Surah Al-Ma'arij ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Ma'arij pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (44 Ẹsẹ — مكية). Al-Ma'arij Gbọ, Al-Ma'arij Itumọ, Al-Ma'arij mp3, Al-Ma'arij pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Ma'arij

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
سَأَلَ سَائِلٌ بِعَذَابٍ وَاقِعٍ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Onibeeere kan beere nipa iya t’o maa sele
لِّلْكَافِرِينَ لَيْسَ لَهُ دَافِعٌ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
si awon alaigbagbo. Ko si si eni ti o maa di i lowo
مِّنَ اللَّهِ ذِي الْمَعَارِجِ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
lodo Allahu, Onipo-aye giga
تَعْرُجُ الْمَلَائِكَةُ وَالرُّوحُ إِلَيْهِ فِي يَوْمٍ كَانَ مِقْدَارُهُ خَمْسِينَ أَلْفَ سَنَةٍ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Awon molaika ati molaika Jibril n gunke wa si odo Re ninu ojo kan ti odiwon re je oke meji aabo (ti e ba fe rin in)
فَاصْبِرْ صَبْرًا جَمِيلًا ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Nitori naa, se suuru ni suuru t’o rewa
إِنَّهُمْ يَرَوْنَهُ بَعِيدًا ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Dajudaju won n wo (iya naa) ni ohun t’o jinna
وَنَرَاهُ قَرِيبًا ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
A si n wo o ni ohun t’o sunmo
يَوْمَ تَكُونُ السَّمَاءُ كَالْمُهْلِ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
(Ojo naa ni) ojo ti sanmo yo da bi ide t’o yo
وَتَكُونُ الْجِبَالُ كَالْعِهْنِ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
awon apata yo si da bi egbon owu-irun
وَلَا يَسْأَلُ حَمِيمٌ حَمِيمًا ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
ore imule kan ko si nii beere ore imule (re)
يُبَصَّرُونَهُمْ ۚ يَوَدُّ الْمُجْرِمُ لَوْ يَفْتَدِي مِنْ عَذَابِ يَوْمِئِذٍ بِبَنِيهِ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Won maa ri ara won (won si maa dara won mo). Elese si maa fe ki oun fi awon omo re serapada emi ara re nibi Iya ni ojo yen
وَصَاحِبَتِهِ وَأَخِيهِ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
Iyawo re ati arakunrin re
وَفَصِيلَتِهِ الَّتِي تُؤْوِيهِ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
ati awon ebi re t’o pa ti, ti awon si n gba a sodo nile aye
وَمَن فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ يُنجِيهِ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
ati gbogbo eni t’o wa lori ile aye patapata, (o maa fe fi won serapada emi ara re nibi Iya). Leyin naa, (o maa fe) ki Allahu gba oun la (ninu iya Ina)
كَلَّا ۖ إِنَّهَا لَظَىٰ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Rara! Dajudaju (o maa wo) ina Latho (ina t’o n jo fofo)
نَزَّاعَةً لِّلشَّوَىٰ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
O maa bo awo ori toro
تَدْعُو مَنْ أَدْبَرَ وَتَوَلَّىٰ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
(Ina) yo maa ke si eni t’o keyin si (igbagbo ododo), ti o si takete si i
وَجَمَعَ فَأَوْعَىٰ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
o ko (oro) jo, o si fi pamo (ko na an fun esin)
۞ إِنَّ الْإِنسَانَ خُلِقَ هَلُوعًا ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Dajudaju eniyan, A seda re ni alailokan, okanjua
إِذَا مَسَّهُ الشَّرُّ جَزُوعًا ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
Nigba ti aburu ba fowo ba a, o maa kanra gogo
وَإِذَا مَسَّهُ الْخَيْرُ مَنُوعًا ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Nigba ti owo re ba si te oore, o maa yahun
إِلَّا الْمُصَلِّينَ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Ayafi awon olukirun
الَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ دَائِمُونَ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
awon oludunnimo irun won
وَالَّذِينَ فِي أَمْوَالِهِمْ حَقٌّ مَّعْلُومٌ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
awon t’o mo ojuse (won) ninu dukia won
لِّلسَّائِلِ وَالْمَحْرُومِ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
si alagbe ati eni ti A se arisiki ni eewo fun
وَالَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوْمِ الدِّينِ ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
awon t’o n gba ojo esan gbo ni ododo
وَالَّذِينَ هُم مِّنْ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشْفِقُونَ ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
awon t’o n paya iya Oluwa won
إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمْ غَيْرُ مَأْمُونٍ ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
dajudaju iya Oluwa won ko see fayabale si
وَالَّذِينَ هُمْ لِفُرُوجِهِمْ حَافِظُونَ ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
awon t’o n so abe won
إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِينَ ۝٣٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 30
ayafi lodo awon iyawo won tabi erubinrin won ni won ko ti le je eni-eebu
فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ ۝٣١
📖 Itumọ Ẹsẹ 31
nitori naa, eni keni t’o ba n wa nnkan miiran leyin iyen, awon wonyen ni awon olutayo-enu ala
وَالَّذِينَ هُمْ لِأَمَانَاتِهِمْ وَعَهْدِهِمْ رَاعُونَ ۝٣٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 32
awon t’o n so agbafipamo won ati adehun won
وَالَّذِينَ هُم بِشَهَادَاتِهِمْ قَائِمُونَ ۝٣٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 33
awon t’o n duro ti ijerii won
وَالَّذِينَ هُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ ۝٣٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 34
ati awon t’o n so awon irun won
أُولَٰئِكَ فِي جَنَّاتٍ مُّكْرَمُونَ ۝٣٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 35
Awon wonyen ni alapon-onle ninu awon Ogba Idera
فَمَالِ الَّذِينَ كَفَرُوا قِبَلَكَ مُهْطِعِينَ ۝٣٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 36
Ki lo mu awon ti ko gbagbo ti ara won ko bale niwaju re
عَنِ الْيَمِينِ وَعَنِ الشِّمَالِ عِزِينَ ۝٣٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 37
ti won si jokoo ni isori isori si owo otun ati owo osi (re)
أَيَطْمَعُ كُلُّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُدْخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٍ ۝٣٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 38
Se eni kookan ninu won n jerankan pe A oo mu oun wo inu Ogba Idera ni
كَلَّا ۖ إِنَّا خَلَقْنَاهُم مِّمَّا يَعْلَمُونَ ۝٣٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 39
Rara o! Dajudaju Awa seda won lati inu ohun ti won mo
فَلَا أُقْسِمُ بِرَبِّ الْمَشَارِقِ وَالْمَغَارِبِ إِنَّا لَقَادِرُونَ ۝٤٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 40
Nitori naa, Emi n bura pelu Oluwa awon ibuyo oorun ati awon ibuwo oorun , dajudaju Awa ni Alagbara
عَلَىٰ أَن نُّبَدِّلَ خَيْرًا مِّنْهُمْ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ ۝٤١
📖 Itumọ Ẹsẹ 41
lati le fi awon t’o dara ju won lo paaro won. Ko si si eni t’o le ko agara ba Wa
فَذَرْهُمْ يَخُوضُوا وَيَلْعَبُوا حَتَّىٰ يُلَاقُوا يَوْمَهُمُ الَّذِي يُوعَدُونَ ۝٤٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 42
Nitori naa, fi won sile ki won maa so isokuso (won), ki won si maa sere titi won yoo fi pade ojo won ti A n se ni adehun fun won
يَوْمَ يَخْرُجُونَ مِنَ الْأَجْدَاثِ سِرَاعًا كَأَنَّهُمْ إِلَىٰ نُصُبٍ يُوفِضُونَ ۝٤٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 43
Ojo ti won yoo sare jade werewere lati inu awon saree, won yo si da bi eni pe won n yara lo sidii ohun afojusun kan
خَاشِعَةً أَبْصَارُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۚ ذَٰلِكَ الْيَوْمُ الَّذِي كَانُوا يُوعَدُونَ ۝٤٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 44
Oju won yoo wale. Iyepere maa bo won mole. Ojo yen ni eyi ti A n se ni adehun fun won
← 69 Al-Ma'arij (70/114) 71 →
Kika Surah Al-Ma'arij ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

70المعارج Al-Ma'arij 📚 44 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Ma'arij — 44 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers