Surah Al-Fajr pdf — Gbà (Yorùbá)
Surah Al-Fajr pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Fajr Itumọ. Surah Al-Fajr (Meccan) 30 Ẹsẹ.
Related
- Surah Al-Fajr ItumọYorùbá
- Surah Al-Fajr mp3Gbọ
- Quran Index Yorùbá114
More Surah PDF
Surah Al-Fajr

ﭤﭥ
89:1
Allahu bura pelu afemojumo
ﭦﭧﭨ
89:2
O tun bura pelu awon oru mewaa kan
ﭩﭪﭫ
89:3
O tun bura pelu meji ati eyo
ﭬﭭﭮﭯ
89:4
O tun bura pelu oru nigba ti o ba lo (ti o ba de)
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
89:5
Nje ibura wa ninu iyen fun onilaakaye
ﭷﭸﭹﭺﭻﭼﭽ
89:6
Se o o ri bi Oluwa re ti se oro ara ‘Ad
ﭾﭿﮀﮁ
89:7
(iyen awon iran) ’Irom, awon omiran
ﮂﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
89:8
awon ti A o da iru won mo sinu ilu
ﮉﮊﮋﮌﮍﮎ
89:9
Ati awon Thamud ti won gbe (ile igbe) sinu apata ninu afonifoji
ﮏﮐﮑﮒ
89:10
ati Fir‘aon eleekan (iya)
ﮓﮔﮕﮖﮗ
89:11
(Awon wonyi ni) awon t’o tayo enu-ala ninu ilu
ﮘﮙﮚﮛ
89:12
Won si se ibaje pupo sinu re
ﮜﮝﮞﮟﮠﮡ
89:13
Oluwa re si rojo iya le won lori
ﮢﮣﮤﮥ
89:14
Dajudaju Oluwa re wa ni ibuso (ise eda)
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫﮬﮭﮮﮯﮰﮱ
89:15
Nitori naa, ni ti eniyan, nigba ti Oluwa re ba dan an wo, ti O pon on le, ti O si se idera fun un, nigba naa o maa wi pe: "Oluwa mi ti pon mi le
ﯓﯔﯕﯖﯗﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
89:16
Sugbon nigba ti O ba dan an wo, ti O gan arisiki re le e lowo, nigba naa o maa wi pe: "Oluwa mi ti yepere mi
ﯞﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
89:17
Rara, ko ri bee. Amo, eyin ko saponle omo-orukan
ﯥﯦﯧﯨﯩﯪ
89:18
Ati pe eyin ko gbera yin longbe lati fun mekunnu ni ounje
ﯫﯬﯭﯮﯯ
89:19
E tun n je ogun ni ijekuje
ﯰﯱﯲﯳﯴ
89:20
Ati pe e nifee si dukia ni ife pupo
ﯵﯶﯷﯸﯹﯺﯻﯼ
89:21
Rara, (ko ye ko ri bee). Nigba ti won ba mi ile titi ni mimi titi (t’o run womuwomu, ti ko si koto, ti ko si gelemo)
ﯽﯾﯿﰀﰁﰂ
89:22
(ti) Oluwa re de pelu awon molaika ni owoowo owoowo
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚﭛ
89:23
ni ojo yen ni won maa mu ina Jahanamo wa. Ni ojo yen, eniyan yoo ranti (oro ara re). Bawo si ni iranti naa se le wulo fun un
ﭜﭝﭞﭟﭠ
89:24
O maa wi pe: "Yee, emi iba ti ti (ise rere) siwaju fun isemi mi
ﭡﭢﭣﭤﭥﭦ
89:25
Ni ojo yen, eni kan ko le fi iya je (eda) bi iru iya (ti) Allahu (yoo fi je e)
ﭧﭨﭩﭪﭫ
89:26
Eni kan ko si le de (eda) ni igbekun bi iru igbekun (ti) Allahu (yoo fi de e)
ﭬﭭﭮﭯ
89:27
Iwo emi olufokanbale
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
89:28
pada si odo Oluwa re ni oluyonu, eni iyonu
ﭶﭷﭸﭹ
89:29
Nitori naa, wole saaarin awon erusin Mi
ﭺﭻﭼ
89:30
Wo inu Ogba Idera Mi
Al-Kur'an
Wednesday, September 9, 2026
Don't forget us in your sincere prayers







