Surah At-Tariq ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah At-Tariq pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (17 Ẹsẹ — مكية). At-Tariq Gbọ, At-Tariq Itumọ, At-Tariq mp3, At-Tariq pdf.

Ka ati Gbọ Surah At-Tariq

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
وَالسَّمَاءِ وَالطَّارِقِ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
(Allahu) bura pelu sanmo ati Toriƙ
وَمَا أَدْرَاكَ مَا الطَّارِقُ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Toriƙ
النَّجْمُ الثَّاقِبُ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Irawo ti imole re n tan roro (ni ale ni)
إِن كُلُّ نَفْسٍ لَّمَّا عَلَيْهَا حَافِظٌ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Ko si emi kan afi ki eso kan wa fun un (ninu awon molaika)
فَلْيَنظُرِ الْإِنسَانُ مِمَّ خُلِقَ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Nitori naa, ki eniyan woye si ohun ti A fi seda re
خُلِقَ مِن مَّاءٍ دَافِقٍ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Won seda re lati inu omi t’o n tu jade kookoo
يَخْرُجُ مِن بَيْنِ الصُّلْبِ وَالتَّرَائِبِ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
O n jade lati aarin ibadi okunrin ati awon efonha igba-aya obinrin
إِنَّهُ عَلَىٰ رَجْعِهِ لَقَادِرٌ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Dajudaju Allahu ni Alagbara lori idapada re
يَوْمَ تُبْلَى السَّرَائِرُ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
ni ojo ti won maa se ayewo awon (ise) asepamo
فَمَا لَهُ مِن قُوَّةٍ وَلَا نَاصِرٍ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Nigba naa, ko nii si agbara tabi alaranse kan fun un
وَالسَّمَاءِ ذَاتِ الرَّجْعِ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Allahu bura pelu sanmo t’o n ro ojo ni odoodun
وَالْأَرْضِ ذَاتِ الصَّدْعِ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
O tun bura pelu ile t’o n san kankan (fun hihujade eso)
إِنَّهُ لَقَوْلٌ فَصْلٌ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
Dajudaju al-Ƙur’an ni oro-ipinya (laaarin ododo ati iro)
وَمَا هُوَ بِالْهَزْلِ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
Ki i si se awada
إِنَّهُمْ يَكِيدُونَ كَيْدًا ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Dajudaju won n dete gan-an
وَأَكِيدُ كَيْدًا ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Emi naa si n dete gan-an
فَمَهِّلِ الْكَافِرِينَ أَمْهِلْهُمْ رُوَيْدًا ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Nitori naa, lora fun awon alaigbagbo. Lo won lara se fun igba die
← 85 At-Tariq (86/114) 87 →
Kika Surah At-Tariq ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

86الطارق At-Tariq 📚 17 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah At-Tariq — 17 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers