Müminun suresi çevirisi Yoruba
Dajudaju awon onigbagbo ododo ti jere |
Awon t’o n paya (Allahu) ninu irun won |
ati awon t’o n seri kuro nibi isokuso |
ati awon t’o n yo Zakah |
ati awon t’o n so abe won |
إِلَّا عَلَىٰ أَزْوَاجِهِمْ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَإِنَّهُمْ غَيْرُ مَلُومِينَ(6) afi ni odo awon iyawo won ati erubinrin won. Dajudaju won ki i se eni eebu (ti won ba sunmo won) |
فَمَنِ ابْتَغَىٰ وَرَاءَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْعَادُونَ(7) nitori naa, enikeni ti o ba wa omiran (sunmo) leyin iyen, awon wonyen ni awon olutayo enu-ala |
ati awon t’o n so agbafipamo won ati adehun won |
ati awon t’o n so irun won |
awon wonyen ni awon olujogun |
الَّذِينَ يَرِثُونَ الْفِرْدَوْسَ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ(11) awon t’o maa jogun ogba idera Firdaos. Olusegbere ni won ninu re |
Dajudaju A ti se eda eniyan lati inu ohun ti A mo jade lati inu erupe amo |
Leyin naa, A se e ni ato sinu aye aabo (iyen, ile-omo) |
Leyin naa, A so ato di eje didi. Leyin naa, A so eje didi di baasi eran. Leyin naa, A so baasi eran di eegun. Leyin naa, A fi eran bo eegun. Leyin naa, A so o di eda miiran.1 Nitori naa, ibukun ni fun Allahu, Eni t’O dara julo ninu awon eledaa (onise-ona) |
Leyin naa, leyin iyen, dajudaju eyin yo si di oku |
Leyin naa, dajudaju ni Ojo Ajinde Won maa gbe yin dide |
وَلَقَدْ خَلَقْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعَ طَرَائِقَ وَمَا كُنَّا عَنِ الْخَلْقِ غَافِلِينَ(17) Dajudaju A da awon sanmo meje si oke yin. Awa ko si nii dagunla si awon eda |
A n so omi kale lati sanmo niwon niwon. Leyin naa, A n mu un duro sinu ile. Dajudaju Awa kuku lagbara lati mu un lo |
Leyin naa, A da awon ogba oko dabinu ati ajara fun yin; opolopo eso wa ninu re fun yin, e si n je ninu re |
وَشَجَرَةً تَخْرُجُ مِن طُورِ سَيْنَاءَ تَنبُتُ بِالدُّهْنِ وَصِبْغٍ لِّلْآكِلِينَ(20) Ati igi kan t’o n hu jade nibi apata Sina’; o n mu epo ati nnkan isebe jade fun awon t’o n je e |
Ati pe dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin; A n fun yin mu ninu ohun ti o wa ninu ikun won. Awon anfaani opolopo (miiran) tun wa fun yin lara won, e si n je ninu re |
E si n ko eru si ori awon eran osin ati oko oju-omi |
Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Se e o nii beru (Re) ni?” |
Awon olori ti won sai gbagbo ninu awon eniyan re so pe: “Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin, ti o fe gbe ajulo fun ara re lori yin. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe (ranse si wa ni), iba so molaika kan kale ni. A ko si gbo eyi ri lodo awon baba wa, awon eni akoko |
إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ بِهِ جِنَّةٌ فَتَرَبَّصُوا بِهِ حَتَّىٰ حِينٍ(25) Ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti alujannu n be lara re. Nitori naa, e maa reti (ikangun) re titi di igba kan na.” |
(Anabi) Nuh so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro |
Nitori naa, A fi imisi ranse si i pe: "Se oko oju-omi ni oju Wa (bayii) pelu imisi Wa. Nigba ti ase Wa ba de, ti omi ba se yo ni oju aro, nigba naa ni ki o ko sinu oko oju-omi gbogbo nnkan ni orisi meji tako-tabo ati ara ile re, ayafi eni ti oro naa ko le lori ninu won (fun iparun). Ma se ba Mi soro nipa awon t’o sabosi; dajudaju A oo te won ri sinu omi ni |
Nigba ti o ba jokoo sinu oko oju-omi naa, iwo ati awon t’o wa pelu re, so pe: Ope ni fun Allahu, Eni ti O gba wa la lowo ijo alabosi |
وَقُل رَّبِّ أَنزِلْنِي مُنزَلًا مُّبَارَكًا وَأَنتَ خَيْرُ الْمُنزِلِينَ(29) So pe: “Oluwa mi, so mi kale si ibuso ibukun. Iwo si loore julo ninu awon amunigunle.” |
Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Awa si ni A n dan eda wo |
Leyin naa, A mu awon iran miiran wa leyin won |
A tun ran Ojise kan si won laaarin ara won (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Nitori naa, se e o nii beru (Re) ni?” |
Awon olori t’o sai gbagbo ninu ijo re, awon t’o pe ipade Ojo Ikeyin niro, awon ti A se gbedemuke fun ninu isemi aye yii, won wi pe: "Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin; o n je ninu ohun ti e n je, o si n mu ninu ohun ti e n mu |
وَلَئِنْ أَطَعْتُم بَشَرًا مِّثْلَكُمْ إِنَّكُمْ إِذًا لَّخَاسِرُونَ(34) Ti e ba fi le tele abara kan bi iru yin, dajudaju e ma ti di eni ofo niyen |
أَيَعِدُكُمْ أَنَّكُمْ إِذَا مِتُّمْ وَكُنتُمْ تُرَابًا وَعِظَامًا أَنَّكُم مُّخْرَجُونَ(35) Se o n se adehun fun yin pe nigba ti e ba ku, ti e si di erupe ati egungun tan, dajudaju Won yoo mu yin jade (ni alaaye) |
Ohun ti Won n se ni adehun fun yin (yii) jinna tefetefe (si ododo) |
إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا نَمُوتُ وَنَحْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ(37) Ko si isemi aye kan mo ayafi eyi ti a n lo yii; awa kan n ku, awa kan n waye. Ko si si pe Won yoo gbe wa dide mo |
إِنْ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا وَمَا نَحْنُ لَهُ بِمُؤْمِنِينَ(38) (Ojise naa) ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti o da adapa iro mo Allahu. Awa ko si nii gba a gbo |
(Ojise naa) so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro |
(Allahu) so pe: “Laipe nse ni won yoo di alabaamo.” |
فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ بِالْحَقِّ فَجَعَلْنَاهُمْ غُثَاءً ۚ فَبُعْدًا لِّلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ(41) Nitori naa, ohun igbe mu won lona eto. A si so won di panti. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo alabosi |
Leyin naa, A tun mu awon iran miiran wa leyin won |
مَا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ(43) Ijo kan ko nii lo siwaju akoko (iparun) re, won ko si nii sun (iparun won) siwaju |
Leyin naa, A ran awon Ojise Wa nise ni telentele. Igbakigba ti Ojise ijo kan ba de, won n pe e ni opuro. A si mu apa kan won tele apa kan ninu iparun. A tun so won di itan. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo ti ko gbagbo lododo |
ثُمَّ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ وَأَخَاهُ هَارُونَ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ(45) Leyin naa, A ran (Anabi) Musa ati omo-iya re (Anabi) Harun nise pelu awon ami Wa ati eri ponnbele |
إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَاسْتَكْبَرُوا وَكَانُوا قَوْمًا عَالِينَ(46) (A ran won nise) si Fir‘aon ati awon ijoye re. Sugbon won segberaga, won si je ijo olujegaba |
فَقَالُوا أَنُؤْمِنُ لِبَشَرَيْنِ مِثْلِنَا وَقَوْمُهُمَا لَنَا عَابِدُونَ(47) Won wi pe: “Se ki a gba abara meji bi iru wa gbo, nigba ti o je pe eru wa ni awon eniyan won?” |
Nitori naa, won pe awon mejeeji ni opuro. Won si wa ninu awon eni- iparun |
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ لَعَلَّهُمْ يَهْتَدُونَ(49) Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira nitori ki won le mona |
وَجَعَلْنَا ابْنَ مَرْيَمَ وَأُمَّهُ آيَةً وَآوَيْنَاهُمَا إِلَىٰ رَبْوَةٍ ذَاتِ قَرَارٍ وَمَعِينٍ(50) A se omo Moryam ati iya re ni ami kan. A si se ibugbe fun awon mejeeji si ibi giga kan, t’o ni ibugbe, t’o si ni omi iseleru |
Eyin Ojise, e je ninu awon nnkan daadaa, ki e si se ise rere. Dajudaju Emi ni Onimo nipa ohun ti e n se nise |
وَإِنَّ هَٰذِهِ أُمَّتُكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَأَنَا رَبُّكُمْ فَاتَّقُونِ(52) Ati pe dajudaju (’Islam) yii ni esin yin. (O je) esin kan soso. Emi si ni Oluwa yin. Nitori naa, e beru Mi |
فَتَقَطَّعُوا أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ زُبُرًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ(53) Sugbon won ge oro esin won laaarin ara won si kelekele. Ijo kookan si n yo si ohun t’o n be ni odo won |
Nitori naa, fi won sile sinu isina won titi di igba kan na |
أَيَحْسَبُونَ أَنَّمَا نُمِدُّهُم بِهِ مِن مَّالٍ وَبَنِينَ(55) Se won n lero pe (bi) A se n fi dukia ati omo nikan se iranlowo fun won |
نُسَارِعُ لَهُمْ فِي الْخَيْرَاتِ ۚ بَل لَّا يَشْعُرُونَ(56) ni A oo se maa yara ti awon oore si odo won lo (titi laelae). Rara, won ko fura ni |
إِنَّ الَّذِينَ هُم مِّنْ خَشْيَةِ رَبِّهِم مُّشْفِقُونَ(57) Dajudaju awon t’o n paya (isiro-ise) fun ipaya won ninu Oluwa won |
ati awon t’o n gba awon ayah Oluwa won gbo |
ati awon ti ki i sebo si Oluwa won |
وَالَّذِينَ يُؤْتُونَ مَا آتَوا وَّقُلُوبُهُمْ وَجِلَةٌ أَنَّهُمْ إِلَىٰ رَبِّهِمْ رَاجِعُونَ(60) ati awon t’o n se ohun rere (ninu ise) ti won se, pelu iberu ninu okan won pe dajudaju awon yoo pada si odo Oluwa won |
أُولَٰئِكَ يُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَهُمْ لَهَا سَابِقُونَ(61) awon wonyen ni won n yara se awon ise rere. Awon si ni asiwaju ninu (awon esan) ise naa |
Ati pe A ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Tira kan t’o n so ododo (nipa ise eda) n be lodo Wa. A o si nii sabosi si won |
Amo okan awon alaigbagbo wa ninu ifonufora nipa (al-Ƙur’an) yii. Ati pe won ni awon ise kan lowo, ti o yato si ise rere yen. Won si n se ise naa |
حَتَّىٰ إِذَا أَخَذْنَا مُتْرَفِيهِم بِالْعَذَابِ إِذَا هُمْ يَجْأَرُونَ(64) titi di igba ti A maa gba awon onigbedemuke ninu won mu pelu iya. Nigba naa ni won maa ke gbajari |
لَا تَجْأَرُوا الْيَوْمَ ۖ إِنَّكُم مِّنَّا لَا تُنصَرُونَ(65) E ma kee gbajari lonii. Dajudaju ko si eni ti o maa ran yin lowo lodo Wa |
قَدْ كَانَتْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنتُمْ عَلَىٰ أَعْقَابِكُمْ تَنكِصُونَ(66) Won kuku n ka awon ayah Mi fun yin. Amo nse ni e n fa seyin (nibi ododo) |
E si n fi Kaaba segberaga, e tun n fi oru yin so isokuso (nipa al-Ƙur’an) |
أَفَلَمْ يَدَّبَّرُوا الْقَوْلَ أَمْ جَاءَهُم مَّا لَمْ يَأْتِ آبَاءَهُمُ الْأَوَّلِينَ(68) Se won ko ronu si oro naa ni? Tabi ohun t’o de ba won je ohun ti ko de ba awon baba won akoko ri ni |
Tabi won ko mo Ojise won mo ni won fi di alatako re |
أَمْ يَقُولُونَ بِهِ جِنَّةٌ ۚ بَلْ جَاءَهُم بِالْحَقِّ وَأَكْثَرُهُمْ لِلْحَقِّ كَارِهُونَ(70) Tabi won n wi pe alujannu kan n be lara re ni? Rara o. O mu ododo wa ba won ni. Amo opolopo won si je olukorira ododo |
Ti o ba je pe (Allahu), Oba Ododo tele ife-inu won ni, awon sanmo ati ile ati awon t’o wa ninu won iba kuku ti baje. Sugbon A mu isiti nipa oro ara won wa fun won ni, won si n gbunri kuro nibi isiti (ti A mu wa fun) won |
أَمْ تَسْأَلُهُمْ خَرْجًا فَخَرَاجُ رَبِّكَ خَيْرٌ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ(72) Tabi o n beere owo-oya kan lowo won ni? Owo-oya Oluwa re loore julo. Ati pe Oun l’oore julo ninu awon olupese |
Ati pe dajudaju o n pe won soju ona taara ni |
وَإِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ عَنِ الصِّرَاطِ لَنَاكِبُونَ(74) Awon ti ko si gba Ojo Ikeyin gbo ni won n seri kuro loju ona naa |
۞ وَلَوْ رَحِمْنَاهُمْ وَكَشَفْنَا مَا بِهِم مِّن ضُرٍّ لَّلَجُّوا فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ(75) Ti o ba je pe A ke won (nile aye), ti A si gbe gbogbo isoro ara won kuro fun won, won iba tun wonkoko mo itayo enu-ala won, ti won yoo maa pa ridarida (ninu isina) |
وَلَقَدْ أَخَذْنَاهُم بِالْعَذَابِ فَمَا اسْتَكَانُوا لِرَبِّهِمْ وَمَا يَتَضَرَّعُونَ(76) Dajudaju A fi iya je won. Amo won ko teriba fun Oluwa won, won ko si rawo rase si I |
حَتَّىٰ إِذَا فَتَحْنَا عَلَيْهِم بَابًا ذَا عَذَابٍ شَدِيدٍ إِذَا هُمْ فِيهِ مُبْلِسُونَ(77) titi di igba ti A fi silekun iya lile fun won; nigba naa ni won soreti nu |
وَهُوَ الَّذِي أَنشَأَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۚ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ(78) (Allahu), Oun ni Eni ti O se igboro, iriran ati okan fun yin, idupe yin si kere |
وَهُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ(79) Oun ni Eni ti O da yin sori ile, odo Re si ni won yoo ko yin jo si |
وَهُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ وَلَهُ اخْتِلَافُ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ(80) Oun ni Eni t’O n so eda di alaaye, O n so eda di oku, tiRe si ni itelentele ati iyato oru ati osan, se e o nii se laakaye ni |
Rara (won ko nii se laakaye, sebi) iru ohun ti awon eni akoko wi ni awon naa wi |
قَالُوا أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ(82) Won wi pe: “Se nigba ti a ba ti ku, ti a ti di erupe ati egungun, se won yoo gbe wa dide ni |
لَقَدْ وُعِدْنَا نَحْنُ وَآبَاؤُنَا هَٰذَا مِن قَبْلُ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ(83) Won kuku ti se adehun yii fun awa ati awon baba wa teletele. Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko.” |
قُل لِّمَنِ الْأَرْضُ وَمَن فِيهَا إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ(84) So pe: “Ta ni Eni ti O ni ile ati eni ti o wa ni ori re ti e ba mo?” |
Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii lo iranti ni?” |
قُلْ مَن رَّبُّ السَّمَاوَاتِ السَّبْعِ وَرَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ(86) So pe: “Ta ni Oluwa awon sanmo mejeeje ati Oluwa Ite nla?” |
Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii beru (Re) ni?” |
So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?” So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?” |
Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Nitori naa, bawo ni won se n dan yin?” |
Amo sa, ododo ni A mu wa ba won. Dajudaju awon si ni opuro |
Allahu ko fi eni kan kan se omo, ko si si olohun kan pelu Re. (Ti ko ba ri bee) nigba naa, olohun kookan iba ti ko eda t’o da lo, apa kan won iba si bori apa kan. Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re nipa omo bibi) |
عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ(92) (Allahu) Onimo-ikoko ati gbangba. Nitori naa, O ga tayo nnkan ti won fi n sebo si I |
So pe: “Oluwa mi, O see se ki O fi ohun ti won n se ni adehun fun won han mi |
Oluwa mi, ma se fi mi sinu ijo alabosi.” |
وَإِنَّا عَلَىٰ أَن نُّرِيَكَ مَا نَعِدُهُمْ لَقَادِرُونَ(95) Dajudaju Awa lagbara lati fi ohun ti A se ni ileri fun won han o |
ادْفَعْ بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ السَّيِّئَةَ ۚ نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَصِفُونَ(96) Fi eyi t’o dara ti aidara danu. Awa nimo julo nipa ohun ti won fi n royin (Wa) |
So pe: "Oluwa mi, mo n sadi O nibi royiroyi t’awon esu |
Mo n sadi O, Oluwa mi, nibi ki won wa ba mi |
حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ رَبِّ ارْجِعُونِ(99) (Won n semi lo) titi di igba ti iku fi maa de ba okan ninu won. O si maa wi pe: “Oluwa mi, E da mi pada (sile aye) |
nitori ki ng le se ise rere ninu eyi ti mo gbe ju sile. Ko ri bee rara, dajudaju o je oro kan ti o kan n wi ni, (amo) gaga ti wa ni eyin won titi di ojo ti A oo gbe won dide. ayeta okigbe |
فَإِذَا نُفِخَ فِي الصُّورِ فَلَا أَنسَابَ بَيْنَهُمْ يَوْمَئِذٍ وَلَا يَتَسَاءَلُونَ(101) Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde, ko nii si ibatan laaarin won ni ojo yen, won ko si nii bira won leere ibeere |
فَمَن ثَقُلَتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ(102) Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba tewon, awon wonyen ni olujere |
وَمَنْ خَفَّتْ مَوَازِينُهُ فَأُولَٰئِكَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ فِي جَهَنَّمَ خَالِدُونَ(103) Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba fuye, awon wonyen ni awon t’o se emi ara won lofo. Olusegbere si ni won ninu ina Jahanamo |
Ina yoo maa jo won loju. Won yo si wa ninu re, ti Ina yoo ti ba won loju je |
أَلَمْ تَكُنْ آيَاتِي تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فَكُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ(105) Se won ki i ka awon ayah Mi fun yin ni, amo ti e n pe e niro |
قَالُوا رَبَّنَا غَلَبَتْ عَلَيْنَا شِقْوَتُنَا وَكُنَّا قَوْمًا ضَالِّينَ(106) Won wi pe: "Oluwa wa, ori buruku l’o kolu wa; awa si je ijo olusina |
رَبَّنَا أَخْرِجْنَا مِنْهَا فَإِنْ عُدْنَا فَإِنَّا ظَالِمُونَ(107) Oluwa wa, mu wa jade kuro ninu Ina. Ti a ba fi le pada (sibi ise ibi nile aye), dajudaju nigba naa alabosi ni awa |
(Allahu) so pe: “E teri sinu re. E ma se ba Mi soro.” |
Dajudaju igun kan wa ninu awon erusin Mi, ti won n so pe: “Oluwa wa, a gbagbo ni ododo. Nitori naa, forijin wa, ki O si ke wa. Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.” |
فَاتَّخَذْتُمُوهُمْ سِخْرِيًّا حَتَّىٰ أَنسَوْكُمْ ذِكْرِي وَكُنتُم مِّنْهُمْ تَضْحَكُونَ(110) Sugbon e so won di oniyeye to bee ge ti awon yeye (yin) fi mu yin gbagbe iranti Mi. Eyin si n fi won rerin-in |
إِنِّي جَزَيْتُهُمُ الْيَوْمَ بِمَا صَبَرُوا أَنَّهُمْ هُمُ الْفَائِزُونَ(111) Dajudaju Mo san won ni esan ni oni nitori suuru won; dajudaju awon, awon ni olujere |
(Allahu) so pe: "Odun meloo ni eyin (alaigbagbo) lo lori ile aye |
قَالُوا لَبِثْنَا يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ فَاسْأَلِ الْعَادِّينَ(113) Won wi pe: “A lo ojo kan tabi abala ojo kan, bi awon olusiro-ojo leere wo.” |
قَالَ إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا قَلِيلًا ۖ لَّوْ أَنَّكُمْ كُنتُمْ تَعْلَمُونَ(114) (Allahu) so pe: “E ko gbe ile aye bi ko se fun igba die, ti o ba je pe e mo.” |
أَفَحَسِبْتُمْ أَنَّمَا خَلَقْنَاكُمْ عَبَثًا وَأَنَّكُمْ إِلَيْنَا لَا تُرْجَعُونَ(115) Se e lero pe A kan seda yin fun iranu ni, ati pe dajudaju won o nii da yin pada sodo Wa?” |
فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْكَرِيمِ(116) Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun, Oluwa Ite alapon-onle |
Eni ti o ba pe olohun miiran pelu Allahu, ko ni eri lowo lori re. Dajudaju isiro-ise re si wa lodo Oluwa re. Dajudaju awon alaigbagbo ko nii jere |
وَقُل رَّبِّ اغْفِرْ وَارْحَمْ وَأَنتَ خَيْرُ الرَّاحِمِينَ(118) So pe: “Oluwa mi, saforijin, ki O si ke (mi). Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.” |
Yoruba diğer sureler:
En ünlü okuyucuların sesiyle Müminun Suresi indirin:
Surah Al-Muminun mp3: yüksek kalitede dinlemek ve indirmek için okuyucuyu seçerek
Ahmed El Agamy
Saad Al Ghamdi
Saud Al Shuraim
Abdul Basit
Abdullah Basfar
Abdullah Al Juhani
Ali Al Hudhaifi
Fares Abbad
Maher Al Muaiqly
Muhammad Jibril
Al Minshawi
Al Hosary
Mishari Al-afasi
Nasser Al Qatami
Yasser Al Dosari
Bizim için dua et, teşekkürler