PDF —
60 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Adh-Dhariyat pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Adh-Dhariyat pdf Yorùbá — Gbà Surah Adh-Dhariyat Itumọ. Surah Adh-Dhariyat (Meccan) 60 Ẹsẹ.

← QafSurah Adh-Dhariyat At-Tur →


60 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﯤﯥﯦ
51:1 (Allahu bura pelu) ategun t’o n tu erupe jade nile taara
ﯧﯨﯩ
51:2 (O bura pelu) awon esujo t’o wuwo rinrin
ﯪﯫﯬ
51:3 (O bura pelu) awon oko oju-omi t’o n rin pelu irorun
ﯭﯮﯯ
51:4 (O bura pelu) awon molaika t’o n pin nnkan (ti O ti pin fun eda)
ﯰﯱﯲﯳ
51:5 Ododo ma ni ohun ti A n se ni adehun fun yin
ﯴﯵﯶﯷ
51:6 Ati pe dajudaju Ojo Esan maa sele
ﭑﭒﭓﭔ
51:7 (Allahu tun bura pelu) sanmo olosoo
ﭕﭖﭗﭘﭙ
51:8 Dajudaju eyin wa lori oro t’o n takora won (nipa al-Ƙur’an)
ﭚﭛﭜﭝﭞ
51:9 Eni ti won n se lori kuro nibi al-Ƙur’an ni eni ti Won ti se lori kuro nibe (lati inu Laohul-Mahfuth)
ﭟﭠﭡ
51:10 Egbe ni fun awon opuro
ﭢﭣﭤﭥﭦﭧ
51:11 awon ni won wa ninu aimokan, awon onigbagbe
ﭨﭩﭪﭫﭬ
51:12 ti won n beere igba ti Ojo Esan maa sele
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
51:13 Ni ojo naa si ni won yoo maa fi Ina je won niya
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
51:14 E to iya yin wo. Eyi ni nnkan ti e ti n wa pelu ikanju
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
51:15 Dajudaju awon oluberu (Allahu) yoo wa ninu awon Ogba Idera pelu awon omi odo (ni isale re)
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
51:16 Won yoo maa gba nnkan ti Oluwa won ba fun won. Dajudaju won ti je oluse-rere siwaju iyen
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒ
51:17 Won maa n sun oorun die ninu oru
ﮓﮔﮕﮖ
51:18 Won maa n toro aforijin ni afemojumo
ﮗﮘﮙﮚﮛﮜ
51:19 Ninu dukia won, won ni ojuse ti won n se fun alagbe ati eni ti A se arisiki ni eewo fun
ﮝﮞﮟﮠﮡ
51:20 Awon ami wa ni ori ile fun awon alamodaju
ﮢﮣﮤﮥﮦﮧ
51:21 Ninu emi ara yin gan-an (ami iyanu wa ninu re). Se e o riran ni
ﮨﮩﮪﮫﮬﮭ
51:22 Arisiki yin ati ohun ti A n se ni adehun fun yin wa ninu sanmo
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔﯕﯖﯗﯘ
51:23 Nitori naa, Mo fi Oluwa sanmo ati ile bura, dajudaju ododo ni (oro naa) gege bi o se je ododo pe e n fenu soro
ﯙﯚﯛﯜﯝﯞﯟ
51:24 Nje oro awon alejo (Anabi) ’Ibrohim, awon alapon-onle, ti de odo re
ﯠﯡﯢﯣﯤﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
51:25 (Ranti) nigba ti won wole to o wa, won si so pe: "Alaafia (fun o)." Oun naa so pe: "Alaafia (fun yin), eyin ajoji eniyan
ﯫﯬﯭﯮﯯﯰﯱ
51:26 O lo si odo awon ara ile re, o si de pelu omo maalu oloraa (ayangbe)
ﯲﯳﯴﯵﯶﯷ
51:27 O gbe e sunmo odo won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni
ﯸﯹﯺﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂﰃ
51:28 Nigba naa, o ni ipaya won ninu okan. Won so pe: "Ma se paya." Won si fun un ni iro idunnu nipa bibi omokunrin onimo kan
ﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌﰍ
51:29 Nigba naa, iyawo re si bere igbe, o si gbara re loju, o so pe: "Arugbo, agan (ma ni mi)
ﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗ
51:30 Won so pe: "Bayen ni Oluwa re so. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗ
51:31 (Anabi ’Ibrohim) so pe: "Ki tun ni oro ti e ba wa, eyin Ojise
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
51:32 Won so pe: "Dajudaju Won ran wa nise si ijo elese ni
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤ
51:33 nitori ki a le fi okuta amo (sisun) ranse si won
ﭥﭦﭧﭨﭩ
51:34 Won ti fami si i lara lodo Oluwa re fun awon alakoyo
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯﭰ
51:35 Nitori naa, A mu awon t’o je onigbagbo ododo jade kuro ninu (ilu naa)
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
51:36 A o si ri ninu (ilu naa) tayo ile kan t’o je ti awon musulumi
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
51:37 A si fi ami kan sile ninu (ilu naa) fun awon t’o n paya iya eleta-elero
ﮁﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈﮉ
51:38 (Ami tun wa) lara (Anabi) Musa. Nigba ti A fi eri ponnbele ran an nise si Fir‘aon
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
51:39 Sugbon (Fir‘aon) gbunri pelu awon omo ogun re. O si wi pe: "Opidan tabi were kan (niyi)
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
51:40 Nitori naa, A mu oun ati awon omo ogun re. A si ju won sinu agbami odo nigba ti o je alabuku
ﮙﮚﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
51:41 (Ami tun wa) lara ijo ‘Ad. (Ranti) nigba ti A ran ategun iparun si won
ﮡﮢﮣﮤﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
51:42 ko fi kini kan to fe si lara sile bee afi ko so o di bi eso rirun tuutu
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
51:43 (Ami tun wa) lara ijo Thamud. (Ranti) nigba ti A so fun won pe: "E jaye fun igba die na
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
51:44 Won segberaga si ase Oluwa won. Nitori naa, igbe iparun mu won; won si n wo boo
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤﯥ
51:45 Won ko le dide naro. Won ko si le ran ara won lowo
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
51:46 Ati ijo Nuh ti o siwaju (won), dajudaju Awa si ni olugbooro
ﯰﯱﯲﯳﯴﯵ
51:47 Ati pe sanmo, A mo on (si oke yin) pelu agbara. Dajudaju Awa si ni olugbooro
ﯶﯷﯸﯹﯺ
51:48 Ati ile, A se e ni ite. Awon olutele-sile si dara
ﯻﯼﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
51:49 Ati pe gbogbo nnkan ni A seda ni orisi meji-meji nitori ki e le lo iranti
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈﰉﰊﰋﰌ
51:50 Nitori naa, e sa lo si odo Allahu (nipa ironupiwada). Dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin lati odo Re
ﰍﰎﰏﰐﰑﰒﰓﰔﰕﰖﰗﰘﰙ
51:51 E ma se mu olohun miiran mo Allahu. Dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin lati odo Re
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛﭜﭝﭞ
51:52 Bayen ni (oro se ri)! Ojise kan ko wa ba awon t’o siwaju won afi ki won wi pe: "Opidan tabi were ni
ﭟﭠﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
51:53 Se won so asoole nipa re laaarin ara won ni? Rara o! Ijo olutayo-enu-ala ni won ni
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
51:54 Nitori naa, seri kuro lodo won na. Iwo ki i se alabuku
ﭭﭮﭯﭰﭱﭲ
51:55 Seranti nitori pe, dajudaju iranti maa wulo fun awon onigbagbo ododo
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸﭹ
51:56 Ati pe Emi ko seda alujannu ati eniyan bi ko se pe ki won le josin fun Mi
ﭺﭻﭼﭽﭾﭿﮀﮁﮂﮃ
51:57 Emi ko gbero arisiki kan lati odo won. Emi ko si gbero pe ki won maa bo Mi
ﮄﮅﮆﮇﮈﮉﮊﮋ
51:58 Dajudaju Allahu, Oun ni Olupese, Alagbara lile
ﮌﮍﮎﮏﮐﮑﮒﮓﮔﮕ
51:59 Dajudaju ipin iya ti o maa je awon t’o sabosi (wonyi) ni iru ipin iya ti o je ijo elese (iru) won. Nitori naa, ki won ma se kan Mi loju (nipa iya won)
ﮖﮗﮘﮙﮚﮛﮜﮝ
51:60 Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo ni ojo won ti A n se ni adehun fun won

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers