Surah Al-Infitar ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Infitar pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (19 Ẹsẹ — مكية). Al-Infitar Gbọ, Al-Infitar Itumọ, Al-Infitar mp3, Al-Infitar pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Infitar

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
إِذَا السَّمَاءُ انفَطَرَتْ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Nigba ti sanmo ba fa ya perepere
وَإِذَا الْكَوَاكِبُ انتَثَرَتْ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri
وَإِذَا الْبِحَارُ فُجِّرَتْ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
ati nigba ti awon ibudo ba san jara won
وَإِذَا الْقُبُورُ بُعْثِرَتْ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
ati (nigba ti A ba ta ile soke), ti A si mu awon oku jade (laaye) lati inu awon saree
عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّا قَدَّمَتْ وَأَخَّرَتْ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
(nigba naa ni) emi kookan yoo mo ohun ti o ti siwaju (ninu ise re) ati ohun ti o fi seyin (ninu oripa ise re)
يَا أَيُّهَا الْإِنسَانُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ الْكَرِيمِ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Iwo eniyan, ki ni o tan o je nipa Oluwa re, Alapon-onle
الَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّاكَ فَعَدَلَكَ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Eni t’O seda re? O seda re ni pipe. O si mu o dogba jale leeyan
فِي أَيِّ صُورَةٍ مَّا شَاءَ رَكَّبَكَ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
O to eya ara re papo sinu eyikeyii aworan ti O fe
كَلَّا بَلْ تُكَذِّبُونَ بِالدِّينِ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Ni ti ododo, nse l’e n pe Ojo esan niro
وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَافِظِينَ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Dajudaju awon eso si wa ni odo yin
كِرَامًا كَاتِبِينَ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
(Won je) alapon-onle, onkowe-ise eda
يَعْلَمُونَ مَا تَفْعَلُونَ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Won mo ohun ti e n se nise
إِنَّ الْأَبْرَارَ لَفِي نَعِيمٍ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Dajudaju awon eni rere yoo kuku wa ninu igbadun
وَإِنَّ الْفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٍ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Dajudaju awon eni ibi yo si kuku wa ninu ina Jehim
يَصْلَوْنَهَا يَوْمَ الدِّينِ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Won yoo wo inu re ni Ojo esan
وَمَا هُمْ عَنْهَا بِغَائِبِينَ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Won ko si nii kuro ninu re
وَمَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan
ثُمَّ مَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Leyin naa, ki ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan
يَوْمَ لَا تَمْلِكُ نَفْسٌ لِّنَفْسٍ شَيْئًا ۖ وَالْأَمْرُ يَوْمَئِذٍ لِّلَّهِ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
(Ojo esan ni) ojo ti emi kan ko nii kapa kini kan fun emi kan. Gbogbo ase ojo yen si n je ti Allahu
← 81 Al-Infitar (82/114) 83 →
Kika Surah Al-Infitar ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

82الإنفطار Al-Infitar 📚 19 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Infitar — 19 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers