nitori esin Mi, won jagun esin, won si pa won. Dajudaju Emi yoo ba won pa awon asise won re. Emi yo si mu won wo inu awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. (O je) esan lati odo Allahu. Ni odo Allahu si ni esan daadaa wa |
لَا يَغُرَّنَّكَ تَقَلُّبُ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي الْبِلَادِ(196) Ma se gba etan pelu igboke-gbodo awon t’o sai gbagbo ninu ilu |
مَتَاعٌ قَلِيلٌ ثُمَّ مَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۚ وَبِئْسَ الْمِهَادُ(197) Igbadun die (le wa fun won), leyin naa ina Jahanamo ni ibugbe won. Ibugbe naa si buru |
Sugbon awon t’o beru Oluwa won, awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re n be fun won. Olusegbere ni won ninu re. Ibudesi kan ni lati odo Allahu. Ohun ti n be lodo Allahu si loore julo fun awon eni rere |
Dajudaju o n be ninu awon ahlul-kitab eni t’o gbagbo ninu Allahu, ati ohun ti A sokale fun yin ati ohun ti A sokale fun won; won n paya Allahu, won ki i ta awon oro Allahu ni owo kekere. Awon wonyen ni esan lodo Oluwa won. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise |
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e se suuru, e parowa suuru, e so bode ilu yin (lati le dena awon omo-ogun ota esin). Ki e si beru Allahu nitori ki e le jere |
Plus de sourates en Yoruba :
Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :
Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al Imran : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al Imran complète en haute qualité.
Ahmed Al Ajmy Bandar Balila Khalid Al Jalil Saad Al Ghamdi Saud Al Shuraim Abdul Basit Abdul Rashid Sufi Abdullah Basfar Abdullah Al Juhani Fares Abbad Maher Al Muaiqly Al Minshawi Al Hosary Mishari Al-afasi Yasser Al Dosari
Donnez-nous une invitation valide