Surah Al-Anbiya with Yoruba
اقْتَرَبَ لِلنَّاسِ حِسَابُهُمْ وَهُمْ فِي غَفْلَةٍ مُّعْرِضُونَ(1) Isiro-ise sunmo fun awon eniyan, won si wa ninu ifonufora, ti won n gbunri (kuro nibi ododo) |
مَا يَأْتِيهِم مِّن ذِكْرٍ مِّن رَّبِّهِم مُّحْدَثٍ إِلَّا اسْتَمَعُوهُ وَهُمْ يَلْعَبُونَ(2) Ko si iranti titun kan ti o maa de ba won lati odo Oluwa won afi ki won gbo o pelu ere sise |
Won fonufora ni. Awon t’o sabosi si fi oro ikoko (aarin ara won) pamo pe: "Se eyi tayo abara bi iru yin ni? Se e maa tele idan ni, nigba ti eyin naa riran |
قَالَ رَبِّي يَعْلَمُ الْقَوْلَ فِي السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(4) O so pe: “Oluwa mi mo oro t’o n be ninu sanmo ati ile. Oun ni Olugbo, Onimo.” |
Rara, won tun wi pe: “Awon ala ti itumo re lopo mora won ni (al-Ƙur’an.” Won tun wi pe): “Rara, o hun un ni.” (Won tun wi pe): “Rara, elewi ni. Bi bee ko ki o mu ami kan wa fun wa gege bi won se fi ran awon eni akoko.” |
مَا آمَنَتْ قَبْلَهُم مِّن قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا ۖ أَفَهُمْ يُؤْمِنُونَ(6) Ko si awon t’o gbagbo siwaju won ninu awon ilu ti A ti pare (leyin isokale ami). Se awon si maa gbagbo (nigba ti ami ba de) |
A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo |
وَمَا جَعَلْنَاهُمْ جَسَدًا لَّا يَأْكُلُونَ الطَّعَامَ وَمَا كَانُوا خَالِدِينَ(8) A ko si se won ni abara ti ko nii jeun. Won ko si je olusegbere (nile aye). abara ni ki i se olohun. Allahu awon oku ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye ni ibamu si surah an-Naml; 27:80 surah ar-Rum; 30:52 ati surah Fatir; 35:22. Anabi wa Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) si pada di oku ti won bo mo inu saree ninu ilu Modinah Onimoole ni ibamu si surah az-Zumor; 39:30. Ko si si ayah taara kan ninu al-Ƙur’an ti o yo Anabi wa Muhammad (sollalahu alayhi wa sallam) sile ninu awon oku ti ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye. Amo hadith t’o fese rinle wa ti o n fi rinle pe “Ko si eni kan ti o maa salamo si mi afi ki Allahu da emi mi pada si mi lara titi mo maa fi da salamo naa pada fun un.” Abu Daud l’o gba a wa labe akole: bab ziyaratul-ƙubur. Seek al-Baniy so pe “hadith naa dara”. Hadith yii tun wa ninu musnad ’Ahmad ati sunan Baehaƙiy. Ojise Allahu (sollalahu alayhi wa sallam) so pe “Dajudaju ojo Jum‘ah wa ninu awon ojo yin t’o loore julo; Won seda Anabi Adam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ninu re ni isele t’o tayo oye wa amo ti o tenu Anabi wa Muhammad olododo (sollalahu alayhi wa sallam) jade ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin.” Eni kan ninu awon t’o gba hadith yii wa so pe “Ki ni itumo “ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin”? Tabi ki ni itumo “ti ohun ti o maa fi dari yin si maa wa lati odo yin?” Ibnu Abi Thanb si fesi pe |
ثُمَّ صَدَقْنَاهُمُ الْوَعْدَ فَأَنجَيْنَاهُمْ وَمَن نَّشَاءُ وَأَهْلَكْنَا الْمُسْرِفِينَ(9) Leyin naa, A mu adehun Wa se fun won. A si gba awon Ojise ati awon ti A ba fe la. A si pa awon olutayo enu-ala run |
لَقَدْ أَنزَلْنَا إِلَيْكُمْ كِتَابًا فِيهِ ذِكْرُكُمْ ۖ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(10) Dajudaju A ti so tira kan kale fun yin, ti iranti nipa oro ara yin wa ninu re. Nitori naa, se e o se laakaye ni |
وَكَمْ قَصَمْنَا مِن قَرْيَةٍ كَانَتْ ظَالِمَةً وَأَنشَأْنَا بَعْدَهَا قَوْمًا آخَرِينَ(11) Meloo meloo ninu ilu ti A ti pare, ti o je alabosi! A si gbe awon ijo miiran dide leyin won |
فَلَمَّا أَحَسُّوا بَأْسَنَا إِذَا هُم مِّنْهَا يَرْكُضُونَ(12) Nigba ti won ri iya Wa (t’o n bo), won si n sa lo fun un |
لَا تَرْكُضُوا وَارْجِعُوا إِلَىٰ مَا أُتْرِفْتُمْ فِيهِ وَمَسَاكِنِكُمْ لَعَلَّكُمْ تُسْأَلُونَ(13) E ma se sa lo. E pada sibi nnkan ti A fi se gbedemuke fun yin ati awon ibugbe yin nitori ki A le bi yin ni ibeere |
Won wi pe: “Egbe wa o! Dajudaju awa je alabosi.” |
فَمَا زَالَت تِّلْكَ دَعْوَاهُمْ حَتَّىٰ جَعَلْنَاهُمْ حَصِيدًا خَامِدِينَ(15) Igbe won yii ko duro titi A fi so won di koriko ti won ge, won si doku kale |
وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاءَ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَاعِبِينَ(16) Awa ko da sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin awon mejeeji pelu ere sise |
لَوْ أَرَدْنَا أَن نَّتَّخِذَ لَهْوًا لَّاتَّخَذْنَاهُ مِن لَّدُنَّا إِن كُنَّا فَاعِلِينَ(17) Ti o ba je pe A gbero lati sere ni, odo Wa ni A kuku ti maa se e ti A ba je oluse-(ere) |
Rara o! A n so ododo lu iro (mole ni). Ododo si maa fo agbari iro. Iro si maa poora. Egbe si ni fun yin nipa ohun ti e n fi royin (Re ni ti iro) |
TiRe ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Ati pe awon t’o n be lodo Re, won ki i segberaga nibi ijosin Re. Ati pe won ko kole |
Won n safomo ni oru ati ni osan; ko si re won |
Tabi won ni awon olohun kan ti won mu jade lati ara ile, ti won n ji oku dide ni |
Ti o ba je pe awon olohun kan wa ninu sanmo ati ile leyin Allahu, sanmo ati ile iba ti baje. Mimo ni fun Allahu, Oluwa Ite-ola, tayo ohun ti won n fi royin (Re) |
Won ko nii bi (Allahu) ni ibeere nipa nnkan ti O n se. Awon ni won maa bi ni ibeere (nipa ise owo won) |
Tabi won so awon kan di olohun leyin Allahu ni? So pe: “E mu eri oro yin wa.” (Al-Ƙur’an) yii ni iranti nipa awon t’o wa pelu mi ati iranti nipa awon t’o siwaju mi. Sugbon opolopo won ko mo ododo; won si n gbunri kuro nibe |
A ko ran ojise kan nise siwaju re afi ki A fi imisi ranse si i pe: “Dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Emi (Allahu). Nitori naa, e josin fun Mi.” |
وَقَالُوا اتَّخَذَ الرَّحْمَٰنُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۚ بَلْ عِبَادٌ مُّكْرَمُونَ(26) Won wi pe: “Ajoke-aye so eni kan di omo.” Mimo ni fun Un – Ko ri bee; erusin alapon-onle ni won |
لَا يَسْبِقُونَهُ بِالْقَوْلِ وَهُم بِأَمْرِهِ يَعْمَلُونَ(27) Won ki i siwaju Allahu soro. Won si n sise pelu ase Re |
(Allahu) mo ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won. Won ko si nii sipe (eni kan) afi eni ti (Allahu) ba yonu si. Won tun n paya fun iberu Re |
Ati pe enikeni ninu won ti o ba wi pe: “Dajudaju emi ni olohun leyin Re.” Nitori iyen si ni A oo fi san an ni esan ina Jahanamo. Bayen si ni A se n san awon alabosi ni esan |
Se awon t’o sai gbagbo ko ri i pe dajudaju awon sanmo le po ati ile naa le po tele ni, A si ya won si otooto, A si se gbogbo nnkan ni abemi lati inu omi? Nitori naa, se won ko nii gbagbo ni? lile-papo” itumo “fatƙ” si ni “ela |
A si fi awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le mi mo won lese. A si fi awon ona fife saaarin awon apata nitori ki won le ri ona to |
وَجَعَلْنَا السَّمَاءَ سَقْفًا مَّحْفُوظًا ۖ وَهُمْ عَنْ آيَاتِهَا مُعْرِضُونَ(32) A tun se sanmo ni aja ti won n so (nibi jijabo). Sibesibe won n gbunri kuro nibi awon ami re |
وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ(33) Oun ni Eni ti O da oru ati osan pelu oorun ati osupa. Ikookan (oorun ati osupa) wa ni opopona roboto t’o n to |
وَمَا جَعَلْنَا لِبَشَرٍ مِّن قَبْلِكَ الْخُلْدَ ۖ أَفَإِن مِّتَّ فَهُمُ الْخَالِدُونَ(34) A ko se bibe gbere fun abara kan siwaju re. Nje ti o ba ku, awon si ni olusegbere bi |
Emi kookan l’o maa to iku wo. A si maa fi aburu ati rere sadanwo fun yin. Odo Wa si ni won yoo da yin pada si |
Nigba ti awon t’o sai gbagbo ba ri o, won ko si nii ka o kun kini kan bi ko se oniyeye pe: “Se eyi ni eni t’o n soro nipa awon olohun yin?” Alaigbagbo si ni awon naa nipa iranti Ajoke-aye |
خُلِقَ الْإِنسَانُ مِنْ عَجَلٍ ۚ سَأُرِيكُمْ آيَاتِي فَلَا تَسْتَعْجِلُونِ(37) Won fi ikanju se eniyan. Mo maa fi awon ami Mi han yin. Nitori naa, e ma se kan Mi loju |
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(38) Won si n wi pe: “Igba wo ni ileri yii yoo se na, ti e ba je olododo?” |
Ti o ba je pe awon t’o sai gbagbo mo igba ti won ko nii da Ina duro niwaju won ati ni eyin won, ti A o si nii ran won lowo, (won iba ti wa iya pelu ikanju) |
بَلْ تَأْتِيهِم بَغْتَةً فَتَبْهَتُهُمْ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ رَدَّهَا وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ(40) Sugbon (iya Ina) yoo ba won ni ojiji, nigba naa o maa ko idaamu ba won; won ko si nii le da a pada. A o si nii sun (iya naa) siwaju fun won |
Won kuku ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re! Nitori naa, ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi awon t’o n fi won se yeye po |
So pe: "Ta ni eni ti o n so yin ni oru ati ni osan nibi iya Ajoke-aye?" Amo nse ni won n gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye |
Tabi won ni awon olohun kan t’o maa gba won sile leyin Wa ni? Won ko le ran ara won lowo. Won ko si le gba won sile lodo Wa |
Bee ni, A fun awon wonyi ati awon baba won ni igbadun titi isemi aye won fi gun. Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A n mu ile dinku (mo awon alaigbagbo lowo) lati awon eti ilu (wonu ilu nipa fifun awon musulumi ni isegun lori won). Nitori naa, se awon ni olubori ni |
قُلْ إِنَّمَا أُنذِرُكُم بِالْوَحْيِ ۚ وَلَا يَسْمَعُ الصُّمُّ الدُّعَاءَ إِذَا مَا يُنذَرُونَ(45) So pe: “Imisi ni mo fi n kilo fun yin. Awon aditi ko si nii gbo ipe nigba ti won ba n kilo fun won.” |
Ati pe dajudaju ti abala kan ninu iya Oluwa re ba fowo ba won, dajudaju won a wi pe: “Egbe wa o; dajudaju awa je alabosi.” |
A maa gbe awon osuwon deede kale ni Ojo Ajinde. Nitori naa, won ko nii se abosi kini kan fun emi kan. Ki (ise) je iwon eso kardal (bin-intin), A maa mu un wa. A si to ni Olusiro |
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَىٰ وَهَارُونَ الْفُرْقَانَ وَضِيَاءً وَذِكْرًا لِّلْمُتَّقِينَ(48) Dajudaju A fun (Anabi) Musa ati (Anabi) Harun ni oro-ipinya (ohun t’o n sopinya laaarin ododo ati iro), imole ati iranti fun awon oluberu (Allahu) |
الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِالْغَيْبِ وَهُم مِّنَ السَّاعَةِ مُشْفِقُونَ(49) (Awon ni) awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko. Olupaya si ni won nipa Akoko naa |
وَهَٰذَا ذِكْرٌ مُّبَارَكٌ أَنزَلْنَاهُ ۚ أَفَأَنتُمْ لَهُ مُنكِرُونَ(50) Eyi si ni iranti onibukun ti A sokale. Se eyin yoo tako o ni |
۞ وَلَقَدْ آتَيْنَا إِبْرَاهِيمَ رُشْدَهُ مِن قَبْلُ وَكُنَّا بِهِ عَالِمِينَ(51) Dajudaju A ti fun (Anabi) ’Ibrohim ni imona tire siwaju (ki o to dagba). Awa si n je Onimo nipa re |
إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا هَٰذِهِ التَّمَاثِيلُ الَّتِي أَنتُمْ لَهَا عَاكِفُونَ(52) (Ranti) nigba ti o so fun baba re ati ijo re pe: “Ki ni awon ere wonyi ti e n duro ti lorun se je na?” |
Won wi pe: “A ba awon baba wa ti won n josin fun won ni.” |
قَالَ لَقَدْ كُنتُمْ أَنتُمْ وَآبَاؤُكُمْ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ(54) O so pe: “Dajudaju eyin ati awon baba yin ti wa ninu isina ponnbele.” |
قَالُوا أَجِئْتَنَا بِالْحَقِّ أَمْ أَنتَ مِنَ اللَّاعِبِينَ(55) Won wi pe: “Se o mu ododo wa fun wa ni tabi iwo wa lara awon elefe.” |
O so pe: "Rara. Oluwa yin ni Oluwa awon sanmo ati ile; Eni ti O pile iseda won. Emi si wa ninu awon elerii lori iyen |
وَتَاللَّهِ لَأَكِيدَنَّ أَصْنَامَكُم بَعْدَ أَن تُوَلُّوا مُدْبِرِينَ(57) Ati pe mo fi Allahu bura, dajudaju mo maa dete si awon orisa yin leyin ti e ba peyin da, ti e lo |
فَجَعَلَهُمْ جُذَاذًا إِلَّا كَبِيرًا لَّهُمْ لَعَلَّهُمْ إِلَيْهِ يَرْجِعُونَ(58) O si fo won si wewe afi agba (orisa) won nitori ki won le pada de ba a |
قَالُوا مَن فَعَلَ هَٰذَا بِآلِهَتِنَا إِنَّهُ لَمِنَ الظَّالِمِينَ(59) Won wi pe: “Ta ni o se eyi pelu awon olohun wa? Dajudaju onitoun wa ninu awon alabosi.” |
قَالُوا سَمِعْنَا فَتًى يَذْكُرُهُمْ يُقَالُ لَهُ إِبْرَاهِيمُ(60) Won wi pe: “A gbo ti odokunrin kan n bu enu ate lu won. Won n pe (omo naa) ni ’Ibrohim.” |
قَالُوا فَأْتُوا بِهِ عَلَىٰ أَعْيُنِ النَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَشْهَدُونَ(61) Won wi pe: “E mu un wa han awon eniyan ki won le jerii le e lori.” |
قَالُوا أَأَنتَ فَعَلْتَ هَٰذَا بِآلِهَتِنَا يَا إِبْرَاهِيمُ(62) Won wi pe: “Se iwo l’o se eyi pelu awon olohun wa, ’Ibrohim?” |
قَالَ بَلْ فَعَلَهُ كَبِيرُهُمْ هَٰذَا فَاسْأَلُوهُمْ إِن كَانُوا يَنطِقُونَ(63) O so pe: “Rara o, agba won yii l’o se (won bee). Nitori naa, e bi won leere wo ti won ba maa n soro.” |
فَرَجَعُوا إِلَىٰ أَنفُسِهِمْ فَقَالُوا إِنَّكُمْ أَنتُمُ الظَّالِمُونَ(64) Nigba naa, won yiju sira won, won si wi pe: “Dajudaju eyin ni alabosi.” |
ثُمَّ نُكِسُوا عَلَىٰ رُءُوسِهِمْ لَقَدْ عَلِمْتَ مَا هَٰؤُلَاءِ يَنطِقُونَ(65) Leyin naa, won sori ko (won si wi pe): “Iwo naa kuku mo pe awon wonyi ki i soro.” |
قَالَ أَفَتَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكُمْ شَيْئًا وَلَا يَضُرُّكُمْ(66) O so pe: "Se eyin yoo maa josin fun nnkan ti ko le se yin ni anfaani, ti ko si le ko inira ba yin leyin Allahu |
أُفٍّ لَّكُمْ وَلِمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ ۖ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(67) Sio eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu, se eyin ko nii se laakaye ni |
قَالُوا حَرِّقُوهُ وَانصُرُوا آلِهَتَكُمْ إِن كُنتُمْ فَاعِلِينَ(68) Won wi pe: “E dana sun un; ki e si ran awon olohun yin lowo, ti eyin ba nikan-an se.” |
قُلْنَا يَا نَارُ كُونِي بَرْدًا وَسَلَامًا عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ(69) A so pe: “Ina, di tutu ati alaafia lara ’Ibrohim.” |
Won gbero ete si i, sugbon A se won ni olofo julo |
وَنَجَّيْنَاهُ وَلُوطًا إِلَى الْأَرْضِ الَّتِي بَارَكْنَا فِيهَا لِلْعَالَمِينَ(71) A si gba oun ati Lut la sori ile ti A fi ibukun si fun gbogbo eda |
وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ نَافِلَةً ۖ وَكُلًّا جَعَلْنَا صَالِحِينَ(72) A ta a ni ore omo, ’Is-haƙ ati Ya‘ƙub ti o je alekun (iyen, omoomo). Olukuluku (won) ni A se ni eni rere |
A se won ni asiwaju t’o n to awon eniyan si ona pelu ase Wa. A si fi imisi ranse si won nipa sise ise rere, irun kiki ati Zakah yiyo. Won si je olujosin fun Wa |
(E ranti Anabi) Lut. A fun un ni ipo Anabi ati imo. A si gba a la ninu ilu ti won ti n se awon ise buruku. Dajudaju won je ijo buruku, obileje |
وَأَدْخَلْنَاهُ فِي رَحْمَتِنَا ۖ إِنَّهُ مِنَ الصَّالِحِينَ(75) A si mu un wo inu ike Wa. Dajudaju o wa ninu awon eni rere |
(E ranti Anabi) Nuh, nigba ti o pe ipe siwaju (yin). A si da a lohun. A si gba oun ati awon eniyan re la ninu ibanuje nla |
A si saranse fun un lori awon eniyan t’o pe awon ayah Wa niro. Dajudaju won je ijo buruku. A si te won ri patapata |
(E ranti Anabi) Dawud ati (Anabi) Sulaemon, nigba ti awon mejeeji n se idajo lori (oro) oko, nigba ti agutan ijo kan jeko wo inu oko naa. Awa si je Olujerii si idajo won |
A si fun (Anabi) Sulaemon ni agboye re. Ati pe ikookan (won) ni A fun ni ipo Anabi ati imo. A si te awon apata ati eye ba; won n se afomo (fun Allahu) pelu (Anabi) Dawud. Awa l’A se won bee |
وَعَلَّمْنَاهُ صَنْعَةَ لَبُوسٍ لَّكُمْ لِتُحْصِنَكُم مِّن بَأْسِكُمْ ۖ فَهَلْ أَنتُمْ شَاكِرُونَ(80) A tun fun un ni imo nipa sise ewu irin fun yin nitori ki o le je odi iso fun yin nibi ogun yin. Nitori naa, nje oludupe (fun Allahu) ni eyin bi |
A si te ategun lile lori ba fun (Anabi) Sulaemon. O n gbe e lo pelu ase re sori ile ti A fi ibukun si. A si n je Onimo nipa gbogbo nnkan |
Ninu awon esu, awon t’o n wa kusa okun tun wa fun un. Won tun n se ise miiran yato si iyen. Awa si n je Oluso fun won |
۞ وَأَيُّوبَ إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ أَنِّي مَسَّنِيَ الضُّرُّ وَأَنتَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ(83) (E ranti Anabi) ’Ayyub, nigba ti o pe Oluwa re pe: "Dajudaju owo inira ti kan mi. Iwo si ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu |
A si je ipe re. A mu gbogbo inira re kuro fun un. A tun fun un ni awon ebi re (pada) ati iru won pelu won; (o je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon olujosin (fun Wa) |
وَإِسْمَاعِيلَ وَإِدْرِيسَ وَذَا الْكِفْلِ ۖ كُلٌّ مِّنَ الصَّابِرِينَ(85) (E ranti Anabi) ’Ismo‘il ati (Anabi) ’Idris ati (Anabi) Thul-Kifl; eni kookan (won) wa ninu awon onisuuru |
وَأَدْخَلْنَاهُمْ فِي رَحْمَتِنَا ۖ إِنَّهُم مِّنَ الصَّالِحِينَ(86) A si fi won sinu ike Wa. Dajudaju won wa ninu awon eni rere |
(E ranti) eleja, nigba ti o ba ibinu lo, o si lero pe A o nii gba oun mu. O si pe (Oluwa re) ninu awon okunkun (inu eja) pe: "Ko si olohun ti ijosin to si afi Iwo (Allahu). Mimo ni fun O. Dajudaju emi je okan ninu awon alabosi |
فَاسْتَجَبْنَا لَهُ وَنَجَّيْنَاهُ مِنَ الْغَمِّ ۚ وَكَذَٰلِكَ نُنجِي الْمُؤْمِنِينَ(88) A je ipe re. A si gba a la ninu ibanuje. Bayen ni A se n gba awon onigbagbo ododo la |
وَزَكَرِيَّا إِذْ نَادَىٰ رَبَّهُ رَبِّ لَا تَذَرْنِي فَرْدًا وَأَنتَ خَيْرُ الْوَارِثِينَ(89) (E ranti Anabi) Zakariyya nigba ti o pe Oluwa re pe: “Oluwa mi, ma fi mi sile ni emi nikan (ti ko nii bimo). Iwo si loore julo ninu awon olujogun.” |
A je ipe re. A si ta a lore omo, (Anabi) Yahya. A si se atunse iyawo re fun un. Dajudaju won n yara gaga nibi awon ise rere. Won n pe Wa pelu ireti ati ipaya. Won si je oluteriba fun Wa |
(E ranti obinrin) eyi ti o so abe re. A si fe ategun ninu awon ategun emi ti A da si i lara. A si se oun ati omokunrin re ni ami fun gbogbo eda |
إِنَّ هَٰذِهِ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَأَنَا رَبُّكُمْ فَاعْبُدُونِ(92) Dajudaju (’Islam) yii ni esin yin. (O je) esin kan soso. Emi si ni Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Mi |
وَتَقَطَّعُوا أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ ۖ كُلٌّ إِلَيْنَا رَاجِعُونَ(93) (Awon yehudi ati nasara), won si da oro (esin) won si kelekele laaarin ara won; eni kookan (won) si maa pada si odo Wa |
Nitori naa, enikeni ti o ba se ninu awon ise rere, ti o si je onigbagbo ododo, ko si kiko fun ise re. Ati pe dajudaju Awa maa se akosile re fun un |
وَحَرَامٌ عَلَىٰ قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا أَنَّهُمْ لَا يَرْجِعُونَ(95) Eewo ni fun ara ilu kan ti A ti pare (pe ki o tun pada si aye); dajudaju won ko nii pada mo (si ile aye) |
حَتَّىٰ إِذَا فُتِحَتْ يَأْجُوجُ وَمَأْجُوجُ وَهُم مِّن كُلِّ حَدَبٍ يَنسِلُونَ(96) (Won yoo wa ninu barsaku) titi A oo fi si awon Ya’juj ati Ma’juj sile. Awon (wonyi) yo si maa sare jade lati inu gbogbo aye giga |
Adehun ododo naa sunmo pekipeki. Nigba naa, awon t’o sai gbagbo yoo maa ranju kale rangandan, (won yo si wi pe): “Egbe ni fun wa! Dajudaju awa ti wa ninu igbagbera nipa eyi. Rara, awa je alabosi ni.” |
إِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ حَصَبُ جَهَنَّمَ أَنتُمْ لَهَا وَارِدُونَ(98) Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu ni ikona Jahanamo; eyin yo si wo inu re |
لَوْ كَانَ هَٰؤُلَاءِ آلِهَةً مَّا وَرَدُوهَا ۖ وَكُلٌّ فِيهَا خَالِدُونَ(99) Ti o ba je pe awon wonyi ni olohun ni, won iba ti wo inu Ina. Olusegbere si ni eni kookan won ninu re |
Ina yoo maa kun yun-un si won leti; won ko si nii gbo (oro miiran) |
إِنَّ الَّذِينَ سَبَقَتْ لَهُم مِّنَّا الْحُسْنَىٰ أُولَٰئِكَ عَنْهَا مُبْعَدُونَ(101) Dajudaju awon ti rere ti siwaju fun lati odo Wa, awon wonyen ni A oo gbe jinna si Ina |
لَا يَسْمَعُونَ حَسِيسَهَا ۖ وَهُمْ فِي مَا اشْتَهَتْ أَنفُسُهُمْ خَالِدُونَ(102) Won ko si nii gbo kikun re. Olusegbere si ni won ninu igbadun ti emi won n fe |
Ipaya t’o tobi julo ko nii ba won ninu je. Awon molaika yoo maa pade won, (won yoo so pe): “Eyi ni ojo yin ti A n se ni adehun fun yin.” |
(Ojo naa ni) ojo ti A maa ka sanmo bi kika ewe tira. Gege bi A ti se bere iseda eda ni ibere pepe (ibe naa ni) A oo da a pada si. (O je) adehun ti A se. Dajudaju Awa maa se bee |
Ati pe A ti ko o sinu awon ipin-ipin Tira (ti A sokale) leyin (eyi ti o wa ninu) Tira Ipile (iyen, Laohul-Mahfuth) pe dajudaju ile (Ogba Idera), awon erusin Mi, awon eni rere, ni won yoo jogun re |
Dajudaju ohun t’o to mu ni gunle sinu Ogba Idera ti wa ninu (al-Ƙur’an) yii fun ijo olujosin (fun Mi) |
A ko si fi ise imisi ran o bi ko se pe ki o le je ike fun gbogbo eda |
قُلْ إِنَّمَا يُوحَىٰ إِلَيَّ أَنَّمَا إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ فَهَلْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ(108) So pe: “Ohun ti Won n fi ranse si mi ni imisi ni pe, Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, se eyin maa di musulumi?” |
Ti won ba gbunri, so nigba naa pe: "Emi n fi to yin leti pe emi ati eyin di jo da duro fun ogun esin (ti o maa sele laaarin wa bayii). Emi ko si mo boya ohun ti Won n se ni adehun fun yin ti sunmo tabi o si jinna |
إِنَّهُ يَعْلَمُ الْجَهْرَ مِنَ الْقَوْلِ وَيَعْلَمُ مَا تَكْتُمُونَ(110) Dajudaju (Allahu) mo ohun ti o han ninu oro. O si mo ohun ti e n fi pamo |
وَإِنْ أَدْرِي لَعَلَّهُ فِتْنَةٌ لَّكُمْ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ(111) Emi ko si mo boya (lilo yin lara) maa je adanwo ati igbadun fun yin titi di igba die |
قَالَ رَبِّ احْكُم بِالْحَقِّ ۗ وَرَبُّنَا الرَّحْمَٰنُ الْمُسْتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ(112) O so pe: “Oluwa mi, sedajo pelu ododo. Oluwa wa ni Ajoke-aye, Oluranlowo lori ohun ti e n fi royin (Re).” |
More surahs in Yoruba:
Download surah Al-Anbiya with the voice of the most famous Quran reciters :
surah Al-Anbiya mp3 : choose the reciter to listen and download the chapter Al-Anbiya Complete with high quality
Ahmed Al Ajmy
Bandar Balila
Khalid Al Jalil
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdul Rashid Sufi
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Yasser Al Dosari
لا تنسنا من دعوة صالحة بظهر الغيب