La sourate Al-Baqarah en Yoruba

  1. mp3 sourate
  2. Plus
  3. Yoruba
Le Saint Coran | Traduction du Coran | Langue Yoruba | Sourate Al-Baqara | - Nombre de versets 286 - Le numéro de la sourate dans le mushaf: 2 - La signification de la sourate en English: The Cow.

الم(1)

 ’Alif lam mim

ذَٰلِكَ الْكِتَابُ لَا رَيْبَ ۛ فِيهِ ۛ هُدًى لِّلْمُتَّقِينَ(2)

 Eyi ni Tira naa, ti ko si iyemeji ninu re. Imona ni fun awon oluberu (Allahu)

الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِالْغَيْبِ وَيُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنفِقُونَ(3)

 awon t’o gbagbo ninu (iro) ikoko, ti won n kirun, ti won si n na ninu ohun ti A pese fun won

وَالَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِمَا أُنزِلَ إِلَيْكَ وَمَا أُنزِلَ مِن قَبْلِكَ وَبِالْآخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ(4)

 ati awon t’o gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, ti won si ni amodaju nipa Ojo Ikeyin

أُولَٰئِكَ عَلَىٰ هُدًى مِّن رَّبِّهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ(5)

 Awon wonyen wa lori imona lati odo Oluwa won. Awon wonyen, awon ni olujere

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا سَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَأَنذَرْتَهُمْ أَمْ لَمْ تُنذِرْهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ(6)

 Dajudaju awon t’o sai gbagbo, bakan naa ni fun won, yala o kilo fun won tabi o o kilo fun won, won ko nii gbagbo

خَتَمَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَعَلَىٰ سَمْعِهِمْ ۖ وَعَلَىٰ أَبْصَارِهِمْ غِشَاوَةٌ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ(7)

 Allahu fi edidi di okan won ati igboro won. Ebibo si bo iriran won. Iya nla si wa fun won

وَمِنَ النَّاسِ مَن يَقُولُ آمَنَّا بِاللَّهِ وَبِالْيَوْمِ الْآخِرِ وَمَا هُم بِمُؤْمِنِينَ(8)

 O si n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin.” Won ki i si se onigbagbo ododo

يُخَادِعُونَ اللَّهَ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَمَا يَخْدَعُونَ إِلَّا أَنفُسَهُمْ وَمَا يَشْعُرُونَ(9)

 Won n tan Allahu ati awon t’o gbagbo ni ododo je. Won ko si le tan eni kan je bi ko se emi ara won; won ko si fura

فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ فَزَادَهُمُ اللَّهُ مَرَضًا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْذِبُونَ(10)

 Arun kan wa ninu okan won, nitori naa Allahu se alekun arun fun won. Iya eleta-elero si wa fun won nitori pe won n paro

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ لَا تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ قَالُوا إِنَّمَا نَحْنُ مُصْلِحُونَ(11)

 Nigba ti won ba so fun won pe: “E ma sebaje lori ile.” Won a wi pe: “Awa ni alatun-unse.”

أَلَا إِنَّهُمْ هُمُ الْمُفْسِدُونَ وَلَٰكِن لَّا يَشْعُرُونَ(12)

 E kiye si i! Dajudaju awon gan-an ni obileje, sugbon won ko fura

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ آمِنُوا كَمَا آمَنَ النَّاسُ قَالُوا أَنُؤْمِنُ كَمَا آمَنَ السُّفَهَاءُ ۗ أَلَا إِنَّهُمْ هُمُ السُّفَهَاءُ وَلَٰكِن لَّا يَعْلَمُونَ(13)

 Nigba ti won ba so fun won pe: “E gbagbo ni ododo gege bi awon eniyan se gbagbo.” Won a wi pe: “Se ki a gbagbo gege bi awon omugo se gbagbo ni?” E kiye si i! Dajudaju awon gan-an ni omugo, sugbon won ko mo

وَإِذَا لَقُوا الَّذِينَ آمَنُوا قَالُوا آمَنَّا وَإِذَا خَلَوْا إِلَىٰ شَيَاطِينِهِمْ قَالُوا إِنَّا مَعَكُمْ إِنَّمَا نَحْنُ مُسْتَهْزِئُونَ(14)

 Nigba ti won ba pade awon t’o gbagbo ni ododo, won a wi pe: “A gbagbo.” Nigba ti o ba si ku won ku awon (eni) esu won, won a wi pe: “Dajudaju awa n be pelu yin, awa kan n se yeye ni.”

اللَّهُ يَسْتَهْزِئُ بِهِمْ وَيَمُدُّهُمْ فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ(15)

 Allahu maa fi won se yeye. O si maa mu won lekun si i ninu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida. ti awon ise naa je ise t’o duro sori fifi oruko ise eda so oruko esan ise naa. Iru re l’o sele ninu ayah ti a n tose re lowo yii. Allahu (subhanahu wa ta’ala) ki i se oluseyeye (eni ti o maa n se yeye) tabi oniyeye (eni ti eda le fi se yeye). Eni kan ko si nii maa se yeye afi ki o je alawada oniranu. Allahu (subhanahu wa ta’ala) ki i se awada Allahu ki i se eletan. Eni kan ko nii je eletan afi ki o je opuro oluyapa-adehun. Allahu ki i se opuro. Allahu gan-an ni Ododo. Bakan naa

أُولَٰئِكَ الَّذِينَ اشْتَرَوُا الضَّلَالَةَ بِالْهُدَىٰ فَمَا رَبِحَت تِّجَارَتُهُمْ وَمَا كَانُوا مُهْتَدِينَ(16)

 Awon wonyen ni awon t’o fi imona ra isina. Nitori naa, okowo won ko lere, won ko si je olumona

مَثَلُهُمْ كَمَثَلِ الَّذِي اسْتَوْقَدَ نَارًا فَلَمَّا أَضَاءَتْ مَا حَوْلَهُ ذَهَبَ اللَّهُ بِنُورِهِمْ وَتَرَكَهُمْ فِي ظُلُمَاتٍ لَّا يُبْصِرُونَ(17)

 Apejuwe won da bi apejuwe eni ti o tan ina, sugbon nigba ti imole tan si ayika re tan, Allahu mu imole won lo, O si fi won sile sinu awon okunkun; won ko si riran mo

صُمٌّ بُكْمٌ عُمْيٌ فَهُمْ لَا يَرْجِعُونَ(18)

 Aditi, ayaya, afoju ni won; nitori naa won ko nii seri pada

أَوْ كَصَيِّبٍ مِّنَ السَّمَاءِ فِيهِ ظُلُمَاتٌ وَرَعْدٌ وَبَرْقٌ يَجْعَلُونَ أَصَابِعَهُمْ فِي آذَانِهِم مِّنَ الصَّوَاعِقِ حَذَرَ الْمَوْتِ ۚ وَاللَّهُ مُحِيطٌ بِالْكَافِرِينَ(19)

 Tabi (apejuwe won) da bi ojo nla ti n ro lati sanmo. O mu awon okunkun, ara sisan ati monamona lowo. Won n fi ika won sinu eti won nitori igbe ara sisan fun iberu iku. Allahu si yi awon alaigbagbo ka

يَكَادُ الْبَرْقُ يَخْطَفُ أَبْصَارَهُمْ ۖ كُلَّمَا أَضَاءَ لَهُم مَّشَوْا فِيهِ وَإِذَا أَظْلَمَ عَلَيْهِمْ قَامُوا ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَذَهَبَ بِسَمْعِهِمْ وَأَبْصَارِهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(20)

 Monamona naa fee mu iriran won lo. Nigbakigba ti o ba tan imole si won, won a rin lo ninu re. Nigba ti o ba si soookun mo won, won a duro si. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, dajudaju iba gba igboro won ati iriran won. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

يَا أَيُّهَا النَّاسُ اعْبُدُوا رَبَّكُمُ الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ(21)

 Eyin eniyan, e josin fun Oluwa yin, Eni ti O da eyin ati awon t’o siwaju yin, nitori ki e le sora (fun iya Ina)

الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ فِرَاشًا وَالسَّمَاءَ بِنَاءً وَأَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجَ بِهِ مِنَ الثَّمَرَاتِ رِزْقًا لَّكُمْ ۖ فَلَا تَجْعَلُوا لِلَّهِ أَندَادًا وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ(22)

 (E josin fun) Eni ti O se ile fun yin ni ite, (O se) sanmo ni aja, O so omi ojo kale lati sanmo, O si fi mu awon eso jade ni ije-imu fun yin. Nitori naa, e ma se ba Allahu wa akegbe, e si mo (pe ko ni akegbe)

وَإِن كُنتُمْ فِي رَيْبٍ مِّمَّا نَزَّلْنَا عَلَىٰ عَبْدِنَا فَأْتُوا بِسُورَةٍ مِّن مِّثْلِهِ وَادْعُوا شُهَدَاءَكُم مِّن دُونِ اللَّهِ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(23)

 Ti e ba wa ninu iyemeji nipa ohun ti A sokale fun erusin Wa, nitori naa, e mu surah kan wa bi iru re, ki e si pe awon elerii yin, yato si Allahu, ti e ba je olododo

فَإِن لَّمْ تَفْعَلُوا وَلَن تَفْعَلُوا فَاتَّقُوا النَّارَ الَّتِي وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ ۖ أُعِدَّتْ لِلْكَافِرِينَ(24)

 Ti e o ba si se bee, e o wule le se bee, nitori naa e sora fun Ina, eyi ti ikona re je awon eniyan ati okuta ti Won pa lese sile de awon alaigbagbo

وَبَشِّرِ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أَنَّ لَهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ كُلَّمَا رُزِقُوا مِنْهَا مِن ثَمَرَةٍ رِّزْقًا ۙ قَالُوا هَٰذَا الَّذِي رُزِقْنَا مِن قَبْلُ ۖ وَأُتُوا بِهِ مُتَشَابِهًا ۖ وَلَهُمْ فِيهَا أَزْوَاجٌ مُّطَهَّرَةٌ ۖ وَهُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(25)

 Fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere ni iro idunnu pe, dajudaju awon Ogba Idera kan n be fun won, eyi ti awon odo n san ni isale re. Nigbakigba ti A ba p’ese jije-mimu kan fun won ninu eso re, won yoo so pe: “Eyi ni won ti pese fun wa teletele.” – Won mu un wa fun won ni irisi kan naa ni (amo pelu adun otooto). – Awon iyawo mimo si n be fun won ninu Ogba Idera. Olusegbere si ni won ninu re

۞ إِنَّ اللَّهَ لَا يَسْتَحْيِي أَن يَضْرِبَ مَثَلًا مَّا بَعُوضَةً فَمَا فَوْقَهَا ۚ فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا فَيَعْلَمُونَ أَنَّهُ الْحَقُّ مِن رَّبِّهِمْ ۖ وَأَمَّا الَّذِينَ كَفَرُوا فَيَقُولُونَ مَاذَا أَرَادَ اللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًا ۘ يُضِلُّ بِهِ كَثِيرًا وَيَهْدِي بِهِ كَثِيرًا ۚ وَمَا يُضِلُّ بِهِ إِلَّا الْفَاسِقِينَ(26)

 Dajudaju Allahu ko nii tiju lati fi ohun kan bi efon tabi ohun ti o ju u lo sakawe oro. Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, won yoo mo pe dajudaju ododo ni lati odo Oluwa won. Ni ti awon t’o sai gbagbo, won yoo wi pe: “Ki ni ohun ti Allahu gba lero pelu akawe yii?” Allahu n fi si lona. O si n fi to opolopo sona. Ko si nii fi si enikeni lona ayafi awon arufin

الَّذِينَ يَنقُضُونَ عَهْدَ اللَّهِ مِن بَعْدِ مِيثَاقِهِ وَيَقْطَعُونَ مَا أَمَرَ اللَّهُ بِهِ أَن يُوصَلَ وَيُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ(27)

 Awon t’o n ye majemu Allahu leyin ti majemu naa ti fidi mule, won tun n ja ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo, won si n se ibaje lori ile, awon wonyen gan-an ni eni ofo

كَيْفَ تَكْفُرُونَ بِاللَّهِ وَكُنتُمْ أَمْوَاتًا فَأَحْيَاكُمْ ۖ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ(28)

 Bawo ni e se n sai gbagbo ninu Allahu na! Bee si ni oku ni yin (tele), O si so yin di alaaye. Leyin naa, O maa so yin di oku. Leyin naa, O maa so yin di alaaye. Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si

هُوَ الَّذِي خَلَقَ لَكُم مَّا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ اسْتَوَىٰ إِلَى السَّمَاءِ فَسَوَّاهُنَّ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ ۚ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(29)

 Oun ni Eni ti O da ohunkohun t’o wa lori ile fun yin patapata. Leyin naa, O wa l’oke sanmo, O si se won togun rege si sanmo meje. Oun si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي جَاعِلٌ فِي الْأَرْضِ خَلِيفَةً ۖ قَالُوا أَتَجْعَلُ فِيهَا مَن يُفْسِدُ فِيهَا وَيَسْفِكُ الدِّمَاءَ وَنَحْنُ نُسَبِّحُ بِحَمْدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَ ۖ قَالَ إِنِّي أَعْلَمُ مَا لَا تَعْلَمُونَ(30)

 iseda ile siwaju iseda sanmo gege bi ayah inu surah Baƙorah yen se fi rinle. Amo ki i se oro nipa iseda ile ni ayah surah an-Nazi‘at n soro nipa re. Allahu (subhanahu wa ta’ala) ko si lo oro t’o tumo si iseda ile ninu ayah t’O ti daruko ile iyen ayah 30 ninu surah iseda gbogbo ohun t’o maa wa ninu ile ni awon igi awon ibudo 30 (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: “Dajudaju Emi yoo fi arole kan sori ile.” Won so pe: “Se Iwo yoo fi eni ti o maa sebaje sibe, ti o si maa teje sile? Awa si n se afomo pelu idupe fun O. A si n fi ogo fun O!" O so pe: “Dajudaju Emi mo ohun ti eyin ko mo.”

وَعَلَّمَ آدَمَ الْأَسْمَاءَ كُلَّهَا ثُمَّ عَرَضَهُمْ عَلَى الْمَلَائِكَةِ فَقَالَ أَنبِئُونِي بِأَسْمَاءِ هَٰؤُلَاءِ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(31)

 Allahu fi awon oruko naa, gbogbo won patapata, mo Adam. Leyin naa, O ko won siwaju awon molaika, O si so pe: “E so awon oruko wonyi fun Mi, ti e ba je olododo.”

قَالُوا سُبْحَانَكَ لَا عِلْمَ لَنَا إِلَّا مَا عَلَّمْتَنَا ۖ إِنَّكَ أَنتَ الْعَلِيمُ الْحَكِيمُ(32)

 Won so pe: “Mimo ni fun O, ko si imo kan fun wa ayafi ohun ti O fi mo wa. Dajudaju Iwo, Iwo ni Onimo, Ologbon.”

قَالَ يَا آدَمُ أَنبِئْهُم بِأَسْمَائِهِمْ ۖ فَلَمَّا أَنبَأَهُم بِأَسْمَائِهِمْ قَالَ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ إِنِّي أَعْلَمُ غَيْبَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَأَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا كُنتُمْ تَكْتُمُونَ(33)

 O so pe: “Adam, so oruko won fun won.” Nigba ti o so oruko won fun won tan, O so pe: “Se Emi ko so fun yin pe dajudaju Emi nimo ikoko awon sanmo ati ile, Mo si nimo ohun ti e n se afihan re ati ohun ti e n fi pamo?”

وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ وَاسْتَكْبَرَ وَكَانَ مِنَ الْكَافِرِينَ(34)

 (Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Adam.” Won si fori kanle ki i ayafi ’Iblis. O ko, o si se igberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo

وَقُلْنَا يَا آدَمُ اسْكُنْ أَنتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ وَكُلَا مِنْهَا رَغَدًا حَيْثُ شِئْتُمَا وَلَا تَقْرَبَا هَٰذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الظَّالِمِينَ(35)

 A si so pe: “Adam, iwo ati iyawo re, e maa gbe ninu Ogba Idera. Ki e maa je ninu re ni gbedemuke ni ibikibi ti e ba fe. Ki e si ma se sunmo igi yii, ki e ma baa wa ninu awon alabosi.”

فَأَزَلَّهُمَا الشَّيْطَانُ عَنْهَا فَأَخْرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِ ۖ وَقُلْنَا اهْبِطُوا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ ۖ وَلَكُمْ فِي الْأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ(36)

 Amo Esu ye awon mejeeji lese kuro ninu Ogba Idera, o si mu won jade kuro ninu ibi ti won wa. A si so pe: "E sokale, ota ni apa kan yin je fun apa kan. Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin lori ile fun igba (die).”

فَتَلَقَّىٰ آدَمُ مِن رَّبِّهِ كَلِمَاتٍ فَتَابَ عَلَيْهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ(37)

 Leyin naa, (Anabi) Adam ri awon oro kan gba lati odo Oluwa re. O si gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

قُلْنَا اهْبِطُوا مِنْهَا جَمِيعًا ۖ فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدًى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(38)

 A so pe : “Gbogbo yin, e sokale kuro ninu re. Nigba ti imona ba de ba yin lati odo Mi, eni ti o ba tele imona Mi, ipaya ko nii si fun won. Won ko si nii banuje

وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(39)

 Awon t’o ba si sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re.”

يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اذْكُرُوا نِعْمَتِيَ الَّتِي أَنْعَمْتُ عَلَيْكُمْ وَأَوْفُوا بِعَهْدِي أُوفِ بِعَهْدِكُمْ وَإِيَّايَ فَارْهَبُونِ(40)

 Eyin omo ’Isro’il, e ranti idera Mi, eyi ti Mo se fun yin. E mu majemu Mi se, Mo maa mu (esan) majemu yin se. Emi nikan ni ki e si paya

وَآمِنُوا بِمَا أَنزَلْتُ مُصَدِّقًا لِّمَا مَعَكُمْ وَلَا تَكُونُوا أَوَّلَ كَافِرٍ بِهِ ۖ وَلَا تَشْتَرُوا بِآيَاتِي ثَمَنًا قَلِيلًا وَإِيَّايَ فَاتَّقُونِ(41)

 E gbagbo ninu ohun ti Mo sokale, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin. E ma se je eni akoko ti o maa sai gbagbo ninu re. E ma se ta awon ayah Mi l’owo pooku.Emi nikan soso ni ki e si beru

وَلَا تَلْبِسُوا الْحَقَّ بِالْبَاطِلِ وَتَكْتُمُوا الْحَقَّ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ(42)

 E ma da iro po mo ododo, e si ma fi ododo pamo nigba ti eyin mo (ododo)

وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَارْكَعُوا مَعَ الرَّاكِعِينَ(43)

 E kirun, e yo zakah, ki e si dawo te orunkun pelu awon oludawote-orunkun (lori irun)

۞ أَتَأْمُرُونَ النَّاسَ بِالْبِرِّ وَتَنسَوْنَ أَنفُسَكُمْ وَأَنتُمْ تَتْلُونَ الْكِتَابَ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(44)

 Se eyin yoo maa pa awon eniyan l’ase ohun rere, e si n gbagbe emi ara yin, eyin si n ke Tira, se e o se laakaye ni

وَاسْتَعِينُوا بِالصَّبْرِ وَالصَّلَاةِ ۚ وَإِنَّهَا لَكَبِيرَةٌ إِلَّا عَلَى الْخَاشِعِينَ(45)

 E wa oore (Allahu) pelu suuru ati irun kiki. Dajudaju o lagbara (lati se bee) ayafi fun awon olupaya (Allahu)

الَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُم مُّلَاقُو رَبِّهِمْ وَأَنَّهُمْ إِلَيْهِ رَاجِعُونَ(46)

 awon t’o mo pe dajudaju awon yoo pade Oluwa won, ati pe dajudaju awon yoo pada si odo Re

يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اذْكُرُوا نِعْمَتِيَ الَّتِي أَنْعَمْتُ عَلَيْكُمْ وَأَنِّي فَضَّلْتُكُمْ عَلَى الْعَالَمِينَ(47)

 Eyin omo ’Isro’il, e ranti idera Mi, eyi ti Mo fi sedera fun yin. Dajudaju Emi tun soore ajulo fun yin lori awon eda (asiko yin)

وَاتَّقُوا يَوْمًا لَّا تَجْزِي نَفْسٌ عَن نَّفْسٍ شَيْئًا وَلَا يُقْبَلُ مِنْهَا شَفَاعَةٌ وَلَا يُؤْخَذُ مِنْهَا عَدْلٌ وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ(48)

 E beru ojo kan ti emi kan ko nii sanfaani kini kan fun emi kan. A o nii gba isipe kan lowo re.1 A o si nii gba aaro l’owo re. A o si nii ran won lowo.2 awon ayah miiran so pe isipe wa.” Won ni “Itakora niyen.” 123 ati 254 ati surah al-’Ani‘am; 6:51. Amo awon ayah t’o n so pe isipe maa wa lojo Ajinde n so nipa awon majemu ti o wa fun isipe olusipe ati olusipe-fun. Irufe awon ayah naa ni surah al-Baƙorah

وَإِذْ نَجَّيْنَاكُم مِّنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ يُذَبِّحُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَاءٌ مِّن رَّبِّكُمْ عَظِيمٌ(49)

 (E ranti) nigba ti A gba yin la lowo awon eniyan Fir‘aon, ti won n fi iya buruku je yin, ti won n dunbu awon omokunrin yin, ti won si n je ki awon obinrin yin semi. Adanwo nla wa ninu iyen fun yin lati odo Oluwa yin

وَإِذْ فَرَقْنَا بِكُمُ الْبَحْرَ فَأَنجَيْنَاكُمْ وَأَغْرَقْنَا آلَ فِرْعَوْنَ وَأَنتُمْ تَنظُرُونَ(50)

 (E ranti) nigba ti A pin agbami odo si otooto fun yin, A si gba yin la. A te awon eniyan Fir‘aon ri. Eyin naa si n wo (won ninu agbami odo)

وَإِذْ وَاعَدْنَا مُوسَىٰ أَرْبَعِينَ لَيْلَةً ثُمَّ اتَّخَذْتُمُ الْعِجْلَ مِن بَعْدِهِ وَأَنتُمْ ظَالِمُونَ(51)

 (E ranti) nigba ti A se adehun ogoji oru fun (Anabi) Musa. Leyin naa, e tun bo oborogidi omo maalu leyin re. Alabosi si ni yin

ثُمَّ عَفَوْنَا عَنكُم مِّن بَعْدِ ذَٰلِكَ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ(52)

 Leyin naa, A moju kuro fun yin leyin iyen nitori ki e le dupe (fun Allahu)

وَإِذْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَالْفُرْقَانَ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ(53)

 (E ranti) nigba ti A fun (Anabi) Musa ni Tira ati oro-ipinya nitori ki e le mona

وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ إِنَّكُمْ ظَلَمْتُمْ أَنفُسَكُم بِاتِّخَاذِكُمُ الْعِجْلَ فَتُوبُوا إِلَىٰ بَارِئِكُمْ فَاقْتُلُوا أَنفُسَكُمْ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ عِندَ بَارِئِكُمْ فَتَابَ عَلَيْكُمْ ۚ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ(54)

 (E ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: “Eyin ijo mi, dajudaju eyin sabosi si emi ara yin nipa siso oborogidi omo maalu di orisa. Nitori naa, e ronu piwada si odo Eledaa yin, ki awon ti ko bo maalu pa awon t’o bo o laaarin yin. Iyen l’oore julo fun yin ni odo Eledaa yin. O si maa gba ironupiwada yin. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

وَإِذْ قُلْتُمْ يَا مُوسَىٰ لَن نُّؤْمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى اللَّهَ جَهْرَةً فَأَخَذَتْكُمُ الصَّاعِقَةُ وَأَنتُمْ تَنظُرُونَ(55)

 (E ranti) nigba ti e wi pe: “Musa, a o nii gba o gbo afi ki a ri Allahu ni ojukoroju.” Nitori naa, ohun igbe lati inu sanmo gba yin mu, e si n wo boo

ثُمَّ بَعَثْنَاكُم مِّن بَعْدِ مَوْتِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ(56)

 Leyin naa, A ji yin dide leyin iku yin, nitori ki e le dupe (fun Allahu)

وَظَلَّلْنَا عَلَيْكُمُ الْغَمَامَ وَأَنزَلْنَا عَلَيْكُمُ الْمَنَّ وَالسَّلْوَىٰ ۖ كُلُوا مِن طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ ۖ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ(57)

 A tun fi esujo se iboji fun yin. A si tun so (ohun mimu) monnu ati (ohun jije) salwa kale fun yin. E je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin. Won ko si sabosi si Wa, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

وَإِذْ قُلْنَا ادْخُلُوا هَٰذِهِ الْقَرْيَةَ فَكُلُوا مِنْهَا حَيْثُ شِئْتُمْ رَغَدًا وَادْخُلُوا الْبَابَ سُجَّدًا وَقُولُوا حِطَّةٌ نَّغْفِرْ لَكُمْ خَطَايَاكُمْ ۚ وَسَنَزِيدُ الْمُحْسِنِينَ(58)

 (E ranti) nigba ti A so pe: “E wo inu ilu yii. E je ninu ilu naa nibikibi ti e ba fe ni gbedemuke. E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba. Ki e si wi pe: “Ha ese wa danu.” A oo fori awon ese yin jin yin. A o si se alekun (esan rere) fun awon oluse-rere

فَبَدَّلَ الَّذِينَ ظَلَمُوا قَوْلًا غَيْرَ الَّذِي قِيلَ لَهُمْ فَأَنزَلْنَا عَلَى الَّذِينَ ظَلَمُوا رِجْزًا مِّنَ السَّمَاءِ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ(59)

 Awon t’o sabosi yi oro naa pada (si nnkan miiran) yato si eyi ti A so fun won. Nitori naa, A so iya kale lati sanmo le awon t’o sabosi lori nitori pe won n ru ofin

۞ وَإِذِ اسْتَسْقَىٰ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ فَقُلْنَا اضْرِب بِّعَصَاكَ الْحَجَرَ ۖ فَانفَجَرَتْ مِنْهُ اثْنَتَا عَشْرَةَ عَيْنًا ۖ قَدْ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٍ مَّشْرَبَهُمْ ۖ كُلُوا وَاشْرَبُوا مِن رِّزْقِ اللَّهِ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ(60)

 (E ranti) nigba ti (Anabi) Musa toro omi fun ijo re. A si so pe: “Fi opa re na okuta.” Orisun omi mejila si san jade lati inu re. Iran kookan si ti mo ibumu won. E je, ki e si mu ninu arisiki Allahu. E ma bale je ni ti obileje

وَإِذْ قُلْتُمْ يَا مُوسَىٰ لَن نَّصْبِرَ عَلَىٰ طَعَامٍ وَاحِدٍ فَادْعُ لَنَا رَبَّكَ يُخْرِجْ لَنَا مِمَّا تُنبِتُ الْأَرْضُ مِن بَقْلِهَا وَقِثَّائِهَا وَفُومِهَا وَعَدَسِهَا وَبَصَلِهَا ۖ قَالَ أَتَسْتَبْدِلُونَ الَّذِي هُوَ أَدْنَىٰ بِالَّذِي هُوَ خَيْرٌ ۚ اهْبِطُوا مِصْرًا فَإِنَّ لَكُم مَّا سَأَلْتُمْ ۗ وَضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ الذِّلَّةُ وَالْمَسْكَنَةُ وَبَاءُوا بِغَضَبٍ مِّنَ اللَّهِ ۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانُوا يَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَيَقْتُلُونَ النَّبِيِّينَ بِغَيْرِ الْحَقِّ ۗ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوا وَّكَانُوا يَعْتَدُونَ(61)

 (E ranti) nigba ti e wi pe: “Musa, a o nii se ifarada lori ounje eyo kan. Nitori naa, pe Oluwa re fun wa. Ki O mu jade fun wa ninu ohun ti ile n hu jade bi ewebe re, kukumba re, oka baba re, ewa re ati alubosa re.” (Anabi Musa) so pe: “Se eyin yoo fi eyi to yepere paaro eyi ti o dara julo ni? E sokale sinu ilu (miiran). Dajudaju ohun ti e n beere fun n be (nibe) fun yin.” A si mu iyepere ati osi ba won. Won si pada wale pelu ibinu lati odo Allahu. Iyen nitori pe dajudaju won n sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, won si n pa awon Anabi lai letoo. Iyen nitori pe won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu-ala

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ هَادُوا وَالنَّصَارَىٰ وَالصَّابِئِينَ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَعَمِلَ صَالِحًا فَلَهُمْ أَجْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(62)

 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon yehudi, nasara ati awon sobi’u; enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si se ise rere, esan won n be fun won ni odo Oluwa won. Ko si iberu fun won. Won ko si nii banuje

وَإِذْ أَخَذْنَا مِيثَاقَكُمْ وَرَفَعْنَا فَوْقَكُمُ الطُّورَ خُذُوا مَا آتَيْنَاكُم بِقُوَّةٍ وَاذْكُرُوا مَا فِيهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ(63)

 E ranti nigba ti A gba adehun yin, A si gbe apata wa soke ori yin, (A si so pe): “E gba ohun ti A fun yin mu daradara, ki e si ranti ohun t’o wa ninu re, nitori ki e le beru (Allahu)

ثُمَّ تَوَلَّيْتُم مِّن بَعْدِ ذَٰلِكَ ۖ فَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ لَكُنتُم مِّنَ الْخَاسِرِينَ(64)

 Leyin naa, e peyinda leyin iyen. Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati aanu Re lori yin, eyin iba wa ninu eni ofo

وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ الَّذِينَ اعْتَدَوْا مِنكُمْ فِي السَّبْتِ فَقُلْنَا لَهُمْ كُونُوا قِرَدَةً خَاسِئِينَ(65)

 Dajudaju e mo awon t’o koja enu-ala ninu yin nipa ojo Sabt. A si so fun won pe: "E di obo, eni-igbejinna si ike

فَجَعَلْنَاهَا نَكَالًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهَا وَمَا خَلْفَهَا وَمَوْعِظَةً لِّلْمُتَّقِينَ(66)

 A si se e ni arikogbon fun eni t’o soju re ati eni t’o n bo leyin re. (O tun je) eko fun awon oluberu (Allahu)

وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَن تَذْبَحُوا بَقَرَةً ۖ قَالُوا أَتَتَّخِذُنَا هُزُوًا ۖ قَالَ أَعُوذُ بِاللَّهِ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْجَاهِلِينَ(67)

 (E ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: “Dajudaju Allahu n pa yin ni ase pe ki e pa abo maalu kan.” Won wi pe: “Se o n fi wa se yeye ni!” O so pe: "Mo n sadi Allahu nibi ki ng je ara awon ope

قَالُوا ادْعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَ ۚ قَالَ إِنَّهُ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٌ لَّا فَارِضٌ وَلَا بِكْرٌ عَوَانٌ بَيْنَ ذَٰلِكَ ۖ فَافْعَلُوا مَا تُؤْمَرُونَ(68)

 Won wi pe: “Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ewo ni.” O so pe: "Dajudaju O n so pe abo maalu ni. Ko nii je ogbologboo, ko si nii je godogbo. O maa wa laaarin (mejeeji) yen. Nitori naa, e se ohun ti Won n pa yin lase

قَالُوا ادْعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا لَوْنُهَا ۚ قَالَ إِنَّهُ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٌ صَفْرَاءُ فَاقِعٌ لَّوْنُهَا تَسُرُّ النَّاظِرِينَ(69)

 Won wi pe: “Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ki ni awo re.” O so pe: “Dajudaju O n so pe abo maalu, alawo omi-osan ni. Awo re yo si mo fonifoni, ti o maa dun-un wo l’oju awon oluworan

قَالُوا ادْعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَ إِنَّ الْبَقَرَ تَشَابَهَ عَلَيْنَا وَإِنَّا إِن شَاءَ اللَّهُ لَمُهْتَدُونَ(70)

 Won wi pe: "Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ewo ni. Dajudaju awon abo maalu jora won loju wa. Ati pe dajudaju, ti Allahu ba fe, awa maa mona (ti a o gba ri i)

قَالَ إِنَّهُ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٌ لَّا ذَلُولٌ تُثِيرُ الْأَرْضَ وَلَا تَسْقِي الْحَرْثَ مُسَلَّمَةٌ لَّا شِيَةَ فِيهَا ۚ قَالُوا الْآنَ جِئْتَ بِالْحَقِّ ۚ فَذَبَحُوهَا وَمَا كَادُوا يَفْعَلُونَ(71)

 O so pe: “Dajudaju O n so pe abo maalu ni. Ko nii je maalu yepere ti n roko. Ko si nii maa fomi won oko. O maa ni alaafia, ko si nii ni abawon kan lara.” Won wi pe: “Nisinsin yii l’o mu ododo wa.” Won si pa maalu naa. Won fee ma se e mo

وَإِذْ قَتَلْتُمْ نَفْسًا فَادَّارَأْتُمْ فِيهَا ۖ وَاللَّهُ مُخْرِجٌ مَّا كُنتُمْ تَكْتُمُونَ(72)

 (E ranti) nigba ti e pa eni kan, e si n ti i sira yin. Allahu yo si safi han ohun ti e n fi pamo

فَقُلْنَا اضْرِبُوهُ بِبَعْضِهَا ۚ كَذَٰلِكَ يُحْيِي اللَّهُ الْمَوْتَىٰ وَيُرِيكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ(73)

 Nitori naa, A so pe: “E fi bure kan (lara maalu) lu (oku naa).” Bayen ni Allahu se n so oku di alaaye. O si n fi awon ami Re han yin, nitori ki e le se laakaye

ثُمَّ قَسَتْ قُلُوبُكُم مِّن بَعْدِ ذَٰلِكَ فَهِيَ كَالْحِجَارَةِ أَوْ أَشَدُّ قَسْوَةً ۚ وَإِنَّ مِنَ الْحِجَارَةِ لَمَا يَتَفَجَّرُ مِنْهُ الْأَنْهَارُ ۚ وَإِنَّ مِنْهَا لَمَا يَشَّقَّقُ فَيَخْرُجُ مِنْهُ الْمَاءُ ۚ وَإِنَّ مِنْهَا لَمَا يَهْبِطُ مِنْ خَشْيَةِ اللَّهِ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ(74)

 Leyin naa, okan yin le leyin iyen. O si da bi okuta tabi lile t’o lagbara ju bee lo. Dajudaju o n be ninu awon okuta ti awon odo n san jade lati inu re. Dajudaju o tun n be ninu won ti o maa san kankan. Omi si maa jade lati inu re. Dajudaju o tun n be ninu won ti o n wo lule gbi fun ipaya Allahu. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

۞ أَفَتَطْمَعُونَ أَن يُؤْمِنُوا لَكُمْ وَقَدْ كَانَ فَرِيقٌ مِّنْهُمْ يَسْمَعُونَ كَلَامَ اللَّهِ ثُمَّ يُحَرِّفُونَهُ مِن بَعْدِ مَا عَقَلُوهُ وَهُمْ يَعْلَمُونَ(75)

 Nje e lero pe won yoo gba yin gbo, nigba ti o je pe igun kan ninu won kuku n gbo oro Allahu. Leyin naa, won a yi i pada sodi leyin ti won ti gbo o ye; won si mo

وَإِذَا لَقُوا الَّذِينَ آمَنُوا قَالُوا آمَنَّا وَإِذَا خَلَا بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ قَالُوا أَتُحَدِّثُونَهُم بِمَا فَتَحَ اللَّهُ عَلَيْكُمْ لِيُحَاجُّوكُم بِهِ عِندَ رَبِّكُمْ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(76)

 Nigba ti won ba si pade awon t’o gbagbo ni ododo, won a wi pe: “A gbagbo.” Nigba ti o ba si ku apa kan won ku apa kan, won a wi pe: “Se ki i se pe e n ba won soro nipa ohun ti Allahu ti sipaya re fun yin, ki won le fi ja yin niyan ni odo Oluwa yin? Se e o se laakaye ni!”

أَوَلَا يَعْلَمُونَ أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ(77)

 Se won ko mo pe dajudaju Allahu mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n safi han re

وَمِنْهُمْ أُمِّيُّونَ لَا يَعْلَمُونَ الْكِتَابَ إِلَّا أَمَانِيَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَظُنُّونَ(78)

 Ati pe o wa ninu won, awon alaimoonkomoonka, ti won ko nimo nipa Tira afi awon oro-iro. Ki ni won (n so) bi ko se pe won n saroso

فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ يَكْتُبُونَ الْكِتَابَ بِأَيْدِيهِمْ ثُمَّ يَقُولُونَ هَٰذَا مِنْ عِندِ اللَّهِ لِيَشْتَرُوا بِهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۖ فَوَيْلٌ لَّهُم مِّمَّا كَتَبَتْ أَيْدِيهِمْ وَوَيْلٌ لَّهُم مِّمَّا يَكْسِبُونَ(79)

 Nitori naa, egbe ni fun awon t’o n fi owo ara won ko Tira, leyin naa ti won n wi pe: “Eyi wa lati odo Allahu.” Nitori ki won le ta a ni owo pooku. Egbe ni fun won se nipa ohun ti owo won ko. Egbe si ni fun won pelu nipa ohun ti won n se nise

وَقَالُوا لَن تَمَسَّنَا النَّارُ إِلَّا أَيَّامًا مَّعْدُودَةً ۚ قُلْ أَتَّخَذْتُمْ عِندَ اللَّهِ عَهْدًا فَلَن يُخْلِفَ اللَّهُ عَهْدَهُ ۖ أَمْ تَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ(80)

 Won si wi pe: “Ina ko le fowo ba wa tayo ojo t’o lonka.” So pe: “Se e ti ri adehun kan gba lodo Allahu ni?”Allahu ko si nii yapa adehun Re. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni

بَلَىٰ مَن كَسَبَ سَيِّئَةً وَأَحَاطَتْ بِهِ خَطِيئَتُهُ فَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(81)

 Rara (Ina ko ri bi won se ro o si); enikeni ti o ba se ise ibi kan, ti awon ese re tun yi i ka, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(82)

 Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re

وَإِذْ أَخَذْنَا مِيثَاقَ بَنِي إِسْرَائِيلَ لَا تَعْبُدُونَ إِلَّا اللَّهَ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا وَذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَقُولُوا لِلنَّاسِ حُسْنًا وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ ثُمَّ تَوَلَّيْتُمْ إِلَّا قَلِيلًا مِّنكُمْ وَأَنتُم مُّعْرِضُونَ(83)

 (E ranti) nigba ti A gba adehun lowo awon omo ‘Isro’il pe, eyin ko gbodo josin fun olohun kan ayafi Allahu. Ki e si se daadaa si awon obi mejeeji, ibatan, awon omo orukan ati awon mekunnu. E ba awon eniyan soro rere. E kirun, ki e si yo Zakah. Leyin naa le peyin da afi die ninu yin. Eyin si n gbunri (kuro nibi adehun)

وَإِذْ أَخَذْنَا مِيثَاقَكُمْ لَا تَسْفِكُونَ دِمَاءَكُمْ وَلَا تُخْرِجُونَ أَنفُسَكُم مِّن دِيَارِكُمْ ثُمَّ أَقْرَرْتُمْ وَأَنتُمْ تَشْهَدُونَ(84)

 (E ranti) nigba ti A gba adehun lowo yin pe eyin ko gbodo ta eje yin sile, eyin ko si gbodo lera yin jade kuro ninu ile yin. Leyin naa, e fi rinle, e si n jerii si i

ثُمَّ أَنتُمْ هَٰؤُلَاءِ تَقْتُلُونَ أَنفُسَكُمْ وَتُخْرِجُونَ فَرِيقًا مِّنكُم مِّن دِيَارِهِمْ تَظَاهَرُونَ عَلَيْهِم بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَإِن يَأْتُوكُمْ أُسَارَىٰ تُفَادُوهُمْ وَهُوَ مُحَرَّمٌ عَلَيْكُمْ إِخْرَاجُهُمْ ۚ أَفَتُؤْمِنُونَ بِبَعْضِ الْكِتَابِ وَتَكْفُرُونَ بِبَعْضٍ ۚ فَمَا جَزَاءُ مَن يَفْعَلُ ذَٰلِكَ مِنكُمْ إِلَّا خِزْيٌ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ يُرَدُّونَ إِلَىٰ أَشَدِّ الْعَذَابِ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ(85)

 Leyin naa, eyin wonyi l’e n p’ara yin. E tun n le apa kan ninu yin jade kuro ninu ile won. E n fi ese ati abosi seranwo (fun awon ota) lori won. Ti won ba si wa ba yin (ti won ti di) eru, eyin n ra won (lati fi’ra yin seru). Eewo si feekan ni fun yin lati le won jade. Se eyin yoo gba apa kan Tira gbo, e si n sai gbagbo ninu apa kan? Nitori naa, ki ni esan fun eni to se yen ninu yin bi ko se abuku ninu isemi aye. Ni ojo Ajinde, won si maa da won pada sinu iya to le julo. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

أُولَٰئِكَ الَّذِينَ اشْتَرَوُا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا بِالْآخِرَةِ ۖ فَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمُ الْعَذَابُ وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ(86)

 Awon wonyen ni awon ti won fi orun ra isemi aye. Nitori naa, A o nii gbe iya fuye fun won, A o si nii ran won lowo

وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَقَفَّيْنَا مِن بَعْدِهِ بِالرُّسُلِ ۖ وَآتَيْنَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ الْبَيِّنَاتِ وَأَيَّدْنَاهُ بِرُوحِ الْقُدُسِ ۗ أَفَكُلَّمَا جَاءَكُمْ رَسُولٌ بِمَا لَا تَهْوَىٰ أَنفُسُكُمُ اسْتَكْبَرْتُمْ فَفَرِيقًا كَذَّبْتُمْ وَفَرِيقًا تَقْتُلُونَ(87)

 Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira. A si mu awon Ojise wa ni telentele leyin re. A tun fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fun ni agbara nipase Emi Mimo (iyen, Molaika Jibril). Se gbogbo igba ti Ojise kan ba wa ba yin pelu ohun ti okan yin ko fe ni e o maa segberaga? E si pe apa kan (awon Anabi) ni opuro, e si n pa apa kan

وَقَالُوا قُلُوبُنَا غُلْفٌ ۚ بَل لَّعَنَهُمُ اللَّهُ بِكُفْرِهِمْ فَقَلِيلًا مَّا يُؤْمِنُونَ(88)

 Won si wi pe: “Ebibo bo wa lokan.” Ko si ri bee. Allahu ti sebi le won ni nitori aigbagbo won. Sebi die ni won n gbagbo

وَلَمَّا جَاءَهُمْ كِتَابٌ مِّنْ عِندِ اللَّهِ مُصَدِّقٌ لِّمَا مَعَهُمْ وَكَانُوا مِن قَبْلُ يَسْتَفْتِحُونَ عَلَى الَّذِينَ كَفَرُوا فَلَمَّا جَاءَهُم مَّا عَرَفُوا كَفَرُوا بِهِ ۚ فَلَعْنَةُ اللَّهِ عَلَى الْكَافِرِينَ(89)

 Nigba ti Tira kan si de ba won lati odo Allahu, ti o n fi idi ododo mule nipa ohun ti o wa pelu won, bee si ni teletele won ti n toro isegun lori awon to sai gbagbo, amo nigba ti ohun ti won nimo nipa re de ba won, won sai gbagbo ninu re. Nitori naa, ibi dandan Allahu ki o maa ba awon alaigbagbo

بِئْسَمَا اشْتَرَوْا بِهِ أَنفُسَهُمْ أَن يَكْفُرُوا بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ بَغْيًا أَن يُنَزِّلَ اللَّهُ مِن فَضْلِهِ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۖ فَبَاءُوا بِغَضَبٍ عَلَىٰ غَضَبٍ ۚ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ مُّهِينٌ(90)

 Aburu ni ohun ti won ra fun emi ara won nipa bi won se sai gbagbo ninu ohun ti Allahu sokale, ni ti ilara pe Allahu n so (Tira) kale ninu oore ajulo Re fun eni ti O fe ninu awon erusin Re. Won si pada pelu ibinu (miiran) lori ibinu (Allahu ti o ti wa lori won tele). Iya ti i yepere (eda) si n be fun awon alaigbagbo

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ آمِنُوا بِمَا أَنزَلَ اللَّهُ قَالُوا نُؤْمِنُ بِمَا أُنزِلَ عَلَيْنَا وَيَكْفُرُونَ بِمَا وَرَاءَهُ وَهُوَ الْحَقُّ مُصَدِّقًا لِّمَا مَعَهُمْ ۗ قُلْ فَلِمَ تَقْتُلُونَ أَنبِيَاءَ اللَّهِ مِن قَبْلُ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(91)

 Nigba ti won ba so fun won pe: “E gbagbo ninu ohun ti Allahu sokale.” Won a wi pe: “A gbagbo ninu ohun ti won sokale fun wa.” Won si n sai gbagbo ninu ohun t’o wa leyin re, ti o si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu won. So pe: “Nitori ki ni e fi n pa awon Anabi Allahu teletele ti e ba je onigbagbo ododo

۞ وَلَقَدْ جَاءَكُم مُّوسَىٰ بِالْبَيِّنَاتِ ثُمَّ اتَّخَذْتُمُ الْعِجْلَ مِن بَعْدِهِ وَأَنتُمْ ظَالِمُونَ(92)

 Ati pe dajudaju (Anabi) Musa ti mu awon eri t’o yanju wa ba yin. Leyin naa, e tun bo oborogidi omo maalu leyin re. Alabosi si ni yin.”

وَإِذْ أَخَذْنَا مِيثَاقَكُمْ وَرَفَعْنَا فَوْقَكُمُ الطُّورَ خُذُوا مَا آتَيْنَاكُم بِقُوَّةٍ وَاسْمَعُوا ۖ قَالُوا سَمِعْنَا وَعَصَيْنَا وَأُشْرِبُوا فِي قُلُوبِهِمُ الْعِجْلَ بِكُفْرِهِمْ ۚ قُلْ بِئْسَمَا يَأْمُرُكُم بِهِ إِيمَانُكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(93)

 (E ranti) nigba ti A gba adehun lowo yin, A si gbe apata s’oke ori yin, (A so pe:) "E gba ohun ti A fun yin mu daradara. Ki e si teti gboro." Won wi pe: "A gbo (ase), a si yapa (ase)." Won ti ko ife bibo oborogidi omo maalu sinu okan won nipase aigbagbo won. So pe: "Aburu ni ohun ti igbagbo (iborisa) yin n pa yin lase re, ti e ba je onigbagbo ododo

قُلْ إِن كَانَتْ لَكُمُ الدَّارُ الْآخِرَةُ عِندَ اللَّهِ خَالِصَةً مِّن دُونِ النَّاسِ فَتَمَنَّوُا الْمَوْتَ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(94)

 So pe: “Ti o ba je pe tiyin nikan ni Ile Ikeyin ti n be ni odo Allahu, ti ko si nii je ti awon eniyan (miiran), e toro iku, ti e ba je olododo

وَلَن يَتَمَنَّوْهُ أَبَدًا بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ(95)

 Won ko nii toro iku laelae nitori ohun ti owo won ti siwaju. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi

وَلَتَجِدَنَّهُمْ أَحْرَصَ النَّاسِ عَلَىٰ حَيَاةٍ وَمِنَ الَّذِينَ أَشْرَكُوا ۚ يَوَدُّ أَحَدُهُمْ لَوْ يُعَمَّرُ أَلْفَ سَنَةٍ وَمَا هُوَ بِمُزَحْزِحِهِ مِنَ الْعَذَابِ أَن يُعَمَّرَ ۗ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا يَعْمَلُونَ(96)

 Dajudaju o maa ri won pe awon ni eniyan t’o l’oju kokoro julo nipa isemi aye, (won tun l’oju kokoro ju) awon osebo lo. Ikookan won n fe pe ti A ba le fun oun ni egberun odun lo laye. Bee si ni, ki i se ohun ti o maa la a ninu iya ni pe ki A fun un ni isemi gigun lo. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

قُلْ مَن كَانَ عَدُوًّا لِّجِبْرِيلَ فَإِنَّهُ نَزَّلَهُ عَلَىٰ قَلْبِكَ بِإِذْنِ اللَّهِ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ وَهُدًى وَبُشْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ(97)

 So pe: “Enikeni ti o ba je ota fun (molaika) Jibril, (o ti di ota Allahu) nitori pe dajudaju (molaika) Jibril lo mu al-Ƙur’an wa sinu okan re pelu ase Allahu. Al-Ƙur’an si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re. O je imona ati idunnu fun awon onigbagbo ododo

مَن كَانَ عَدُوًّا لِّلَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَرُسُلِهِ وَجِبْرِيلَ وَمِيكَالَ فَإِنَّ اللَّهَ عَدُوٌّ لِّلْكَافِرِينَ(98)

 Enikeni ti o ba je ota fun Allahu, awon molaika Re, awon Ojise Re, Jibril ati Mikal, dajudaju Allahu ni ota fun awon alaigbagbo

وَلَقَدْ أَنزَلْنَا إِلَيْكَ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ ۖ وَمَا يَكْفُرُ بِهَا إِلَّا الْفَاسِقُونَ(99)

 Dajudaju A ti so awon ayah to yanju kale fun o. Eni kan ko nii sai gbagbo ninu re ayafi awon arufin

أَوَكُلَّمَا عَاهَدُوا عَهْدًا نَّبَذَهُ فَرِيقٌ مِّنْهُم ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ(100)

 Ati pe se gbogbo igba ti won ba da majemu kan ni apa kan ninu won yoo maa ju u nu? Rara, opolopo won ni ko gbagbo

وَلَمَّا جَاءَهُمْ رَسُولٌ مِّنْ عِندِ اللَّهِ مُصَدِّقٌ لِّمَا مَعَهُمْ نَبَذَ فَرِيقٌ مِّنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ كِتَابَ اللَّهِ وَرَاءَ ظُهُورِهِمْ كَأَنَّهُمْ لَا يَعْلَمُونَ(101)

 Ati pe nigba ti Ojise kan lati odo Allahu de ba won, ti o n jerii si eyi t’o je ododo ninu ohun t’o wa pelu won, apa kan ninu awon ti A fun ni Tira gbe Tira Allahu ju s’eyin leyin won bi eni pe won ko mo (pe asoole nipa Anabi s.a.w. wa ninu re)

وَاتَّبَعُوا مَا تَتْلُو الشَّيَاطِينُ عَلَىٰ مُلْكِ سُلَيْمَانَ ۖ وَمَا كَفَرَ سُلَيْمَانُ وَلَٰكِنَّ الشَّيَاطِينَ كَفَرُوا يُعَلِّمُونَ النَّاسَ السِّحْرَ وَمَا أُنزِلَ عَلَى الْمَلَكَيْنِ بِبَابِلَ هَارُوتَ وَمَارُوتَ ۚ وَمَا يُعَلِّمَانِ مِنْ أَحَدٍ حَتَّىٰ يَقُولَا إِنَّمَا نَحْنُ فِتْنَةٌ فَلَا تَكْفُرْ ۖ فَيَتَعَلَّمُونَ مِنْهُمَا مَا يُفَرِّقُونَ بِهِ بَيْنَ الْمَرْءِ وَزَوْجِهِ ۚ وَمَا هُم بِضَارِّينَ بِهِ مِنْ أَحَدٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَيَتَعَلَّمُونَ مَا يَضُرُّهُمْ وَلَا يَنفَعُهُمْ ۚ وَلَقَدْ عَلِمُوا لَمَنِ اشْتَرَاهُ مَا لَهُ فِي الْآخِرَةِ مِنْ خَلَاقٍ ۚ وَلَبِئْسَ مَا شَرَوْا بِهِ أَنفُسَهُمْ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ(102)

 Won si tele ohun ti awon esu alujannu n ka (fun won ninu idan) lasiko ijoba (Anabi) Sulaemon. (Anabi) Sulaemon ko si sai gbagbo, sugbon awon esu alujannu ni won sai gbagbo, ti won n ko awon eniyan ni idan. Awa ko si so (idan) kale fun awon molaika meji naa. (Amo awon esu alujannu wonyi) Harut ati Morut ni (ilu) Babil (ni won n ko awon eniyan nidan). Won ko si nii ko enikeni ayafi ki won wi pe: "Adanwo ni wa. Nitori naa, ma di keferi." Won si n kekoo ohun ti won yoo fi sopinya laaarin omoniyan ati eni keji re lodo awon alujannu mejeeji. - Won ko si le ko inira ba enikeni ayafi pelu iyonda Allahu. - Won n kekoo ohun ti o maa ko inira ba won, ti ko si nii se won ni anfaani. Won kuku ti mo pe enikeni ti o ba ra idan, ko nii si ipin rere kan fun un ni Ojo Ikeyin. Aburu si ni ohun ti won ra fun emi ara won ti o ba je pe won mo. ti awon onimo mu wa lori re. Ma se siju wo itumo miiran … bi itan ti won ti fi esun oti mimu ati esun ipaniyan kan awon molaika… Ipile adisokan ti a ni si awon molaika yo fori sanpon nipa pipe Harut ati Morut ni molaika. Awon molaika ni eni ti Allahu ni afokantan si lori imisi Re ti O fi ran won. Awon si ni asoju Allahu fun awon Ojise Re. E wo surah at-Tahrim; 66:6 ati surah al-’Anbiya’; 21:26-27…” al-Ƙurtubiy. bi Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) se n ko awon eniyan re ni igbagbo ododo ti Allahu (subhanahu wa ta’ala) fi ran an nise si won bee naa ni awon esu alujannu kan n lo ba awon eniyan lati maa ko won ni eko idan lati maa fi tako igbagbo ododo ti won n gbo lodo Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam). Nikete ti iro aburu yii deti igbo Anabi Sulaemon (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) l’o pase lati gba gbogbo akosile idan naa lowo won. O si bo gbogbo re mo inu ile. Amo leyin iku re

وَلَوْ أَنَّهُمْ آمَنُوا وَاتَّقَوْا لَمَثُوبَةٌ مِّنْ عِندِ اللَّهِ خَيْرٌ ۖ لَّوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ(103)

 Ti o ba je pe dajudaju won gbagbo ni ododo, ti won si beru (Allahu), dajudaju esan ti o maa wa lati odo Allahu l’oore julo (fun won), ti won ba mo

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَقُولُوا رَاعِنَا وَقُولُوا انظُرْنَا وَاسْمَعُوا ۗ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٌ(104)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma so pe “ro‘ina”. (Amo) e so pe “unthurna” , ki e si maa teti gbo (oro esin). Iya eleta-elero si wa fun awon alaigbagbo

مَّا يَوَدُّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَلَا الْمُشْرِكِينَ أَن يُنَزَّلَ عَلَيْكُم مِّنْ خَيْرٍ مِّن رَّبِّكُمْ ۗ وَاللَّهُ يَخْتَصُّ بِرَحْمَتِهِ مَن يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ(105)

 Awon t’o sai gbagbo ninu awon ti A fun ni Tira ati awon osebo ko fe ki won so oore kan kan kale fun yin lati odo Oluwa yin. Allahu si n fi ike Re sa eni ti O ba fe lesa. Allahu si ni Oloore nla

۞ مَا نَنسَخْ مِنْ آيَةٍ أَوْ نُنسِهَا نَأْتِ بِخَيْرٍ مِّنْهَا أَوْ مِثْلِهَا ۗ أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(106)

 A o nii fi ayah kan pa ayah kan re tabi ki A fi sile (bee ni ohun kike nikan), A maa mu eyi t’o dara ju u lo tabi iru re wa. Se iwo ko mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ اللَّهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ(107)

 Se iwo ko mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

أَمْ تُرِيدُونَ أَن تَسْأَلُوا رَسُولَكُمْ كَمَا سُئِلَ مُوسَىٰ مِن قَبْلُ ۗ وَمَن يَتَبَدَّلِ الْكُفْرَ بِالْإِيمَانِ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ(108)

 Tabi e fe maa beere (orokoro) lowo Ojise yin ni gege bi won se beere (orokoro) lowo (Anabi) Musa siwaju? Enikeni ti o ba fi aigbagbo ropo igbagbo, dajudaju o ti sina (kuro) l’oju ona taara

وَدَّ كَثِيرٌ مِّنْ أَهْلِ الْكِتَابِ لَوْ يَرُدُّونَكُم مِّن بَعْدِ إِيمَانِكُمْ كُفَّارًا حَسَدًا مِّنْ عِندِ أَنفُسِهِم مِّن بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ الْحَقُّ ۖ فَاعْفُوا وَاصْفَحُوا حَتَّىٰ يَأْتِيَ اللَّهُ بِأَمْرِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(109)

 Opolopo ninu awon ti A fun ni Tira n fe lati da yin pada sipo keferi leyin ti e ti ni igbagbo ododo, ni ti keeta lati inu emi won, (ati) leyin ti ododo (’Islam) ti foju han si won. Nitori naa, e forijin won, ki e samoju kuro fun won (nipa inira ti won n fi kan yin) titi Allahu yo fi mu ase Re wa (lati ja won logun). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ ۚ وَمَا تُقَدِّمُوا لِأَنفُسِكُم مِّنْ خَيْرٍ تَجِدُوهُ عِندَ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(110)

 E kirun, e yo Zakah; ohunkohun ti e ba si ti siwaju fun emi ara yin ni rere, e maa ba a lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

وَقَالُوا لَن يَدْخُلَ الْجَنَّةَ إِلَّا مَن كَانَ هُودًا أَوْ نَصَارَىٰ ۗ تِلْكَ أَمَانِيُّهُمْ ۗ قُلْ هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ(111)

 Won wi pe: “Eni kan ko nii wo inu Ogba Idera afi eni ti o ba je yehudi tabi nasara.” Iyen ni ife-okan won. So pe: “E mu eri oro yin wa ti e ba je olododo

بَلَىٰ مَنْ أَسْلَمَ وَجْهَهُ لِلَّهِ وَهُوَ مُحْسِنٌ فَلَهُ أَجْرُهُ عِندَ رَبِّهِ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(112)

 Bee ko (won ko nii wo inu Ogba Idera afi) eni ti o ba ju ara re sile (ninu ’Islam) fun Allahu, ti o si je oluse rere. Nitori naa, esan (ise) re n be fun un lodo Oluwa re. Ko nii si iberu fun won. Won ko si nii banuje

وَقَالَتِ الْيَهُودُ لَيْسَتِ النَّصَارَىٰ عَلَىٰ شَيْءٍ وَقَالَتِ النَّصَارَىٰ لَيْسَتِ الْيَهُودُ عَلَىٰ شَيْءٍ وَهُمْ يَتْلُونَ الْكِتَابَ ۗ كَذَٰلِكَ قَالَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ مِثْلَ قَوْلِهِمْ ۚ فَاللَّهُ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ(113)

 Awon yehudi wi pe: “Awon nasara ko ri nnkan kan se (ninu esin).” Awon nasara naa wi pe: “Awon yehudi ko ri nnkan kan se (ninu esin.)” Won si n ke Tira! Bayen ni awon ti ko nimo se so iru oro won (yii). Nitori naa, Allahu a dajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن مَّنَعَ مَسَاجِدَ اللَّهِ أَن يُذْكَرَ فِيهَا اسْمُهُ وَسَعَىٰ فِي خَرَابِهَا ۚ أُولَٰئِكَ مَا كَانَ لَهُمْ أَن يَدْخُلُوهَا إِلَّا خَائِفِينَ ۚ لَهُمْ فِي الدُّنْيَا خِزْيٌ وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ(114)

 Ati pe ta l’o sabosi ju eni ti o se awon mosalasi Allahu ni eewo lati seranti oruko Allahu ninu re, ti o tun sise lori iparun awon mosalasi naa? Awon wonyen, ko letoo fun won lati wo inu re ayafi pelu iberu. Abuku n be fun won n’ile aye. Ni orun, iya nla si n be fun won

وَلِلَّهِ الْمَشْرِقُ وَالْمَغْرِبُ ۚ فَأَيْنَمَا تُوَلُّوا فَثَمَّ وَجْهُ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ وَاسِعٌ عَلِيمٌ(115)

 Ti Allahu ni ibuyo oorun ati ibuwo oorun. Nitori naa, ibikibi ti e ba doju ko ibe yen naa ni ƙiblah Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugbaaye, Onimo

وَقَالُوا اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۖ بَل لَّهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَّهُ قَانِتُونَ(116)

 Won wi pe: “Allahu so eni kan di omo.” Mimo ni fun Un! Oro ko ri bee, (amo) tiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Eni kookan si ni olutele-ase Re

بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَإِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُن فَيَكُونُ(117)

 Olupileda awon sanmo ati ile ni (Allahu). Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: “Je bee.” O si maa je bee

وَقَالَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ لَوْلَا يُكَلِّمُنَا اللَّهُ أَوْ تَأْتِينَا آيَةٌ ۗ كَذَٰلِكَ قَالَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِم مِّثْلَ قَوْلِهِمْ ۘ تَشَابَهَتْ قُلُوبُهُمْ ۗ قَدْ بَيَّنَّا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ(118)

 Awon ti ko nimo wi pe: “Ti o ba je pe Allahu n ba wa soro ni tabi ki ami kan wa ba wa (awa iba gbagbo)?” Bayen ni awon t’o siwaju won se so iru oro won (yii). Okan won jora won. A kuku ti se alaye awon ayah fun ijo to ni amodaju

إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ بِالْحَقِّ بَشِيرًا وَنَذِيرًا ۖ وَلَا تُسْأَلُ عَنْ أَصْحَابِ الْجَحِيمِ(119)

 Dajudaju Awa fi ododo ran o nise. (O si je) oniroo-idunnu ati olukilo (fun gbogbo aye). Won ko si nii bi o leere nipa awon ero inu Ina

وَلَن تَرْضَىٰ عَنكَ الْيَهُودُ وَلَا النَّصَارَىٰ حَتَّىٰ تَتَّبِعَ مِلَّتَهُمْ ۗ قُلْ إِنَّ هُدَى اللَّهِ هُوَ الْهُدَىٰ ۗ وَلَئِنِ اتَّبَعْتَ أَهْوَاءَهُم بَعْدَ الَّذِي جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ ۙ مَا لَكَ مِنَ اللَّهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ(120)

 Awon yehudi ati nasara ko nii yonu si o titi o fi maa tele esin won. So pe: “Dajudaju imona ti Allahu ni imona.” Dajudaju ti o ba si tele ife-inu won leyin eyi ti o de ba o ninu imo (’Islam), ko nii si alaabo ati alaranse kan fun o lodo Allahu

الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يَتْلُونَهُ حَقَّ تِلَاوَتِهِ أُولَٰئِكَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۗ وَمَن يَكْفُرْ بِهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ(121)

 Awon ti A fun ni Tira (al-Ƙur’an), won n ke e ni kike eto. Awon wonyen gba a gbo ni ododo. Awon t’o sai gbagbo ninu re, awon wonyen ni eni ofo

يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اذْكُرُوا نِعْمَتِيَ الَّتِي أَنْعَمْتُ عَلَيْكُمْ وَأَنِّي فَضَّلْتُكُمْ عَلَى الْعَالَمِينَ(122)

 Eyin omo ’Isro’il, e ranti ike Mi, eyi ti Mo se fun yin. Dajudaju Emi tun soore ajulo fun yin lori awon

وَاتَّقُوا يَوْمًا لَّا تَجْزِي نَفْسٌ عَن نَّفْسٍ شَيْئًا وَلَا يُقْبَلُ مِنْهَا عَدْلٌ وَلَا تَنفَعُهَا شَفَاعَةٌ وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ(123)

 E beru ojo kan ti emi kan ko nii sanfaani kini kan fun emi kan. A o si nii gba aaro lowo re. Isipe kan ko nii wulo fun un. A o si nii ran won lowo

۞ وَإِذِ ابْتَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ رَبُّهُ بِكَلِمَاتٍ فَأَتَمَّهُنَّ ۖ قَالَ إِنِّي جَاعِلُكَ لِلنَّاسِ إِمَامًا ۖ قَالَ وَمِن ذُرِّيَّتِي ۖ قَالَ لَا يَنَالُ عَهْدِي الظَّالِمِينَ(124)

 (E ranti) nigba ti Oluwa fi awon oro kan dan (Anabi) ’Ibrohim wo. O si pari won ni pipe. (Allahu) so pe: “Dajudaju Emi yo se o ni asiwaju fun awon eniyan.” (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Ati ninu awon aromodomo mi.” (Allahu) so pe: "Adehun Mi (lati so eni kan di Ojise) ko nii te awon alabosi lowo

وَإِذْ جَعَلْنَا الْبَيْتَ مَثَابَةً لِّلنَّاسِ وَأَمْنًا وَاتَّخِذُوا مِن مَّقَامِ إِبْرَاهِيمَ مُصَلًّى ۖ وَعَهِدْنَا إِلَىٰ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ أَن طَهِّرَا بَيْتِيَ لِلطَّائِفِينَ وَالْعَاكِفِينَ وَالرُّكَّعِ السُّجُودِ(125)

 (E ranti) nigba ti A se Ile (Kaaba) ni aye ti awon eniyan yoo maa wa ati aye ifayabale. Ki e si mu ibuduro ’Ibrohim ni ibukirun. A si pa (Anabi) ’Ibrohim ati (Anabi) ’Ismo‘il lase pe “E se Ile Mi ni mimo fun awon oluyipo re, awon olukoraro sinu re ati awon oludawote-orunkun, awon oluforikanle (lori irun)

وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّ اجْعَلْ هَٰذَا بَلَدًا آمِنًا وَارْزُقْ أَهْلَهُ مِنَ الثَّمَرَاتِ مَنْ آمَنَ مِنْهُم بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۖ قَالَ وَمَن كَفَرَ فَأُمَتِّعُهُ قَلِيلًا ثُمَّ أَضْطَرُّهُ إِلَىٰ عَذَابِ النَّارِ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ(126)

 (E ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: “Oluwa mi, se ilu yii ni ilu ifayabale. Ki O si pese awon eso fun awon ara ibe (iyen) enikeni ninu won ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin.” (Allahu) so pe: "Ati eni ti o ba sai gbagbo, Emi yoo fun un ni igbadun die. Leyin naa, Mo maa taari re sinu iya Ina. Ikangun naa si buru

وَإِذْ يَرْفَعُ إِبْرَاهِيمُ الْقَوَاعِدَ مِنَ الْبَيْتِ وَإِسْمَاعِيلُ رَبَّنَا تَقَبَّلْ مِنَّا ۖ إِنَّكَ أَنتَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(127)

 (E ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim ati ’Ismo‘il gbe awon ipile Ile naa duro. (Won sadua pe) "Oluwa wa, gba a lowo wa, dajudaju Iwo, Iwo ni Olugbo, Onimo

رَبَّنَا وَاجْعَلْنَا مُسْلِمَيْنِ لَكَ وَمِن ذُرِّيَّتِنَا أُمَّةً مُّسْلِمَةً لَّكَ وَأَرِنَا مَنَاسِكَنَا وَتُبْ عَلَيْنَا ۖ إِنَّكَ أَنتَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ(128)

 Oluwa wa, se wa ni musulumi fun O. Ki O si se ninu aromodomo wa ni ijo musulumi fun O. Fi ilana esin wa han wa. Ki O si gba ironupiwada wa. Dajudaju Iwo, Iwo ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

رَبَّنَا وَابْعَثْ فِيهِمْ رَسُولًا مِّنْهُمْ يَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِكَ وَيُعَلِّمُهُمُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَيُزَكِّيهِمْ ۚ إِنَّكَ أَنتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ(129)

 Oluwa wa, gbe dide ninu won Ojise kan laaarin won, (eni ti) o maa ke awon ayah Re fun won, ti o maa ko won ni Tira ati ogbon ijinle (sunnah), ti o si maa so won di eni mimo. Dajudaju Iwo, Iwo ni Alagbara, Ologbon

وَمَن يَرْغَبُ عَن مِّلَّةِ إِبْرَاهِيمَ إِلَّا مَن سَفِهَ نَفْسَهُ ۚ وَلَقَدِ اصْطَفَيْنَاهُ فِي الدُّنْيَا ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ لَمِنَ الصَّالِحِينَ(130)

 Ta si ni o maa ko esin (Anabi) ’Ibrohim sile afi eni ti o ba go emi ara re. A kuku ti sa a lesa n’ile aye. Dajudaju o tun wa ninu awon eni rere ni orun

إِذْ قَالَ لَهُ رَبُّهُ أَسْلِمْ ۖ قَالَ أَسْلَمْتُ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ(131)

 (E ranti) nigba ti Oluwa re so fun un pe: “Je musulumi.” O so pe: “Mo je musulumi fun Oluwa gbogbo eda.”

وَوَصَّىٰ بِهَا إِبْرَاهِيمُ بَنِيهِ وَيَعْقُوبُ يَا بَنِيَّ إِنَّ اللَّهَ اصْطَفَىٰ لَكُمُ الدِّينَ فَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنتُم مُّسْلِمُونَ(132)

 (Anabi) ’Ibrohim si pa a lase fun awon omo re. (Anabi) Ya‘ƙub naa se bee. (Ikini keji so pe): "Eyin omo mi, dajudaju Allahu yan esin naa fun yin. Nitori naa, e o gbodo ku ayafi ki e je musulumi

أَمْ كُنتُمْ شُهَدَاءَ إِذْ حَضَرَ يَعْقُوبَ الْمَوْتُ إِذْ قَالَ لِبَنِيهِ مَا تَعْبُدُونَ مِن بَعْدِي قَالُوا نَعْبُدُ إِلَٰهَكَ وَإِلَٰهَ آبَائِكَ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ إِلَٰهًا وَاحِدًا وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ(133)

 Tabi eyin je elerii nigba ti iku de ba (Anabi) Ya‘ƙub? Nigba ti o so fun awon omo re pe: “Ki ni eyin yoo maa josin fun leyin (iku) mi?” Won so pe: "Awa yo maa josin fun Olohun re ati Olohun awon baba re, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il ati ’Ishaƙ, Olohun Okan soso. Awa si ni musulumi (ti a juwo juse sile) fun Un

تِلْكَ أُمَّةٌ قَدْ خَلَتْ ۖ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَلَكُم مَّا كَسَبْتُمْ ۖ وَلَا تُسْأَلُونَ عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ(134)

 Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise

وَقَالُوا كُونُوا هُودًا أَوْ نَصَارَىٰ تَهْتَدُوا ۗ قُلْ بَلْ مِلَّةَ إِبْرَاهِيمَ حَنِيفًا ۖ وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ(135)

 Won wi pe: “E je yehudi tabi nasara ki e mona.” So pe: "Rara, esin (Anabi) ’Ibrohim (lesin), oluduro-deede, ko si si ninu awon osebo

قُولُوا آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْنَا وَمَا أُنزِلَ إِلَىٰ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَمَا أُوتِيَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَمَا أُوتِيَ النَّبِيُّونَ مِن رَّبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِّنْهُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ(136)

 E so pe: “A gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa ati ohun ti Won sokale fun (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo Ya‘ƙub. (A gbagbo ninu) ohun ti Won fun (awon Anabi) Musa ati ‘Isa, ati ohun ti Won fun awon Anabi (yooku) lati odo Oluwa won. A ko ya eni kan soto ninu won. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse sile) fun Un.”

فَإِنْ آمَنُوا بِمِثْلِ مَا آمَنتُم بِهِ فَقَدِ اهْتَدَوا ۖ وَّإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّمَا هُمْ فِي شِقَاقٍ ۖ فَسَيَكْفِيكَهُمُ اللَّهُ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ(137)

 Nitori naa, ti won ba gbagbo ninu iru ohun ti e gbagbo, won ti mona. Ti won ba si gbunri, won ti wa ninu iyapa (ododo). Allahu si maa to o (nibi aburu) won. Oun ni Olugbo, Onimo

صِبْغَةَ اللَّهِ ۖ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ صِبْغَةً ۖ وَنَحْنُ لَهُ عَابِدُونَ(138)

 (E duro ti) aro Allahu. Ta si l’o dara ju Allahu lo ni aro! Awa si ni olujosin fun Un

قُلْ أَتُحَاجُّونَنَا فِي اللَّهِ وَهُوَ رَبُّنَا وَرَبُّكُمْ وَلَنَا أَعْمَالُنَا وَلَكُمْ أَعْمَالُكُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُخْلِصُونَ(139)

 So pe: “Se eyin yo ja wa niyan nipa Allahu ni?” Oun si ni Oluwa wa ati Oluwa yin. Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Awa (musulumi) si ni olusafomo-esin fun Un

أَمْ تَقُولُونَ إِنَّ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطَ كَانُوا هُودًا أَوْ نَصَارَىٰ ۗ قُلْ أَأَنتُمْ أَعْلَمُ أَمِ اللَّهُ ۗ وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن كَتَمَ شَهَادَةً عِندَهُ مِنَ اللَّهِ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ(140)

 Tabi e n wi pe: “Dajudaju (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo Ya‘ƙub, won je yehudi tabi nasara.” So pe: “Se eyin l’e nimo julo (nipa won ni) tabi Allahu?” Ta l’o sabosi ju eni t’o daso bo eri odo re (ti o sokale) lati odo Allahu? Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

تِلْكَ أُمَّةٌ قَدْ خَلَتْ ۖ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَلَكُم مَّا كَسَبْتُمْ ۖ وَلَا تُسْأَلُونَ عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ(141)

 Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise

۞ سَيَقُولُ السُّفَهَاءُ مِنَ النَّاسِ مَا وَلَّاهُمْ عَن قِبْلَتِهِمُ الَّتِي كَانُوا عَلَيْهَا ۚ قُل لِّلَّهِ الْمَشْرِقُ وَالْمَغْرِبُ ۚ يَهْدِي مَن يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(142)

 Awon omugo ninu awon eniyan maa wi pe: “Ki ni o mu won yi kuro nibi Ƙiblah won ti won ti wa tele?” So pe: “Ti Allahu ni ibuyo oorun ati ibuwo oorun. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam).”

وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَاكُمْ أُمَّةً وَسَطًا لِّتَكُونُوا شُهَدَاءَ عَلَى النَّاسِ وَيَكُونَ الرَّسُولُ عَلَيْكُمْ شَهِيدًا ۗ وَمَا جَعَلْنَا الْقِبْلَةَ الَّتِي كُنتَ عَلَيْهَا إِلَّا لِنَعْلَمَ مَن يَتَّبِعُ الرَّسُولَ مِمَّن يَنقَلِبُ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ ۚ وَإِن كَانَتْ لَكَبِيرَةً إِلَّا عَلَى الَّذِينَ هَدَى اللَّهُ ۗ وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُضِيعَ إِيمَانَكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِالنَّاسِ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ(143)

 Bayen ni A ti se yin ni esa ijo t’o loore julo, nitori ki e le je elerii fun awon eniyan, ati nitori ki Ojise naa le je elerii fun yin. A ko si se Ƙiblah ti o wa lori re tele ni ibukoju-kirun bi ko se pe nitori ki A le se afihan eni ti o maa tele Ojise yato si eni ti o maa yise pada. Dajudaju o lagbara ayafi fun awon ti Allahu to sona. Allahu ko si nii fi igbagbo yin rare. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Onikee fun awon eniyan

قَدْ نَرَىٰ تَقَلُّبَ وَجْهِكَ فِي السَّمَاءِ ۖ فَلَنُوَلِّيَنَّكَ قِبْلَةً تَرْضَاهَا ۚ فَوَلِّ وَجْهَكَ شَطْرَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۚ وَحَيْثُ مَا كُنتُمْ فَوَلُّوا وُجُوهَكُمْ شَطْرَهُ ۗ وَإِنَّ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ لَيَعْلَمُونَ أَنَّهُ الْحَقُّ مِن رَّبِّهِمْ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ(144)

 A kuku ri yiyi ti o n yi oju re si sanmo. Nitori naa, A o doju re ko Ƙiblah kan ti o yonu si; nitori naa, koju re si agbegbe Mosalasi Haram (ni Mokkah). Ibikibi ti e ba tun wa, e koju yin si agbegbe re. Dajudaju awon ti A fun ni Tira kuku mo pe dajudaju ododo ni (ase Ƙiblah) lati odo Oluwa won. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti won n se nise

وَلَئِنْ أَتَيْتَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ بِكُلِّ آيَةٍ مَّا تَبِعُوا قِبْلَتَكَ ۚ وَمَا أَنتَ بِتَابِعٍ قِبْلَتَهُمْ ۚ وَمَا بَعْضُهُم بِتَابِعٍ قِبْلَةَ بَعْضٍ ۚ وَلَئِنِ اتَّبَعْتَ أَهْوَاءَهُم مِّن بَعْدِ مَا جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ ۙ إِنَّكَ إِذًا لَّمِنَ الظَّالِمِينَ(145)

 Dajudaju ti o ba fun awon ti A fun ni Tira ni gbogbo ayah, won ko nii tele Ƙiblah re. Iwo naa ko gbodo tele Ƙiblah won. Apa kan won ko si nii tele Ƙiblah apa kan. Dajudaju ti o ba tele ife-inu won leyin ohun ti o de ba o ninu imo, dajudaju nigba naa iwo wa ninu awon alabosi

الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يَعْرِفُونَهُ كَمَا يَعْرِفُونَ أَبْنَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّ فَرِيقًا مِّنْهُمْ لَيَكْتُمُونَ الْحَقَّ وَهُمْ يَعْلَمُونَ(146)

 Awon ti A fun ni Tira, won mo Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) gege bi won se mo awon omo won. Dajudaju awon ijo kan wa ninu won ti won kuku n fi ododo pamo; won si mo

الْحَقُّ مِن رَّبِّكَ ۖ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُمْتَرِينَ(147)

 Ododo naa wa lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji

وَلِكُلٍّ وِجْهَةٌ هُوَ مُوَلِّيهَا ۖ فَاسْتَبِقُوا الْخَيْرَاتِ ۚ أَيْنَ مَا تَكُونُوا يَأْتِ بِكُمُ اللَّهُ جَمِيعًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(148)

 Ikookan (ijo elesin) l’o ni ibukojusi t’o n koju si. Nitori naa, e yara gbawaju nibi awon ise rere. Ibikibi ti e ba wa, Allahu yo mu gbogbo yin wa (ni Ojo Ajinde). Dajudaju Alagbara ni Allahu lori gbogbo nnkan

وَمِنْ حَيْثُ خَرَجْتَ فَوَلِّ وَجْهَكَ شَطْرَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۖ وَإِنَّهُ لَلْحَقُّ مِن رَّبِّكَ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ(149)

 Ibikibi ti o ba jade lo, koju re si agbegbe Mosalasi Haram, nitori pe dajudaju ododo ni lati odo Oluwa re. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

وَمِنْ حَيْثُ خَرَجْتَ فَوَلِّ وَجْهَكَ شَطْرَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۚ وَحَيْثُ مَا كُنتُمْ فَوَلُّوا وُجُوهَكُمْ شَطْرَهُ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَيْكُمْ حُجَّةٌ إِلَّا الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ فَلَا تَخْشَوْهُمْ وَاخْشَوْنِي وَلِأُتِمَّ نِعْمَتِي عَلَيْكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ(150)

 Ibikibi ti o ba jade lo, koju re si agbegbe Mosalasi Haram. Ati pe ibikibi ti e ba wa, e koju yin si agbegbe re, nitori ki awon eniyan ma baa ni awijare lori yin, ayafi awon ti won sabosi ninu won (ti won ko ye ja yin niyan). Nitori naa, e ma se paya won. E paya Mi, nitori ki Ng le pe idera Mi fun yin ati nitori ki e le mona ooji re maa wa ni egbe otun re nikete ti oorun ba yetari. Nigba ti opin eba oke ila oorun n je ariwa-ila oorun (north-east) opin eba isale ila oorun si n je gusu-ila oorun (south-east). Nitori naa

كَمَا أَرْسَلْنَا فِيكُمْ رَسُولًا مِّنكُمْ يَتْلُو عَلَيْكُمْ آيَاتِنَا وَيُزَكِّيكُمْ وَيُعَلِّمُكُمُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَيُعَلِّمُكُم مَّا لَمْ تَكُونُوا تَعْلَمُونَ(151)

 gege bi A se ran Ojise kan si yin laaarin ara yin, ti o n ke awon ayah Wa fun yin, ti o n so yin di eni mimo, ti o n ko yin ni Tira ati ogbon ijinle (sunnah), ti o si n ko yin ni ohun ti e o mo tele

فَاذْكُرُونِي أَذْكُرْكُمْ وَاشْكُرُوا لِي وَلَا تَكْفُرُونِ(152)

 Nitori naa, e ranti Mi, Mo maa ranti yin. E dupe fun Mi, e ma sai moore si Mi

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اسْتَعِينُوا بِالصَّبْرِ وَالصَّلَاةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِينَ(153)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e fi suuru ati irun kiki toro oore (Allahu). Dajudaju Allahu n be pelu awon onisuuru

وَلَا تَقُولُوا لِمَن يُقْتَلُ فِي سَبِيلِ اللَّهِ أَمْوَاتٌ ۚ بَلْ أَحْيَاءٌ وَلَٰكِن لَّا تَشْعُرُونَ(154)

 E ma se pe awon ti won n pa si oju-ogun esin Allahu ni oku (iya), amo alaaye (eni ike) ni won, sugbon eyin ko fura

وَلَنَبْلُوَنَّكُم بِشَيْءٍ مِّنَ الْخَوْفِ وَالْجُوعِ وَنَقْصٍ مِّنَ الْأَمْوَالِ وَالْأَنفُسِ وَالثَّمَرَاتِ ۗ وَبَشِّرِ الصَّابِرِينَ(155)

 Dajudaju A o maa dan yin wo pelu kini kan latara eru, ebi, adinku ninu awon dukia, awon emi ati awon eso. Ki o si fun awon onisuuru ni iro idunnu

الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُم مُّصِيبَةٌ قَالُوا إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّا إِلَيْهِ رَاجِعُونَ(156)

 Awon ti (o je pe) nigba ti adanwo kan ba kan won, won a so pe: “Dajudaju Allahu l’O ni awa; dajudaju odo Re si ni awa yoo pada si.”

أُولَٰئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِّن رَّبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ(157)

 Awon wonyen ni aforijin ati ike yo maa be fun lati odo Oluwa won. Awon wonyen, awon si ni olumona

۞ إِنَّ الصَّفَا وَالْمَرْوَةَ مِن شَعَائِرِ اللَّهِ ۖ فَمَنْ حَجَّ الْبَيْتَ أَوِ اعْتَمَرَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِ أَن يَطَّوَّفَ بِهِمَا ۚ وَمَن تَطَوَّعَ خَيْرًا فَإِنَّ اللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ(158)

 Dajudaju (apata) Sofa ati (apata) Morwah wa ninu awon arisami fun esin Allahu. Nitori naa, enikeni ti o ba se ise Hajj si Ile naa tabi o se ise ‘Umrah, ko si ese fun un lati rin yika (laaarin apata) mejeeji. Enikeni ti o ba si finnu-findo se ise asegbore, dajudaju Allahu ni Amoore, Onimo

إِنَّ الَّذِينَ يَكْتُمُونَ مَا أَنزَلْنَا مِنَ الْبَيِّنَاتِ وَالْهُدَىٰ مِن بَعْدِ مَا بَيَّنَّاهُ لِلنَّاسِ فِي الْكِتَابِ ۙ أُولَٰئِكَ يَلْعَنُهُمُ اللَّهُ وَيَلْعَنُهُمُ اللَّاعِنُونَ(159)

 Dajudaju awon t’o n daso bo ohun ti A sokale ninu awon eri t’o yanju ati imona, leyin ti A ti se alaye re fun awon eniyan sinu Tira, awon wonyen ni Allahu n sebi le. Awon olusebi si n sebi le won

إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا وَأَصْلَحُوا وَبَيَّنُوا فَأُولَٰئِكَ أَتُوبُ عَلَيْهِمْ ۚ وَأَنَا التَّوَّابُ الرَّحِيمُ(160)

 Ayafi awon t’o ronu piwada, ti won se atunse, ti won si safi han ododo, nitori naa awon wonyen ni Mo maa gba ironupiwada won. Emi si ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَمَاتُوا وَهُمْ كُفَّارٌ أُولَٰئِكَ عَلَيْهِمْ لَعْنَةُ اللَّهِ وَالْمَلَائِكَةِ وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ(161)

 Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si ku nigba ti won je alaigbagbo, awon wonyen ni egun Allahu, (egun) awon molaika ati (egun) eniyan patapata n be lori won

خَالِدِينَ فِيهَا ۖ لَا يُخَفَّفُ عَنْهُمُ الْعَذَابُ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ(162)

 Olusegbere ni won ninu re. Nitori naa, A o nii gbe iya fuye fun won. A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina)

وَإِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ لَّا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الرَّحْمَٰنُ الرَّحِيمُ(163)

 Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Ko si olohun kan ti ijosin to si ayafi Oun, Ajoke-aye, Asake-orun

إِنَّ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَالْفُلْكِ الَّتِي تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِمَا يَنفَعُ النَّاسَ وَمَا أَنزَلَ اللَّهُ مِنَ السَّمَاءِ مِن مَّاءٍ فَأَحْيَا بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَابَّةٍ وَتَصْرِيفِ الرِّيَاحِ وَالسَّحَابِ الْمُسَخَّرِ بَيْنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ(164)

 Dajudaju awon ami wa ninu iseda awon sanmo ati ile, itelentele ati iyato oru ati osan, ati awon oko oju-omi t’o n rin lori omi pelu (riru) ohun t’o n se awon eniyan ni anfaani, ati ohun ti Allahu n sokale ni omi ojo lati sanmo, ti O si n fi so ile di aye leyin ti o ti ku, ati (bi) O se fon gbogbo eranko ka si ori ile, ati iyipada ategun ati esujo ti A teba laaarin sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n se laakaye

وَمِنَ النَّاسِ مَن يَتَّخِذُ مِن دُونِ اللَّهِ أَندَادًا يُحِبُّونَهُمْ كَحُبِّ اللَّهِ ۖ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَشَدُّ حُبًّا لِّلَّهِ ۗ وَلَوْ يَرَى الَّذِينَ ظَلَمُوا إِذْ يَرَوْنَ الْعَذَابَ أَنَّ الْقُوَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًا وَأَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعَذَابِ(165)

 O si n be ninu awon eniyan, eni ti n josin fun awon orisa leyin Allahu. Won nifee won gege bi ife (to ye ki won ni si) Allahu. Awon t’o gbagbo ni ododo si le julo ninu ife si

إِذْ تَبَرَّأَ الَّذِينَ اتُّبِعُوا مِنَ الَّذِينَ اتَّبَعُوا وَرَأَوُا الْعَذَابَ وَتَقَطَّعَتْ بِهِمُ الْأَسْبَابُ(166)

 (Ranti) nigba ti awon ti won tele (ninu aigbagbo) maa yowo yose kuro ninu oro awon t’o tele won; (nigba ti) won ba foju ri Iya, ti ohun t’o so won po si ja patapata

وَقَالَ الَّذِينَ اتَّبَعُوا لَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَتَبَرَّأَ مِنْهُمْ كَمَا تَبَرَّءُوا مِنَّا ۗ كَذَٰلِكَ يُرِيهِمُ اللَّهُ أَعْمَالَهُمْ حَسَرَاتٍ عَلَيْهِمْ ۖ وَمَا هُم بِخَارِجِينَ مِنَ النَّارِ(167)

 Awon t’o tele won yo si wi pe: “Ti o ba je pe dajudaju ipadawaye le wa fun wa ni, awa iba yowo yose kuro ninu oro won ni gege bi won se yowo yose kuro ninu oro wa.” Bayen ni Allahu yo se fi awon ise won han won ni (ise) ofo fun won. Won ko si nii jade kuro ninu Ina

يَا أَيُّهَا النَّاسُ كُلُوا مِمَّا فِي الْأَرْضِ حَلَالًا طَيِّبًا وَلَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ(168)

 Eyin eniyan, e je ninu ohun ti n be ninu ile (t’o je) eto (ati nnkan) daadaa.E ma si se tele awon oju-ese Esu. Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

إِنَّمَا يَأْمُرُكُم بِالسُّوءِ وَالْفَحْشَاءِ وَأَن تَقُولُوا عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ(169)

 Ohun ti o maa pa yin ni ase re ni (ise) aburu, ibaje ati siso nipa Allahu ohun ti e o nimo re

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّبِعُوا مَا أَنزَلَ اللَّهُ قَالُوا بَلْ نَتَّبِعُ مَا أَلْفَيْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا ۗ أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ شَيْئًا وَلَا يَهْتَدُونَ(170)

 Nigba ti won ba so fun won pe

وَمَثَلُ الَّذِينَ كَفَرُوا كَمَثَلِ الَّذِي يَنْعِقُ بِمَا لَا يَسْمَعُ إِلَّا دُعَاءً وَنِدَاءً ۚ صُمٌّ بُكْمٌ عُمْيٌ فَهُمْ لَا يَعْقِلُونَ(171)

 Apejuwe awon to sai gbagbo da bi apejuwe eni ti o n ke pe ohun ti ko le gboro tayo ipe ati igbe (asan). Aditi, ayaya, afoju ni won; won ko si nii se laakaye

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُلُوا مِن طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ وَاشْكُرُوا لِلَّهِ إِن كُنتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ(172)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin, ki e si dupe fun Allahu ti o ba je pe Oun nikan soso ni e n josin fun

إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةَ وَالدَّمَ وَلَحْمَ الْخِنزِيرِ وَمَا أُهِلَّ بِهِ لِغَيْرِ اللَّهِ ۖ فَمَنِ اضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(173)

 Ohun ti (Allahu) se ni eewo fun yin ni okunbete, eje, eran elede ati ohun ti won pe oruko miiran le lori yato si (oruko) Allahu. Sugbon eni ti won ba fi inira (ebi) kan, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, ko si ese fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

إِنَّ الَّذِينَ يَكْتُمُونَ مَا أَنزَلَ اللَّهُ مِنَ الْكِتَابِ وَيَشْتَرُونَ بِهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۙ أُولَٰئِكَ مَا يَأْكُلُونَ فِي بُطُونِهِمْ إِلَّا النَّارَ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ اللَّهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ(174)

 Dajudaju awon t’o n daso bo ohun ti Allahu sokale ninu Tira, ti won si n ta a ni owo pooku, awon wonyen ko je kini kan sinu won bi ko se Ina. Allahu ko si nii ba won soro ni Ojo Ajinde, ko si nii fo won mo (ninu ese). Iya eleta-elero si wa fun won

أُولَٰئِكَ الَّذِينَ اشْتَرَوُا الضَّلَالَةَ بِالْهُدَىٰ وَالْعَذَابَ بِالْمَغْفِرَةِ ۚ فَمَا أَصْبَرَهُمْ عَلَى النَّارِ(175)

 Awon wonyen ni awon t’o fi imona ra isina, (won tun fi) aforijin ra iya. Bawo ni won se maa le sefarada fun Ina na

ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ نَزَّلَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ ۗ وَإِنَّ الَّذِينَ اخْتَلَفُوا فِي الْكِتَابِ لَفِي شِقَاقٍ بَعِيدٍ(176)

 Iyen ri bee nitori pe dajudaju Allahu so Tira (al-Ƙur’an) kale pelu ododo. Dajudaju awon t’o si yapa Tira naa ti wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)

۞ لَّيْسَ الْبِرَّ أَن تُوَلُّوا وُجُوهَكُمْ قِبَلَ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَلَٰكِنَّ الْبِرَّ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَالْمَلَائِكَةِ وَالْكِتَابِ وَالنَّبِيِّينَ وَآتَى الْمَالَ عَلَىٰ حُبِّهِ ذَوِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ وَالسَّائِلِينَ وَفِي الرِّقَابِ وَأَقَامَ الصَّلَاةَ وَآتَى الزَّكَاةَ وَالْمُوفُونَ بِعَهْدِهِمْ إِذَا عَاهَدُوا ۖ وَالصَّابِرِينَ فِي الْبَأْسَاءِ وَالضَّرَّاءِ وَحِينَ الْبَأْسِ ۗ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ صَدَقُوا ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُتَّقُونَ(177)

 Ki i se ohun rere ni ki e koju si agbegbe ibuyo oorun ati ibuwo oorun, amo (oluse) rere ni enikeni t’o ba gbagbo ninu Allahu, Ojo Ikeyin, awon molaika, Tira (al-Ƙur’an), ati awon Anabi. Tohun ti ife ti oluse-rere ni si owo, o tun n fi owo naa tore fun awon ebi, awon omo orukan, awon mekunnu, onirin-ajo (ti agara da), awon atoroje ati (itusile) l’oko eru. (Eni rere) yo maa kirun, yo si maa yo Zakah. (Eni rere ni) awon t’o n mu adehun won se nigba ti won ba se adehun ati awon onisuuru nigba airina-airilo, nigba ailera ati l’oju ogun esin. Awon wonyen ni awon t’o se (ise) ododo. Awon wonyen, awon si ni oluberu (Allahu)

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِصَاصُ فِي الْقَتْلَى ۖ الْحُرُّ بِالْحُرِّ وَالْعَبْدُ بِالْعَبْدِ وَالْأُنثَىٰ بِالْأُنثَىٰ ۚ فَمَنْ عُفِيَ لَهُ مِنْ أَخِيهِ شَيْءٌ فَاتِّبَاعٌ بِالْمَعْرُوفِ وَأَدَاءٌ إِلَيْهِ بِإِحْسَانٍ ۗ ذَٰلِكَ تَخْفِيفٌ مِّن رَّبِّكُمْ وَرَحْمَةٌ ۗ فَمَنِ اعْتَدَىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَلَهُ عَذَابٌ أَلِيمٌ(178)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se esan gbigba nibi ipaniyan ni oran- anyan fun yin. Olominira fun olominira, eru fun eru, obinrin fun obinrin. Enikeni ti won ba samoju kuro kini kan fun lati odo omo iya (eni ti won pa, ki eni ti o maa gba owo emi dipo emi) se ohun rere tele (owo ti o gba, ki eni ti o maa san’wo emi) san owo naa fun un ni ona t’o dara. Iyen ni igbefuye ati aanu lati odo Oluwa yin. Sugbon enikeni ti o ba tayo enu-ala (ofin) leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un

وَلَكُمْ فِي الْقِصَاصِ حَيَاةٌ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ(179)

 Isemi wa fun yin ninu (ofin) igbesan ipaniyan, eyin onilaakaye, ki e le beru (Allahu)

كُتِبَ عَلَيْكُمْ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ إِن تَرَكَ خَيْرًا الْوَصِيَّةُ لِلْوَالِدَيْنِ وَالْأَقْرَبِينَ بِالْمَعْرُوفِ ۖ حَقًّا عَلَى الْمُتَّقِينَ(180)

 A se e ni oran-anyan fun yin, nigba ti iku ba de ba eni kan ninu yin, ti o si fi dukia sile, pe ki o so asoole ni ona t’o dara fun awon obi mejeeji ati awon ebi. (Eyi je) ojuse fun awon oluberu (Allahu)

فَمَن بَدَّلَهُ بَعْدَمَا سَمِعَهُ فَإِنَّمَا إِثْمُهُ عَلَى الَّذِينَ يُبَدِّلُونَهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(181)

 Enikeni ti o ba yi i pada leyin ti o ti gbo o, ese re yo si wa lorun awon t’o n yi i pada. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

فَمَنْ خَافَ مِن مُّوصٍ جَنَفًا أَوْ إِثْمًا فَأَصْلَحَ بَيْنَهُمْ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(182)

 Sugbon eni ti o ba beru asise tabi iwa ese lati odo eni ti o so asoole, ti o si se atunse laaarin (awon ti ogun to si). Nitori naa, ko si ese fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى الَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ(183)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se aawe naa ni oran-anyan fun yin, gege bi A ti se e ni oran-anyan fun awon t’o siwaju yin, nitori ki e le beru (Allahu)

أَيَّامًا مَّعْدُودَاتٍ ۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِّنْ أَيَّامٍ أُخَرَ ۚ وَعَلَى الَّذِينَ يُطِيقُونَهُ فِدْيَةٌ طَعَامُ مِسْكِينٍ ۖ فَمَن تَطَوَّعَ خَيْرًا فَهُوَ خَيْرٌ لَّهُ ۚ وَأَن تَصُومُوا خَيْرٌ لَّكُمْ ۖ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ(184)

 (E gba aawe naa) fun awon ojo ti o ni onka. (Sugbon) enikeni ninu yin ti o ba je alaisan, tabi o wa lori irin-ajo, (o maa san) onka (gbese aawe re) ni awon ojo miiran. Ati pe itanran (iyen) fifun mekunnu ni ounje l’o di dandan fun awon t’o maa fi inira gba aawe. Enikeni ti o ba finnufindo se (alekun) ise oloore, o kuku loore julo fun un. Ati pe ki e gba aawe loore julo fun yin ti e ba mo

شَهْرُ رَمَضَانَ الَّذِي أُنزِلَ فِيهِ الْقُرْآنُ هُدًى لِّلنَّاسِ وَبَيِّنَاتٍ مِّنَ الْهُدَىٰ وَالْفُرْقَانِ ۚ فَمَن شَهِدَ مِنكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ ۖ وَمَن كَانَ مَرِيضًا أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِّنْ أَيَّامٍ أُخَرَ ۗ يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ وَلِتُكْمِلُوا الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُوا اللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَاكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ(185)

 Osu Romodon eyi ti A so al-Ƙur’an kale ninu re 1 (ti o je) imona, awon alaye ponnbele nipa imona ati oro-ipinya 2 fun awon eniyan; nitori naa, enikeni ti o ba wa ninu ilu re ninu yin ninu osu naa, 3 ki o gba aawe osu naa. Enikeni ti o ba je alaisan tabi ti o ba wa lori irin-ajo, (o maa san) onka (gbese aawe re) ni awon ojo miiran. Allahu fe irorun fun yin, ko si fe inira fun yin. E pe onka (ojo aawe), ki e si gbe titobi fun Allahu nitori pe O fi ona mo yin ati nitori ki e le dupe fun Un. aye kan naa ni oke ‘Arafah wa sugbon ko pon dandan ki gbogbo aye bere aawe Romodon ni ojo kan naa ti a ba fe ki ojo ibere aawe Romodon wa ati ipari re maa je ojo kan naa gege bi o se pon dandan bee ninu ofin ’Islam a bukata si nnkan meji gbooro. Ikini: asiwaju eyo kan soso ti o maa je onisunnah

وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌ ۖ أُجِيبُ دَعْوَةَ الدَّاعِ إِذَا دَعَانِ ۖ فَلْيَسْتَجِيبُوا لِي وَلْيُؤْمِنُوا بِي لَعَلَّهُمْ يَرْشُدُونَ(186)

 Nigba ti awon erusin Mi ba bi o leere nipa Mi, dajudaju Emi ni Olusunmo. Emi yoo jepe adua aladuua nigba ti o ba pe Mi. Ki won je’pe Mi (nipa itele ase Mi). Ki won si gba Mi gbo nitori ki won le mona (gbigba adua)

أُحِلَّ لَكُمْ لَيْلَةَ الصِّيَامِ الرَّفَثُ إِلَىٰ نِسَائِكُمْ ۚ هُنَّ لِبَاسٌ لَّكُمْ وَأَنتُمْ لِبَاسٌ لَّهُنَّ ۗ عَلِمَ اللَّهُ أَنَّكُمْ كُنتُمْ تَخْتَانُونَ أَنفُسَكُمْ فَتَابَ عَلَيْكُمْ وَعَفَا عَنكُمْ ۖ فَالْآنَ بَاشِرُوهُنَّ وَابْتَغُوا مَا كَتَبَ اللَّهُ لَكُمْ ۚ وَكُلُوا وَاشْرَبُوا حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكُمُ الْخَيْطُ الْأَبْيَضُ مِنَ الْخَيْطِ الْأَسْوَدِ مِنَ الْفَجْرِ ۖ ثُمَّ أَتِمُّوا الصِّيَامَ إِلَى اللَّيْلِ ۚ وَلَا تُبَاشِرُوهُنَّ وَأَنتُمْ عَاكِفُونَ فِي الْمَسَاجِدِ ۗ تِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ فَلَا تَقْرَبُوهَا ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ آيَاتِهِ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ(187)

 Won se ale aawe ni eto fun yin lati sunmo awon iyawo yin; awon ni aso yin, eyin si ni aso won. Allahu mo pe dajudaju e n tan ara yin je (nipa aife sun oorun ife ni ale aawe). O ti gba ironupiwada yin, O si se amojukuro fun yin. Ni bayii, e sunmo won, ki e si wa ohun ti Allahu ko mo yin (ni omo). E je, e mu titi e o fi ri iyato laaarin owu funfun (iyen, imole owuro) ati owu dudu (iyen, okunkun oru) ni afemojumo. Leyin naa, e pari aawe naa si ale (nigba ti oorun ba wo). E ma se sunmo won nigba ti e ba n kora ro ninu awon mosalasi. Iwonyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale), e ma se sunmo on. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le beru (Re)

وَلَا تَأْكُلُوا أَمْوَالَكُم بَيْنَكُم بِالْبَاطِلِ وَتُدْلُوا بِهَا إِلَى الْحُكَّامِ لِتَأْكُلُوا فَرِيقًا مِّنْ أَمْوَالِ النَّاسِ بِالْإِثْمِ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ(188)

 Eyin ko gbodo fi eru je dukia yin laaarin ara yin. Eyin ko si gbodo gbe dukia lo ba awon adajo (ni abetele) nitori ki e le fi ese je ipin kan ninu dukia awon eniyan, eyin si mo

۞ يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْأَهِلَّةِ ۖ قُلْ هِيَ مَوَاقِيتُ لِلنَّاسِ وَالْحَجِّ ۗ وَلَيْسَ الْبِرُّ بِأَن تَأْتُوا الْبُيُوتَ مِن ظُهُورِهَا وَلَٰكِنَّ الْبِرَّ مَنِ اتَّقَىٰ ۗ وَأْتُوا الْبُيُوتَ مِنْ أَبْوَابِهَا ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ(189)

 Won n bi o leere nipa iletesu. So pe: “Ohun ni (onka) akoko fun awon eniyan ati (onka akoko fun) ise Hajj. Ki i se ise rere (fun yin) lati gba eyin-inkule wonu ile, sugbon (oluse) rere ni eni ti o ba beru (Allahu). E gba enu-ona wonu ile. Ki e si beru Allahu nitori ki e le jere

وَقَاتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَكُمْ وَلَا تَعْتَدُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْمُعْتَدِينَ(190)

 Fun aabo esin Allahu, e pa awon t’o n ja yin logun. Ki e si ma se tayo enu-ala. Dajudaju Allahu ko nifee awon olutayo enu-ala

وَاقْتُلُوهُمْ حَيْثُ ثَقِفْتُمُوهُمْ وَأَخْرِجُوهُم مِّنْ حَيْثُ أَخْرَجُوكُمْ ۚ وَالْفِتْنَةُ أَشَدُّ مِنَ الْقَتْلِ ۚ وَلَا تُقَاتِلُوهُمْ عِندَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ حَتَّىٰ يُقَاتِلُوكُمْ فِيهِ ۖ فَإِن قَاتَلُوكُمْ فَاقْتُلُوهُمْ ۗ كَذَٰلِكَ جَزَاءُ الْكَافِرِينَ(191)

 E pa won nibikibi ti owo yin ba ti ba won. Ki e si le won jade kuro nibi ti won ti le yin jade. Ifooro le ju pipa lo. E ma se ba won ja ni Mosalasi Haram afi igba ti won ba ba yin ja ninu re. Nitori naa, ti won ba ba yin ja, e ba won ja. Bayen ni esan awon alaigbagbo

فَإِنِ انتَهَوْا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(192)

 Ti won ba si jawo (ninu iborisa), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

وَقَاتِلُوهُمْ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتْنَةٌ وَيَكُونَ الدِّينُ لِلَّهِ ۖ فَإِنِ انتَهَوْا فَلَا عُدْوَانَ إِلَّا عَلَى الظَّالِمِينَ(193)

 E gbogun ti won titi ko fi nii si ifooro (iborisa) mo. Esin ’Islam yo si wa (ni ominira) fun Allahu. Nitori naa, ti won ba jawo (ninu iborisa), ko si ogun mo ayafi lori awon alabosi

الشَّهْرُ الْحَرَامُ بِالشَّهْرِ الْحَرَامِ وَالْحُرُمَاتُ قِصَاصٌ ۚ فَمَنِ اعْتَدَىٰ عَلَيْكُمْ فَاعْتَدُوا عَلَيْهِ بِمِثْلِ مَا اعْتَدَىٰ عَلَيْكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ(194)

 Osu owo fun osu owo. Awon nnkan owo si ni (ofin) igbesan. Nitori naa, enikeni ti o ba tayo enu-ala si yin, e gb’esan itayo enu-ala lara re pelu iru ohun ti o fi tayo enu-ala si yin. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu n be pelu awon oluberu (Re)

وَأَنفِقُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلَا تُلْقُوا بِأَيْدِيكُمْ إِلَى التَّهْلُكَةِ ۛ وَأَحْسِنُوا ۛ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ(195)

 E nawo fun ogun esin Allahu. Ki e si ma se fi owo ara yin fa iparun (nipa sisa fun ogun esin). E se rere. Dajudaju Allahu nifee awon oluse-rere

وَأَتِمُّوا الْحَجَّ وَالْعُمْرَةَ لِلَّهِ ۚ فَإِنْ أُحْصِرْتُمْ فَمَا اسْتَيْسَرَ مِنَ الْهَدْيِ ۖ وَلَا تَحْلِقُوا رُءُوسَكُمْ حَتَّىٰ يَبْلُغَ الْهَدْيُ مَحِلَّهُ ۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوْ بِهِ أَذًى مِّن رَّأْسِهِ فَفِدْيَةٌ مِّن صِيَامٍ أَوْ صَدَقَةٍ أَوْ نُسُكٍ ۚ فَإِذَا أَمِنتُمْ فَمَن تَمَتَّعَ بِالْعُمْرَةِ إِلَى الْحَجِّ فَمَا اسْتَيْسَرَ مِنَ الْهَدْيِ ۚ فَمَن لَّمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ فِي الْحَجِّ وَسَبْعَةٍ إِذَا رَجَعْتُمْ ۗ تِلْكَ عَشَرَةٌ كَامِلَةٌ ۗ ذَٰلِكَ لِمَن لَّمْ يَكُنْ أَهْلُهُ حَاضِرِي الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ(196)

 E se asepe ise Hajj ati ‘Umrah fun Allahu. Ti won ba si se yin mo oju ona, e fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eyin ko si gbodo fa irun ori yin titi di igba ti eran ore naa yo fi de aye re. Enikeni ninu yin ti o ba je alaisan tabi inira kan n be ni ori re, o maa fi aawe tabi saraa tabi eran pipa se itanran (fun kikanju fa irun ori). Nigba ti e ba fokanbale (ninu ewu), enikeni ti o ba se ‘Umrah ati Hajj ninu osu ise Hajj, o maa fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eni ti ko ba ri (eran ore), ki o gba aawe ojo meta ninu (ise) hajj, meje nigba ti e ba dari wale. Iyen ni (aawe) mewaa t’o pe. Iyen wa fun eni ti ko si ebi re ni Mosalasi Haram. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu le (nibi) iya

الْحَجُّ أَشْهُرٌ مَّعْلُومَاتٌ ۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ الْحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي الْحَجِّ ۗ وَمَا تَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ يَعْلَمْهُ اللَّهُ ۗ وَتَزَوَّدُوا فَإِنَّ خَيْرَ الزَّادِ التَّقْوَىٰ ۚ وَاتَّقُونِ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ(197)

 Hajj sise (wa) ninu awon osu ti A ti mo. Nitori naa, enikeni ti o ba se e ni oran-anyan lori ara re lati se Hajj ninu awon osu naa, ko gbodo si oorun ife, ese dida ati ariyanjiyan ninu ise Hajj. Ohunkohun ti e ba se ni rere, Allahu mo on. E mu ese irin-ajo lowo. Dajudaju ese irin-ajo t’o loore julo ni isora (nibi ese elomiiran ati agbe sise l’asiko ise Hajj). E beru Mi, eyin onilaakaye

لَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَن تَبْتَغُوا فَضْلًا مِّن رَّبِّكُمْ ۚ فَإِذَا أَفَضْتُم مِّنْ عَرَفَاتٍ فَاذْكُرُوا اللَّهَ عِندَ الْمَشْعَرِ الْحَرَامِ ۖ وَاذْكُرُوهُ كَمَا هَدَاكُمْ وَإِن كُنتُم مِّن قَبْلِهِ لَمِنَ الضَّالِّينَ(198)

 Ko si ibawi fun yin (nibi owo sise l’asiko ise hajj) pe ki e wa oore kan lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ti e ba n dari bo lati ‘Arafah, e se iranti Allahu ni aye alapon-onle (Muzdalifah). E se iranti Re gege bi O se fi ona mo yin, bi o tile je pe teletele e wa ninu awon olusina

ثُمَّ أَفِيضُوا مِنْ حَيْثُ أَفَاضَ النَّاسُ وَاسْتَغْفِرُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(199)

 Leyin naa, e da lo si ibi ti awon eniyan ba da lo (ninu ise Hajj), ki e si toro aforijin Allahu. Dajudaju, Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

فَإِذَا قَضَيْتُم مَّنَاسِكَكُمْ فَاذْكُرُوا اللَّهَ كَذِكْرِكُمْ آبَاءَكُمْ أَوْ أَشَدَّ ذِكْرًا ۗ فَمِنَ النَّاسِ مَن يَقُولُ رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا وَمَا لَهُ فِي الْآخِرَةِ مِنْ خَلَاقٍ(200)

 Nigba ti e ba pari ijosin (Hajj) yin, e seranti Allahu gege bi e se n seranti awon baba nla yin. Tabi ki iranti naa lagbara ju bee lo. Nitori naa, o n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “Oluwa wa, fun wa ni oore aye.” Ko si nii si ipin oore kan fun un ni orun

وَمِنْهُم مَّن يَقُولُ رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الْآخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ(201)

 O si n be ninu won, eni t’o n so pe: "Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye ati oore ni orun, ki O si so wa nibi iya Ina

أُولَٰئِكَ لَهُمْ نَصِيبٌ مِّمَّا كَسَبُوا ۚ وَاللَّهُ سَرِيعُ الْحِسَابِ(202)

 Awon wonyen, tiwon ni ipin oore nipa ohun ti won se nise. Allahu si ni Oluyara nibi isiro-ise

۞ وَاذْكُرُوا اللَّهَ فِي أَيَّامٍ مَّعْدُودَاتٍ ۚ فَمَن تَعَجَّلَ فِي يَوْمَيْنِ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ وَمَن تَأَخَّرَ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ ۚ لِمَنِ اتَّقَىٰ ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(203)

 E seranti Allahu laaarin awon ojo t’o ni onka. Nitori naa, eni ti o ba kanju (se e) fun ojo meji, ko si ese fun un. Eni ti o ba keyin (ti o duro di ojo keta), ko si ese fun un fun eni ti o ba sora (fun iwa ese). E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju won yoo ko yin jo si odo Re

وَمِنَ النَّاسِ مَن يُعْجِبُكَ قَوْلُهُ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَيُشْهِدُ اللَّهَ عَلَىٰ مَا فِي قَلْبِهِ وَهُوَ أَلَدُّ الْخِصَامِ(204)

 O n be ninu awon eniyan, eni ti oro (enu) re yo maa se o ni kayefi ninu isemi aye yii, ti yo si maa fi Allahu jerii si ohun ti n be ninu okan re (pe ko si ija), onija t’o le julo si ni

وَإِذَا تَوَلَّىٰ سَعَىٰ فِي الْأَرْضِ لِيُفْسِدَ فِيهَا وَيُهْلِكَ الْحَرْثَ وَالنَّسْلَ ۗ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ الْفَسَادَ(205)

 Nigba ti o ba si yise pada, o maa sise kiri lori ile nitori ki o le sebaje sori ile, ki o si le pa nnkan oko ati eran-osin run. Allahu ko si feran ibaje

وَإِذَا قِيلَ لَهُ اتَّقِ اللَّهَ أَخَذَتْهُ الْعِزَّةُ بِالْإِثْمِ ۚ فَحَسْبُهُ جَهَنَّمُ ۚ وَلَبِئْسَ الْمِهَادُ(206)

 Ati pe nigba ti won ba so fun un pe: “Beru Allahu.” Igberaga si maa mu un dese. Nitori naa, ina Jahanamo yoo to o (ni esan). Ibugbe naa si buru

وَمِنَ النَّاسِ مَن يَشْرِي نَفْسَهُ ابْتِغَاءَ مَرْضَاتِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ رَءُوفٌ بِالْعِبَادِ(207)

 O n be ninu awon eniyan, eni t’o n ta emi ara re lati wa iyonu Allahu. Allahu si ni Alaaanu fun awon erusin (Re)

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا ادْخُلُوا فِي السِّلْمِ كَافَّةً وَلَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ(208)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ko s’inu esin ’Islam patapata. Eyin ko si gbodo tele oju-ese Esu. Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

فَإِن زَلَلْتُم مِّن بَعْدِ مَا جَاءَتْكُمُ الْبَيِّنَاتُ فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(209)

 Nitori naa, ti ese yin ba ye (kuro ninu ’Islam) leyin ti awon eri t’o yanju ti de ba yin, ki e mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا أَن يَأْتِيَهُمُ اللَّهُ فِي ظُلَلٍ مِّنَ الْغَمَامِ وَالْمَلَائِكَةُ وَقُضِيَ الْأَمْرُ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ(210)

 Se won n reti kini kan bi ko se pe ki Allahu wa ba won ninu iboji esujo, awon molaika naa (si maa wa, nigba naa) A o si yanju oro (isiro ise eda)! Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

سَلْ بَنِي إِسْرَائِيلَ كَمْ آتَيْنَاهُم مِّنْ آيَةٍ بَيِّنَةٍ ۗ وَمَن يُبَدِّلْ نِعْمَةَ اللَّهِ مِن بَعْدِ مَا جَاءَتْهُ فَإِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ(211)

 Bi awon omo ’Isro’il leere pe: “Meloo ni A ti fun won ninu ayah t’o yanju?” Enikeni ti o ba (fi aigbagbo) jiro idera Allahu leyin ti o de ba a, dajudaju Allahu le (nibi) iya

زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا وَيَسْخَرُونَ مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا ۘ وَالَّذِينَ اتَّقَوْا فَوْقَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ وَاللَّهُ يَرْزُقُ مَن يَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ(212)

 Won se isemi aye ni oso (etan) fun awon alaigbagbo. (Ti aye ba si ye won tan,) won yo maa fi awon t’o gbagbo ni ododo se yeye. Awon t’o si beru Allahu maa wa l’oke won ni Ojo Ajinde. Ati pe Allahu n pese arisiki fun eni ti O ba fe lai la isiro lo

كَانَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً فَبَعَثَ اللَّهُ النَّبِيِّينَ مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ وَأَنزَلَ مَعَهُمُ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ لِيَحْكُمَ بَيْنَ النَّاسِ فِيمَا اخْتَلَفُوا فِيهِ ۚ وَمَا اخْتَلَفَ فِيهِ إِلَّا الَّذِينَ أُوتُوهُ مِن بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ ۖ فَهَدَى اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا لِمَا اخْتَلَفُوا فِيهِ مِنَ الْحَقِّ بِإِذْنِهِ ۗ وَاللَّهُ يَهْدِي مَن يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ(213)

 Awon eniyan je ijo kan soso (elesin ’Islam nipile). Allahu si gbe awon Anabi dide ni oniroo idunnu ati olukilo. O so Tira kale fun won pelu ododo nitori ki O le fi se idajo laaarin awon eniyan nipa ohun ti won yapa enu si. Ko si si eni t’o yapa enu (si ’Islam) afi awon ti A fun ni Tira, leyin ti awon eri t’o yanju de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Nitori naa, Allahu to awon t’o gbagbo ni ododo sona pelu iyonda Re nipa ohun ti awon olote1 yapa enu si nipa ododo (’Islam). Allahu yo maa to eni ti O ba fe si ona taara

أَمْ حَسِبْتُمْ أَن تَدْخُلُوا الْجَنَّةَ وَلَمَّا يَأْتِكُم مَّثَلُ الَّذِينَ خَلَوْا مِن قَبْلِكُم ۖ مَّسَّتْهُمُ الْبَأْسَاءُ وَالضَّرَّاءُ وَزُلْزِلُوا حَتَّىٰ يَقُولَ الرَّسُولُ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ مَتَىٰ نَصْرُ اللَّهِ ۗ أَلَا إِنَّ نَصْرَ اللَّهِ قَرِيبٌ(214)

 Tabi e lero pe e maa wo inu Ogba Idera nigba ti irufe (adanwo) t’o kan awon t’o ti lo siwaju yin ko ti i kan yin? Iponju ati ailera mu won. Won si ri amiwo to bee ge ti Ojise ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re fi so pe: “Igba wo ni aranse Allahu maa de se?” Kiye si i! Dajudaju aranse Allahu sunmo

يَسْأَلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَ ۖ قُلْ مَا أَنفَقْتُم مِّنْ خَيْرٍ فَلِلْوَالِدَيْنِ وَالْأَقْرَبِينَ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَابْنِ السَّبِيلِ ۗ وَمَا تَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ اللَّهَ بِهِ عَلِيمٌ(215)

 Won n bi o leere pe ki ni awon yo maa nawo si. So pe: "Ohun ti e ba na ninu ohun rere, ki o maa je ti awon obi mejeeji, awon ebi, awon omo orukan, awon mekunnu ati onirin-ajo (ti agara da). Ohunkohun ti e ba se ninu ohun rere, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re

كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِتَالُ وَهُوَ كُرْهٌ لَّكُمْ ۖ وَعَسَىٰ أَن تَكْرَهُوا شَيْئًا وَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ ۖ وَعَسَىٰ أَن تُحِبُّوا شَيْئًا وَهُوَ شَرٌّ لَّكُمْ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ(216)

 A se ogun esin ni oran-anyan le yin lori, ohun ikorira si ni fun yin. O si le je pe e korira kini kan, ki ohun naa si je oore fun yin. O si tun le je pe e nifee si kini kan, ki ohun naa si je aburu fun yin. Allahu nimo, eyin ko si nimo

يَسْأَلُونَكَ عَنِ الشَّهْرِ الْحَرَامِ قِتَالٍ فِيهِ ۖ قُلْ قِتَالٌ فِيهِ كَبِيرٌ ۖ وَصَدٌّ عَن سَبِيلِ اللَّهِ وَكُفْرٌ بِهِ وَالْمَسْجِدِ الْحَرَامِ وَإِخْرَاجُ أَهْلِهِ مِنْهُ أَكْبَرُ عِندَ اللَّهِ ۚ وَالْفِتْنَةُ أَكْبَرُ مِنَ الْقَتْلِ ۗ وَلَا يَزَالُونَ يُقَاتِلُونَكُمْ حَتَّىٰ يَرُدُّوكُمْ عَن دِينِكُمْ إِنِ اسْتَطَاعُوا ۚ وَمَن يَرْتَدِدْ مِنكُمْ عَن دِينِهِ فَيَمُتْ وَهُوَ كَافِرٌ فَأُولَٰئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(217)

 Won n bi o leere nipa ogun jija ninu osu owo. So pe: "Ese nla ni ogun jija ninu re. Ati pe siseri awon eniyan kuro l’oju ona (esin) Allahu, sise aigbagbo ninu Allahu, didi awon musulumi lowo lati wo inu Mosalasi Haram ati lile awon musulumi jade kuro ninu re, (iwonyi) tun tobi julo ni ese ni odo Allahu." Ifooro si buru ju ipaniyan lo. Won ko ni yee gbogun ti yin titi won yo fi se yin lori kuro ninu esin yin, ti won ba lagbara (ona lati se bee). Enikeni ninu yin ti o ba seri kuroninu esin re, ti o si ku si ipo keferi, nitori naa awon wonyen ni awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ هَاجَرُوا وَجَاهَدُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ أُولَٰئِكَ يَرْجُونَ رَحْمَتَ اللَّهِ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(218)

 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, awon t’o gbe ilu (won) ju sile ati awon t’o jagun fun esin Allahu, awon wonyen n reti ike Allahu. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

۞ يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ ۖ قُلْ فِيهِمَا إِثْمٌ كَبِيرٌ وَمَنَافِعُ لِلنَّاسِ وَإِثْمُهُمَا أَكْبَرُ مِن نَّفْعِهِمَا ۗ وَيَسْأَلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَ قُلِ الْعَفْوَ ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَتَفَكَّرُونَ(219)

 Won n bi o leere nipa oti ati tete. So pe: "Ese nla ati awon anfaani kan wa ninu mejeeji fun awon eniyan. Ese mejeeji si tobi ju anfaani won lo." Won tun n bi o leere pe ki ni awon yo maa na ni saraa. So pe: “Ohun ti o ba seku leyin ti e ba ti gbo bukata inu ile tan (ni ki e fi se saraa).” Bayen ni Allahu se n s’alaye awon ayah fun yin nitori ki e le ronu jinle

فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۗ وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْيَتَامَىٰ ۖ قُلْ إِصْلَاحٌ لَّهُمْ خَيْرٌ ۖ وَإِن تُخَالِطُوهُمْ فَإِخْوَانُكُمْ ۚ وَاللَّهُ يَعْلَمُ الْمُفْسِدَ مِنَ الْمُصْلِحِ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَأَعْنَتَكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(220)

 nipa aye ati orun. Won n bi o leere nipa awon omo orukan. So pe: "Sise atunse dukia won (lai nii da a po mo dukia yin) l’o dara julo. Ti e ba si da a po mo dukia yin, omo iya yin (ninu esin) kuku ni won. Allahu si mo obileje yato si alatun-unse. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe (ki e ya dukia won si oto nikan ni) iba ko inira ba yin. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

وَلَا تَنكِحُوا الْمُشْرِكَاتِ حَتَّىٰ يُؤْمِنَّ ۚ وَلَأَمَةٌ مُّؤْمِنَةٌ خَيْرٌ مِّن مُّشْرِكَةٍ وَلَوْ أَعْجَبَتْكُمْ ۗ وَلَا تُنكِحُوا الْمُشْرِكِينَ حَتَّىٰ يُؤْمِنُوا ۚ وَلَعَبْدٌ مُّؤْمِنٌ خَيْرٌ مِّن مُّشْرِكٍ وَلَوْ أَعْجَبَكُمْ ۗ أُولَٰئِكَ يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَاللَّهُ يَدْعُو إِلَى الْجَنَّةِ وَالْمَغْفِرَةِ بِإِذْنِهِ ۖ وَيُبَيِّنُ آيَاتِهِ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ(221)

 E ma fi awon aborisa lobinrin saya titi won yo fi gbagbo ni ododo. Dajudaju erubinrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lobinrin, koda ki aborisa lobinrin jo yin loju. E ma si fi onigbagbo ododo lobinrin fun awon aborisa lokunrin titi won yo fi gbagbo ni ododo. Erukunrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lokunrin, koda ki aborisa lokunrin jo yin loju. Awon (aborisa) wonyen n pepe sinu Ina. Allahu si n pepe sinu Ogba Idera ati aforijin pelu iyonda Re. O si n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le lo iranti

وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْمَحِيضِ ۖ قُلْ هُوَ أَذًى فَاعْتَزِلُوا النِّسَاءَ فِي الْمَحِيضِ ۖ وَلَا تَقْرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطْهُرْنَ ۖ فَإِذَا تَطَهَّرْنَ فَأْتُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ أَمَرَكُمُ اللَّهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ التَّوَّابِينَ وَيُحِبُّ الْمُتَطَهِّرِينَ(222)

 Won si n bi o leere nipa nnkan osu (obinrin). So pe: “Inira ni (sisunmo won lasiko naa). Nitori naa, e yera fun awon obinrin l’asiko nnkan osu. E ma se sunmo won (fun oorun ife) titi won yo fi se imora. Ti won ba si ti se imora, e sunmo won ni aye ti Allahu pa lase fun yin. Dajudaju Allahu nifee awon oluronu-piwada. O si nifee awon olumora

نِسَاؤُكُمْ حَرْثٌ لَّكُمْ فَأْتُوا حَرْثَكُمْ أَنَّىٰ شِئْتُمْ ۖ وَقَدِّمُوا لِأَنفُسِكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّكُم مُّلَاقُوهُ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ(223)

 Awon obinrin yin, oko ni won fun yin. E lo s’inu oko yin bi e ba se fe, ki e si ti (ise rere) siwaju fun emi ara yin. E beru Allahu. Ki e mo pe dajudaju e maa pade Re. Ki o si fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu

وَلَا تَجْعَلُوا اللَّهَ عُرْضَةً لِّأَيْمَانِكُمْ أَن تَبَرُّوا وَتَتَّقُوا وَتُصْلِحُوا بَيْنَ النَّاسِ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(224)

 E ma se fi Allahu se ikewo fun ibura yin pe e o nii se rere, e o nii sora (nibi iwa ese), e o si nii se atunse laaarin awon eniyan. Allahu ni Olugbo, Onimo

لَّا يُؤَاخِذُكُمُ اللَّهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا كَسَبَتْ قُلُوبُكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٌ(225)

 Allahu ko nii fi ibura yin ti ko ti inu yin wa bi yin, sugbon O maa fi ohun ti o ba t’inu okan yin wa bi yin. Allahu ni Alaforijin, Alafarada

لِّلَّذِينَ يُؤْلُونَ مِن نِّسَائِهِمْ تَرَبُّصُ أَرْبَعَةِ أَشْهُرٍ ۖ فَإِن فَاءُوا فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ(226)

 Ikoraro fun osu merin wa fun awon t’o bura pe awon ko nii sunmo obinrin won. Ti won ba seri pada (laaarin igba naa), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

وَإِنْ عَزَمُوا الطَّلَاقَ فَإِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(227)

 Ti won ba si pinnu ikosile, (ki won ko won sile.) Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

وَالْمُطَلَّقَاتُ يَتَرَبَّصْنَ بِأَنفُسِهِنَّ ثَلَاثَةَ قُرُوءٍ ۚ وَلَا يَحِلُّ لَهُنَّ أَن يَكْتُمْنَ مَا خَلَقَ اللَّهُ فِي أَرْحَامِهِنَّ إِن كُنَّ يُؤْمِنَّ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۚ وَبُعُولَتُهُنَّ أَحَقُّ بِرَدِّهِنَّ فِي ذَٰلِكَ إِنْ أَرَادُوا إِصْلَاحًا ۚ وَلَهُنَّ مِثْلُ الَّذِي عَلَيْهِنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ وَلِلرِّجَالِ عَلَيْهِنَّ دَرَجَةٌ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(228)

 Awon obinrin ti won ko sile maa kora ro fun nnkan osu meta. Ko si letoo fun won lati fi ohun ti Allahu s’eda (re) s’inu apo-omo won pamo, ti won ba je eni to gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Awon oko won ni eto si dida won pada l’aaarin (asiko) yen, ti won ba gbero atunse. Awon iyawo ni eto l’odo oko won gege bi iru eyi ti awon oko won ni l’odo won lona t’o dara. Ipo ajulo tun wa fun awon okunrin lori won. Allahu ni Alagbara, Ologbon

الطَّلَاقُ مَرَّتَانِ ۖ فَإِمْسَاكٌ بِمَعْرُوفٍ أَوْ تَسْرِيحٌ بِإِحْسَانٍ ۗ وَلَا يَحِلُّ لَكُمْ أَن تَأْخُذُوا مِمَّا آتَيْتُمُوهُنَّ شَيْئًا إِلَّا أَن يَخَافَا أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ اللَّهِ ۖ فَإِنْ خِفْتُمْ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ اللَّهِ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَا فِيمَا افْتَدَتْ بِهِ ۗ تِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ فَلَا تَعْتَدُوهَا ۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ اللَّهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ(229)

 Ee meji ni ikosile. Nitori naa, e mu won mora pelu daadaa tabi ki e fi won sile pelu daadaa. Ko si letoo fun yin lati gba kini kan ninu ohun ti e ti fun won ayafi ti awon mejeeji ba n paya pe awon ko nii le so awon enu-ala (ofin) Allahu (laaarin ara won). Nitori naa, ti e ba n paya pe awon mejeeji ko nii le so awon enu-ala (ofin) Allahu, ko si ese fun won nigba naa nipa ohun ti obinrin ba fi serapada (emi ara re) Iwonyi ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale. Nitori naa, e ma se tayo re. Enikeni ti o ba tayo awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale, awon wonyen ni alabosi

فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا تَحِلُّ لَهُ مِن بَعْدُ حَتَّىٰ تَنكِحَ زَوْجًا غَيْرَهُ ۗ فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَا أَن يَتَرَاجَعَا إِن ظَنَّا أَن يُقِيمَا حُدُودَ اللَّهِ ۗ وَتِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ يُبَيِّنُهَا لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ(230)

 Nitori naa, ti oko ba ko o (ni ee keta), obinrin naa ko letoo si i mo leyin naa titi obinrin naa yo fi fe elomiiran. Ti eni naa ba tun ko o sile, ko si ese fun awon mejeeji nigba naa lati pada si odo ara won, ti awon mejeeji ba ti lero pe awon maa so awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbekale. Iwonyen ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbekale (fun won), ti O n salaye re fun ijo t’o nimo

وَإِذَا طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ فَبَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمْسِكُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ أَوْ سَرِّحُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ ۚ وَلَا تُمْسِكُوهُنَّ ضِرَارًا لِّتَعْتَدُوا ۚ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَقَدْ ظَلَمَ نَفْسَهُ ۚ وَلَا تَتَّخِذُوا آيَاتِ اللَّهِ هُزُوًا ۚ وَاذْكُرُوا نِعْمَتَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَمَا أَنزَلَ عَلَيْكُم مِّنَ الْكِتَابِ وَالْحِكْمَةِ يَعِظُكُم بِهِ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(231)

 Nigba ti e ba ko awon obinrin sile (ni ee kini tabi ee keji), ti asiko (opo) won sunmo ko pari, e le mu won mora pelu daadaa tabi ki e tu won sile (ni ipari opo won) pelu daadaa. E ma se mu won mora ni ona inira lati le tayo enu-ala. Enikeni ti o ba se iyen, o kuku ti sabosi si emi ara re. E ma se so awon ayah Allahu di nnkan yeye. E ranti idera Allahu lori yin ati ohun ti O sokale fun yin ninu Tira ati oye ijinle (iyen, sunnah Anabi s.a.w.), ti O n fi se isiti fun yin. E beru Allahu, ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

وَإِذَا طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ فَبَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا تَعْضُلُوهُنَّ أَن يَنكِحْنَ أَزْوَاجَهُنَّ إِذَا تَرَاضَوْا بَيْنَهُم بِالْمَعْرُوفِ ۗ ذَٰلِكَ يُوعَظُ بِهِ مَن كَانَ مِنكُمْ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۗ ذَٰلِكُمْ أَزْكَىٰ لَكُمْ وَأَطْهَرُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ(232)

 Nigba ti e ba ko awon obinrin sile (ni ee kini tabi ee keji), ti won si pari asiko (opo) won, e ma se di won lowo lati fe oko won, nigba ti won ba jo yonu sira won (ti won si gba) ona to dara . Iyen ni A n fi se waasi fun enikeni ninu yin, t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Iyen l’o fo yin mo julo. O si tun safomo (okan yin) julo. Allahu nimo, eyin ko si nimo

۞ وَالْوَالِدَاتُ يُرْضِعْنَ أَوْلَادَهُنَّ حَوْلَيْنِ كَامِلَيْنِ ۖ لِمَنْ أَرَادَ أَن يُتِمَّ الرَّضَاعَةَ ۚ وَعَلَى الْمَوْلُودِ لَهُ رِزْقُهُنَّ وَكِسْوَتُهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ لَا تُكَلَّفُ نَفْسٌ إِلَّا وُسْعَهَا ۚ لَا تُضَارَّ وَالِدَةٌ بِوَلَدِهَا وَلَا مَوْلُودٌ لَّهُ بِوَلَدِهِ ۚ وَعَلَى الْوَارِثِ مِثْلُ ذَٰلِكَ ۗ فَإِنْ أَرَادَا فِصَالًا عَن تَرَاضٍ مِّنْهُمَا وَتَشَاوُرٍ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَا ۗ وَإِنْ أَرَدتُّمْ أَن تَسْتَرْضِعُوا أَوْلَادَكُمْ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِذَا سَلَّمْتُم مَّا آتَيْتُم بِالْمَعْرُوفِ ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(233)

 Awon abiyamo yoo maa fun awon omo won ni oyan mu fun odun meji gbako, fun eni ti o ba fe pari (asiko) ifomoloyan. Ojuse ni fun eni ti won bimo fun lati maa se (eto) ije-imu won ati aso won ni ona t’o dara. Won ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Won ko nii ko inira ba abiyamo nitori omo re. Won ko si nii ko inira ba eni ti won bimo fun nitori omo re. Iru (ojuse) yen tun n be fun olujogun. Ti awon mejeeji ba si fe gba oyan l’enu omo pelu ipanupo ati asaro awon mejeeji, ko si ese fun awon mejeeji. Ti e ba si fe gba eni ti o maa fun awon omo yin loyan mu, ko si ese fun yin, ti e ba ti fun won ni ohun ti e fe fun won (ni owo-oya) ni ona t’o dara. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

وَالَّذِينَ يُتَوَفَّوْنَ مِنكُمْ وَيَذَرُونَ أَزْوَاجًا يَتَرَبَّصْنَ بِأَنفُسِهِنَّ أَرْبَعَةَ أَشْهُرٍ وَعَشْرًا ۖ فَإِذَا بَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا فَعَلْنَ فِي أَنفُسِهِنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ(234)

 Awon ti oko won ku ninu yin, ti won si fi awon iyawo sile, won yoo kora ro fun osu merin ati ojo mewaa. Nigba ti won ba pari asiko (opo) won, ko si ese fun yin nipa ohun ti won ba se funra won (lati ni oko miiran) ni ona t’o dara. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا عَرَّضْتُم بِهِ مِنْ خِطْبَةِ النِّسَاءِ أَوْ أَكْنَنتُمْ فِي أَنفُسِكُمْ ۚ عَلِمَ اللَّهُ أَنَّكُمْ سَتَذْكُرُونَهُنَّ وَلَٰكِن لَّا تُوَاعِدُوهُنَّ سِرًّا إِلَّا أَن تَقُولُوا قَوْلًا مَّعْرُوفًا ۚ وَلَا تَعْزِمُوا عُقْدَةَ النِّكَاحِ حَتَّىٰ يَبْلُغَ الْكِتَابُ أَجَلَهُ ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِي أَنفُسِكُمْ فَاحْذَرُوهُ ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٌ(235)

 Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e peso ninu ibanisoro ife tabi ti e fi pamo sinu emi yin. Allahu mo pe dajudaju eyin yo maa ranti won, sugbon e ma se ba won se adehun ni ikoko, ayafi pe ki e maa so oro daadaa. E ma se pinnu ita koko yigi titi asiko (opo) maa fi pari. E mo pe dajudaju Allahu mo ohun ti n be ninu emi yin, nitori naa, e beru Re. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alafarada

لَّا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِن طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ مَا لَمْ تَمَسُّوهُنَّ أَوْ تَفْرِضُوا لَهُنَّ فَرِيضَةً ۚ وَمَتِّعُوهُنَّ عَلَى الْمُوسِعِ قَدَرُهُ وَعَلَى الْمُقْتِرِ قَدَرُهُ مَتَاعًا بِالْمَعْرُوفِ ۖ حَقًّا عَلَى الْمُحْسِنِينَ(236)

 Ko si ese fun yin, ti e ba ko awon obinrin sile, lai ti i sunmo won tabi lai ti i so odiwon sodaaki kan fun won ni pato. Ki e si fun won ni ebun (ikosile); ki olugbooro (ninu arisiki) fi iwon (agbara) re sile, ki talika si fi iwon (agbara) re sile ni ona t’o dara. Ojuse l’o je fun awon oluse-rere

وَإِن طَلَّقْتُمُوهُنَّ مِن قَبْلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ وَقَدْ فَرَضْتُمْ لَهُنَّ فَرِيضَةً فَنِصْفُ مَا فَرَضْتُمْ إِلَّا أَن يَعْفُونَ أَوْ يَعْفُوَ الَّذِي بِيَدِهِ عُقْدَةُ النِّكَاحِ ۚ وَأَن تَعْفُوا أَقْرَبُ لِلتَّقْوَىٰ ۚ وَلَا تَنسَوُا الْفَضْلَ بَيْنَكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(237)

 Ti e ba si ko won sile siwaju ki e to sunmo won, ti e si ti so odiwon sodaaki kan fun won, ilaji ohun ti e ti sodiwon re ni sodaaki (ni ki e fun won), afi ti won ba samoju kuro (fun gbogbo re, iyen awon obinrin) tabi ti eni ti koko yigi n be ni owo re ba samoju kuro (fun gbogbo re, iyen awon oko). Ki e samoju kuro lo sunmo iberu Allahu julo. E ma se gbagbe oore ajulo aarin yin. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

حَافِظُوا عَلَى الصَّلَوَاتِ وَالصَّلَاةِ الْوُسْطَىٰ وَقُومُوا لِلَّهِ قَانِتِينَ(238)

 E so awon irun (wakati maraarun) ati (ni paapaa julo) irun aarin. Ki e si duro (kirun gege bi) oluteriba fun Allahu, lai nii soro (miiran lori irun)

فَإِنْ خِفْتُمْ فَرِجَالًا أَوْ رُكْبَانًا ۖ فَإِذَا أَمِنتُمْ فَاذْكُرُوا اللَّهَ كَمَا عَلَّمَكُم مَّا لَمْ تَكُونُوا تَعْلَمُونَ(239)

 Sugbon ti e ba n beru (ota l’oju ogun esin), e kirun yin lori irin (ese) tabi lori nnkan igun. Nigba ti okan yin ba si bale, e kirun fun Allahu gege bi O se fi ohun ti eyin ko mo (tele) mo yin

وَالَّذِينَ يُتَوَفَّوْنَ مِنكُمْ وَيَذَرُونَ أَزْوَاجًا وَصِيَّةً لِّأَزْوَاجِهِم مَّتَاعًا إِلَى الْحَوْلِ غَيْرَ إِخْرَاجٍ ۚ فَإِنْ خَرَجْنَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِي مَا فَعَلْنَ فِي أَنفُسِهِنَّ مِن مَّعْرُوفٍ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(240)

 Awon ti won ku ninu yin, ti won si fi awon iyawo saye lo, ki won se asoole ije-imu odun kan fun awon iyawo won, lai si nii le won jade kuro ninu ile won. Ti won ba si jade (funra won leyin ijade opo), ko si ese fun yin nipa ohun ti won ba fi’ra won se ni daadaa (lati ni oko miiran). Allahu ni Alagbara, Ologbon

وَلِلْمُطَلَّقَاتِ مَتَاعٌ بِالْمَعْرُوفِ ۖ حَقًّا عَلَى الْمُتَّقِينَ(241)

 Nnkan igbadun ni ona t’o dara tun maa wa fun awon obinrin ti won kosile. Ojuse l’o je fun awon oluberu Allahu

كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ(242)

 Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le se laakaye

۞ أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ خَرَجُوا مِن دِيَارِهِمْ وَهُمْ أُلُوفٌ حَذَرَ الْمَوْتِ فَقَالَ لَهُمُ اللَّهُ مُوتُوا ثُمَّ أَحْيَاهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ(243)

 Se o o ri awon t’o jade lati inu ile won legbeegberun nitori iberu iku! Allahu si so fun won pe: “E ku.” Leyin naa, O so won di alaaye. Dajudaju Allahu ni Oloore-ajulo lori awon eniyan, sugbon opolopo eniyan ko dupe (fun Un)

وَقَاتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(244)

 E jagun fun aabo esin Allahu, ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

مَّن ذَا الَّذِي يُقْرِضُ اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا فَيُضَاعِفَهُ لَهُ أَضْعَافًا كَثِيرَةً ۚ وَاللَّهُ يَقْبِضُ وَيَبْسُطُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ(245)

 Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, ki Allahu si se adipele (esan) fun un ni adipele pupo? Allahu n ka oro nile, O si n te e sile. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

أَلَمْ تَرَ إِلَى الْمَلَإِ مِن بَنِي إِسْرَائِيلَ مِن بَعْدِ مُوسَىٰ إِذْ قَالُوا لِنَبِيٍّ لَّهُمُ ابْعَثْ لَنَا مَلِكًا نُّقَاتِلْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۖ قَالَ هَلْ عَسَيْتُمْ إِن كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِتَالُ أَلَّا تُقَاتِلُوا ۖ قَالُوا وَمَا لَنَا أَلَّا نُقَاتِلَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَقَدْ أُخْرِجْنَا مِن دِيَارِنَا وَأَبْنَائِنَا ۖ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيْهِمُ الْقِتَالُ تَوَلَّوْا إِلَّا قَلِيلًا مِّنْهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ(246)

 Se o o ri awon asiwaju ninu awon omo ’Isro’il, leyin (igba Anabi) Musa? Nigba ti won wi fun Anabi tiwon pe: “Yan oba kan fun wa, ki a lo jagun fun aabo esin Allahu.” O so pe: “Sebi o se e se pe ti Won ba se ogun jija ni oran-anyan le yin lori tan e o kuku nii jagun?” Won wi pe: "Ki ni o maa di wa lowo lati jagun fun aabo esin Allahu? Won kuku ti le awa ati awon omo wa jade kuro ninu ile wa!" Amo nigba ti A se ogun esin ni oran-anyan le won lori tan, won peyin da afi die ninu won. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi

وَقَالَ لَهُمْ نَبِيُّهُمْ إِنَّ اللَّهَ قَدْ بَعَثَ لَكُمْ طَالُوتَ مَلِكًا ۚ قَالُوا أَنَّىٰ يَكُونُ لَهُ الْمُلْكُ عَلَيْنَا وَنَحْنُ أَحَقُّ بِالْمُلْكِ مِنْهُ وَلَمْ يُؤْتَ سَعَةً مِّنَ الْمَالِ ۚ قَالَ إِنَّ اللَّهَ اصْطَفَاهُ عَلَيْكُمْ وَزَادَهُ بَسْطَةً فِي الْعِلْمِ وَالْجِسْمِ ۖ وَاللَّهُ يُؤْتِي مُلْكَهُ مَن يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ(247)

 Anabi won so fun won pe: “Dajudaju Allahu ti gbe Tolut dide fun yin ni oba.” Won wi pe: “Bawo ni o se le je oba le wa lori nigba ti o je pe awa ni eto si ipo oba ju u lo? Ko si ni owo pupo lowo?” O so pe: "Dajudaju Allahu sa a lesa le yin lori. O si fun un ni alekun pupo ninu imo ati okun ara. Allahu n fun eni ti O ba fe ni ijoba Re. Allahu ni Olugbaaye, Onimo

وَقَالَ لَهُمْ نَبِيُّهُمْ إِنَّ آيَةَ مُلْكِهِ أَن يَأْتِيَكُمُ التَّابُوتُ فِيهِ سَكِينَةٌ مِّن رَّبِّكُمْ وَبَقِيَّةٌ مِّمَّا تَرَكَ آلُ مُوسَىٰ وَآلُ هَارُونَ تَحْمِلُهُ الْمَلَائِكَةُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لَّكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(248)

 Anabi won tun so fun won pe: "Dajudaju ami ijoba re ni pe, apoti yoo wa ba yin. Nnkan ifayabale lati odo Oluwa yin ati ohun t’o seku ninu ohun ti awon eniyan (Anabi) Musa ati eniyan (Anabi) Harun fi sile n be ninu apoti naa. Awon molaika maa ru u wa (ba yin). Dajudaju ami wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo

فَلَمَّا فَصَلَ طَالُوتُ بِالْجُنُودِ قَالَ إِنَّ اللَّهَ مُبْتَلِيكُم بِنَهَرٍ فَمَن شَرِبَ مِنْهُ فَلَيْسَ مِنِّي وَمَن لَّمْ يَطْعَمْهُ فَإِنَّهُ مِنِّي إِلَّا مَنِ اغْتَرَفَ غُرْفَةً بِيَدِهِ ۚ فَشَرِبُوا مِنْهُ إِلَّا قَلِيلًا مِّنْهُمْ ۚ فَلَمَّا جَاوَزَهُ هُوَ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ قَالُوا لَا طَاقَةَ لَنَا الْيَوْمَ بِجَالُوتَ وَجُنُودِهِ ۚ قَالَ الَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُم مُّلَاقُو اللَّهِ كَم مِّن فِئَةٍ قَلِيلَةٍ غَلَبَتْ فِئَةً كَثِيرَةً بِإِذْنِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ مَعَ الصَّابِرِينَ(249)

 Nigba ti Tolut jade pelu awon omo ogun, o so pe: “Dajudaju Allahu maa fi odo kan dan yin wo. Nitori naa, enikeni ti o ba mu ninu re, ki i se eni mi. Eni ti ko ba to o wo dajudaju oun ni eni mi, ayafi eni ti o ba bu iwon ekunwo re kan mu.” (Sugbon) won mu ninu re afi die ninu won. Nigba ti oun ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re soda odo naa, won so pe: “Ko si agbara kan fun wa lonii ti a le fi k’oju Jalut ati awon omo ogun re.” Awon t’o mo pe dajudaju awon maa pade Allahu, won so pe: "Meloo meloo ninu awon ijo (ogun) kekere t’o ti segun ijo (ogun) pupo pelu iyonda Allahu. Allahu n be pelu awon onisuuru

وَلَمَّا بَرَزُوا لِجَالُوتَ وَجُنُودِهِ قَالُوا رَبَّنَا أَفْرِغْ عَلَيْنَا صَبْرًا وَثَبِّتْ أَقْدَامَنَا وَانصُرْنَا عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ(250)

 Nigba ti won jade si Jalut ati awon omo ogun re, won so pe: "Oluwa wa, fun wa ni omi suuru mu, fi ese wa rinle sinsin, ki O si ran wa lowo lori ijo alaigbagbo

فَهَزَمُوهُم بِإِذْنِ اللَّهِ وَقَتَلَ دَاوُودُ جَالُوتَ وَآتَاهُ اللَّهُ الْمُلْكَ وَالْحِكْمَةَ وَعَلَّمَهُ مِمَّا يَشَاءُ ۗ وَلَوْلَا دَفْعُ اللَّهِ النَّاسَ بَعْضَهُم بِبَعْضٍ لَّفَسَدَتِ الْأَرْضُ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ ذُو فَضْلٍ عَلَى الْعَالَمِينَ(251)

 Won si segun won pelu iyonda Allahu. Dawud si pa Jalut. Allahu si fun un ni ijoba ati ogbon. O tun fi imo mo on ninu ohun ti O ba fe. Ti ko ba je pe Allahu n dena (aburu) fun awon eniyan ni, ti O n fi apa kan won dena (aburu) fun apa kan, ori ile iba ti baje. Sugbon Allahu ni Oloore ajulo lori gbogbo eda

تِلْكَ آيَاتُ اللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِالْحَقِّ ۚ وَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ(252)

 Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Ati pe dajudaju iwo wa lara awon Ojise

۞ تِلْكَ الرُّسُلُ فَضَّلْنَا بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۘ مِّنْهُم مَّن كَلَّمَ اللَّهُ ۖ وَرَفَعَ بَعْضَهُمْ دَرَجَاتٍ ۚ وَآتَيْنَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ الْبَيِّنَاتِ وَأَيَّدْنَاهُ بِرُوحِ الْقُدُسِ ۗ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا اقْتَتَلَ الَّذِينَ مِن بَعْدِهِم مِّن بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ وَلَٰكِنِ اخْتَلَفُوا فَمِنْهُم مَّنْ آمَنَ وَمِنْهُم مَّن كَفَرَ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا اقْتَتَلُوا وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَفْعَلُ مَا يُرِيدُ(253)

 Awon Ojise wonyen, A soore ajulo fun apa kan won lori apa kan. O n be ninu won, eni ti Allahu ba soro (taara). O si se agbega awon ipo fun apa kan won. A fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fi Emi Mimo (iyen, molaika Jibril) ran an lowo. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, awon t’o wa leyin won iba ti bara won ja leyin ti awon eri to yanju ti de ba won. Sugbon won yapa enu (si esin ’Islam). O n be ninu won eni t’o gbagbo ni ododo (ti o je musulumi). O si n be ninu won eni t’o sai gbagbo (ti o di nasara). Ati pe ti Allahu ba fe, won iba ti ba’ra won ja, sugbon Allahu n se ohun ti O ba fe

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَنفِقُوا مِمَّا رَزَقْنَاكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِيَ يَوْمٌ لَّا بَيْعٌ فِيهِ وَلَا خُلَّةٌ وَلَا شَفَاعَةٌ ۗ وَالْكَافِرُونَ هُمُ الظَّالِمُونَ(254)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e na ninu ohun ti A se ni arisiki fun yin siwaju ki ojo kan to de. Ko nii si tita-rira kan ninu re. Ko nii si ololufe kan, ko si nii si isipe kan (fun awon alaigbagbo). Awon alaigbagbo, awon si ni alabosi

اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ ۚ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ ۚ لَّهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ مَن ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِندَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ ۚ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ ۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِّنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ ۚ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ ۖ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا ۚ وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ(255)

 Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuuto-eda. Oogbe ki i ta A. Ati pe oorun ki i kun Un. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ta ni eni ti o maa sipe lodo Re afi pelu iyonda Re? O mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be leyin won. Won ko si ni imo amotan nipa kini kan ninu imo Re afi ohun ti O ba fe (fi mo won). Aga Re gbaaye ju awon sanmo ati ile. Siso sanmo ati ile ko si da A lagara. Allahu ga, O tobi

لَا إِكْرَاهَ فِي الدِّينِ ۖ قَد تَّبَيَّنَ الرُّشْدُ مِنَ الْغَيِّ ۚ فَمَن يَكْفُرْ بِالطَّاغُوتِ وَيُؤْمِن بِاللَّهِ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَىٰ لَا انفِصَامَ لَهَا ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ(256)

 Ko si ijenipa ninu esin. Imona ti foju han kuro ninu isina. Enikeni ti o ba lodi si awon orisa, ti o si ni igbagbo ododo ninu Allahu, o kuku ti dimo okun t’o fokan bale julo, ti ko nii ja. Allahu ni Olugbo, Onimo

اللَّهُ وَلِيُّ الَّذِينَ آمَنُوا يُخْرِجُهُم مِّنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا أَوْلِيَاؤُهُمُ الطَّاغُوتُ يُخْرِجُونَهُم مِّنَ النُّورِ إِلَى الظُّلُمَاتِ ۗ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(257)

 Allahu ni Alaranse awon t’o gbagbo ni ododo. O n mu won jade kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Awon t’o si sai gbagbo, awon orisa ni alafeyinti won. Awon orisa n mu won jade kuro ninu imole wa sinu awon okunkun. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re

أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِي حَاجَّ إِبْرَاهِيمَ فِي رَبِّهِ أَنْ آتَاهُ اللَّهُ الْمُلْكَ إِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّيَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا أُحْيِي وَأُمِيتُ ۖ قَالَ إِبْرَاهِيمُ فَإِنَّ اللَّهَ يَأْتِي بِالشَّمْسِ مِنَ الْمَشْرِقِ فَأْتِ بِهَا مِنَ الْمَغْرِبِ فَبُهِتَ الَّذِي كَفَرَ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ(258)

 Se o o ri eni t’o ba (Anabi) ’Ibrohim jiyan nipa Oluwa re, nitori pe Allahu fun un ni ijoba? Nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: “Oluwa mi ni Eni ti n so eda di alaaye. O si n so eda di oku.” O wi pe: “Emi naa n so eda di alaaye. Mo si n so eda di oku.” (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Dajudaju Allahu n mu oorun wa lati ibuyo. Mu un wa nigba naa lati ibuwo." Won si pa oro mo eni t’o sai gbagbo lenu. Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

أَوْ كَالَّذِي مَرَّ عَلَىٰ قَرْيَةٍ وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا قَالَ أَنَّىٰ يُحْيِي هَٰذِهِ اللَّهُ بَعْدَ مَوْتِهَا ۖ فَأَمَاتَهُ اللَّهُ مِائَةَ عَامٍ ثُمَّ بَعَثَهُ ۖ قَالَ كَمْ لَبِثْتَ ۖ قَالَ لَبِثْتُ يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ ۖ قَالَ بَل لَّبِثْتَ مِائَةَ عَامٍ فَانظُرْ إِلَىٰ طَعَامِكَ وَشَرَابِكَ لَمْ يَتَسَنَّهْ ۖ وَانظُرْ إِلَىٰ حِمَارِكَ وَلِنَجْعَلَكَ آيَةً لِّلنَّاسِ ۖ وَانظُرْ إِلَى الْعِظَامِ كَيْفَ نُنشِزُهَا ثُمَّ نَكْسُوهَا لَحْمًا ۚ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُ قَالَ أَعْلَمُ أَنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(259)

 Tabi bi eni ti o koja ninu ilu kan nigba ti o ti tu torule-torule re. O so pe: “Bawo ni Allahu yo se so eyi di alaaye leyin iku re!” Allahu si so o di oku fun ogorun-un odun. Leyin naa, O gbe e dide. O so pe: “Igba wo ni o ti wa nibi?” O so pe: “Mo wa nibi fun ojo kan tabi ilaji ojo.” O so pe: “Bee ko, o wa nibi fun ogorun-un odun. Wo ounje re ati omi re, ko yi pada. Tun wo ketekete re, ki A le fi o se ami kan fun awon eniyan. Si tun wo eegun naa bi A o se to won papo mora won. Leyin naa, (wo) bi A o se da eran bo o lara. Nigba ti o foju han si i kedere (bee), o so pe: “Mo mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.”

وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّ أَرِنِي كَيْفَ تُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۖ قَالَ أَوَلَمْ تُؤْمِن ۖ قَالَ بَلَىٰ وَلَٰكِن لِّيَطْمَئِنَّ قَلْبِي ۖ قَالَ فَخُذْ أَرْبَعَةً مِّنَ الطَّيْرِ فَصُرْهُنَّ إِلَيْكَ ثُمَّ اجْعَلْ عَلَىٰ كُلِّ جَبَلٍ مِّنْهُنَّ جُزْءًا ثُمَّ ادْعُهُنَّ يَأْتِينَكَ سَعْيًا ۚ وَاعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ(260)

 Nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Oluwa mi, fi han mi bi Iwo yo se so awon oku di alaaye." (Allahu) so pe: “Se iwo ko gbagbo ni?” O so pe: “Rara, sugbon ki okan mi le bale ni”. (Allahu) so pe: "Mu merin ninu awon eye, ki o so won mole si odo re (ki o pa won, ki o si gun won papo mora won). Leyin naa, fi ipin ninu won sori apata kookan. Leyin naa, pe won. Won maa sare wa ba o. Ki o si mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

مَّثَلُ الَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ كَمَثَلِ حَبَّةٍ أَنبَتَتْ سَبْعَ سَنَابِلَ فِي كُلِّ سُنبُلَةٍ مِّائَةُ حَبَّةٍ ۗ وَاللَّهُ يُضَاعِفُ لِمَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ(261)

 Apejuwe awon t’o n na owo won fun esin Allahu da bi apejuwe koro eso kan ti o hu siri meje jade, ti ogorun-un koro si wa lara siri kookan. Allahu yo se adipele fun eni ti O ba fe. Allahu ni Olugbaaye, Onimo

الَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ثُمَّ لَا يُتْبِعُونَ مَا أَنفَقُوا مَنًّا وَلَا أَذًى ۙ لَّهُمْ أَجْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(262)

 Awon t’o n na owo won fun esin Allahu, ti won ko si fi iregun ati ipalara tele ohun ti won na, esan won n be fun won lodo Oluwa won. Iberu ko nii si fun won. Won ko si nii banuje

۞ قَوْلٌ مَّعْرُوفٌ وَمَغْفِرَةٌ خَيْرٌ مِّن صَدَقَةٍ يَتْبَعُهَا أَذًى ۗ وَاللَّهُ غَنِيٌّ حَلِيمٌ(263)

 Oro rere ati aforijin loore julo si saraa ti ipalara tele. Allahu si ni Oloro, Alafarada

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُبْطِلُوا صَدَقَاتِكُم بِالْمَنِّ وَالْأَذَىٰ كَالَّذِي يُنفِقُ مَالَهُ رِئَاءَ النَّاسِ وَلَا يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۖ فَمَثَلُهُ كَمَثَلِ صَفْوَانٍ عَلَيْهِ تُرَابٌ فَأَصَابَهُ وَابِلٌ فَتَرَكَهُ صَلْدًا ۖ لَّا يَقْدِرُونَ عَلَىٰ شَيْءٍ مِّمَّا كَسَبُوا ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ(264)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se fi iregun ati ipalara ba awon saraa yin je, bi eni ti n na owo re pelu sekarimi, ko si gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Apejuwe re da bi apejuwe apata kan ti erupe n be lori re. Ojo nla ro si i, o si ko erupe kuro lori re patapata. Won ko ni agbara lori kini kan ninu ohun ti won se nise. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo

وَمَثَلُ الَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمْوَالَهُمُ ابْتِغَاءَ مَرْضَاتِ اللَّهِ وَتَثْبِيتًا مِّنْ أَنفُسِهِمْ كَمَثَلِ جَنَّةٍ بِرَبْوَةٍ أَصَابَهَا وَابِلٌ فَآتَتْ أُكُلَهَا ضِعْفَيْنِ فَإِن لَّمْ يُصِبْهَا وَابِلٌ فَطَلٌّ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ(265)

 Apejuwe awon t’o n na owo won lati wa iyonu Allahu ati (nitori) ifeserinle ninu emi won, o da bi apejuwe ogba oko t’o wa lori ile giga kan, ti ojo nla ro si, ti awon eso re si yo jade ni ilopo meji. Ti ojo nla ko ba si ro si i, iri n se si i. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se

أَيَوَدُّ أَحَدُكُمْ أَن تَكُونَ لَهُ جَنَّةٌ مِّن نَّخِيلٍ وَأَعْنَابٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ لَهُ فِيهَا مِن كُلِّ الثَّمَرَاتِ وَأَصَابَهُ الْكِبَرُ وَلَهُ ذُرِّيَّةٌ ضُعَفَاءُ فَأَصَابَهَا إِعْصَارٌ فِيهِ نَارٌ فَاحْتَرَقَتْ ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَتَفَكَّرُونَ(266)

 Nje eni kan ninu yin nifee si ki oun ni ogba oko dabinu ati ajara, ti awon odo n san ni abe re, ti orisirisi eso tun wa fun un ninu re, ki ogbo de ba a, o si ni awon omo weere ti ko lagbara (ise oko sise), ki ategun lile ti ina n be ninu re kolu oko naa, ki o si jona? Bayen ni Allahu se n s’alaye awon ayah naa fun yin nitori ki e le ronu jinle

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَنفِقُوا مِن طَيِّبَاتِ مَا كَسَبْتُمْ وَمِمَّا أَخْرَجْنَا لَكُم مِّنَ الْأَرْضِ ۖ وَلَا تَيَمَّمُوا الْخَبِيثَ مِنْهُ تُنفِقُونَ وَلَسْتُم بِآخِذِيهِ إِلَّا أَن تُغْمِضُوا فِيهِ ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ غَنِيٌّ حَمِيدٌ(267)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e na ninu awon nnkan daadaa ti e se nise ati ninu awon nnkan ti A mu jade fun yin lati inu ile. E ma se gbero lati na ninu eyi ti ko dara. Eyin naa ko nii gba a afi ki e diju gba a. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Oloro, Eleyin

الشَّيْطَانُ يَعِدُكُمُ الْفَقْرَ وَيَأْمُرُكُم بِالْفَحْشَاءِ ۖ وَاللَّهُ يَعِدُكُم مَّغْفِرَةً مِّنْهُ وَفَضْلًا ۗ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ(268)

 Esu n fi osi deru ba yin, o si n pa yin ni ase ibaje sise. Allahu si n se adehun aforijin ati oore ajulo lati odo Re fun yin. Allahu ni Olugbaaye, Onimo

يُؤْتِي الْحِكْمَةَ مَن يَشَاءُ ۚ وَمَن يُؤْتَ الْحِكْمَةَ فَقَدْ أُوتِيَ خَيْرًا كَثِيرًا ۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّا أُولُو الْأَلْبَابِ(269)

 O n fun eni ti O ba fe ni oye ijinle. Eni ti A ba si fun ni oye ijinle, A kuku ti fun un ni oore pupo. Eni kan ko nii lo iranti afi awon onilaakaye

وَمَا أَنفَقْتُم مِّن نَّفَقَةٍ أَوْ نَذَرْتُم مِّن نَّذْرٍ فَإِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُهُ ۗ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ(270)

 Ohunkohun ti e ba na ni inawo tabi (ohunkohun) ti e ba je ni eje, dajudaju Allahu mo on. Ko si nii si oluranlowo kan fun awon alabosi

إِن تُبْدُوا الصَّدَقَاتِ فَنِعِمَّا هِيَ ۖ وَإِن تُخْفُوهَا وَتُؤْتُوهَا الْفُقَرَاءَ فَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ ۚ وَيُكَفِّرُ عَنكُم مِّن سَيِّئَاتِكُمْ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ(271)

 Ti e ba safi han awon saraa, o kuku dara. Ti e ba si fi pamo, ti e lo fun awon alaini, o si dara julo fun yin. Allahu si maa pa awon iwa aidaa yin re fun yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

۞ لَّيْسَ عَلَيْكَ هُدَاهُمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَهْدِي مَن يَشَاءُ ۗ وَمَا تُنفِقُوا مِنْ خَيْرٍ فَلِأَنفُسِكُمْ ۚ وَمَا تُنفِقُونَ إِلَّا ابْتِغَاءَ وَجْهِ اللَّهِ ۚ وَمَا تُنفِقُوا مِنْ خَيْرٍ يُوَفَّ إِلَيْكُمْ وَأَنتُمْ لَا تُظْلَمُونَ(272)

 Imona won ko si lorun re, sugbon Allahu l’O n fi eni ti O ba fe mona. Ohunkohun ti e ba n na ni ohun rere, fun emi ara yin ni. E o si nii nawo afi lati fi wa oju rere Allahu. Ohunkohun ti e ba si na ni ohun rere, A o san yin ni esan (re) ni ekun-rere. Won ko si nii sabosi si yin

لِلْفُقَرَاءِ الَّذِينَ أُحْصِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ لَا يَسْتَطِيعُونَ ضَرْبًا فِي الْأَرْضِ يَحْسَبُهُمُ الْجَاهِلُ أَغْنِيَاءَ مِنَ التَّعَفُّفِ تَعْرِفُهُم بِسِيمَاهُمْ لَا يَسْأَلُونَ النَّاسَ إِلْحَافًا ۗ وَمَا تُنفِقُوا مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ اللَّهَ بِهِ عَلِيمٌ(273)

 (E tore) fun awon alaini ti won se (ara won monu mosalasi Anabi nitori ki won le maa jagun) fun aabo esin Allahu. Won ko si lagbara lilo-bibo lori ile (fun okowo sise). Eni ti ko mo won maa ka won kun oloro latara aisagbe. O maa mo won pelu ami won. Won ko nii toro nnkan lowo eniyan lemolemo. Ohunkohun ti e ba na ni ohun rere, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re

الَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمْوَالَهُم بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ سِرًّا وَعَلَانِيَةً فَلَهُمْ أَجْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(274)

 Awon t’o n na owo won ni oru ati ni osan, ni ikoko ati ni gbangba, esan won n be fun won ni odo Oluwa won. Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje

الَّذِينَ يَأْكُلُونَ الرِّبَا لَا يَقُومُونَ إِلَّا كَمَا يَقُومُ الَّذِي يَتَخَبَّطُهُ الشَّيْطَانُ مِنَ الْمَسِّ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا إِنَّمَا الْبَيْعُ مِثْلُ الرِّبَا ۗ وَأَحَلَّ اللَّهُ الْبَيْعَ وَحَرَّمَ الرِّبَا ۚ فَمَن جَاءَهُ مَوْعِظَةٌ مِّن رَّبِّهِ فَانتَهَىٰ فَلَهُ مَا سَلَفَ وَأَمْرُهُ إِلَى اللَّهِ ۖ وَمَنْ عَادَ فَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(275)

 Awon t’o n je ele ko nii dide (ninu saree) afi bi eni ti Esu fowo ba ti n ta geegee yo se dide. Iyen ri bee nitori pe won wi pe: “Owo sise da bi owo ele.” Allahu si se owo sise ni eto, O si se owo ele ni eewo. Enikeni ti waasi ba de ba lati odo Oluwa re, ti o si jawo, tire ni eyi t’o siwaju, oro re si di odo Allahu. Enikeni ti o ba si pada (sibi owo ele), awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re

يَمْحَقُ اللَّهُ الرِّبَا وَيُرْبِي الصَّدَقَاتِ ۗ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ كَفَّارٍ أَثِيمٍ(276)

 Allahu maa run owo ele. O si maa bu si awon ore. Allahu ko nifee gbogbo alaigbagbo, elese

إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ لَهُمْ أَجْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ(277)

 Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won kirun, ti won si yo Zakah, esan won n be fun won ni odo Oluwa won. Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَذَرُوا مَا بَقِيَ مِنَ الرِّبَا إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ(278)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si fi ohun t’o seku ninu ele sile, ti e ba je onigbagbo ododo

فَإِن لَّمْ تَفْعَلُوا فَأْذَنُوا بِحَرْبٍ مِّنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ ۖ وَإِن تُبْتُمْ فَلَكُمْ رُءُوسُ أَمْوَالِكُمْ لَا تَظْلِمُونَ وَلَا تُظْلَمُونَ(279)

 Ti e o ba se bee, e lo mo pe ogun kan lati odo Allahu ati Ojise Re (n bo wa ba yin). Ti e ba si ronu piwada, tiyin ni oju-owo yin. E o nii sabosi (si won). Won ko si nii sabosi si yin

وَإِن كَانَ ذُو عُسْرَةٍ فَنَظِرَةٌ إِلَىٰ مَيْسَرَةٍ ۚ وَأَن تَصَدَّقُوا خَيْرٌ لَّكُمْ ۖ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ(280)

 Ti (onigbese) ba je eni ti ara n ni, e wo o niran di asiko idera. Ati pe ki e fi se saraa (fun un) loore julo fun yin, ti e ba mo

وَاتَّقُوا يَوْمًا تُرْجَعُونَ فِيهِ إِلَى اللَّهِ ۖ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفْسٍ مَّا كَسَبَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ(281)

 E beru ojo kan ti won maa da yin pada si odo Allahu. Leyin naa, Won maa san emi kookan ni esan ni ekun rere (nipa) ohun ti o se nise. Won ko si nii sabosi si won

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا تَدَايَنتُم بِدَيْنٍ إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى فَاكْتُبُوهُ ۚ وَلْيَكْتُب بَّيْنَكُمْ كَاتِبٌ بِالْعَدْلِ ۚ وَلَا يَأْبَ كَاتِبٌ أَن يَكْتُبَ كَمَا عَلَّمَهُ اللَّهُ ۚ فَلْيَكْتُبْ وَلْيُمْلِلِ الَّذِي عَلَيْهِ الْحَقُّ وَلْيَتَّقِ اللَّهَ رَبَّهُ وَلَا يَبْخَسْ مِنْهُ شَيْئًا ۚ فَإِن كَانَ الَّذِي عَلَيْهِ الْحَقُّ سَفِيهًا أَوْ ضَعِيفًا أَوْ لَا يَسْتَطِيعُ أَن يُمِلَّ هُوَ فَلْيُمْلِلْ وَلِيُّهُ بِالْعَدْلِ ۚ وَاسْتَشْهِدُوا شَهِيدَيْنِ مِن رِّجَالِكُمْ ۖ فَإِن لَّمْ يَكُونَا رَجُلَيْنِ فَرَجُلٌ وَامْرَأَتَانِ مِمَّن تَرْضَوْنَ مِنَ الشُّهَدَاءِ أَن تَضِلَّ إِحْدَاهُمَا فَتُذَكِّرَ إِحْدَاهُمَا الْأُخْرَىٰ ۚ وَلَا يَأْبَ الشُّهَدَاءُ إِذَا مَا دُعُوا ۚ وَلَا تَسْأَمُوا أَن تَكْتُبُوهُ صَغِيرًا أَوْ كَبِيرًا إِلَىٰ أَجَلِهِ ۚ ذَٰلِكُمْ أَقْسَطُ عِندَ اللَّهِ وَأَقْوَمُ لِلشَّهَادَةِ وَأَدْنَىٰ أَلَّا تَرْتَابُوا ۖ إِلَّا أَن تَكُونَ تِجَارَةً حَاضِرَةً تُدِيرُونَهَا بَيْنَكُمْ فَلَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَلَّا تَكْتُبُوهَا ۗ وَأَشْهِدُوا إِذَا تَبَايَعْتُمْ ۚ وَلَا يُضَارَّ كَاتِبٌ وَلَا شَهِيدٌ ۚ وَإِن تَفْعَلُوا فَإِنَّهُ فُسُوقٌ بِكُمْ ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۖ وَيُعَلِّمُكُمُ اللَّهُ ۗ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ(282)

 Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n se kata-kara ni awin fun gbedeke akoko kan, e se akosile re. Ki akowe se akosile re laaarin yin ni ona eto. Ki akowe ma se ko lati se akosile gege bi Allahu se fi mo on. Nitori naa. ki o se akosile. Ki eni ti eto wa lorun re pe e fun un. Ki o beru Allahu, Oluwa re. Ko ma se din kini kan ku ninu re. Ti eni ti eto wa lorun re ba je alailoye tabi alaisan, tabi ko le pe e (funra re), ki alamojuuto re ba a pe e ni ona eto. Ki e pe elerii meji ninu awon okunrin yin lati jerii si i. Ti ko ba si okunrin meji, ki e wa okunrin kan ati obinrin meji ninu awon elerii ti e yonu si; nitori pe ti okan ninu awon obinrin mejeeji ba gbagbe, okan yo si ran ikeji leti. Ki awon elerii ma se ko ti won ba pe won (lati jerii). E ma se kaaare lati se akosile re, o kere ni tabi o tobi, titi di asiko isangbese re. Iyen ni deede julo lodo Allahu. O si gbe ijerii duro julo. O tun fi sunmo julo pe eyin ko fi nii seyemeji. Afi ti o ba je kata-kara oju ese ti e n se ni atowodowo laaarin ara yin, ko si ese fun yin ti e o ba se akosile re. E wa elerii se nigba ti e ba n se kata-kara (oja awin). Won ko si nii ko inira ba akowe ati elerii. Ti e ba si se bee, dajudaju ibaje l’e se. E beru Allahu. Allahu yo si maa fi imo mo yin. Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

۞ وَإِن كُنتُمْ عَلَىٰ سَفَرٍ وَلَمْ تَجِدُوا كَاتِبًا فَرِهَانٌ مَّقْبُوضَةٌ ۖ فَإِنْ أَمِنَ بَعْضُكُم بَعْضًا فَلْيُؤَدِّ الَّذِي اؤْتُمِنَ أَمَانَتَهُ وَلْيَتَّقِ اللَّهَ رَبَّهُ ۗ وَلَا تَكْتُمُوا الشَّهَادَةَ ۚ وَمَن يَكْتُمْهَا فَإِنَّهُ آثِمٌ قَلْبُهُ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ(283)

 Ati pe ti e ba wa lori irin-ajo, ti eyin ko si ri akowe, e gba ohun idogo. (Sugbon) ti apa kan yin ba fi okan tan apa kan, ki eni ti won fi okan tan da ohun ti won fi okan tan an le lori pada, ki o si beru Allahu, Oluwa re. E ma se fi eri pamo. Enikeni ti o ba fi pamo, dajudaju okan re ti dese. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti e n se

لِّلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَإِن تُبْدُوا مَا فِي أَنفُسِكُمْ أَوْ تُخْفُوهُ يُحَاسِبْكُم بِهِ اللَّهُ ۖ فَيَغْفِرُ لِمَن يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ(284)

 Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ti e ba safi han ohun t’o wa ninu emi yin, tabi e fi pamo, Allahu yo siro re fun yin (ti e ba se e nise). Leyin naa, O maa forijin eni ti O ba fe. O si maa je eni ti O ba fe niya. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

آمَنَ الرَّسُولُ بِمَا أُنزِلَ إِلَيْهِ مِن رَّبِّهِ وَالْمُؤْمِنُونَ ۚ كُلٌّ آمَنَ بِاللَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِّن رُّسُلِهِ ۚ وَقَالُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا ۖ غُفْرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ(285)

 Ojise naa (sollalahu alayhi wa sallam) gbagbo ninu ohun ti won sokale fun un lati odo Oluwa re. Awon onigbagbo ododo naa (gbagbo ninu re). Eni kookan (won) gbagbo ninu Allahu, awon molaika Re, awon Tira Re ati awon Ojise Re. A ko ya eni kan soto ninu awon Ojise Re. Won si so pe: “A gbo (ase), a si tele (ase). A n toro aforijin Re, Oluwa wa. Odo Re si ni abo eda.”

لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا ۚ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَعَلَيْهَا مَا اكْتَسَبَتْ ۗ رَبَّنَا لَا تُؤَاخِذْنَا إِن نَّسِينَا أَوْ أَخْطَأْنَا ۚ رَبَّنَا وَلَا تَحْمِلْ عَلَيْنَا إِصْرًا كَمَا حَمَلْتَهُ عَلَى الَّذِينَ مِن قَبْلِنَا ۚ رَبَّنَا وَلَا تُحَمِّلْنَا مَا لَا طَاقَةَ لَنَا بِهِ ۖ وَاعْفُ عَنَّا وَاغْفِرْ لَنَا وَارْحَمْنَا ۚ أَنتَ مَوْلَانَا فَانصُرْنَا عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ(286)

 Allahu ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. (Esan) ohun ti o se nise (rere) n be fun un. (Iya) ohun ti o se ni’se (ibi) n be fun un pelu. Oluwa wa, ma se mu wa ti a ba gbagbera tabi (ti) a ba sasise. Oluwa wa, ma se di eru t’o wuwo le wa lori, gege bi O se di i ru awon t’o siwaju wa. Oluwa wa, ma se diru wa ohun ti ko si agbara re fun wa. Samoju kuro fun wa, forijin wa, ki O si saanu wa. Iwo ni Alafeyinti wa. Nitori naa, ran wa lowo lori ijo alaigbagbo


Plus de sourates en Yoruba :


Al-Baqarah Al-'Imran An-Nisa'
Al-Ma'idah Yusuf Ibrahim
Al-Hijr Al-Kahf Maryam
Al-Hajj Al-Qasas Al-'Ankabut
As-Sajdah Ya Sin Ad-Dukhan
Al-Fath Al-Hujurat Qaf
An-Najm Ar-Rahman Al-Waqi'ah
Al-Hashr Al-Mulk Al-Haqqah
Al-Inshiqaq Al-A'la Al-Ghashiyah

Téléchargez la sourate avec la voix des récitants du Coran les plus célèbres :

Téléchargez le fichier mp3 de la sourate Al-Baqarah : choisissez le récitateur pour écouter et télécharger la sourate Al-Baqarah complète en haute qualité.


surah Al-Baqarah Ahmed El Agamy
Ahmed Al Ajmy
surah Al-Baqarah Bandar Balila
Bandar Balila
surah Al-Baqarah Khalid Al Jalil
Khalid Al Jalil
surah Al-Baqarah Saad Al Ghamdi
Saad Al Ghamdi
surah Al-Baqarah Saud Al Shuraim
Saud Al Shuraim
surah Al-Baqarah Abdul Basit Abdul Samad
Abdul Basit
surah Al-Baqarah Abdul Rashid Sufi
Abdul Rashid Sufi
surah Al-Baqarah Abdullah Basfar
Abdullah Basfar
surah Al-Baqarah Abdullah Awwad Al Juhani
Abdullah Al Juhani
surah Al-Baqarah Fares Abbad
Fares Abbad
surah Al-Baqarah Maher Al Muaiqly
Maher Al Muaiqly
surah Al-Baqarah Muhammad Siddiq Al Minshawi
Al Minshawi
surah Al-Baqarah Al Hosary
Al Hosary
surah Al-Baqarah Al-afasi
Mishari Al-afasi
surah Al-Baqarah Yasser Al Dosari
Yasser Al Dosari


Thursday, November 21, 2024

Donnez-nous une invitation valide