Перевод суры Ас-Саффат на Йоруба язык
(Allahu bura pelu) awon molaika oluto-lowoowo taara |
ati awon molaika t’o n wo esujo kiri taara |
ati awon molaika onke-tira iranti |
Dajudaju Olohun yin, Okan soso ni |
رَّبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَرَبُّ الْمَشَارِقِ(5) Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Oun si ni Oluwa awon ibuyo oorun |
إِنَّا زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِزِينَةٍ الْكَوَاكِبِ(6) Dajudaju Awa fi awon irawo se sanmo ile aye ni oso |
ati iso nibi (aburu) gbogbo esu olorikunkun |
لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى الْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ وَيُقْذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٍ(8) (Awon esu) ko si nii le teti si ijo (molaika t’o wa ni) aye giga julo (ninu sanmo). (Awon molaika) yo si maa ku (awon esu) loko (eta irawo) ni gbogbo agbegbe (sanmo) |
Won n le won danu. Iya ailopin si wa fun won |
إِلَّا مَنْ خَطِفَ الْخَطْفَةَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ ثَاقِبٌ(10) (Won ko nii gbo oro ni kikun) ayafi eni ti o ba ri oro ajigbo gbe, nigba naa (ni molaika) yo si fi eta irawo ina t’o maa jo o tele e |
فَاسْتَفْتِهِمْ أَهُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَم مَّنْ خَلَقْنَا ۚ إِنَّا خَلَقْنَاهُم مِّن طِينٍ لَّازِبٍ(11) Bi won leere wo pe se awon ni iseda won lagbara julo ni tabi awon (eniyan) ti A da? Dajudaju Awa da won lati ara erupe t’o le mora won |
Rara (ko jora won); iwo seemo (nipa al-Ƙur’an), awon si n se yeye |
Ati pe nigba ti won ba se iranti fun won, won ko nii lo iranti |
Nigba ti won ba tun ri ami kan, won yoo maa se yeye |
Won si wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele |
أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ(16) Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo tun gbe wa dide ni |
Se ati awon baba wa, awon eni akoko |
So pe: "Bee ni. Eyin yo si di eni yepere |
فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ فَإِذَا هُمْ يَنظُرُونَ(19) Nitori naa, igbe eyo kan ma ni. Nigba naa ni won yoo maa wo sun |
Won a wi pe: "Egbe wa! Eyi ni Ojo esan |
هَٰذَا يَوْمُ الْفَصْلِ الَّذِي كُنتُم بِهِ تُكَذِّبُونَ(21) Eyi ni ojo Idajo eyi ti e n pe niro |
۞ احْشُرُوا الَّذِينَ ظَلَمُوا وَأَزْوَاجَهُمْ وَمَا كَانُوا يَعْبُدُونَ(22) E ko awon t’o sabosi jo, awon iyawo won ati ohun ti won n josin fun |
مِن دُونِ اللَّهِ فَاهْدُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْجَحِيمِ(23) leyin Allahu. Ki e si juwe won si oju ona ina Jehim |
E da won duro na, dajudaju won maa bi won leere ibeere |
Ki ni ko je ki e ranra yin lowo |
Rara, won ti juwo juse sile ni oni ni |
Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere |
(Awon eniyan) wi pe: "Dajudaju eyin l’e n gba otun wole si wa lara (lati si wa lona) |
(Awon alujannu) wi pe: "Rara o (awa ko), eyin ni e ko je onigbagbo ododo |
وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيْكُم مِّن سُلْطَانٍ ۖ بَلْ كُنتُمْ قَوْمًا طَاغِينَ(30) Ati pe awa ko ni agbara kan lori yin, sugbon eyin je ijo olutayo-enu ala |
Oro Oluwa wa si ko le wa lori pe dajudaju awa yoo to Ina wo |
Nitori naa, a si yin lona. Dajudaju awa naa si je olusina |
Dajudaju ni ojo yen, akegbe ni won ninu Iya |
Dajudaju bayen ni Awa yoo ti se pelu awon elese |
إِنَّهُمْ كَانُوا إِذَا قِيلَ لَهُمْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللَّهُ يَسْتَكْبِرُونَ(35) Dajudaju nigba ti won ba so fun won pe "Ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu.", won yoo maa segberaga |
وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُو آلِهَتِنَا لِشَاعِرٍ مَّجْنُونٍ(36) Won si n wi pe: "Se a maa fi awon orisa wa sile nitori elewi were kan |
Ko ri bee. O mu ododo wa ni. O si n jerii si ododo awon Ojise naa |
Dajudaju e maa to iya eleta-elero wo |
A o nii san yin ni esan kan afi ohun ti e n se nise |
Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
Ti awon wonyen si ni arisiki ti won ti mo |
awon eso. Awon si ni alapon-onle |
ninu awon Ogba Idera |
Lori awon ite ni won yoo ti koju sira won |
Won yoo maa gbe ife oti mimo kaa kiri odo won |
Funfun ni (oti naa). O n dun lenu awon t’o maa mu un |
Ko si ipalara kan fun won ninu re, won ko si nii hunrira lori re |
Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, awon eleyinju ege yo si wa lodo won |
Won da bi tinu eyin. o tun je ki a mo pe won ko reti ike kan kan lorun ni tiwon. Ti o ba je pe won n reti ike kan ni orun |
Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere |
Onsoro kan ninu won yoo so pe: "Dajudaju emi ni ore kan |
ti o n wi pe, “Se dajudaju iwo wa ninu awon onigbagbo ninu Ojo Ajinde |
أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَدِينُونَ(53) Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo san wa ni esan ni?” |
O so pe: "Se eyin yoo yoju wo (eni naa ti ko gbagbo ninu Ojo ajinde) |
O yoju wo o. O si ri i laaarin gbungbun ninu ina Jehim |
O (si) so pe: "Mo fi Allahu bura, iwo fee ko iparun ba mi tan |
Ati pe ti ki i ba se idera Oluwa mi ni, emi naa iba wa ninu eni ti won maa mu wa sinu Ina |
Awa ko sa nii ku mo bayii |
إِلَّا مَوْتَتَنَا الْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ(59) Afi iku wa akoko. Won ko si nii je awa niya |
Dajudaju eyi, ohun ni erenje nla |
Nitori iru eyi, ki awon olusesin maa sesin lo |
Nje iyen l’o loore julo ni ibudesi ni tabi igi zaƙum (igi elegun-un) |
Dajudaju Awa se e ni adanwo fun awon alabosi |
Dajudaju ohun ni igi kan ti o maa hu jade lati idi ina Jehim |
Eso re da bi ori awon esu |
فَإِنَّهُمْ لَآكِلُونَ مِنْهَا فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ(66) Dajudaju won yoo maa je ninu re. Nitori naa, won yoo fi kun inu won bamubamu |
Leyin naa, dajudaju won yoo mu nnkan mimu awoyunweje gbigbona le e lori |
Leyin naa, dajudaju ibupadasi won ni ina Jehim |
Dajudaju won ba awon baba won ni olusina |
Awon naa si n yara tele oripa won |
Dajudaju opolopo awon eni akoko ti sina siwaju won |
Dajudaju A ti ran awon olukilo si won |
Nitori naa, wo bi atubotan awon eni-akilo-fun ti ri |
Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
Dajudaju (Anabi) Nuh pe Wa. A si dara ni olujepe |
A gba oun ati awon ara ile re la kuro ninu ibanuje nla |
A da awon aromodomo re si leyin re |
A si fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
Alaafia ki o maa ba (Anabi) Nuh laaarin gbogbo eda |
Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
Dajudaju oun wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
Leyin naa, A te awon yooku ri sinu agbami |
Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim wa ninu ijo (ti o tele ilana) re |
(E ranti) nigba ti oun naa doju ko Oluwa re pelu okan mimo |
(Ranti) nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Ki ni e n josin fun |
Se e n gbero lati so iro di olohun leyin Allahu |
Ki si ni ero okan yin si Oluwa gbogbo eda?” |
O siju wo awon irawo gan-an |
O si so pe: "Dajudaju o re mi |
Nitori naa, won pa a ti, won si lo |
Nigba naa, o lo si odo awon orisa won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni |
Ki ni o se yin ti e o soro |
Nigba naa, o doju lilu ko won pelu owo otun (o si run won womuwomu) |
(Awon aborisa) sare wa doju ko o |
O so pe: "Se e oo maa josin fun nnkan ti e gbe kale lere ni |
Allahu l’O si da eyin ati nnkan ti e n se nise |
قَالُوا ابْنُوا لَهُ بُنْيَانًا فَأَلْقُوهُ فِي الْجَحِيمِ(97) Won wi pe: "E mo ile kan fun un, ki e si ju u sinu ina |
Won gbero ete si i. A si so won di eni yepere |
O so pe: "Dajudaju mo maa lo si (ilu ti) Oluwa mi (pa mi lase lati lo). O si maa to mi sona (lati de ibe) |
Oluwa mi, ta mi lore omo ninu awon eni rere |
A si fun un ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin alafarada |
Nigba ti (omo naa) dagba, ti o to ba (baba re) se ise, (baba re) so pe: "Omo mi, dajudaju emi la ala pe dajudaju mo n dunbu re. Nitori naa, woye si i, ki ni o ri si i." O so pe: "Baba mi, se ohun ti Won pa lase fun o. O maa ba mi ninu awon onisuuru, ti Allahu ba fe |
Nigba ti awon mejeeji juwo juse sile, ti (Anabi ’Ibrohim) si doju (omo) re bole |
A pe e (bayii) pe, ’Ibrohim |
قَدْ صَدَّقْتَ الرُّؤْيَا ۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(105) o kuku ti mu ala naa se. Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
Dajudaju eyi, ohun ni adanwo ponnbele |
A si fi agbo nla serapada re |
A tun fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ibrohim |
Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
وَبَشَّرْنَاهُ بِإِسْحَاقَ نَبِيًّا مِّنَ الصَّالِحِينَ(112) A tun fun un ni iro idunnu (nipa bibi) ’Ishaƙ, (o maa je) Anabi. (O si maa wa) ninu awon eni rere |
Ati pe A fun oun ati ’Ishaƙ ni ibukun. Eni rere ati alabosi ponnbele (t’o n sabosi si) emi ara re wa ninu aromodomo awon mejeeji |
Dajudaju A soore fun (Anabi) Musa ati Harun |
وَنَجَّيْنَاهُمَا وَقَوْمَهُمَا مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ(115) A gba awon mejeeji ati ijo awon mejeeji la kuro ninu ibanuje nla |
A tun saranse fun won. Awon ni won je olubori (ota won) |
A si fun awon mejeeji ni Tira t’o yanju |
A tun fi awon mejeeji mona taara |
A fun awon mejeeji ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
Alaafia ki o maa ba (Anabi) Musa ati Harun |
Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
Dajudaju awon mejeeji wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
Dajudaju (Anabi) ’Ilyas wa ninu awon Ojise |
(E ranti) nigba ti o so fun ijo re pe: "Se e o nii beru Allahu ni |
Se e oo maa pe orisa kan, e si maa fi Eni t’O dara julo ninu awon eledaa sile, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Oun l’O si dara julo ninu awon oludajo. (surah al-’A‘rof 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Oun si yara julo ninu awon onisiro. (surah al-’Ani‘am 6:62) oludajo alaaanu ibaa mo bii omo ina igun afi ki Allahu je Eledaa re. Koda adamo owo ati okowo ti won so di “oro-Aje. Awon t’o n bo elomiiran naa n sora won di olupese. Yato si pe Allahu ti fi rinle pe Oun nikan ni Olupese fun gbogbo eda Re. Ti eyi ko ba ti i da awon kan loju bee ti won si fe gbe gbogbo ipese olukuluku lori iwon ninu aanu ti Allahu fi si awon eda kan lokan ni won fi di alaaanu. Nitori naa Allahu ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu |
(e n fi) Allahu (sile), Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko |
Won si pe e ni opuro. Nitori naa, won maa mu won wa sinu Ina |
Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
A fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ilyas |
Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
Dajudaju (Anabi) Lut wa ninu awon Ojise |
(E ranti) nigba ti A gba oun ati gbogbo awon ara ile re la |
Ayafi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare) |
Leyin naa, A pa awon yooku run |
Dajudaju eyin naa kuku n gba odo won koja laaaro-laaaro |
ati ni alaale. Se e o nii se laakaye ni |
Dajudaju (Anabi) Yunus kuku wa ninu awon Ojise |
(E ranti) nigba ti o sa lo sinu oko oju-omi t’o kun keke |
O si ba won muje po. O si wa ninu awon ti aje si mo lori |
Nitori naa, eja gbe e mi; o si n da ara re lebi |
Nitori naa, ti ko ba je pe o wa ninu awon olusafomo fun Allahu |
dajudaju iba wa ninu eja titi di ojo ti won yoo gbe eda dide |
Nitori naa, A ju u si ori ile gbansasa leti omi. O si je alailera |
A si mu igi Yeƙtin hu jade lati siji bo o |
A tun ran an nise si oke marun-un (eniyan) tabi ki won lekun si i |
Won gbagbo ni ododo. A si fun won ni igbadun titi di igba die |
فَاسْتَفْتِهِمْ أَلِرَبِّكَ الْبَنَاتُ وَلَهُمُ الْبَنُونَ(149) Bi won leere wo pe: "Se Oluwa re l’o ni awon omobinrin, tiwon si ni omokunrin |
أَمْ خَلَقْنَا الْمَلَائِكَةَ إِنَاثًا وَهُمْ شَاهِدُونَ(150) Tabi A da awon molaika ni obinrin, ti awon si je elerii |
Gbo, ninu iro won ni pe dajudaju won n wi pe |
Allahu bimo." Dajudaju opuro ni won |
Se (Allahu) sesa awon omobinrin lori awon omokunrin ni |
Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii |
أَفَلَا تَذَكَّرُونَ(155) Se e o nii lo iranti ni |
Tabi e ni eri t’o yanju lowo ni |
E mu tira yin wa nigba naa ti e ba je olododo |
Won tun fi ibatan saaarin (Allahu) ati alujannu! Awon alujannu si ti mo pe dajudaju won kuku maa mu awon wa sinu Ina ni |
Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re) |
Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun (leyin Allahu) |
e o le fi si eni kan kan lona |
afi eni ti o ba fe wo inu ina Jehim |
Ko si eni kan ninu awa (molaika) afi ki o ni ibuduro ti won ti mo |
Dajudaju awa, a kuku wa ni owoowo |
Ati pe dajudaju awa, awa kuku ni olusafomo (fun Allahu) |
Won kuku n wi pe |
Ti o ba je pe dajudaju a ba ni (tira) iranti kan ninu (awon tira) awon eni akoko |
dajudaju awa iba je erusin Allahu, awon eni esa |
Sugbon won sai gbagbo ninu (Allahu). Laipe won maa mo |
وَلَقَدْ سَبَقَتْ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا الْمُرْسَلِينَ(171) Dajudaju oro Wa ti siwaju fun awon erusin Wa, awon Ojise |
Dajudaju awon, awon l’a kuku maa saranse fun |
Ati pe dajudaju awon omo ogun Wa, awon kuku ni olubori |
Nitori naa, seri kuro lodo won fun igba die |
Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo |
Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju |
فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمْ فَسَاءَ صَبَاحُ الْمُنذَرِينَ(177) Nigba ti o ba sokale si agboole won, owuro ojo naa yo si buru fun awon eni-akilo-fun |
Kuro lodo won titi di igba kan na |
Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo |
Mimo ni fun Oluwa re, Oluwa agbara, tayo ohun ti won n fi royin (Re) |
Ki alaafia maa ba awon Ojise |
Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda |
Больше сур в Йоруба:
Скачать суру As-Saaffat с голосом самых известных рекитаторов Корана:
Сура As-Saaffat mp3: выберите рекитатора, чтобы прослушать и скачать главу As-Saaffat полностью в высоком качестве
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
Помолитесь за нас хорошей молитвой