Aal-Imran · 46/200
Itumọ Aṣẹ ohun — Aal-Imran
وَيُكَلِّمُ النَّاسَ فِي الْمَهْدِ وَكَهْلًا وَمِنَ الصَّالِحِينَ ۝٤٦
Wa yukallimun naasa filmahdi wa kahlanw wa minassaaliheen
📖 Ni Yorùbá
O maa ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba t’o ba dagba. O si wa ninu awon eni rere
🎧 Gbọ

📜 Ẹsẹ 44-48 — Aal-Imran

44ذَٰلِكَ مِنْ أَنبَاءِ الْغَيْبِ نُوحِيهِ إِلَيْكَ ۚ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ يُلْقُونَ أَقْلَامَهُمْ أَيُّهُمْ يَكْفُلُ مَرْيَمَ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ يَخْتَصِمُونَ
Iyen wa ninu iro ikoko ti A n fi imisi re ranse si o. Iwo ko kuku si lodo won nigba ti won n ju gege won (lati mo) ta ni ninu won ni o maa gba Moryam wo. Iwo ko si si lodo won nigba ti won n se ifanfa (lori re)
45إِذْ قَالَتِ الْمَلَائِكَةُ يَا مَرْيَمُ إِنَّ اللَّهَ يُبَشِّرُكِ بِكَلِمَةٍ مِّنْهُ اسْمُهُ الْمَسِيحُ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ وَجِيهًا فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَمِنَ الْمُقَرَّبِينَ
(E ranti) nigba ti awon molaika so pe: "Moryam, dajudaju Allahu n fun o ni iro idunnu (nipa dida eda kan pelu) oro kan lati odo Re. Oruko re ni Mosih ‘Isa omo Moryam. Abiyi ni ni aye ati ni orun. O si wa lara alasun-unmo (Allahu). ninu ayah ti ali ‘Imron Allahu (subhanahu wa ta’ala) n so nipa bi awon mola’ikah se wa so asotele nipa bibi ‘Isa (’alaehi-ssolatu wa-ssalam). Awon molaika t’o wa so asotele naa ju eyo kan lo. Idi niyi ti “mola’ikah” fi je opo ninu ayah yen. Amo ninu ayah ti Moryam
46وَيُكَلِّمُ النَّاسَ فِي الْمَهْدِ وَكَهْلًا وَمِنَ الصَّالِحِينَ
O maa ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba t’o ba dagba. O si wa ninu awon eni rere
47قَالَتْ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي وَلَدٌ وَلَمْ يَمْسَسْنِي بَشَرٌ ۖ قَالَ كَذَٰلِكِ اللَّهُ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ إِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُن فَيَكُونُ
(Moryam) so pe: “Oluwa mi bawo ni emi yo se ni omokunrin, (nigba ti) abara kan ko fowo kan mi.” O so pe: Bayen ni Allahu se n da ohun ti O ba fe. Nigba ti O ba (gbero) lati da eda kan ohun ti O maa so fun un ni pe: "Je bee." O si maa je bee
48وَيُعَلِّمُهُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَالتَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ
(Allahu) yoo fun un ni imo ikowe, ijinle oye, Taorah ati ’Injil
Aal-ImranAtokọ Kurani
200Ẹsẹ
MedinanRevelation
46Ẹsẹ

Itumọ — Aal-Imran 46

Surah Aal-Imran Ẹsẹ 46 - Kika, Gbọ, Itumọ, Yorùbá : O maa ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo…

Surah Ẹsẹ 46/200 — Aal-Imran آل عمران (Medinan). Kika Gbọ Itumọ (Yorùbá). Gbọ: Aal-Imran Gbọ, Aal-Imran Itumọ, Aal-Imran mp3, Aal-Imran pdf. Ẹsẹ 44–48. Ni Yorùbá: العربية.




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers