Surah Al-Inshiqaq ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Inshiqaq pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (25 Ẹsẹ — مكية). Al-Inshiqaq Gbọ, Al-Inshiqaq Itumọ, Al-Inshiqaq mp3, Al-Inshiqaq pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Inshiqaq

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
إِذَا السَّمَاءُ انشَقَّتْ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Nigba ti sanmo ba faya perepere
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
o gbo, o si tele ase Oluwa re ni. O si di dandan fun un lati se bee –
وَإِذَا الْأَرْضُ مُدَّتْ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
ati nigba ti A ba fe ile loju
وَأَلْقَتْ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتْ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
o maa ju ohun ti o wa ninu re sita, o si maa pa sofo
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
– o gbo, o si tele ase Oluwa re ni. O si di dandan fun un lati se bee – (ni ojo yen ni eda maa ri ise owo re)
يَا أَيُّهَا الْإِنسَانُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدْحًا فَمُلَاقِيهِ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Iwo eniyan dajudaju iwo n se ise karakara ni ise asepade Oluwa re. O si maa mu un pade Re
فَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Nitori naa, ni ti eni ti won ba fun ni iwe ise re ni owo otun re
فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
laipe A maa se isiro-ise (re) ni isiro irorun
وَيَنقَلِبُ إِلَىٰ أَهْلِهِ مَسْرُورًا ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
O si maa pada si odo awon eniyan re (ninu Ogba Idera) leni idunnu
وَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ وَرَاءَ ظَهْرِهِ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Ni ti eni ti won ba si fun ni iwe ise re lati eyin re
فَسَوْفَ يَدْعُو ثُبُورًا ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
laipe o maa kigbe iparun
وَيَصْلَىٰ سَعِيرًا ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
O si maa wo inu Ina t’o n jo fofo
إِنَّهُ كَانَ فِي أَهْلِهِ مَسْرُورًا ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Dajudaju o ti wa laaarin awon eniyan re leni idunnu (si aigbagbo nile aye)
إِنَّهُ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Dajudaju o lero pe oun ko nii pada (si odo Allahu ni)
بَلَىٰ إِنَّ رَبَّهُ كَانَ بِهِ بَصِيرًا ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Rara (o maa pada). Dajudaju Oluwa re je Oluriran nipa re
فَلَا أُقْسِمُ بِالشَّفَقِ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Nitori naa, Emi (Allahu) n bura pelu awonpapa
وَاللَّيْلِ وَمَا وَسَقَ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Mo tun bura pelu oru ati ohun ti o ko jo sinu re
وَالْقَمَرِ إِذَا اتَّسَقَ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Mo tun bura pelu osupa nigba ti o ba degba (pelu imole re)
لَتَرْكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٍ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Dajudaju eyin yoo maa bo sinu wahala kan lati inu wahala kan
فَمَا لَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
Ki l’o se won na ti won ko fi gbagbo ni ododo
وَإِذَا قُرِئَ عَلَيْهِمُ الْقُرْآنُ لَا يَسْجُدُونَ ۩ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Nigba ti won ba si ke al-Ƙur’an fun won, won ko nii fori kanle
بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا يُكَذِّبُونَ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Rara, nse ni awon t’o sai gbagbo n pe e niro
وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُوعُونَ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo (sinu okan won)
فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
Nitori naa, fun won ni iro iya eleta-elero
إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Ayafi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, esan ti ko nii pin n be fun won
← 83 Al-Inshiqaq (84/114) 85 →
Kika Surah Al-Inshiqaq ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

84الإنشقاق Al-Inshiqaq 📚 25 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Inshiqaq — 25 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers