La sourate As-Saaffat en Yoruba

  1. mp3 sourate
  2. Plus
  3. Yoruba
Le Saint Coran | Traduction du Coran | Langue Yoruba | Sourate As-Saaffat | - Nombre de versets 182 - Le numéro de la sourate dans le mushaf: 37 - La signification de la sourate en English: Those Who Set The Ranks.

وَالصَّافَّاتِ صَفًّا(1)

 (Allahu bura pelu) awon molaika oluto-lowoowo taara

فَالزَّاجِرَاتِ زَجْرًا(2)

 ati awon molaika t’o n wo esujo kiri taara

فَالتَّالِيَاتِ ذِكْرًا(3)

 ati awon molaika onke-tira iranti

إِنَّ إِلَٰهَكُمْ لَوَاحِدٌ(4)

 Dajudaju Olohun yin, Okan soso ni

رَّبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَرَبُّ الْمَشَارِقِ(5)

 Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Oun si ni Oluwa awon ibuyo oorun

إِنَّا زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِزِينَةٍ الْكَوَاكِبِ(6)

 Dajudaju Awa fi awon irawo se sanmo ile aye ni oso

وَحِفْظًا مِّن كُلِّ شَيْطَانٍ مَّارِدٍ(7)

 ati iso nibi (aburu) gbogbo esu olorikunkun

لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى الْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ وَيُقْذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٍ(8)

 (Awon esu) ko si nii le teti si ijo (molaika t’o wa ni) aye giga julo (ninu sanmo). (Awon molaika) yo si maa ku (awon esu) loko (eta irawo) ni gbogbo agbegbe (sanmo)

دُحُورًا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ وَاصِبٌ(9)

 Won n le won danu. Iya ailopin si wa fun won

إِلَّا مَنْ خَطِفَ الْخَطْفَةَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ ثَاقِبٌ(10)

 (Won ko nii gbo oro ni kikun) ayafi eni ti o ba ri oro ajigbo gbe, nigba naa (ni molaika) yo si fi eta irawo ina t’o maa jo o tele e

فَاسْتَفْتِهِمْ أَهُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَم مَّنْ خَلَقْنَا ۚ إِنَّا خَلَقْنَاهُم مِّن طِينٍ لَّازِبٍ(11)

 Bi won leere wo pe se awon ni iseda won lagbara julo ni tabi awon (eniyan) ti A da? Dajudaju Awa da won lati ara erupe t’o le mora won

بَلْ عَجِبْتَ وَيَسْخَرُونَ(12)

 Rara (ko jora won); iwo seemo (nipa al-Ƙur’an), awon si n se yeye

وَإِذَا ذُكِّرُوا لَا يَذْكُرُونَ(13)

 Ati pe nigba ti won ba se iranti fun won, won ko nii lo iranti

وَإِذَا رَأَوْا آيَةً يَسْتَسْخِرُونَ(14)

 Nigba ti won ba tun ri ami kan, won yoo maa se yeye

وَقَالُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّبِينٌ(15)

 Won si wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele

أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ(16)

 Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo tun gbe wa dide ni

أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ(17)

 Se ati awon baba wa, awon eni akoko

قُلْ نَعَمْ وَأَنتُمْ دَاخِرُونَ(18)

 So pe: "Bee ni. Eyin yo si di eni yepere

فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ فَإِذَا هُمْ يَنظُرُونَ(19)

 Nitori naa, igbe eyo kan ma ni. Nigba naa ni won yoo maa wo sun

وَقَالُوا يَا وَيْلَنَا هَٰذَا يَوْمُ الدِّينِ(20)

 Won a wi pe: "Egbe wa! Eyi ni Ojo esan

هَٰذَا يَوْمُ الْفَصْلِ الَّذِي كُنتُم بِهِ تُكَذِّبُونَ(21)

 Eyi ni ojo Idajo eyi ti e n pe niro

۞ احْشُرُوا الَّذِينَ ظَلَمُوا وَأَزْوَاجَهُمْ وَمَا كَانُوا يَعْبُدُونَ(22)

 E ko awon t’o sabosi jo, awon iyawo won ati ohun ti won n josin fun

مِن دُونِ اللَّهِ فَاهْدُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْجَحِيمِ(23)

 leyin Allahu. Ki e si juwe won si oju ona ina Jehim

وَقِفُوهُمْ ۖ إِنَّهُم مَّسْئُولُونَ(24)

 E da won duro na, dajudaju won maa bi won leere ibeere

مَا لَكُمْ لَا تَنَاصَرُونَ(25)

 Ki ni ko je ki e ranra yin lowo

بَلْ هُمُ الْيَوْمَ مُسْتَسْلِمُونَ(26)

 Rara, won ti juwo juse sile ni oni ni

وَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ(27)

 Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere

قَالُوا إِنَّكُمْ كُنتُمْ تَأْتُونَنَا عَنِ الْيَمِينِ(28)

 (Awon eniyan) wi pe: "Dajudaju eyin l’e n gba otun wole si wa lara (lati si wa lona)

قَالُوا بَل لَّمْ تَكُونُوا مُؤْمِنِينَ(29)

 (Awon alujannu) wi pe: "Rara o (awa ko), eyin ni e ko je onigbagbo ododo

وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيْكُم مِّن سُلْطَانٍ ۖ بَلْ كُنتُمْ قَوْمًا طَاغِينَ(30)

 Ati pe awa ko ni agbara kan lori yin, sugbon eyin je ijo olutayo-enu ala

فَحَقَّ عَلَيْنَا قَوْلُ رَبِّنَا ۖ إِنَّا لَذَائِقُونَ(31)

 Oro Oluwa wa si ko le wa lori pe dajudaju awa yoo to Ina wo

فَأَغْوَيْنَاكُمْ إِنَّا كُنَّا غَاوِينَ(32)

 Nitori naa, a si yin lona. Dajudaju awa naa si je olusina

فَإِنَّهُمْ يَوْمَئِذٍ فِي الْعَذَابِ مُشْتَرِكُونَ(33)

 Dajudaju ni ojo yen, akegbe ni won ninu Iya

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِالْمُجْرِمِينَ(34)

 Dajudaju bayen ni Awa yoo ti se pelu awon elese

إِنَّهُمْ كَانُوا إِذَا قِيلَ لَهُمْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللَّهُ يَسْتَكْبِرُونَ(35)

 Dajudaju nigba ti won ba so fun won pe "Ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu.", won yoo maa segberaga

وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُو آلِهَتِنَا لِشَاعِرٍ مَّجْنُونٍ(36)

 Won si n wi pe: "Se a maa fi awon orisa wa sile nitori elewi were kan

بَلْ جَاءَ بِالْحَقِّ وَصَدَّقَ الْمُرْسَلِينَ(37)

 Ko ri bee. O mu ododo wa ni. O si n jerii si ododo awon Ojise naa

إِنَّكُمْ لَذَائِقُو الْعَذَابِ الْأَلِيمِ(38)

 Dajudaju e maa to iya eleta-elero wo

وَمَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ(39)

 A o nii san yin ni esan kan afi ohun ti e n se nise

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ(40)

 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

أُولَٰئِكَ لَهُمْ رِزْقٌ مَّعْلُومٌ(41)

 Ti awon wonyen si ni arisiki ti won ti mo

فَوَاكِهُ ۖ وَهُم مُّكْرَمُونَ(42)

 awon eso. Awon si ni alapon-onle

فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ(43)

 ninu awon Ogba Idera

عَلَىٰ سُرُرٍ مُّتَقَابِلِينَ(44)

 Lori awon ite ni won yoo ti koju sira won

يُطَافُ عَلَيْهِم بِكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ(45)

 Won yoo maa gbe ife oti mimo kaa kiri odo won

بَيْضَاءَ لَذَّةٍ لِّلشَّارِبِينَ(46)

 Funfun ni (oti naa). O n dun lenu awon t’o maa mu un

لَا فِيهَا غَوْلٌ وَلَا هُمْ عَنْهَا يُنزَفُونَ(47)

 Ko si ipalara kan fun won ninu re, won ko si nii hunrira lori re

وَعِندَهُمْ قَاصِرَاتُ الطَّرْفِ عِينٌ(48)

 Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, awon eleyinju ege yo si wa lodo won

كَأَنَّهُنَّ بَيْضٌ مَّكْنُونٌ(49)

 Won da bi tinu eyin. o tun je ki a mo pe won ko reti ike kan kan lorun ni tiwon. Ti o ba je pe won n reti ike kan ni orun

فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ(50)

 Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere

قَالَ قَائِلٌ مِّنْهُمْ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٌ(51)

 Onsoro kan ninu won yoo so pe: "Dajudaju emi ni ore kan

يَقُولُ أَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُصَدِّقِينَ(52)

 ti o n wi pe, “Se dajudaju iwo wa ninu awon onigbagbo ninu Ojo Ajinde

أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَدِينُونَ(53)

 Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo san wa ni esan ni?”

قَالَ هَلْ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ(54)

 O so pe: "Se eyin yoo yoju wo (eni naa ti ko gbagbo ninu Ojo ajinde)

فَاطَّلَعَ فَرَآهُ فِي سَوَاءِ الْجَحِيمِ(55)

 O yoju wo o. O si ri i laaarin gbungbun ninu ina Jehim

قَالَ تَاللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرْدِينِ(56)

 O (si) so pe: "Mo fi Allahu bura, iwo fee ko iparun ba mi tan

وَلَوْلَا نِعْمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ الْمُحْضَرِينَ(57)

 Ati pe ti ki i ba se idera Oluwa mi ni, emi naa iba wa ninu eni ti won maa mu wa sinu Ina

أَفَمَا نَحْنُ بِمَيِّتِينَ(58)

 Awa ko sa nii ku mo bayii

إِلَّا مَوْتَتَنَا الْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ(59)

 Afi iku wa akoko. Won ko si nii je awa niya

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ(60)

 Dajudaju eyi, ohun ni erenje nla

لِمِثْلِ هَٰذَا فَلْيَعْمَلِ الْعَامِلُونَ(61)

 Nitori iru eyi, ki awon olusesin maa sesin lo

أَذَٰلِكَ خَيْرٌ نُّزُلًا أَمْ شَجَرَةُ الزَّقُّومِ(62)

 Nje iyen l’o loore julo ni ibudesi ni tabi igi zaƙum (igi elegun-un)

إِنَّا جَعَلْنَاهَا فِتْنَةً لِّلظَّالِمِينَ(63)

 Dajudaju Awa se e ni adanwo fun awon alabosi

إِنَّهَا شَجَرَةٌ تَخْرُجُ فِي أَصْلِ الْجَحِيمِ(64)

 Dajudaju ohun ni igi kan ti o maa hu jade lati idi ina Jehim

طَلْعُهَا كَأَنَّهُ رُءُوسُ الشَّيَاطِينِ(65)

 Eso re da bi ori awon esu

فَإِنَّهُمْ لَآكِلُونَ مِنْهَا فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ(66)

 Dajudaju won yoo maa je ninu re. Nitori naa, won yoo fi kun inu won bamubamu

ثُمَّ إِنَّ لَهُمْ عَلَيْهَا لَشَوْبًا مِّنْ حَمِيمٍ(67)

 Leyin naa, dajudaju won yoo mu nnkan mimu awoyunweje gbigbona le e lori

ثُمَّ إِنَّ مَرْجِعَهُمْ لَإِلَى الْجَحِيمِ(68)

 Leyin naa, dajudaju ibupadasi won ni ina Jehim

إِنَّهُمْ أَلْفَوْا آبَاءَهُمْ ضَالِّينَ(69)

 Dajudaju won ba awon baba won ni olusina

فَهُمْ عَلَىٰ آثَارِهِمْ يُهْرَعُونَ(70)

 Awon naa si n yara tele oripa won

وَلَقَدْ ضَلَّ قَبْلَهُمْ أَكْثَرُ الْأَوَّلِينَ(71)

 Dajudaju opolopo awon eni akoko ti sina siwaju won

وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ(72)

 Dajudaju A ti ran awon olukilo si won

فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُنذَرِينَ(73)

 Nitori naa, wo bi atubotan awon eni-akilo-fun ti ri

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ(74)

 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

وَلَقَدْ نَادَانَا نُوحٌ فَلَنِعْمَ الْمُجِيبُونَ(75)

 Dajudaju (Anabi) Nuh pe Wa. A si dara ni olujepe

وَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ(76)

 A gba oun ati awon ara ile re la kuro ninu ibanuje nla

وَجَعَلْنَا ذُرِّيَّتَهُ هُمُ الْبَاقِينَ(77)

 A da awon aromodomo re si leyin re

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ(78)

 A si fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

سَلَامٌ عَلَىٰ نُوحٍ فِي الْعَالَمِينَ(79)

 Alaafia ki o maa ba (Anabi) Nuh laaarin gbogbo eda

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(80)

 Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ(81)

 Dajudaju oun wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ(82)

 Leyin naa, A te awon yooku ri sinu agbami

۞ وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِ لَإِبْرَاهِيمَ(83)

 Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim wa ninu ijo (ti o tele ilana) re

إِذْ جَاءَ رَبَّهُ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ(84)

 (E ranti) nigba ti oun naa doju ko Oluwa re pelu okan mimo

إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَاذَا تَعْبُدُونَ(85)

 (Ranti) nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Ki ni e n josin fun

أَئِفْكًا آلِهَةً دُونَ اللَّهِ تُرِيدُونَ(86)

 Se e n gbero lati so iro di olohun leyin Allahu

فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ الْعَالَمِينَ(87)

 Ki si ni ero okan yin si Oluwa gbogbo eda?”

فَنَظَرَ نَظْرَةً فِي النُّجُومِ(88)

 O siju wo awon irawo gan-an

فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٌ(89)

 O si so pe: "Dajudaju o re mi

فَتَوَلَّوْا عَنْهُ مُدْبِرِينَ(90)

 Nitori naa, won pa a ti, won si lo

فَرَاغَ إِلَىٰ آلِهَتِهِمْ فَقَالَ أَلَا تَأْكُلُونَ(91)

 Nigba naa, o lo si odo awon orisa won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni

مَا لَكُمْ لَا تَنطِقُونَ(92)

 Ki ni o se yin ti e o soro

فَرَاغَ عَلَيْهِمْ ضَرْبًا بِالْيَمِينِ(93)

 Nigba naa, o doju lilu ko won pelu owo otun (o si run won womuwomu)

فَأَقْبَلُوا إِلَيْهِ يَزِفُّونَ(94)

 (Awon aborisa) sare wa doju ko o

قَالَ أَتَعْبُدُونَ مَا تَنْحِتُونَ(95)

 O so pe: "Se e oo maa josin fun nnkan ti e gbe kale lere ni

وَاللَّهُ خَلَقَكُمْ وَمَا تَعْمَلُونَ(96)

 Allahu l’O si da eyin ati nnkan ti e n se nise

قَالُوا ابْنُوا لَهُ بُنْيَانًا فَأَلْقُوهُ فِي الْجَحِيمِ(97)

 Won wi pe: "E mo ile kan fun un, ki e si ju u sinu ina

فَأَرَادُوا بِهِ كَيْدًا فَجَعَلْنَاهُمُ الْأَسْفَلِينَ(98)

 Won gbero ete si i. A si so won di eni yepere

وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهْدِينِ(99)

 O so pe: "Dajudaju mo maa lo si (ilu ti) Oluwa mi (pa mi lase lati lo). O si maa to mi sona (lati de ibe)

رَبِّ هَبْ لِي مِنَ الصَّالِحِينَ(100)

 Oluwa mi, ta mi lore omo ninu awon eni rere

فَبَشَّرْنَاهُ بِغُلَامٍ حَلِيمٍ(101)

 A si fun un ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin alafarada

فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ السَّعْيَ قَالَ يَا بُنَيَّ إِنِّي أَرَىٰ فِي الْمَنَامِ أَنِّي أَذْبَحُكَ فَانظُرْ مَاذَا تَرَىٰ ۚ قَالَ يَا أَبَتِ افْعَلْ مَا تُؤْمَرُ ۖ سَتَجِدُنِي إِن شَاءَ اللَّهُ مِنَ الصَّابِرِينَ(102)

 Nigba ti (omo naa) dagba, ti o to ba (baba re) se ise, (baba re) so pe: "Omo mi, dajudaju emi la ala pe dajudaju mo n dunbu re. Nitori naa, woye si i, ki ni o ri si i." O so pe: "Baba mi, se ohun ti Won pa lase fun o. O maa ba mi ninu awon onisuuru, ti Allahu ba fe

فَلَمَّا أَسْلَمَا وَتَلَّهُ لِلْجَبِينِ(103)

 Nigba ti awon mejeeji juwo juse sile, ti (Anabi ’Ibrohim) si doju (omo) re bole

وَنَادَيْنَاهُ أَن يَا إِبْرَاهِيمُ(104)

 A pe e (bayii) pe, ’Ibrohim

قَدْ صَدَّقْتَ الرُّؤْيَا ۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(105)

 o kuku ti mu ala naa se. Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْبَلَاءُ الْمُبِينُ(106)

 Dajudaju eyi, ohun ni adanwo ponnbele

وَفَدَيْنَاهُ بِذِبْحٍ عَظِيمٍ(107)

 A si fi agbo nla serapada re

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ(108)

 A tun fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

سَلَامٌ عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ(109)

 Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ibrohim

كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(110)

 Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ(111)

 Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

وَبَشَّرْنَاهُ بِإِسْحَاقَ نَبِيًّا مِّنَ الصَّالِحِينَ(112)

 A tun fun un ni iro idunnu (nipa bibi) ’Ishaƙ, (o maa je) Anabi. (O si maa wa) ninu awon eni rere

وَبَارَكْنَا عَلَيْهِ وَعَلَىٰ إِسْحَاقَ ۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحْسِنٌ وَظَالِمٌ لِّنَفْسِهِ مُبِينٌ(113)

 Ati pe A fun oun ati ’Ishaƙ ni ibukun. Eni rere ati alabosi ponnbele (t’o n sabosi si) emi ara re wa ninu aromodomo awon mejeeji

وَلَقَدْ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ(114)

 Dajudaju A soore fun (Anabi) Musa ati Harun

وَنَجَّيْنَاهُمَا وَقَوْمَهُمَا مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ(115)

 A gba awon mejeeji ati ijo awon mejeeji la kuro ninu ibanuje nla

وَنَصَرْنَاهُمْ فَكَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ(116)

 A tun saranse fun won. Awon ni won je olubori (ota won)

وَآتَيْنَاهُمَا الْكِتَابَ الْمُسْتَبِينَ(117)

 A si fun awon mejeeji ni Tira t’o yanju

وَهَدَيْنَاهُمَا الصِّرَاطَ الْمُسْتَقِيمَ(118)

 A tun fi awon mejeeji mona taara

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِمَا فِي الْآخِرِينَ(119)

 A fun awon mejeeji ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

سَلَامٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ(120)

 Alaafia ki o maa ba (Anabi) Musa ati Harun

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(121)

 Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

إِنَّهُمَا مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ(122)

 Dajudaju awon mejeeji wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

وَإِنَّ إِلْيَاسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ(123)

 Dajudaju (Anabi) ’Ilyas wa ninu awon Ojise

إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ أَلَا تَتَّقُونَ(124)

 (E ranti) nigba ti o so fun ijo re pe: "Se e o nii beru Allahu ni

أَتَدْعُونَ بَعْلًا وَتَذَرُونَ أَحْسَنَ الْخَالِقِينَ(125)

 Se e oo maa pe orisa kan, e si maa fi Eni t’O dara julo ninu awon eledaa sile, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Oun l’O si dara julo ninu awon oludajo. (surah al-’A‘rof 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Oun si yara julo ninu awon onisiro. (surah al-’Ani‘am 6:62) oludajo alaaanu ibaa mo bii omo ina igun afi ki Allahu je Eledaa re. Koda adamo owo ati okowo ti won so di “oro-Aje. Awon t’o n bo elomiiran naa n sora won di olupese. Yato si pe Allahu ti fi rinle pe Oun nikan ni Olupese fun gbogbo eda Re. Ti eyi ko ba ti i da awon kan loju bee ti won si fe gbe gbogbo ipese olukuluku lori iwon ninu aanu ti Allahu fi si awon eda kan lokan ni won fi di alaaanu. Nitori naa Allahu ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu

اللَّهَ رَبَّكُمْ وَرَبَّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ(126)

 (e n fi) Allahu (sile), Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko

فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ(127)

 Won si pe e ni opuro. Nitori naa, won maa mu won wa sinu Ina

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ(128)

 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ(129)

 A fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

سَلَامٌ عَلَىٰ إِلْ يَاسِينَ(130)

 Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ilyas

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ(131)

 Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ(132)

 Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

وَإِنَّ لُوطًا لَّمِنَ الْمُرْسَلِينَ(133)

 Dajudaju (Anabi) Lut wa ninu awon Ojise

إِذْ نَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ(134)

 (E ranti) nigba ti A gba oun ati gbogbo awon ara ile re la

إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ(135)

 Ayafi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare)

ثُمَّ دَمَّرْنَا الْآخَرِينَ(136)

 Leyin naa, A pa awon yooku run

وَإِنَّكُمْ لَتَمُرُّونَ عَلَيْهِم مُّصْبِحِينَ(137)

 Dajudaju eyin naa kuku n gba odo won koja laaaro-laaaro

وَبِاللَّيْلِ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(138)

 ati ni alaale. Se e o nii se laakaye ni

وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ(139)

 Dajudaju (Anabi) Yunus kuku wa ninu awon Ojise

إِذْ أَبَقَ إِلَى الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ(140)

 (E ranti) nigba ti o sa lo sinu oko oju-omi t’o kun keke

فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ الْمُدْحَضِينَ(141)

 O si ba won muje po. O si wa ninu awon ti aje si mo lori

فَالْتَقَمَهُ الْحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٌ(142)

 Nitori naa, eja gbe e mi; o si n da ara re lebi

فَلَوْلَا أَنَّهُ كَانَ مِنَ الْمُسَبِّحِينَ(143)

 Nitori naa, ti ko ba je pe o wa ninu awon olusafomo fun Allahu

لَلَبِثَ فِي بَطْنِهِ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ(144)

 dajudaju iba wa ninu eja titi di ojo ti won yoo gbe eda dide

۞ فَنَبَذْنَاهُ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ سَقِيمٌ(145)

 Nitori naa, A ju u si ori ile gbansasa leti omi. O si je alailera

وَأَنبَتْنَا عَلَيْهِ شَجَرَةً مِّن يَقْطِينٍ(146)

 A si mu igi Yeƙtin hu jade lati siji bo o

وَأَرْسَلْنَاهُ إِلَىٰ مِائَةِ أَلْفٍ أَوْ يَزِيدُونَ(147)

 A tun ran an nise si oke marun-un (eniyan) tabi ki won lekun si i

فَآمَنُوا فَمَتَّعْنَاهُمْ إِلَىٰ حِينٍ(148)

 Won gbagbo ni ododo. A si fun won ni igbadun titi di igba die

فَاسْتَفْتِهِمْ أَلِرَبِّكَ الْبَنَاتُ وَلَهُمُ الْبَنُونَ(149)

 Bi won leere wo pe: "Se Oluwa re l’o ni awon omobinrin, tiwon si ni omokunrin

أَمْ خَلَقْنَا الْمَلَائِكَةَ إِنَاثًا وَهُمْ شَاهِدُونَ(150)

 Tabi A da awon molaika ni obinrin, ti awon si je elerii

أَلَا إِنَّهُم مِّنْ إِفْكِهِمْ لَيَقُولُونَ(151)

 Gbo, ninu iro won ni pe dajudaju won n wi pe

وَلَدَ اللَّهُ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ(152)

 Allahu bimo." Dajudaju opuro ni won

أَصْطَفَى الْبَنَاتِ عَلَى الْبَنِينَ(153)

 Se (Allahu) sesa awon omobinrin lori awon omokunrin ni

مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ(154)

 Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii

أَفَلَا تَذَكَّرُونَ(155)

 Se e o nii lo iranti ni

أَمْ لَكُمْ سُلْطَانٌ مُّبِينٌ(156)

 Tabi e ni eri t’o yanju lowo ni

فَأْتُوا بِكِتَابِكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(157)

 E mu tira yin wa nigba naa ti e ba je olododo

وَجَعَلُوا بَيْنَهُ وَبَيْنَ الْجِنَّةِ نَسَبًا ۚ وَلَقَدْ عَلِمَتِ الْجِنَّةُ إِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ(158)

 Won tun fi ibatan saaarin (Allahu) ati alujannu! Awon alujannu si ti mo pe dajudaju won kuku maa mu awon wa sinu Ina ni

سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ(159)

 Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re)

إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ(160)

 Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

فَإِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ(161)

 Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun (leyin Allahu)

مَا أَنتُمْ عَلَيْهِ بِفَاتِنِينَ(162)

 e o le fi si eni kan kan lona

إِلَّا مَنْ هُوَ صَالِ الْجَحِيمِ(163)

 afi eni ti o ba fe wo inu ina Jehim

وَمَا مِنَّا إِلَّا لَهُ مَقَامٌ مَّعْلُومٌ(164)

 Ko si eni kan ninu awa (molaika) afi ki o ni ibuduro ti won ti mo

وَإِنَّا لَنَحْنُ الصَّافُّونَ(165)

 Dajudaju awa, a kuku wa ni owoowo

وَإِنَّا لَنَحْنُ الْمُسَبِّحُونَ(166)

 Ati pe dajudaju awa, awa kuku ni olusafomo (fun Allahu)

وَإِن كَانُوا لَيَقُولُونَ(167)

 Won kuku n wi pe

لَوْ أَنَّ عِندَنَا ذِكْرًا مِّنَ الْأَوَّلِينَ(168)

 Ti o ba je pe dajudaju a ba ni (tira) iranti kan ninu (awon tira) awon eni akoko

لَكُنَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ(169)

 dajudaju awa iba je erusin Allahu, awon eni esa

فَكَفَرُوا بِهِ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ(170)

 Sugbon won sai gbagbo ninu (Allahu). Laipe won maa mo

وَلَقَدْ سَبَقَتْ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا الْمُرْسَلِينَ(171)

 Dajudaju oro Wa ti siwaju fun awon erusin Wa, awon Ojise

إِنَّهُمْ لَهُمُ الْمَنصُورُونَ(172)

 Dajudaju awon, awon l’a kuku maa saranse fun

وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ الْغَالِبُونَ(173)

 Ati pe dajudaju awon omo ogun Wa, awon kuku ni olubori

فَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ(174)

 Nitori naa, seri kuro lodo won fun igba die

وَأَبْصِرْهُمْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ(175)

 Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo

أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ(176)

 Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju

فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمْ فَسَاءَ صَبَاحُ الْمُنذَرِينَ(177)

 Nigba ti o ba sokale si agboole won, owuro ojo naa yo si buru fun awon eni-akilo-fun

وَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ(178)

 Kuro lodo won titi di igba kan na

وَأَبْصِرْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ(179)

 Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo

سُبْحَانَ رَبِّكَ رَبِّ الْعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ(180)

 Mimo ni fun Oluwa re, Oluwa agbara, tayo ohun ti won n fi royin (Re)

وَسَلَامٌ عَلَى الْمُرْسَلِينَ(181)

 Ki alaafia maa ba awon Ojise

وَالْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ(182)

 Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda


Plus de sourates en Yoruba :


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :

Téléchargez le fichier mp3 de la sourate As-Saaffat : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate As-Saaffat complète en haute qualité.


surah As-Saaffat Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah As-Saaffat Bandar Balila
Bandar Balila
surah As-Saaffat Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah As-Saaffat Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah As-Saaffat Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah As-Saaffat Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah As-Saaffat Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah As-Saaffat Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah As-Saaffat Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah As-Saaffat Fares Abbad
Fares Abbad
surah As-Saaffat Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah As-Saaffat Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah As-Saaffat Al Hosary
Al Hosary
surah As-Saaffat Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah As-Saaffat Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Monday, November 4, 2024

Donnez-nous une invitation valide