PDF —
21 Ẹsẹ Meccan PDF
Built right in your browser — download starts automatically

Surah Al-Layl pdf — Gbà (Yorùbá)

Surah Al-Layl pdf Yorùbá — Gbà Surah Al-Layl Itumọ. Surah Al-Layl (Meccan) 21 Ẹsẹ.



21 Ẹsẹ · Meccan · Yorùbá
bismillah
ﮡﮢﮣﮤ
92:1 (Allahu) bura pelu ale nigba ti (ile) ba su
ﮥﮦﮧﮨ
92:2 O tun bura pelu osan nigba ti (osan) ba pon
ﮩﮪﮫﮬﮭ
92:3 O tun bura pelu Eni ti O da ako ati abo
ﮮﮯﮰﮱ
92:4 Dajudaju ise yin, otooto ni
ﯓﯔﯕﯖﯗ
92:5 Ni ti eni ti o ba tore, ti o si beru (Allahu)
ﯘﯙﯚ
92:6 (ti) o tun pe esan rere ni ododo
ﯛﯜﯝ
92:7 A si maa se ise rere ni irorun fun un
ﯞﯟﯠﯡﯢ
92:8 Ni ti eni ti o ba yahun, ti o si ri ara re leni t’o roro tayo esan orun
ﯣﯤﯥ
92:9 (ti) o tun pe esan rere ni iro
ﭑﭒﭓ
92:10 A si maa se ise aburu ni irorun fun un
ﭔﭕﭖﭗﭘﭙﭚ
92:11 Dukia re ko si nii ro o loro nigba ti o ba ja bo (sinu Ina)
ﭛﭜﭝﭞ
92:12 Dajudaju tiWa ni (lati salaye) imona
ﭟﭠﭡﭢﭣ
92:13 Ati pe dajudaju tiWa ni orun ati aye
ﭤﭥﭦﭧ
92:14 Nitori naa, Mo ti fi Ina elejo fofo kilo fun yin
ﭨﭩﭪﭫﭬ
92:15 Ko si eni ti o maa wo inu re afi olori buruku
ﭭﭮﭯﭰ
92:16 eni ti o pe ododo niro, ti o si keyin si i
ﭱﭲﭳ
92:17 Won si maa gbe (Ina) jinna si oluberu (Allahu)
ﭴﭵﭶﭷﭸ
92:18 eni t’o n fi dukia re tore, ti o n safomo (re)
ﭹﭺﭻﭼﭽﭾﭿ
92:19 Ko si si oore idera kan ti (o ni lokan) lati gba ni esan ni odo enikeni
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
92:20 bi ko se pe lati fi wa oju rere Oluwa re, Eni Giga julo
ﮆﮇﮈ
92:21 Laipe o si maa yonu (si esan re)

Al-Kur'an


Wednesday, September 9, 2026

Don't forget us in your sincere prayers