Surah Al-Qamar ni Arabic ati Yorùbá

Ka Surah Al-Qamar pẹlu itumọ pipe ni Yorùbá ati iṣẹ́-ohun. Itumọ ẹsẹ kọọkan. (55 Ẹsẹ — مكية). Al-Qamar Gbọ, Al-Qamar Itumọ, Al-Qamar mp3, Al-Qamar pdf.

Ka ati Gbọ Surah Al-Qamar

🎧 Ẹsẹ
M Mishary Rashid Alafasy
M Mahmoud Khalil Al-Husary
A Abdurrahman As-Sudais
M Mohamed Siddiq Al-Minshawi
A Abdul Basit Abdul Samad
A Ali Al-Hudhaify
A Ahmed ibn Ali al-Ajamy
A Abu Bakr Ash-Shaatree
M Muhammad Ayyoub
A Abdullah Basfar
A Abdullah Al-Juhani
M Maher Al Muaiqly
x1
اقْتَرَبَتِ السَّاعَةُ وَانشَقَّ الْقَمَرُ ۝١
📖 Itumọ Ẹsẹ 1
Akoko naa sunmo. Osupa si la peregede (si meji)
وَإِن يَرَوْا آيَةً يُعْرِضُوا وَيَقُولُوا سِحْرٌ مُّسْتَمِرٌّ ۝٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 2
Ti won ba ri ami kan, won maa gbunri. Won yo si wi pe: "Idan kan (t’o lagbara) t’o maa lo ni
وَكَذَّبُوا وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ ۚ وَكُلُّ أَمْرٍ مُّسْتَقِرٌّ ۝٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 3
Won pe e niro. Won si tele ife-inu won. Gbogbo ise eda si maa jokoo ti i lorun
وَلَقَدْ جَاءَهُم مِّنَ الْأَنبَاءِ مَا فِيهِ مُزْدَجَرٌ ۝٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 4
Dajudaju eyi ti won fi ohun lile ko wa ninu awon iro t’o de ba won
حِكْمَةٌ بَالِغَةٌ ۖ فَمَا تُغْنِ النُّذُرُ ۝٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 5
Ijinle oye t’o peye ni; sugbon awon ikilo naa ko ro won loro
فَتَوَلَّ عَنْهُمْ ۘ يَوْمَ يَدْعُ الدَّاعِ إِلَىٰ شَيْءٍ نُّكُرٍ ۝٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 6
Seri kuro ni odo won. Ni ojo ti olupepe yoo pepe fun kini kan ti emi korira (iyen, Ajinde)
خُشَّعًا أَبْصَارُهُمْ يَخْرُجُونَ مِنَ الْأَجْدَاثِ كَأَنَّهُمْ جَرَادٌ مُّنتَشِرٌ ۝٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 7
Oju won maa wale ni ti abuku. Won yo si maa jade lati inu saree bi eni pe esu ti won fonka sita ni won
مُّهْطِعِينَ إِلَى الدَّاعِ ۖ يَقُولُ الْكَافِرُونَ هَٰذَا يَوْمٌ عَسِرٌ ۝٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 8
Won yo si maa yara lo si odo olupepe naa. Awon alaigbagbo yo si wi pe: "Eyi ni ojo isoro
۞ كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ فَكَذَّبُوا عَبْدَنَا وَقَالُوا مَجْنُونٌ وَازْدُجِرَ ۝٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 9
Ijo (Anabi) Nuh pe ododo niro siwaju won. Nigba naa, won pe erusin Wa ni opuro. Won si wi pe: "Were ni." Won si ko fun un pelu ohun lile. won fi ohun lile ko ododo sile fun Anabi Nuh (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni kiko alesa-seyin fun won nipase siso oro buruku si i hihale mo on
فَدَعَا رَبَّهُ أَنِّي مَغْلُوبٌ فَانتَصِرْ ۝١٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 10
Nitori naa, o pe Oluwa re pe: "Dajudaju won ti bori mi. Ran mi lowo
فَفَتَحْنَا أَبْوَابَ السَّمَاءِ بِمَاءٍ مُّنْهَمِرٍ ۝١١
📖 Itumọ Ẹsẹ 11
Nitori naa, A si awon ilekun sanmo sile pelu omi t’o lagbara
وَفَجَّرْنَا الْأَرْضَ عُيُونًا فَالْتَقَى الْمَاءُ عَلَىٰ أَمْرٍ قَدْ قُدِرَ ۝١٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 12
A tun mu awon odo seyo lori ile. Omi (sanmo) pade (omi ile) pelu ase ti A ti ko (le won lori)
وَحَمَلْنَاهُ عَلَىٰ ذَاتِ أَلْوَاحٍ وَدُسُرٍ ۝١٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 13
A si gbe (Anabi) Nuh gun oko onipako, oko elesoo
تَجْرِي بِأَعْيُنِنَا جَزَاءً لِّمَن كَانَ كُفِرَ ۝١٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 14
t’o n rin (lori omi) loju Wa. (O je) esan fun eni ti won tako
وَلَقَد تَّرَكْنَاهَا آيَةً فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ ۝١٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 15
Dajudaju A fi sile ni ami. Nje oluranti wa bayii bi
فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ ۝١٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 16
Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ ۝١٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 17
Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi
كَذَّبَتْ عَادٌ فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ ۝١٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 18
Iran ‘Ad pe ododo niro. Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)
إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِيحًا صَرْصَرًا فِي يَوْمِ نَحْسٍ مُّسْتَمِرٍّ ۝١٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 19
Dajudaju Awa ran ategun lile si won ni ojo buruku kan t’o n te siwaju
تَنزِعُ النَّاسَ كَأَنَّهُمْ أَعْجَازُ نَخْلٍ مُّنقَعِرٍ ۝٢٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 20
O n fa awon eniyan jade bi eni pe kukute igi ope ti won fa tu tegbotegbo ni won
فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ ۝٢١
📖 Itumọ Ẹsẹ 21
Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ ۝٢٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 22
Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi
كَذَّبَتْ ثَمُودُ بِالنُّذُرِ ۝٢٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 23
Ijo Thamud pe awon ikilo niro
فَقَالُوا أَبَشَرًا مِّنَّا وَاحِدًا نَّتَّبِعُهُ إِنَّا إِذًا لَّفِي ضَلَالٍ وَسُعُرٍ ۝٢٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 24
Won wi pe: "Se abara kan, eni kan soso ninu wa ni a oo maa tele. (Bi o ba ri bee) nigba naa dajudaju awa ti wa ninu isina ati iya
أَأُلْقِيَ الذِّكْرُ عَلَيْهِ مِن بَيْنِنَا بَلْ هُوَ كَذَّابٌ أَشِرٌ ۝٢٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 25
Se oun ni won so iranti kale fun laaarin wa? Rara o, opuro onigbeeraga ni
سَيَعْلَمُونَ غَدًا مَّنِ الْكَذَّابُ الْأَشِرُ ۝٢٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 26
Ni ola ni won yoo mo ta ni opuro onigbeeraga
إِنَّا مُرْسِلُو النَّاقَةِ فِتْنَةً لَّهُمْ فَارْتَقِبْهُمْ وَاصْطَبِرْ ۝٢٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 27
Dajudaju Awa maa ran abo rakunmi si won; (o maa je) adanwo fun won. Nitori naa, maa wo won niran na, ki o si se suuru
وَنَبِّئْهُمْ أَنَّ الْمَاءَ قِسْمَةٌ بَيْنَهُمْ ۖ كُلُّ شِرْبٍ مُّحْتَضَرٌ ۝٢٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 28
Ki o si fun won ni iro pe dajudaju pipin ni omi laaarin won. Gbogbo ipin omi si wa fun eni ti o ba kan lati wa si odo
فَنَادَوْا صَاحِبَهُمْ فَتَعَاطَىٰ فَعَقَرَ ۝٢٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 29
Nigba naa ni won pe eni won. O wa ona lati mu (rakunmi naa mole). O si pa a
فَكَيْفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ ۝٣٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 30
Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)
إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ صَيْحَةً وَاحِدَةً فَكَانُوا كَهَشِيمِ الْمُحْتَظِرِ ۝٣١
📖 Itumọ Ẹsẹ 31
Dajudaju Awa ran igbe kan soso si won. Won si da bi igi koriko gbigbe
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ ۝٣٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 32
Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi
كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ بِالنُّذُرِ ۝٣٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 33
Ijo Lut pe awon ikilo niro
إِنَّا أَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ حَاصِبًا إِلَّا آلَ لُوطٍ ۖ نَّجَّيْنَاهُم بِسَحَرٍ ۝٣٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 34
Dajudaju Awa fi okuta ina ranse si won afi ara ile Lut, ti A gbala ni asiko saari
نِّعْمَةً مِّنْ عِندِنَا ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي مَن شَكَرَ ۝٣٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 35
(O je) ike kan lati odo Wa. Bayen ni A se n san esan fun eni t’o ba dupe (fun Wa)
وَلَقَدْ أَنذَرَهُم بَطْشَتَنَا فَتَمَارَوْا بِالنُّذُرِ ۝٣٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 36
O kuku fi igbamu Wa se ikilo fun won, sugbon won ja awon ikilo niyan
وَلَقَدْ رَاوَدُوهُ عَن ضَيْفِهِ فَطَمَسْنَا أَعْيُنَهُمْ فَذُوقُوا عَذَابِي وَنُذُرِ ۝٣٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 37
Won kuku lakaka lodo re lati ba awon alejo re sebaje. Nitori naa, A fo oju won. E to iya Mi ati ikilo Mi wo
وَلَقَدْ صَبَّحَهُم بُكْرَةً عَذَابٌ مُّسْتَقِرٌّ ۝٣٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 38
Ati pe dajudaju iya gbere ni won mojumo sinu re ni owuro kutukutu
فَذُوقُوا عَذَابِي وَنُذُرِ ۝٣٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 39
Nitori naa, e to iya Mi ati ikilo Mi wo
وَلَقَدْ يَسَّرْنَا الْقُرْآنَ لِلذِّكْرِ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ ۝٤٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 40
Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi
وَلَقَدْ جَاءَ آلَ فِرْعَوْنَ النُّذُرُ ۝٤١
📖 Itumọ Ẹsẹ 41
Dajudaju awon ikilo de ba awon eniyan Fir‘aon
كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا كُلِّهَا فَأَخَذْنَاهُمْ أَخْذَ عَزِيزٍ مُّقْتَدِرٍ ۝٤٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 42
Won pe awon ayah Wa niro, gbogbo re patapata. A si gba won mu ni igbamu (ti) Alagbara, Olukapa (n gba eda mu)
أَكُفَّارُكُمْ خَيْرٌ مِّنْ أُولَٰئِكُمْ أَمْ لَكُم بَرَاءَةٌ فِي الزُّبُرِ ۝٤٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 43
Se awon alaigbagbo (ninu) yin l’o loore julo si awon wonyen (ti won ti pare bo seyin) ni tabi eyin ni imoribo kan ninu ipin-ipin Tira (pe eyin ko nii jiya)
أَمْ يَقُولُونَ نَحْنُ جَمِيعٌ مُّنتَصِرٌ ۝٤٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 44
Tabi won n wi pe: "Gbogbo wa ni a oo ranra wa lowo lati bori (Ojise)
سَيُهْزَمُ الْجَمْعُ وَيُوَلُّونَ الدُّبُرَ ۝٤٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 45
A maa fo akojo naa logun. Won si maa fese fee loju ogun
بَلِ السَّاعَةُ مَوْعِدُهُمْ وَالسَّاعَةُ أَدْهَىٰ وَأَمَرُّ ۝٤٦
📖 Itumọ Ẹsẹ 46
Amo sa, Akoko naa ni ojo adehun won. Akoko naa buru julo. O si koro julo
إِنَّ الْمُجْرِمِينَ فِي ضَلَالٍ وَسُعُرٍ ۝٤٧
📖 Itumọ Ẹsẹ 47
Dajudaju awon elese wa ninu isina (nile aye, won yo si wa ninu) Ina jijo (ni orun)
يَوْمَ يُسْحَبُونَ فِي النَّارِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمْ ذُوقُوا مَسَّ سَقَرَ ۝٤٨
📖 Itumọ Ẹsẹ 48
Ni ojo ti A oo doju won dele wo inu Ina, (A o si so pe): E to ifowoba Ina wo
إِنَّا كُلَّ شَيْءٍ خَلَقْنَاهُ بِقَدَرٍ ۝٤٩
📖 Itumọ Ẹsẹ 49
Dajudaju A seda gbogbo nnkan pelu kadara
وَمَا أَمْرُنَا إِلَّا وَاحِدَةٌ كَلَمْحٍ بِالْبَصَرِ ۝٥٠
📖 Itumọ Ẹsẹ 50
Ase Wa (fun mimu nnkan be) ko tayo (ase) eyo kan soso gege bi iseju
وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا أَشْيَاعَكُمْ فَهَلْ مِن مُّدَّكِرٍ ۝٥١
📖 Itumọ Ẹsẹ 51
Ati pe dajudaju A ti pa awon iru yin re. Nje oluranti wa bayii bi
وَكُلُّ شَيْءٍ فَعَلُوهُ فِي الزُّبُرِ ۝٥٢
📖 Itumọ Ẹsẹ 52
Gbogbo nnkan ti won se nise si wa ninu ipin-ipin tira
وَكُلُّ صَغِيرٍ وَكَبِيرٍ مُّسْتَطَرٌ ۝٥٣
📖 Itumọ Ẹsẹ 53
Ati pe gbogbo nnkan kekere ati nnkan nla (ti won se) wa ni akosile
إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَنَهَرٍ ۝٥٤
📖 Itumọ Ẹsẹ 54
Dajudaju awon oluberu (Allahu) yoo wa ninu awon Ogba (Idera) pelu awon odo (t’o n san ni isale re)
فِي مَقْعَدِ صِدْقٍ عِندَ مَلِيكٍ مُّقْتَدِرٍ ۝٥٥
📖 Itumọ Ẹsẹ 55
Ni ibujokoo ododo nitosi Oba Alagbara Olukapa
← 53 Al-Qamar (54/114) 55 →
Kika Surah Al-Qamar ni Yorùbá – Itumọ ati Ohun

54القمر Al-Qamar 📚 55 Ẹsẹ مكية

Ẹsẹ kọọkan – Surah Al-Qamar — 55 Ẹsẹ




Al-Kur'an


Tuesday, August 18, 2026

Don't forget us in your sincere prayers